ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/07 ojú ìwé 4-8
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìwọ Lẹni Àkọ́kọ́ Tọ́mọ Ẹ Lè Rí Sá Tọ̀?
  • Kọ́ Ọmọ Ẹ Lóhun Tó Yẹ Kó Mọ̀ Nípa Ìbọ́mọdé-Ṣèṣekúṣe
  • Kọ́ Ọmọ Ẹ Lóhun Tó Lè Fi Gbara Ẹ̀ Sílẹ̀
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa?
    Jí!—1993
  • Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo (Apá Kẹta Nínú Mẹ́rin)
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 10/07 ojú ìwé 4-8

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín

Ọ̀PỌ̀ lára wa ni kì í fẹ́ pẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tó bá ti jẹ mọ́ bíbọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Àwọn òbí kì í tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ohun tó jọ ọ́ nítorí pé ṣe ló máa ń bí wọn nínú! Àmọ́ bíbọ́mọdé ṣèṣekúṣe ti wá di ọ̀ràn sí gbogbo aráyé lọ́rùn báyìí o, ńṣe ni ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ sì máa ń ba àwọn ọmọ láyé jẹ́. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣó wá yẹ ni ohun téèyàn ń gbé yẹ̀ wò? Ìwọ wò ó ná, kí lo rò pó ṣe pàtàkì lójú ẹ ju ààbò àwọn ọmọ ẹ lọ? O lè wá rí i nígbà náà pé ó kúkú sàn kó o mọ̀ nípa àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe nítorí pé ààbò ọmọ ẹ ló yẹ kójẹ ẹ́ lógún jù. Ohun tó o bá sì mọ̀ nípa ẹ̀ á ràn ẹ́ lọ́wọ́ gidigidi láti mú kí ewu fo àwọn ọmọ ẹ dá.

Bí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe bá tiẹ̀ jẹ́ ohun ẹ̀gbin tó gbilẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, má ṣe jẹ́ kó dún mọ̀huru mọ́ ẹ débi tó ò fi ní fẹ́ láti wá nǹkan ṣe sí i . Ó ṣe kò ṣe, o ṣì lágbára tó ju tọmọ ẹ lọ lórí ọ̀ràn náà, agbára tó jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lọmọ ẹ tó máa nírú ẹ̀. Látìgbà tó o ti dáyé, ọ̀pọ̀ ìmọ̀, ìrírí àti ọgbọ́n lo ti ní. Àwọn ohun tó o sì nílò láti ṣàṣeyọrí náà nìyẹn. Ẹnu pé kó o lò wọ́n láti dáàbò bo ọmọ ẹ ló kù. Ní báyìí, a óò jíròrò àwọn ohun mẹ́ta tí gbogbo òbí lè ṣe sí ọ̀ràn náà. Àwọn rèé: (1) Ìwọ ni kó o jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tọ́mọ ẹ á lè rí sá tọ̀, (2) jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe, àti (3) kọ́ àwọn ọmọ ẹ lóhun tí wọ́n lè fi gbara wọn sílẹ̀.

Ṣé Ìwọ Lẹni Àkọ́kọ́ Tọ́mọ Ẹ Lè Rí Sá Tọ̀?

Ojúṣe àwọn òbí ni láti dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ ìṣekúṣe, kì í ṣe ojúṣe àwọn ọmọ fúnra wọn. Nítorí náà, àwọn òbí gan-an ló yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, lẹ́yìn náà lọ̀rọ̀ á tó wá kan àwọn ọmọ. Bó o bá jẹ́ òbí, àwọn ohun díẹ̀ wà tó yẹ kó o mọ̀ nípa ìbọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Ó yẹ kó o mọ irú àwọn èèyàn tó máa ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbé e gbà. Èrò àwọn òbí nípa àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ni pé wọ́n sábà máa ń jẹ́ ẹni táwọn ọmọdé ò mọ̀ rí ṣùgbọ́n tí wọ́n á fòru bojú, tí wọ́n á sì yọ́ kẹ́lẹ́ wọlé láti wá jí àwọn ọmọdé gbé kí wọ́n lè lọ fipá bá wọn lò pọ̀. Àwọn erìkìnà tó bá àpèjúwe yìí mu wà ní tòótọ́. A sì sábà máa ń gbọ́ nípa wọn nínú ìròyìn. Àmọ́, irú wọn ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Nínú gbogbo abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe mẹ́wàá, mẹ́sàn-án ló sábà máa ń jẹ́ ẹni tọ́mọ náà mọ̀ dáadáa tó sì fọkàn tán.

