Jóṣúà
16 Ilẹ̀ tí wọ́n fi kèké pín*+ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù+ bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò dé ibi omi tó wà lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, ó gba inú aginjù láti Jẹ́ríkò lọ sí agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì.+ 2 Ó lọ láti Bẹ́tẹ́lì tó jẹ́ ti Lúsì títí dé ààlà àwọn Áríkì ní Átárótì, 3 ó wá lọ sí ìsàlẹ̀ lápá ìwọ̀ oòrùn dé ààlà àwọn ọmọ Jáfílétì títí lọ dé ààlà Bẹti-hórónì+ Ìsàlẹ̀ àti Gésérì,+ ó sì parí sí òkun.
4 Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù,+ Mánásè àti Éfúrémù, wá gba ilẹ̀ wọn.+ 5 Ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé nìyí: Ààlà ogún wọn lápá ìlà oòrùn ni Ataroti-ádárì+ títí dé Bẹti-hórónì Òkè,+ 6 ó sì dé òkun. Míkímẹ́tátì+ wà ní àríwá, ààlà náà sì yí gba apá ìlà oòrùn lọ sí Taanati-ṣílò, ó sì gba ìlà oòrùn lọ sí Jánóà. 7 Láti Jánóà, ó gba ìsàlẹ̀ lọ sí Átárótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò,+ títí lọ dé Jọ́dánì. 8 Láti Tápúà,+ ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Àfonífojì Kánà, ó sì parí sí òkun.+ Èyí ni ogún ẹ̀yà Éfúrémù ní ìdílé-ìdílé; 9 àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù tún ní àwọn ìlú tí wọ́n yà sọ́tọ̀ ní àárín ogún Mánásè,+ gbogbo ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
10 Àmọ́ wọn ò lé àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Gésérì+ kúrò, àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé láàárín Éfúrémù títí di òní yìí,+ wọ́n sì ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+