Ìwà Tútù
ÌWÉ atúmọ̀ èdè náà, A New Testament Wordbook, ti William Barclay, sọ nípa ọ̀rọ̀ àpèjúwe náà pra·ysʹ pé: “Nínú èdè Gíríìkì ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó fa ìfẹ́ mọ́ra. Nípa àwọn nǹkan, ó túmọ̀ sí ‘pẹ̀lẹ́’. Fún àpẹẹrẹ, a lò ó fún afẹ́fẹ́ lẹlẹ tàbí ohùn pẹ̀lẹ́. Ní ti àwọn ènìyàn, ó túmọ̀ sí ‘jẹ́jẹ́’ tàbí ‘ẹ̀yẹ’. . . . Praus ní ìwà pẹ̀lẹ́ nínú, àmọ́, ìwà pẹ̀lẹ́ náà ní okun lẹ́yìn bí irin . . . Kì í ṣe ìwà pẹ̀lẹ́ tí kò lókun, ìwà òmùgọ̀ tí ìmọ̀lára bò mọ́lẹ̀, ìdákẹ́rọ́rọ́ ti ẹni tí a ń tì gbégbèésẹ̀.” (London, 1956, ojú ìwé 103, 104) Ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pé ọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀, pra·yʹtes, “kò sí nínú kìkì ‘ìrísí òde ìwà ẹni nìkan; bẹ́ẹ̀ ni kò sí nínú ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nìkan; bí kò ti jẹ́ ohun bàbàrà nínú ànímọ́ àdánidá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìwà ẹ̀yẹ àtọkànwá; lílò ó sì jẹ́ sí Ọlọrun lákọ̀ọ́kọ́ àti ní pàtàkì jù lọ. Ó jẹ́ ìwà ẹ̀mí nínú èyí tí a ti tẹ́wọ́ gba àwọn ọ̀nà tí Òún ń gbà bá wa lò gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó dára, tí ó sì wà láìsí awuyewuye tàbí àtakò; ó ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà tapeinophrosunē [ìrẹ̀lẹ̀], ó sì ń tẹ̀ lé e tímọ́tímọ́.’”—1981, Ìdìpọ̀ 3, ojú iwé 55, 56.
Ọ̀rọ̀ náà pra·ysʹ ni a túmọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà nínú àwọn ẹ̀dà Bibeli sí “ọkàn tútù,” “tútù,” “inú tútù,” àti “ìwàpẹ̀lẹ́.” (KJ, AS, NW, NE) Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú ìwé Barclay tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, pra·ysʹ jinlẹ̀ ju jíjẹ́ ẹni jẹ́jẹ́, tí a bá sì lò ó fún ẹnì kan, ó túmọ̀ sí ẹni tútù, oníwà ẹ̀yẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa kò ní gba ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà ibi láyè, ó ti fi tìtẹ́tìfẹ́ pèsè ọ̀nà tí a lè gbà tọ òun wá nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà àti iṣẹ́ àlùfáà Jesu Kristi. Àwọn olùjọ́sìn àti ìránṣẹ́ Jehofa lè tipa bẹ́ẹ̀ wá ojú rere rẹ̀ láìsí ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì àti ìfòyà kankan. (Heberu 4:16; 10:19-22; 1 Johannu 4:17, 18) Jesu ṣojú fún Jehofa Ọlọrun lọ́nà pípé gan-an tí ó fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹlu.” Ó tún sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nitori onínú tútù [Gíríìkì, pra·ysʹ] ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi, ẹ̀yin yoo sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nitori àjàgà mi jẹ́ ti inúrere ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Johannu 14:9; Matteu 11:28-30) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun lè sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́, ó sì ń mú ìwà tútù, ìgbọ́kànlé kíkún, àti okun dàgbà nínú àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
Ìtẹ̀sí Okun. Níní ìwà tàbí ẹ̀mí tútù kì í ṣe ànímọ́ ẹni tí kò ní ìwà aápọn. Jesu Kristi sọ pé: “Onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi.” (Matteu 11:29; 2 Korinti 10:1) Síbẹ̀, Jesu ní agbára ìtìlẹ́yìn kíkún láti ọ̀dọ̀ Bàbá rẹ̀, ó sì dúró gbọn-ingbọn-in fún ohun tí ó tọ̀nà; ó lo àǹfààní ọ̀rọ̀ sísọ fàlàlà àti ìgbésẹ̀ nígbà tí ó bá yẹ fún un.—Matteu 23:13-39; fi wé Matteu 21:5.