Ká sòótọ́, kò sẹ́ni táá fẹ́ gbà gbọ́ pé aládùúgbò tó kóni mọ́ra, olùkọ́, òṣìṣẹ́ ìlera, olùdánilẹ́kọ̀ọ́, tàbí ìbátan òun lè máa rokàn ìbálòpọ̀ sọ́mọ òun. Ná, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló rí bẹ́ẹ̀ yẹn. Nítorí náà, kì í ṣe pé kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí tẹbí, tará àtàwọn ọ̀rẹ́ tó yí ẹ ká o. Síbẹ̀ náà, o lè dáàbò bo ọmọ rẹ bí ìwọ fúnra rẹ bá mọ ọgbọ́n táwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ń dá.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 6.

Bí ìwọ tó o jẹ́ òbí bá mọ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí wọ́n ń lò, wàá lè jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tọ́mọ ẹ á lè máa rí sá tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan tó fẹ́ràn láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé ju àwọn àgbà lọ bá kúndùn àti máa wà pẹ̀lú ọmọ ẹ, tó ń ra ẹ̀bùn fún un, tàbí tó sọ pé òun á máa bá ẹ bójú tó o, tó sì máa ń dá mú un jáde, kí ni wàá ṣe? Ṣé kíá lo ti máa gbà pé abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀? Ó tì o. Má ṣe jẹ́ kó yá ẹ jù láti ronú pé bónítọ̀hún ṣe jẹ́ nìyẹn. Ó lè jẹ́ pé ó kàn ń ṣe tiẹ̀ lásán ni o. Síbẹ̀ náà, má ṣe gbàgbé pé tojú tìyẹ́ làparò fi ń ríran. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Rántí pé, ìwọ̀nba díẹ̀ lohun tó dáa dùn mọ o. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti máa dá wà pẹ̀lú ọmọ ẹ ṣáá, rí i pó o mọ onítọ̀hún dáadáa. Jẹ́ kírú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé ìgbàkigbà lo lè wá bẹ ọmọ ẹ wò. Òbí tó ṣì ń tọ́ ọmọkùnrin mẹ́ta lọ́wọ́ ni Títí àti Dàmọ́lá, àmọ́ ọwọ́ kékeré kọ́ ni wọ́n fi mú ọ̀ràn jíjẹ́ kí ọmọ wọn máa dá wà pẹ̀lú àgbàlagbà. Nígbà tí ẹnì kan wá ń kọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọn ọkùnrin lórin nílé, Melissa sọ fún olùkọ́ náà pé: “Mi ò ní yé máa wá wò yín títí tí wàá fi ṣe tán.” Ó lè dà bíi pé àṣejù ti wọ ọ̀ràn náà, àmọ́ ṣe kò dáa báwọn òbí yìí ṣe fi àbámọ̀ ṣáájú ọ̀ràn.

