ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/22 ojú ìwé 17
  • Àwọn Ìjábá Àdánidá—Ríran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Wọn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìjábá Àdánidá—Ríran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Wọn
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
    Jí!—2007
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Bí O Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Ikú Jẹ́ fún Ọmọ Rẹ
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/22 ojú ìwé 17

Àwọn Ìjábá Àdánidá—Ríran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Wọn

ÀWỌN ìsẹ̀lẹ̀, ìjì líle, iná, àkúnya omi, ìjì líle—ẹ wo bí a ṣe wà láìlọ́nà àbájáde tó, nígbà tí a bá dojú kọ ìbínú ìṣẹ̀dá! Àwọn àgbàlagbà sábà ń rí i pé ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún, kí àwòrán bíbani lẹ́rù inú ọpọlọ tí a ń ní lẹ́yìn tí a bá nírìírí ìjábá àdánidá tó pa rẹ́. Kò yani lẹ́nu, nígbà náà, pé àwọn ọmọdé lè nílò àfikún ìrànwọ́ láti kọ́fẹ padà nínú irú ìrírí bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀ka Àbójútó Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìròtẹ́lẹ̀ ti Ìjọba Àpapọ̀ United States (FEMA) sọ pé, kété lẹ́yìn ìjábá kan, gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, àwọn ọmọdé máa ń bẹ̀rù pé (1) a óò fi wọ́n sílẹ̀ láwọn nìkan, (2) a óò yà wọ́n nípa kúrò lọ́dọ̀ ìdílé wọn, (3) ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò tún ṣẹlẹ̀, (4) ẹnì kan yóò sì fara pa tàbí kú. Kí ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí lè ṣe láti dín hílàhílo ọmọ rẹ kù lẹ́yìn ìjábá kan? Ẹ̀ka FEMA dá àbá wọ̀nyí.a

Gbìyànjú láti mú ìdílé náà wà pọ̀. Wíwà pọ̀ ń fún ọmọ rẹ ní ìdánilójú, ó sì ń dín ìbẹ̀rù pé a pa òun tì kù. Ó sàn láti má ṣe fi àwọn ọmọdé sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ tàbí sí ibùdó ìṣípòpadà, nígbà tí o ń wá ìrànwọ́ kiri. Ẹ̀ka FEMA ṣàkíyèsí pé: “Hílàhílo máa ń bá àwọn ọmọdé, wọn yóò máa dààmú pé òbí kò níí padà wá mọ́.” Bí ó bá pọn dandan fún ọ láti lọ síbikíbi, mú ọmọ rẹ dání lọ, bí ó bá ṣeé ṣe lọ́nàkọnà. Nípa bẹ́ẹ̀, ‘ọmọ rẹ kì yóò mú ànímọ́ rírọ̀ mọ́ òbí nítorí ìbẹ̀rù dàgbà.’

Lo àkókò láti baralẹ̀ ṣàlàyé ipò náà pẹ̀lú ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Sọ ohun tí o mọ̀ nípa ìjábá náà fún ọmọ rẹ. Bí ó bá pọn dandan, tún àlàyé rẹ ṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Wéwèé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. Fún àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, ‘Gbogbo wa yóò wà pa pọ̀ lábẹ́ búkà ní àṣálẹ́ òní.’ Bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀ ní ipò àyè tí kò níí mú kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbójú sókè, bí ó bá pọn dandan, o lè kúnlẹ̀.

Fún ọmọ rẹ ní ìṣírí láti sọ̀rọ̀. Ẹ̀ka FEMA tọ́ka sí i pé: “Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ṣe pàtàkì jù lọ láti dín hílàhílo ọmọ náà kù.” Tẹ́tí sí ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan ń sọ fún ọ nípa ìjábá náà àti ohun tí ń bà á lẹ́rù. (Fi wé Jákọ́bù 1:19.) Sọ fún un pé, ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti bẹ̀rù. Bí ó bá jọ pé ọmọ rẹ ń lọ́ tìkọ̀ láti sọ̀rọ̀, jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ̀rù ń ba ìwọ náà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè mú kí ó rọrùn fún un láti sọ ìbẹ̀rù rẹ̀ jáde, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dín hílàhílo rẹ̀ kù. (Fi wé Òwe 12:25.) “Bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ìdílé náà lódindi lọ́wọ́ sí ìjíròrò náà.”

Jẹ́ kí àwọn ọmọ pẹ̀lú ṣe nínú iṣẹ́ ìpalẹ̀mọ́. Nígbà tí ẹ bá ń palẹ̀ ilé mọ́, tí ẹ sì ń tún un ṣe, pín iṣẹ́ àwọn ọmọ fún wọn. “Níní iṣẹ́ kan láti ṣe yóò mú kí wọ́n lóye pé, kì yóò sí nǹkan.” Bí ó ti wù kí ó rí, ọmọ kan tí ó kéré jù sábà máa ń nílò àkànṣe àfiyèsí. Ẹ̀ka FEMA ṣàlàyé pé: “Irú ọmọ bẹ́ẹ̀ lè nílò àbójútó ti ara púpọ̀ sí i, ìgbámọ́ra púpọ̀ sí i; èyí sì ń mú kí ó túbọ̀ ṣòro fún àwọn òbí láti bójú tó àwọn ohun mìíràn tí ó yẹ ní ṣíṣe. Ó dunni pé kò sí ọ̀nà àbùjá kankan. Bí a kò bá kájú àìní ọmọ náà, ìṣòro náà yóò túbọ̀ máa bá a lọ fún àkókò gígùn.”

A gbọ́dọ̀ fi kókó kan tí ó gbẹ̀yìn sọ́kàn. Ẹ̀ka FEMA gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé: “Níkẹyìn pátápátá, o ní láti pinnu ohun tí ó dára jù lọ fún àwọn ọmọ rẹ.” Lílo àwọn ìlànà ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó dára jù lọ lábẹ́ ipò líle koko kan.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A fà á yọ láti inú àwọn ìtẹ̀jáde Helping Children Cope With Disaster àti Coping With Children’s Reactions to Hurricanes and Other Disasters, ti FEMA.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́