ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 46
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jékọ́bù àti agbo ilé rẹ̀ kó lọ sí Íjíbítì (1-7)

      • Orúkọ àwọn tó ń kó lọ sí Íjíbítì (8-27)

      • Jósẹ́fù lọ pàdé Jékọ́bù ní Góṣénì (28-34)

Jẹ́nẹ́sísì 46:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:31
  • +Jẹ 31:42; Ẹk 3:6

Jẹ́nẹ́sísì 46:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:13
  • +Jẹ 12:1, 2; Ẹk 1:7; Di 26:5

Jẹ́nẹ́sísì 46:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn ni pé yóò fi ọwọ́ rẹ̀ pa ojú Jékọ́bù dé tó bá kú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:16; 28:15; 47:29, 30; 50:13
  • +Jẹ 50:1

Jẹ́nẹ́sísì 46:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:1-4
  • +Jẹ 35:23; 1Kr 5:1

Jẹ́nẹ́sísì 46:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:5, 6

Jẹ́nẹ́sísì 46:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:33
  • +Nọ 26:12, 13; 1Kr 4:24

Jẹ́nẹ́sísì 46:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:34
  • +1Kr 6:16

Jẹ́nẹ́sísì 46:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:35; Ifi 5:5
  • +Jẹ 38:2-5
  • +Lk 3:23, 33
  • +Jẹ 38:30
  • +Jẹ 38:7, 9, 10
  • +Nọ 26:21; 1Kr 2:5

Jẹ́nẹ́sísì 46:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:23, 24; 1Kr 7:1

Jẹ́nẹ́sísì 46:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:20
  • +Nọ 26:26

Jẹ́nẹ́sísì 46:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:21

Jẹ́nẹ́sísì 46:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:11
  • +Nọ 26:15-17

Jẹ́nẹ́sísì 46:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:13
  • +Nọ 26:44, 45

Jẹ́nẹ́sísì 46:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mẹ́rìndínlógún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:24

Jẹ́nẹ́sísì 46:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:24
  • +Jẹ 35:18

Jẹ́nẹ́sísì 46:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Heliopólísì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:50
  • +Jẹ 41:51
  • +Jẹ 41:52

Jẹ́nẹ́sísì 46:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 7:6
  • +1Kr 8:1, 3
  • +1Kr 7:12
  • +Nọ 26:38-40

Jẹ́nẹ́sísì 46:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mẹ́rìnlá.”

Jẹ́nẹ́sísì 46:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Àwọn ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:6
  • +Nọ 26:42

Jẹ́nẹ́sísì 46:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:8
  • +Nọ 26:48, 49

Jẹ́nẹ́sísì 46:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn méje.”

Jẹ́nẹ́sísì 46:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Gbogbo ọkàn tó wá láti ara Jékọ́bù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:10, 11

Jẹ́nẹ́sísì 46:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn méjì.”

  • *

    Tàbí “Gbogbo àwọn ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:5; Di 10:22; Iṣe 7:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2002, ojú ìwé 27

Jẹ́nẹ́sísì 46:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 43:8; 44:18
  • +Jẹ 45:10; 47:1

Jẹ́nẹ́sísì 46:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “sunkún ní ọrùn rẹ̀ léraléra.”

Jẹ́nẹ́sísì 46:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:39, 40
  • +Jẹ 45:19; Iṣe 7:13

Jẹ́nẹ́sísì 46:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:17, 18; 47:3
  • +Jẹ 31:38
  • +Jẹ 46:6

Jẹ́nẹ́sísì 46:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:35, 36
  • +Jẹ 45:17, 18; 47:27
  • +Jẹ 43:32