Má ṣe dá ọmọ ẹ dá gbogbo ohun tó bá ń ṣe, mọ àwọn tó ń bá ṣọ̀rẹ́, máa bá a dá sí iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún un nílé ìwé. Mọ gbogbo bí wọ́n ṣe fẹ́ rìn bó bá ṣẹlẹ̀ pé ilé ẹ̀kọ́ fẹ́ kó wọn rìnrìn àjò lọ síbì kan. Ògbógi kan tó jẹ́ oníṣègùn ọpọlọ tó sì ti fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tọ́jú onírúurú èèyàn tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe sọ pé àìmọye irú ìṣekúṣe bẹ́ẹ̀ ni kì bá tí wáyé ká sọ pé àwọn òbí wà lójú fò. Ó ní abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan tí wọ́n ti dájọ́ fún sọ pé: “Àwọn òbí gan-an ni wọ́n ń fọwọ́ ara wọn fa àwọn ọmọ wọn lé wa lọ́wọ́. . . . Àwọn gan-an ni wọ́n mú kó rọrùn fún mi.” Má ṣe gbà gbé pé àwọn ọmọ tó bá rọrùn láti bá ṣèṣekúṣe lọ̀pọ̀ lára wọn máa ń wá kiri. Kì í rọrùn fún wọn láti dójú sọ àwọn ọmọ táwọn òbí wọn kì í sábà fi sílẹ̀ láwọn nìkan.

Ọ̀nà míì tó o lè gbà mú kó rọrùn fọ́mọ ẹ láti rí ẹ bí ẹni tó lè máa sá tọ̀ ni pé kó o máa tẹ́tí sí i dáadáa. Àwọn ọmọdé kì í sábà sọ bí ẹnikẹ́ni bá bá wọn ṣèṣekúṣe; ojú máa ń tì wọ́n jù, ẹ̀rù ohun táwọn ẹlòmíì á sọ sì máa ń bà wọ́n. Nítorí náà, fetí sílẹ̀ dáadáa, ì báà tiẹ̀ jẹ́ àmì kékeré kan lo rí.a Bí ọmọ ẹ bá sọ ohun kan tí kò fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, fara balẹ̀ fi ìbéèrè wá a lẹ́nu wò.b Bó bá sọ pé òun ò fẹ́ kẹ́ni tẹ́ ẹ ni kó máa wá dúró ti òun nílé wá mọ́, bi í pé kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀. Bó bá sọ pé eré tí àgbàlagbà kan ń bá òun ṣe ò ye òun tó, bi í pé: “Irú eré wo leré náà? Kí lonítọ̀hún ṣe gan-an?” Bó bá sọ pé ẹnì kan fọwọ́ kan òun, bi í pé, “Ibo ló fọwọ́ kàn lára ẹ?” Má máa tètè fojú kò-tó-nǹkan wo ìdáhùn tọ́mọ ẹ bá fún ẹ. Àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe sábà máa ń sọ fáwọn ọmọ náà pé kò sẹ́ni tó máa gba ohun tí wọ́n bá sọ gbọ́; lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Bó bá sì ṣẹlẹ̀ pé wọ́n bá ọmọdé kan ṣèṣekúṣe, báwọn òbí ò bá ṣáà ti ka ọmọ náà sí onírọ́ tí wọn ò sì jáwọ́ lọ́rọ̀ ẹ̀, ó máa tètè bọ̀ sípò.

Kọ́ Ọmọ Ẹ Lóhun Tó Yẹ Kó Mọ̀ Nípa Ìbọ́mọdé-Ṣèṣekúṣe

A rí ohun tí abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan tí wọ́n ti dájọ́ fún sọ nínú ìwé kan tá a ti ṣèwádìí. Ó sọ pé: “Bí mo bá rí ọmọdé kan tí kò mọ ohunkóhun nípa ìbálòpọ̀, ọwọ́ mi ti ba ohun tí mò ń wá nìyẹn.” Ìránnilétí pàtàkì lọ̀rọ̀ tí ń bani lẹ́rù yìí jẹ́ fáwọn òbí. Ó máa ń rọrùn fáwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe láti tan àwọn ọmọ tí ò bá mọ ohunkóhun nípa ìbálòpọ̀ jẹ. Bíbélì sọ pé ìmọ̀ àti ọgbọ́n lè gbà wá “lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà.” (Òwe 2:10-12) Àbí irú ààbò tó ò ń fẹ́ fọ́mọ ẹ kọ́ nìyẹn? Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀nà pàtàkì kejì tó o lè gbà dáàbò bo ọmọ ẹ ni pé kó o má ṣe fà sẹ́yìn láti máa kọ́ ọ nípa kókó pàtàkì tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.

