ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/8 ojú ìwé 11-14
  • Àwọn Akọrin Tí A Tẹ̀ Lọ́dàá—Sísọ Ara Di Alábùkù Lórúkọ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Akọrin Tí A Tẹ̀ Lọ́dàá—Sísọ Ara Di Alábùkù Lórúkọ Ìsìn
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwẹ̀fà Nínú Ìtàn Ìgbàanì
  • Àwọn Ìwẹ̀fà Nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù
  • Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Ṣọ́ọ̀ṣì
  • Ìtẹnilọ́dàá Nítorí Orin
  • Òkìkí, Àwọn Òbí, àti Èrò Àwọn Aráàlú
  • Ìtẹnilọ́dàá—Ó Ha Wà Ní Àwọn Ọdún 1990 Bí? 
  • Ìparí!
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Jí!—1996
g96 2/8 ojú ìwé 11-14

Àwọn Akọrin Tí A Tẹ̀ Lọ́dàá—Sísọ Ara Di Alábùkù Lórúkọ Ìsìn

Àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá—wọ́n jẹ́ àwọn ọmọkùnrin akọrin tí wọ́n ní agbára àgbàlagbà ọkùnrin ṣùgbọ́n tí wọ́n ní ohùn bíi ti ọmọdékùnrin. Sànmánì títẹ àwọn akọrin lọ́dàá jẹ́ ọ̀kan tí ó kún fún ìbànújẹ́ ní ti gidi. Ta ni wọ́n jẹ́? Ìdáhùn rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àṣà kan tí ń dáni níjì—sísọ ara di alábùkù lórúkọ ìsìn.

WỌ́N lè bí àwọn ìwẹ̀fà kan bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n púpọ̀ lára wọn ni àwọn ènìyàn sọ dà bẹ́ẹ̀. Wọ́n jẹ́ ọkùnrin ní ti ìrísí ara àti ìdúró wọn, síbẹ̀ wọn kò lè mú irú ọmọ jáde. Ní àsìkò kan nígbà ìdàgbàsókè ara wọn tàbí nígbà tí wọ́n bá ti dàgbà pàápàá ni a ti tẹ̀ wọ́n lọ́dàá, yálà wọ́n fẹ́ tàbí ní tipátipá.

Kí ló dé tí àwọn ọkùnrin yóò fi yàn láti tẹ ara wọn tàbí àwọn ọkùnrin mìíràn lọ́dàá lọ́nà yìí? Wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lórúkọ ìsìn.

Ìwẹ̀fà Nínú Ìtàn Ìgbàanì

Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, àwọn ará Asiria máa ń lo ìtẹnilọ́dàá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìjẹniníyà. Òun ni ìjìyà fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ní Egipti. Olè kan tí a rí tí ń jalè nínú tẹ́ḿpìlì kan ní Friesland ìgbàanì, tí ó jẹ́ apá kan Netherlands nísinsìnyí, ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ lọ́dàá, kí wọ́n tóó pa á.

Lákòókò ìṣàkóso àwọn Olú Ọba Domitian àti Nerva ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, a ka títẹ ènìyàn lọ́dàá léèwọ̀ ní Romu, ṣùgbọ́n wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é ní àwọn ọdún tí ilẹ̀ ọba náà ń lọ sópin. Àwọn òfin tí ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Alfred Ńlá, gbé jáde ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ní in pé kí a fìyà jẹ ẹrú tí ó bá fipá bá ẹrúbìnrin lò pọ̀ lọ́nà yìí.

Àwọn ìwẹ̀fà tún ṣiṣẹ́ lọ́nà tí ó hàn gbangba nínú ààtò ìsìn. Àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn wúńdíá ń ṣiṣẹ́ sin àwọn abo ọlọrun tí ń jẹ́ Atẹmisi ní ìlú ńlá Efesu. Àwọn ọkùnrin tẹ ara wọn lọ́dàá nínú àwọn ayẹyẹ ẹhànnà tí a ṣe láti bọlá fún òrìṣà Asitate ti Syria ní Hierapoli, tí wọ́n wá ń wọ aṣọ obìnrin lẹ́yìn náà títí gbogbo ìyókù ìwàláàyè wọn.