Àwọn míì

Jẹ́n. 46:1Jẹ 21:31
Jẹ́n. 46:1Jẹ 31:42; Ẹk 3:6
Jẹ́n. 46:3Jẹ 28:13
Jẹ́n. 46:3Jẹ 12:1, 2; Ẹk 1:7; Di 26:5
Jẹ́n. 46:4Jẹ 15:16; 28:15; 47:29, 30; 50:13
Jẹ́n. 46:4Jẹ 50:1
Jẹ́n. 46:8Ẹk 1:1-4
Jẹ́n. 46:8Jẹ 35:23; 1Kr 5:1
Jẹ́n. 46:9Nọ 26:5, 6
Jẹ́n. 46:10Jẹ 29:33
Jẹ́n. 46:10Nọ 26:12, 13; 1Kr 4:24
Jẹ́n. 46:11Jẹ 29:34
Jẹ́n. 46:111Kr 6:16
Jẹ́n. 46:12Jẹ 29:35; Ifi 5:5
Jẹ́n. 46:12Jẹ 38:2-5
Jẹ́n. 46:12Lk 3:23, 33
Jẹ́n. 46:12Jẹ 38:30
Jẹ́n. 46:12Jẹ 38:7, 9, 10
Jẹ́n. 46:12Nọ 26:21; 1Kr 2:5
Jẹ́n. 46:13Nọ 26:23, 24; 1Kr 7:1
Jẹ́n. 46:14Jẹ 30:20
Jẹ́n. 46:14Nọ 26:26
Jẹ́n. 46:15Jẹ 30:21
Jẹ́n. 46:16Jẹ 30:11
Jẹ́n. 46:16Nọ 26:15-17
Jẹ́n. 46:17Jẹ 30:13
Jẹ́n. 46:17Nọ 26:44, 45
Jẹ́n. 46:18Jẹ 29:24
Jẹ́n. 46:19Jẹ 30:24
Jẹ́n. 46:19Jẹ 35:18
Jẹ́n. 46:20Jẹ 41:50
Jẹ́n. 46:20Jẹ 41:51
Jẹ́n. 46:20Jẹ 41:52
Jẹ́n. 46:211Kr 7:6
Jẹ́n. 46:211Kr 8:1, 3
Jẹ́n. 46:211Kr 7:12
Jẹ́n. 46:21Nọ 26:38-40
Jẹ́n. 46:23Jẹ 30:6
Jẹ́n. 46:23Nọ 26:42
Jẹ́n. 46:24Jẹ 30:8
Jẹ́n. 46:24Nọ 26:48, 49
Jẹ́n. 46:26Jẹ 35:10, 11
Jẹ́n. 46:27Ẹk 1:5; Di 10:22; Iṣe 7:14
Jẹ́n. 46:28Jẹ 43:8; 44:18
Jẹ́n. 46:28Jẹ 45:10; 47:1
Jẹ́n. 46:31Jẹ 41:39, 40
Jẹ́n. 46:31Jẹ 45:19; Iṣe 7:13
Jẹ́n. 46:32Jẹ 31:17, 18; 47:3
Jẹ́n. 46:32Jẹ 31:38
Jẹ́n. 46:32Jẹ 46:6
Jẹ́n. 46:34Jẹ 30:35, 36
Jẹ́n. 46:34Jẹ 45:17, 18; 47:27
Jẹ́n. 46:34Jẹ 43:32
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 46:1-34

Jẹ́nẹ́sísì

46 Ísírẹ́lì bá kó gbogbo ohun tó ní,* ó sì gbéra. Nígbà tó dé Bíá-ṣébà,+ ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísákì+ bàbá rẹ̀. 2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lójú ìran ní òru, ó ní: “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 3 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run bàbá+ rẹ. Má bẹ̀rù láti lọ sí Íjíbítì, torí ibẹ̀ ni màá ti sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.+ 4 Èmi fúnra mi yóò bá ọ lọ sí Íjíbítì, èmi fúnra mi yóò sì mú ọ pa dà wá láti ibẹ̀,+ Jósẹ́fù yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ.”*+

5 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù kúrò ní Bíá-ṣébà, àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì fi kẹ̀kẹ́ tí Fáráò fi ránṣẹ́ gbé Jékọ́bù bàbá wọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ìyàwó wọn. 6 Wọ́n kó agbo ẹran wọn àti ẹrù wọn dání, èyí tí wọ́n ti ní nílẹ̀ Kénáánì. Jékọ́bù àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ wá dé sí ilẹ̀ Íjíbítì. 7 Ó kó àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin dání wá sí Íjíbítì, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lóbìnrin. Gbogbo ọmọ rẹ̀ ló kó wá.

8 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó wá sí Íjíbítì  + nìyí, Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀: Rúbẹ́nì+ ni àkọ́bí Jékọ́bù.