Ọ̀nà wo lo wá lè gbé e gbà? Ọ̀pọ̀ òbí lara wọn máa ń kó tìọ̀ láti báwọn ọmọ wọn jíròrò ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Ó lè máa ti ọmọ ẹ pàápàá lójú láti jíròrò nípa ìbálòpọ̀, kó tiẹ̀ dà bíi pé kò fẹ́ láti bá ẹ sọ ohun tó jọ ọ́. Nítorí náà, ìwọ ni kó o kọ́kọ́ dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Títí sọ pé: “A tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lórúkọ táwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ń jẹ́. À ń pè wọ́n lórúkọ tí wọ́n ń jẹ́ gan-an, a ò dà wọ́n pè rárá, kó bàa lè yé wọn pé kò sóhun tó ṣàjèjì tàbí ohun tó ń tini lójú nípa ẹ̀yà èyíkéyìí lára wọn.” Bíbẹ̀rẹ̀ lọ́nà yìí máa ń jẹ́ kó rọrùn láti fún wọn ní ìtọ́ni nípa àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Ọ̀pọ̀ òbí á wulẹ̀ sọ fáwọn ọmọ wọn pé ibi tí wọ́n máa ń fi aṣọ ìnura bò lára wọn yẹn ṣe pàtàkì gan-an ni, ẹlòmíì ò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti fọwọ́ kan ibẹ̀.

Dúpẹ́ tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Èmi àti Baálé mi sọ fún ọmọ wa ọkùnrin pé okó ẹ̀ kì í ṣe bèbí ìṣeré, tiẹ̀ nìkan ni. Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ máa fọwọ́ gbé e ṣiré, ì báà jẹ́ àwa òbí ẹ tàbí dókítà pàápàá. Nígbà tá a gbé e lọ sọ́dọ̀ dókítà, mo ṣàlàyé fún un pé iṣẹ́ dókítà ni láti rí sí i pé ara rẹ yá, nítorí ìyẹn nìkan ló fi lè fọwọ́ kan ibẹ̀.” Àwọn òbí méjèèjì ni wọ́n máa ń dígbà bá ọmọ náà sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì máa ń fi í lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ìgbà tí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kàn án níbi tí kò yẹ tàbí tí wọ́n bá ṣe ohun tó ni ín lára ni kó máa wá sọ fáwọn. Àwọn ògbógi nípa ìtọ́jú ọmọ àti béèyàn ṣe lè dènà ìbọ́mọdé ṣèṣekúṣe dábàá pé káwọn òbí máa báwọn ọmọ wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náàc máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ gan-an láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa kókó yìí. Orí 32, “Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù,” ní àlàyé tààràtà tó lè fi àwọn ọmọdé lọ́kàn balẹ̀ lórí ọ̀ràn ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe àti bó ṣe ṣe pàtàkì tó fún wọn láti máa dáàbò bo ara wọn. Títí sọ pé: “Ìwé náà ti jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó dáa gan-an tá a lè gbà fìdí ohun tá a ti sọ fáwọn ọmọ wa múlẹ̀.”

Nínú ayé tá à ń gbé lónìí, ó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọdé pé àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n á fẹ́ máa fọwọ́ kan wọ́n níbi tí kò yẹ tàbí tí wọ́n á fẹ́ káwọn ọmọdé máa fọwọ́ kan ibi tí kò yẹ lára tiwọn. Kò yẹ kí ìkìlọ̀ yìí mú káwọn ọmọdé máa bẹ̀rù tàbí kó mú kí wọ́n máa sá fáwọn àgbàlagbà. Heather sọ pé: “Ààbò àwọn ọmọ ni irú ìkìlọ̀ yìí wà fún. Ọ̀kan ṣoṣo ló sì jẹ́ lára ọ̀pọ̀ ìkìlọ̀ mìíràn tí ọ̀pọ̀ lára wọn ò ní í ṣe pẹ̀lú ìṣekúṣe. Kò ba ọmọ mi lẹ́rù rárá ni.”