Muhammad kéde pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ ara rẹ̀ tàbí ẹlòmíràn lọ́dàá kì í ṣe ọmọlẹ́yìn mi.” Bí ó ti wù kí ó rí, láìka ìkàléèwọ̀ yìí sí, wọ́n máa ń ka àwọn ìwẹ̀fà sí iyebíye gẹ́gẹ́ bí ẹrú ní àwọn orílẹ̀-èdè Mùsùlùmí, gẹ́gẹ́ bí olùṣètọ́jú ilé àwọn ẹlẹ́hàá àti àwọn ibi mímọ́ ìsìn. Ní àbáyọrí rẹ̀, òwò ẹrú yìí ń bá a lọ láìlópin. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí a mú wá láti Sudan àti àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Àríwá Africa tí ó sún mọ́ ọn mú èrè tabua wá fún àwọn olówò ẹrú náà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Johann L. Burckhardt ṣèbẹ̀wò sí ìhà Gúúsù Egipti, níbi tí ó ti rí àwọn ọmọdékùnrin tí a tẹ̀ lọ́dàá, tí a fẹ́ẹ́ tà bí ẹrú. Wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà fún àwọn ọmọdékùnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 8 sí 12. Àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé méjì láti inú Ṣọ́ọ̀ṣì Coptic ni wọ́n máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ́ náà. Burckhardt sọ pé: “A máa ń pẹ̀gàn iṣẹ́ wọn.”

Èyí ló fa ìbéèrè náà pé, Dé àyè wo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi lọ́wọ́ nínú àṣà yìí, àti fún ète wo?

Àwọn Ìwẹ̀fà Nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù

Origen—tí a mọ̀ dáadáa mọ Hexapla rẹ̀, àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu tí a ṣètò sí òpó ìlà mẹ́fà—ni a bí ní nǹkan bí ọdún 185 Sànmánì Tiwa. Nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 18, àwọn àwíyé rẹ̀ lórí ìsìn Kristian ti sọ ọ́ di olókìkí. Síbẹ̀, ó ń ṣàníyàn nípa pé kí a má ṣi òkìkí òun láàárín àwọn obìnrin túmọ̀. Nítorí náà, ní mímú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu náà lólówuuru pé, “awọn ìwẹ̀fà sì wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà nítìtorí ìjọba awọn ọ̀run,” ó tẹ ara rẹ̀ lọ́dàá. (Matteu 19:12)a Ìwà aláìdàgbàdénú, àláìronújinlẹ̀ ni ó jẹ́—èyí tí ó wá kábàámọ̀ gidigidi nígbà tí ó yá nínú ìgbésí ayé rẹ̀.

Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ìwé òfin àkọ́kọ́ gan-an tí ó jáde níbi Ìgbìmọ̀ Nicaea ní ọdún 325 Sànmánì Tiwa, sọ pé kí a yọ àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti tẹ ara wọn lọ́dàá kúrò nínú ẹgbẹ́ àlùfáà. Ọmọ̀wé J. W. C. Wand sọ nípa ìgbèròpinnu yìí pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan ti fi ìfẹ́ ọkàn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Origen hàn nínú ọ̀ràn yìí, kí wọ́n sì sọ ara wọn di ìwẹ̀fà . . . , ó sì ṣe pàtàkì pé kí a máà fún àwọn Kristian níṣìírí láti tẹ̀ lé àṣà tí a mọ̀ mọ́ àwọn olùfọkànsìn irú àwọn ìsìn kèfèrí kan.”

Nípa ṣíṣe irú ìpinnu pàtàkì bẹ́ẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù wá ọ̀nà láti mú ọ̀ràn ìtẹnilọ́dàá tí ń kóni nírìíra náà kúrò pátápátá. Bí a óò ti rí i, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ. Kọ́kọ́ gbé àkọsílẹ̀ tí a mọ̀ dáradára yìí yẹ̀ wò.

Ní ọdún 1118, Peter Abelard, ọlọ́gbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn, tí ó sì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, wọnú ìfẹ́ pẹ̀lú Héloïse, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí òun fúnra rẹ̀ ń dá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. A kò tí ì fi Abelard joyè, kò sì tipa bẹ́ẹ̀ sí lábẹ́ ẹ̀jẹ́ málàáya, nítorí náà, wọ́n ṣègbéyàwó ní bòókẹ́lẹ́, wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan. Ṣùgbọ́n nítorí pé ìbátan ọmọbìnrin náà, Fulbert, tí ó jẹ́ àlùfáà ní kàtídírà Roman Kátólíìkì ti Paris, ronú pé ńṣe ni ó sún Héloïse dẹ́ṣẹ̀, ó ní kí wọ́n tẹ Abelard lọ́dàá tipátipá. Ìgbésẹ̀ àìlajú tí irú olóyè ṣọ́ọ̀ṣì onípò gíga bẹ́ẹ̀ dá sílẹ̀ yìí, mú kí a fi irú ìyà kan náà jẹ àwọn méjì lára àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

Nípa bẹ́ẹ̀, ìtẹnilọ́dàá ṣì jẹ́ ohun tí a tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ìfìyàjẹni nínú àwọn ipò ọ̀ràn kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àṣà aláìwà-bí-Ọlọrun yìí ni a yára gbé lárugẹ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì nítorí kíkọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì.

Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Ṣọ́ọ̀ṣì

Orin kíkọ ti kó ipa pàtàkì nínú ààtò ìjọsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìhà Ìlà Oòrùn àti Roman Kátólíìkì, tí àwọn ọmọdékùnrin olóhùn tín-ínrín sì jẹ́ lájorí ìtìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́ ṣáá, ohùn ọmọdékùnrin kan máa ń kẹ̀ nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá wọ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ọ̀dọ́langba. Báwo ni ṣọ́ọ̀ṣì ṣe lè borí pípààrọ̀ àti dídá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ látìgbàdégbà? Lótìítọ́, irú ohùn ríròkè tí kò fi bẹ́ẹ̀ fani mọ́ra tí a mọ̀ sí ohùn òkè ni wọ́n sábà máa ń lò, ṣùgbọ́n èyí kì í ṣe ìfirọ́pò tí a tẹ́wọ́ gbà fún ohùn tín-ínrín àwọn ọmọdékùnrin.b

Ohùn tín-ínrín ti àwọn obìnrin ni àfirọ́pò tí ó wà, ṣùgbọ́n láti ìgbà láéláé ni póòpù ti kà á léèwọ̀ fún àwọn obìnrin láti máa kọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ìṣòro kan tí ó tún wà ni pé, a lè ké sí àwọn akọrin ṣọ́ọ̀ṣì láti ṣèrànwọ́ fún àlùfáà wọn, ojúṣe tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọkùnrin nìkan. Nítorí náà, a kò lè lo àwọn obìnrin láti pèlé àwọn ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì.

Ní 1588, Póòpù Sixtus Karùn-ún fòfin de àwọn obìnrin láti má ṣe máa kọrin níbi eré orí ìtàgé ìta gbangba èyíkéyìí tàbí níbi orin aláré. Póòpù Innocent Kọkànlá tún gbé ìfòfindè yìí jáde ní nǹkan bí 100 ọdún lẹ́yìn náà. Olùṣèwádìí Angus Heriot sọ pé: “Àìtẹ́wọ́gba àwọn obìnrin tí ń ṣeré orí ìtàgé yìí àti síso orúkọ wọn pọ̀ mọ́ iṣẹ́ aṣẹ́wó àti ìṣekúṣe jẹ́ àṣà ìgbàanì, ní ọjọ́ Augustine Mímọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún àti ṣáájú rẹ̀ pàápàá.” Bí ó ti wù kí ó rí, nípa mímú irú ìdúró tí ó le dan-indan-in yìí, ṣọ́ọ̀ṣì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìṣòro mìíràn, tí ó túbọ̀ le koko—títẹ àwọn akọrin lọ́dàá!

Àwọn wo ni àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá náà, báwo sì ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn wọn?

Ìtẹnilọ́dàá Nítorí Orin

Orin aláré àti àwọn eré orí ìtàgé ìta gbangba nílò àwọn olóhùn tín-ínrín, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ẹgbẹ́ akọrin ti póòpù pẹ̀lú nílò rẹ̀. Kí ni wọn yóò ṣe sí i? Wọ́n ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé, bí a bá tẹ ọmọdékùnrin kan lọ́dàá, ohùn rẹ̀ kò ní kẹ̀. Àwọn tán-án-ná wulẹ̀ máa ń tóbi díẹ̀ sí i ni, nígbà tí ó sì jẹ́ pé igbáàyà àti abònú máa ń tóbi sí i bí ó ti yẹ. Ní àbáyọrí rẹ̀, akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá náà ní agbára bíi ti ọkùnrin, ṣùgbọ́n ó ní ohùn ọmọdékùnrin—“irú ohùn tí a ronú pé àwọn áńgẹ́lì ní,” ni Maria Luisa Ambrosini sọ nínú The Secret Archives of the Vatican. Ó tún ṣeé ṣe láti ṣàkóso irú ohùn náà dé àyè kan nípa jíjẹ́ kí ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà, nígbà tí a tẹ̀ wọ́n lọ́dàá, yàtọ̀ síra.

Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gíríìkì ti ń lo àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá gẹ́gẹ́ bí mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ akọrin láti ọ̀rúndún kejìlá wá, ṣùgbọ́n kí ni Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì yóò ṣe? Yóò ha fọwọ́ sí títẹ àwọn akọrin lọ́dàá, kí ó sì máa lò wọ́n bí?

A kọ orúkọ Padre Soto, tí ó jẹ́ akọrin kan nínú ẹgbẹ́ àwọn akọrin póòpù ní 1562, sínú ìwé Vatican gẹ́gẹ́ bí olóhùn òkè. Ṣùgbọ́n akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá ni Soto. Nípa bẹ́ẹ̀, ní nǹkan bí ọdún 27 ṣáájú 1589, nígbà tí òfin Póòpù Sixtus Karùn-ún ṣàtúntò àwọn akọrin St. Peter’s Basilica láti ní àwọn akọrin mẹ́rin tí a tẹ̀ lọ́dàá nínú, Vatican ti fi àṣẹ Ìgbìmọ̀ Nicaea sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́.

Láti 1599 ni a ti jẹ́wọ́ pé lótìítọ́ ni àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá wà ní Vatican. Gbàrà tí àwọn aláṣẹ gíga jù lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì ti fọwọ́ sí àṣà náà ní gbangba, àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá wá di ohun ìtẹ́wọ́gbà. Gluck, Handel, Meyerbeer àti Rossini wà lára àwọn tí wọ́n ṣàkójọ orin mímọ́ àti orin tí kò ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn, ní pàtàkì fún àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá.

Òkìkí, Àwọn Òbí, àti Èrò Àwọn Aráàlú

Bí idán ni títẹ àwọn akọrin lọ́dàá yára bẹ̀rẹ̀ sí í lókìkí. Fún àpẹẹrẹ, bí ohùn wọn ti dẹ̀ dáadáa tí ó sì dùn wú Póòpù Clement Kẹjọ (1592 sí 1605) lórí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tí a bá mọ̀ tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àṣà títẹni lọ́dàá ni ó yẹ kí wọ́n ti yọ níjọ, àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ wá bí àìní tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ní nípa orin kò ti kúrò nílẹ̀.

Wọ́n sọ pé àwọn ṣọ́ọ̀bù ń polówó pé, “Qui si castrono ragazzi (A ń tẹ àwọn ọmọdékùnrin lọ́dàá níhìn-ín).” Ṣọ́ọ̀bù onígbàjámọ̀ kan ní Romu fi ìyangàn kéde pé: “A ń tẹ àwọn akọrin lọ́dàá níhìn-ín fún àwọn ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì póòpù.” Wọ́n sọ pé, láàárín ọ̀rúndún kejìdínlógún, nǹkan bí 4,000 àwọn ọmọdékùnrin ará Itali ni ó ṣeé ṣe kí a ti tẹ̀ lọ́dàá fún ète yìí. A kò mọ iye àwọn tí ó kú nígbà tí wọ́n ń ṣe é fún wọn.

Kí ló dé tí àwọn òbí fi gbà kí a sọ àwọn ọmọkùnrin wọn di alábùkù ara lọ́nà yìí? Ó wọ́pọ̀ pé kí àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá jẹ́ àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́. Bí ọmọkùnrin kan bá fi ẹ̀bùn orin kíkọ hàn, nígbà náà, wọ́n lè tà á, nígbà míràn ní tààràtà, fún ilé orin kan. A mú àwọn mìíràn lára àwọn ẹgbẹ́ akọrin St. Peter’s Basilica ní Romu àti láti àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ṣọ́ọ̀ṣì míràn. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè retí, àwọn òbí máa ń lérò pé àwọn ọmọkùnrin wọn tí a tẹ̀ lọ́dàá yóò di olókìkí, wọn yóò sì lè pèsè fún àwọn ní ọjọ́ ogbó àwọn.

Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́pọ̀ ìgbà ni ọ̀ràn ìbìnújẹ́ máa ń ṣẹlẹ̀, nígbà tí ó bá hàn kedere pé ọmọdékùnrin náà kò ní ohùn tí a lè ṣọlọ́jọ̀jọ̀ rẹ̀. Nígbà ti Johann Wilhelm von Archenholz, ń kọ ìwé A Picture of Italy ní òpin ọ̀rúndún kejìdínlógún, ó ṣàlàyé pé irú àwọn ẹni ìṣátì bẹ́ẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí nínú ọ̀pọ̀ yanturu àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá, ni a “gbà láyè láti di àlùfáà [mímọ́]” a sì fún wọn láyè láti ka Máàsì. Èyí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìṣáájú àrà ọ̀tọ̀ tí a gbé kalẹ̀ ní St. Peter’s fúnra rẹ̀, nígbà tí a gba àwọn akọrin ọmọdékùnrin méjì tí a tẹ̀ lọ́dàá wọlé gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Roman Kátólíìkì ní 1599 àti àwọn mìíràn lẹ́yìn náà, ní rírú òfin ṣọ́ọ̀ṣì náà.

Póòpù Benedict Kẹrìnlá fúnra rẹ̀ tọ́ka sẹ́yìn sí ìpinnu Ìgbìmọ̀ Nicaea, ó sì jẹ́wọ́ pé títẹni lọ́dàá kò bófin mu. Ṣùgbọ́n ní 1748, gírígírí ni ó kọ àbá kan tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn bíṣọ́ọ̀bù rẹ̀ pé kí a fòfin de àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá, nítorí ó ń bẹ̀rù pé, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yóò ṣófo bí òún bá ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ète àti ìjẹ́pàtàkì orin ṣọ́ọ̀ṣì ṣe tó nìyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá ń bá a lọ láti máa kọrin nínú àwọn ẹgbẹ́ akọrin àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Itali, ní St. Peter’s, àti nínú Ilé Ìjọsìn Sistine.

Ní 1898, pẹ̀lú bí èrò àwọn aráàlú lòdì sí títẹni lọ́dàá ti ń ga sókè sí i, Póòpù Leo Kẹtàlá fi ọgbọ́n inú dá àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá tí wọ́n wà ní Vatican dúró, ẹni tí ó sì joyè náà lẹ́yìn rẹ̀, Póòpù Pius Kẹwàá, pẹ̀lú fòfin de àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá kúrò nínú ilé ìjọsìn póòpù ní 1903. Ṣùgbọ́n a kò tí ì ṣàtúnṣe òfin tí Póòpù Sixtus Karùn-ún, tí ó bẹ̀rẹ̀ lílò wọ́n, gbé jáde.

Amọṣẹ́dunjú akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá kẹ́yìn, Alessandro Moreschi, kú ní 1922. A gbà àwọn orin rẹ̀ sílẹ̀ ní 1902 àti 1903, a sì ṣì lè gbọ́ wọn lónìí. A ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi “Soprano della Cappella Sistina (Olóhùn Tín-ínrín Ilé Ìjọsìn Sistine)” lára àwọn páálí àwo orin wọ̀nyí. Desmond Shawe-Taylor, aṣelámèyítọ́ orin, kọ̀wé pé: “Ohùn rẹ̀ tí kò sí iyè méjì pé ó jẹ́ ohùn tín-ínrín, kò jọ ti ọmọdékùnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni kò jọ ti obìnrin.”

Bí fífi ìwọra sọ àwọn ọmọdékùnrin di alábùkù ara nítorí iṣẹ́ ọnà ṣe dópin nìyẹn. The Encyclopædia Britannica pè é ní “àṣà tí ń ríni lára” síbẹ̀, tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì gbà láyè fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.

Ìtẹnilọ́dàá—Ó Ha Wà Ní Àwọn Ọdún 1990 Bí? 

Bí a kò ṣe ní àwọn akọrin tí a tẹ̀ lọ́dàá mọ́ nìyẹn. Ṣùgbọ́n ìyẹn ha túmọ̀ sí pé títẹni lọ́dàá lórúkọ ìsìn ti dópin bí? Ó bani nínú jẹ́ pé kò tí ì dópin! Ìwé ìròyìn The Independent Magazine ròyìn pé, India ní àwọn ìwẹ̀fà tí iye wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́, tí wọ́n ń gbé ní àwọn àwùjọ onísìn. Ta ni wọ́n? Àwọn tí a ń pè ní hijra.