9 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni Hánókù, Pálù, Hésírónì àti Kámì.+

10 Àwọn ọmọ Síméónì+ ni Jémúélì, Jámínì, Óhádì, Jákínì, Sóhárì àti Ṣéọ́lù+ ọmọ obìnrin ará Kénáánì.

11 Àwọn ọmọ Léfì+ ni Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+

12 Àwọn ọmọ Júdà+ ni Éérì, Ónánì, Ṣélà,+ Pérésì+ àti Síírà.+ Àmọ́ Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+

Àwọn ọmọ Pérésì ni Hésírónì àti Hámúlù.+

13 Àwọn ọmọ Ísákà ni Tólà, Púfà, Íóbù àti Ṣímúrónì.+

14 Àwọn ọmọ Sébúlúnì+ ni Sérédì, Élónì àti Jálíẹ́lì.+

15 Àwọn ni ọmọkùnrin tí Líà bí fún Jékọ́bù ní Padani-árámù, pẹ̀lú Dínà+ ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀* jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33).

16 Àwọn ọmọ Gádì+ ni Sífíónì, Hágì, Ṣúnì, Ésíbónì, Érì, Áródì àti Árélì.+

17 Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ ni Ímúnà, Íṣífà, Íṣífì àti Bẹráyà, pẹ̀lú Sírà arábìnrin wọn.

Àwọn ọmọ Bẹráyà ni Hébà àti Málíkíélì.+

18 Àwọn ni ọmọ Sílípà,+ tí Lábánì fún Líà ọmọ rẹ̀. Ó bí wọn fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún (16).*

19 Àwọn ọmọ Réṣẹ́lì ìyàwó Jékọ́bù ni Jósẹ́fù+ àti Bẹ́ńjámínì.+

20 Ásénátì+ ọmọ Pọ́tíférà àlùfáà Ónì* bí Mánásè+ àti Éfúrémù+ fún Jósẹ́fù ní ilẹ̀ Íjíbítì.

21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ ni Bélà, Békérì, Áṣíbélì, Gérà,+ Náámánì, Éhì, Róṣì, Múpímù, Húpímù+ àti Áádì.+

22 Àwọn ni ọmọ tí Réṣẹ́lì bí fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìnlá (14).*

23 Ọmọ* Dánì+ ni Húṣímù.+

24 Àwọn ọmọ Náfútálì+ ni Jáséélì, Gúnì, Jésérì àti Ṣílẹ́mù.+

25 Àwọn ni ọmọ Bílíhà, tí Lábánì fún Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀. Ó bí wọn fún Jékọ́bù: gbogbo wọn jẹ́ méje.*

26 Gbogbo ọmọ Jékọ́bù* tó bá a lọ sí Íjíbítì, yàtọ̀ sí ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66).+ 27 Ọmọ méjì* ni Jósẹ́fù bí ní Íjíbítì. Gbogbo ará* ilé Jékọ́bù tó wá sí Íjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70).+

28 Jékọ́bù rán Júdà+ ṣáájú pé kó lọ sọ fún Jósẹ́fù pé òun ti wà lọ́nà Góṣénì. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Góṣénì,+ 29 Jósẹ́fù múra kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ pàdé Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀ ní Góṣénì. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó dì mọ́ ọn* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì sunkún fúngbà díẹ̀.* 30 Ísírẹ́lì wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo lè wá kú báyìí; mo ti rí ojú rẹ, mo sì wá mọ̀ pé o ṣì wà láàyè.”

31 Jósẹ́fù wá sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé bàbá rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n lọ bá Fáráò,+ kí n sì sọ fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti agbo ilé bàbá mi láti ilẹ̀ Kénáánì ti wá bá mi níbí.+ 32 Olùṣọ́ àgùntàn+ ni wọ́n, wọ́n sì ní àwọn ẹran ọ̀sìn.+ Wọ́n ti kó agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn wá.’+ 33 Tí Fáráò bá pè yín, tó sì bi yín pé, ‘Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?’ 34 Kí ẹ sọ pé, ‘Àti kékeré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa,’ kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ torí àwọn ará Íjíbítì+ kórìíra gbogbo àwọn tó ń da àgùntàn.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́