Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Kí A Kọ Orúkọ Ẹnì Kan Sínú “Ìwé” Ọlọrun Tàbí “Ìwé Ìyè”?
KÍKỌ orúkọ ẹnì kan sínú “ìwé ìyè” kì í ṣe àyànmọ́ pé ẹni yẹn yóò ní ìyè ayérayé. Ìgbọràn rẹ̀ ni yóò pinnu bóyá orúkọ rẹ̀ yóò máa wà níbẹ̀ lọ. Ìdí nìyí tí Mose fi bẹ Jehofa nítorí Israeli pé: “Nísinsìnyí, bí ìwọ óò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n—; bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, èmí bẹ̀ ọ́, pa mi rẹ́ kúrò nínú ìwé rẹ tí ìwọ́ ti kọ.” Jehofa fèsì pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ̀ mí, òun ni èmi óò pa rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” (Eksodu 32:32, 33) Èyí fi hàn pé àwọn orúkọ tí ó wà nínú “ìwé náà” yóò ní ìyípadà nítorí àìgbọ́ràn àwọn kan, tí orúkọ wọn yóò di èyí tí ‘a nù’ tàbí ‘pa rẹ́’ kúrò nínú “ìwé náà.”—Ìṣípayá 3:5.
Nínú ìran ìdájọ́ ti inú Ìṣípayá 20:11-15, nígbà Ìṣàkóso Kristi Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún, a fi hàn pé “ìwé ìyè” wà ní ṣíṣí sílẹ̀ kí àwọn orúkọ mìíràn baà lè wọnú rẹ̀; a ṣí àwọn ìwé ìtọ́ni sílẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn tí wọ́n padà wá nínú ‘àjíǹde àwọn olódodo’ yóò tipa bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní pé a kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìyè,” bí wọ́n bá fi tìgbọràntìgbọràn ṣe àwọn ohun tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó wà nínú ìwé ìtọ́ni náà. (Ìṣe 24:15) Dájúdájú, àwọn ìránṣẹ́ olódodo ti Ọlọrun tí wọ́n bá padà wá nínú ‘àjíǹde àwọn olódodo’ ni orúkọ wọn yóò ti wà nínú “ìwé ìyè” tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Nípa ìgbọràn wọn sí àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá, wọn óò pa orúkọ wọn mọ́ sínú rẹ̀.
Báwo ni ẹnì kan ṣe lè jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ wà nínú “ìwé ìyè” títí gbére? Ní ti àwọn tí wọ́n wà lójú ìlà láti jèrè ìwàláàyè ti ọ̀run, ó jẹ́ nípa ‘ṣíṣẹ́gun’ ayé yìí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ní fífi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí “olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú.” (Ìṣípayá 2:10; 3:5) Ní ti àwọn tí wọ́n wà lójú ìlà láti jèrè ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ nípa dídúró ṣinṣin sí ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa la ìdánwò onípinnu, tí ó kẹ́yìn lópin Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Kristi já. (Ìṣípayá 20:7, 8) Àwọn tí wọ́n pa ìwà títọ́ mọ́ la ìdánwò ìkẹyìn yẹn já ni Ọlọrun yóò fi orúkọ wọn sínú “ìwé ìyè” títí gbére, tí Jehofa sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́wọ́ pé olódodo ni wọ́n àti pé wọ́n tóyeyẹ fún ẹ̀tọ́ ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé ní ìtumọ̀ èro pípé.—Romu 8:33.