“Ẹ Ṣeun fún Ríràn Mí Lọ́wọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jehofa!”
Ìyẹ́n jẹ́ ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí ọmọdébìnrin ọlọ́dún 16 kan láti Florida, U.S.A., sọ. Lẹ́yìn kíka ìtẹ̀jáde tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ̀ jáde, ó kọ̀wé pé:
“N kò lè rántí orúkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n mo ka ìwé kan tí mo gbà gbọ́ pé ẹ̀yin ni ẹ tẹ̀ ẹ́ jáde, nípa ìgbésí ayé Jesu. Kí n tó ka ìwé yẹn, mo rò pé mo mọ gbogbo ohun tí ó yẹ kí n mọ̀. Mo gbà gbọ́ nínú Ọlọrun àti Jesu, mo ń gbàdúrà ṣáájú oúnjẹ alẹ́, àti lẹ́ẹ̀kan sí i ní àṣálẹ́, mo sì ń gbé ìgbésí ayé rere níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí mo ka ìwé yẹn, mo rí i pé n kò mọ ohunkóhun àti pé, mo ní láti máa kà nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu àti àwọn ẹlòmíràn nínú Bibeli, kí n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn.
“Mo ń yí díẹ̀ nínú àwọn ìwà mi padà díẹ̀díẹ̀ kí n baà lè jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun tí ó dára sí i. Bí kì í bá ṣe ti Watch Tower Society ni, èmi ì bá ṣì jẹ́ òpè síbẹ̀ nípa Ọlọrun àti àwọn ìtàn inú Bibeli. Ẹ ṣeun fún ríràn mí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa!”
Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí ni orúkọ ìwé tí ọmọdébìnrin náà ń tọ́ka sí. A ti ṣe ìsapá láti gbé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jesu lórí ilẹ̀ ayé tí a tò lẹ́sẹẹsẹ nínú àwọn Ìròyìn Rere mẹ́rin kalẹ̀ nínú rẹ̀. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ bí o ṣe lè gba ẹ̀dà kan tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú ní ojú ìwé 5.