Onínú tútù ènìyàn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó ní ìgbàgbọ́, àti orísun okun kan. Kì í ṣe ẹni tí ó tètè máa ń yẹsẹ̀ tàbí tí a tètè ń mú sọ agbára èrò orí rere rẹ̀ nù. Àìní ìwà tútù jẹ́ àbájáde àìláàbò, ìjákulẹ̀, àìní ìgbàgbọ́ àti ìrètí, àti ìgbékútà pàápàá. Àpèjúwe tí a ṣe nípa ẹnì tí kò ní inú tútù nínú òwe ni pé: “Ẹni tí kò lè ṣe àkóso ara rẹ̀, ó dà bí ìlú tí a wó lulẹ̀, tí kò sì ní odi.” (Owe 25:28) Ó wà gbayawu, ó sì ṣí sílẹ̀ sí ìkọlù èrò èyíkéyìí àti èyí tí kò tọ́, tí ó lè sún un gbégbèésẹ̀ tí kò tọ́.
Èso ti Ẹ̀mí. Ìwà tútù jẹ́ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀. (Galatia 5:22, 23) Nítorí náà, Ọlọrun ni Orísun ìwà tútù, ènìyàn ní láti bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó sì mú èso ti ẹ̀mí yìí dàgbà láti lè ní ojúlówó ìwà tútù. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í wá nípasẹ̀ lílo agbára ìfẹ́ inú ẹni, àmọ́ ó ń wá láti inú fífà tímọ́tímọ́ mọ́ Ọlọrun.
Àìní ìwà tútú máa ń yọrí sí ìrunú láìyẹ, ìrorò, àìní ìkóra-ẹni-níjàánu, àti ìjà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a gba Kristian nímọ̀ràn láti pa ìṣọ̀kan àti àlàáfíà mọ́ nípa “ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò-inú ati ìwàtútù.”—Efesu 4:1-3.
Bí a bá gba owú àti asọ̀ láyè láti fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí wọ́n sì dàgbà, yóò ṣamọ̀nà sí oríṣiríṣi ìdàrúdàpọ̀. Ìwà tútù, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kì yóò jẹ́ kí irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ gbèrú láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Nítorí náà, òǹkọ̀wé Bibeli náà Jakọbu rọ àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n tí wọ́n sì lóye nínú ìjọ láti fi “ìwà . . . tí ó dára” hàn gẹ́gẹ́ bí “ìwàtútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n,” “ọgbọ́n tí ó wá lati òkè.”—Jakọbu 3:13, 17.
“Ìwàtútù,” ni a sábà máa ń so pọ̀ mọ́ “ẹ̀mí” nínú Bibeli, fún àpẹẹrẹ, “ẹ̀mí ìwàtútù,” tàbí “ẹ̀mí tútù.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ojúlówó ìwà tútù ju ànímọ́ ojú tàbí ti òòrèkóòrè, tí ó jẹ́ fún ìgbà kúkúrú lọ; kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ apá kan ohun tí ènìyàn jẹ́ lódindi, tàbí ànímọ́ rẹ̀. Aposteli Peteru tọ́ka sí òtítọ́ yìí nígbà tí ó sọ pé: “Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì ṣe jẹ́ ti irun dídì lóde ara ati ti fífi awọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tabi ti wíwọ awọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà ninu aṣọ-ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ati ti ìwàtútù, èyí tí ó ní ìníyelórí ńláǹlà ní ojú Ọlọrun.”—1 Peteru 3:3, 4.
Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ fi . . . ìwàtútù . . . wọ ara yín láṣọ,” tí ó jẹ́ pé bí a bá kà á lólówuuru, lè jọ bí èyí tí ń fi hàn pé ó wulẹ̀ jẹ́ ìbòjú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìrísí lásán; àmọ́, nínú àyíká ọ̀rọ̀ kan náà, ó fúnni ní ìṣítí pé: “Ẹ sì fi àkópọ̀-ìwà titun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di titun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹlu àwòrán Ẹni tí ó dá a.” (Kolosse 3:10, 12; Efesu 4:22-24) Èyí fi hàn pé ìwà tútù jẹ́ ànímọ́ àkópọ̀ ìwà ní ti gidi, ní pàtàkì tí a máa ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí èso ẹ̀mí Ọlọrun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípé àti fífi í sílò, dípò kí ó jẹ́ èyí tí a jogún lọ́nà àdánidá.