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn hijra ni a bí nínú agbo ilé Mùsùlùmí—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onísìn Hindu pọ̀ lára wọn—gbogbo wọn sì ń jọ́sìn Bharuchra Mata, abo-ọlọ́run Hindu kan láti Gujarat. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn yàn pé kí a tẹ àwọn lọ́dàá, àwọn kan sọ pé, ohun tí ó tó ẹgbẹ̀rún kan lára àwọn ọkùnrin ilẹ̀ India ni a ń fipá tẹ̀ lọ́dàá lọ́dọọdún láti fipá mú wọn láti di ara àwọn hijra, lẹ́yìn èyí tí a óò wá lù wọ́n ní gbàǹjo fún àwọn gúrú tí wọ́n bá kó owó tí ó pọ̀ jù lé wọn.

Àwùjọ àwọn aláṣẹ gúrú kan ní ń ṣàkóso àwọn hijra, oríṣiríṣi ẹgbẹ́ àwọn hijra máa ń mú kí àwọn ìlú ńlá wà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Àwọn hijra máa ń rí ọ̀nà àtijẹ-àtimu nípa ṣíṣe bárà àti iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ḿpìlì. Gbogbo ènìyàn máa ń tẹ́ḿbẹ́lú wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tún máa ń bẹ̀rù wọn nítorí pé wọ́n ronú pé wọ́n ní agbára idán ẹlẹ́mìí èṣù. Nítorí èyí, àwọn ènìyàn máa ń sanwó fún wọn láti súre fún àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó.

Ìròyìn sọ pé àwọn hijra kan máa ń sá lọ. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn India Today sọ pé, “àwọn ètò awo ọ̀daràn hijra tí a sọ pé wọ́n ń ṣàkóso ìtẹnilọ́dàá náà máa ń ṣiṣẹ́ ní bòókẹ́lẹ́ àti pẹ̀lú ìpániláyà.”

Ìparí!

Ayé yóò ha bọ́ lọ́wọ́ irú ìwà ibi báyìí láé bí? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ ọba ìsìn èké náà—tí a tọ́ka sí nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, “Babiloni Ńlá”—“ti wọ́jọpọ̀ títí dé ọ̀run.” Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun afúngbàgbọ́-lókun tó láti kẹ́kọ̀ọ́ pé, gbogbo àwọn àṣà tí kì í fọlá fún Ọlọrun bẹ́ẹ̀ ni yóò wá sí òpin amúnijígìrì láìpẹ́! O kò ṣe kúkú kà nípa èyí fúnra rẹ nínú ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bibeli, Ìṣípayá, orí 18? Ní pàtàkì, wo ẹsẹ 2 àti 5.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nípa ọ̀rọ̀ Jesu, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé lórí Westminster Version of the Sacred Scriptures: The New Testament ti Roman Kátólíìkì ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe nípa títẹ ara ìyára lọ́dàá, ṣùgbọ́n nípa ti ẹ̀mí nípa ète tàbí ẹ̀jẹ́.” Bákan náà, ìwé A Commentary on the New Testament, láti ọwọ́ John Trapp, sọ pé: “Kì í ṣe pé kí wọ́n tẹ ara wọn lọ́dàá, bí Origen àti àwọn kan ti ṣe ní ìgbà láéláé, nítorí ṣíṣi ẹsẹ yìí lóye . . . ṣùgbọ́n, kí wọ́n wà ní àpọ́n, kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọrun pẹ̀lú òmìnira tí ó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i.”

b Ohùn òkè máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ohùn tí wọ́n túbọ̀ jẹ́ àdánidá bá ń lọ díẹ̀díẹ̀, a sì sọ pé kìkì etí àwọn tán-án-ná nìkan ní ó máa ń gbé e jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìlànà Gíga Jù Lọ

A kò gba ìwẹ̀fà kankan láyè láti di apá kan ìjọ Israeli, bí Òfin Jehofa ti sọ ní kedere. (Deuteronomi 23:1) Lábẹ̀ Òfin yìí, a kò fàyè gba títẹni lọ́dàá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pé: “Òfin àwọn Júù kórìíra iru àwọn iṣẹ́ abẹ bẹ́ẹ̀.” Nítorí rẹ̀, kò sí ọmọ Israeli tàbí àwọn àtìpó olùgbé èyíkéyìí tí a sọ di ìwẹ̀fà fún iṣẹ́ ìsìn nínú ààfin àwọn ọba Israeli, bí wọ́n ti ń ṣe ní àwọn ààfin aláyélúwà míràn, bíi ti ọba ilẹ̀ Persia náà, Ahaswerusi.—Esteri 2:14, 15; 4:4, 5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ìpinnu kan tí Póòpù Sixtus Karùn-ún ṣe ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún títẹ àwọn akọrin lọ́dàá

[Credit Line]

The Bettmann Archive

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́