Lára ohun tó yẹ kó o jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ̀ ni pé kì í ṣe gbogbo ohun tẹ́nì kan bá ní kó ṣe náà ló gbọ́dọ̀ máa ṣe. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tó sì nira ni láti kọ́ ọmọ pé kó jẹ́ onígbọràn. (Kólósè 3:20) Àmọ́ ṣá o, àṣejù lè wọ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Bá a bá kọ́ ọmọ kan pé lábẹ́ ipò èyíkéyìí, ó gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí àgbàlagbà èyíkéyìí ní gbogbo ìgbà, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ò ní pẹ́ bọ́ sọ́wọ́ àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe tètè máa ń kíyè sí àwọn ọmọdé tí wọ́n bá máa ń yára ṣègbọràn jù. Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló yẹ kí wọ́n máa ṣègbọràn sí, pàápàá bónítọ̀hún bá ní kí wọ́n ṣe ohun tí kò dáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn lè dún bí ohun tó ṣòroó ṣe, lójú àwa tá a jẹ́ Kristẹni ohun tó rọrùn gbáà ni. Ohun tó túmọ̀ sí ò ju pé kó o sọ fọ́mọ ẹ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún ẹ pé kó o ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run sọ pé ó burú, o ò gbọ́dọ̀ ṣe é o. Kódà, àwa tá a jẹ́ òbí ẹ gan-an ò gbọ́dọ̀ sọ pé kó o ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé ó burú. Gbogbo ìgbà tẹ́nì kan bá sì ń fẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa ni kó o máa jẹ́ káwa òbí ẹ gbọ́.”

Lákòótán, jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ̀ pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ sọ fún un pé kó pa ọ̀rọ̀ mọ́ láṣìírí fún ẹ. Sọ fún un pé bí ẹnikẹ́ni bá ní kó pa ohunkóhun mọ́ láṣìírí fún ẹ, ṣe ni kó máa wá sọ nǹkan náà fún ẹ. Ká tiẹ̀ wá sọ pé onítọ̀hún fi ohunkóhun dẹ́rù bà á tàbí kó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ ti ṣe ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó, jẹ́ kó mọ̀ pé kò sígbà kankan tó burú pé kó wá fi ẹjọ́ onítọ̀hún sun ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ òbí rẹ̀. Kò yẹ kí irú ìtọ́ni bí èyí bà á lẹ́rù. O lè fi í lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní jẹ́ fọwọ́ kàn án níbi tí kò yẹ, tàbí kí wọ́n sọ fún un pé kó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tàbí kí wọ́n sọ fún un pé kó pa ohun kan mọ́ láṣìírí. Ńṣe ni àwọn ìkìlọ̀ tó dá lórí ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe yìí dà bí ìgbà téèyàn ń ronú nípa ibi tó máa gbà sá jáde bí iná bá ń jó. Ìmúrasílẹ̀ ni gbogbo ẹ̀ wà fún, ó ṣeé ṣe kí ohun tó máa mú kó fi ìkìlọ̀ náà sílò má tiẹ̀ wáyé rárá.

Kọ́ Ọmọ Ẹ Lóhun Tó Lè Fi Gbara Ẹ̀ Sílẹ̀

Ohun kẹta tá a máa jíròrò báyìí ni pé kó o jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ àwọn nǹkan díẹ̀-dìẹ̀-díẹ̀ tó lè ṣe bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni gbìyànjú láti bá a ṣe ohun tí kò tọ́ nígbà tó ò sí níbẹ̀. Ńṣe làwọn kan máa ń jẹ́ kó dà bí ìgbà téèyàn ń ṣeré. Àwọn òbí á béèrè pé “Kí lo máa ṣe bí . . . ?” Ọmọ náà á sì dáhùn nípa sísọ ohun tó máa ṣe. O tún lè bi í pé, “Ká sọ pé a jọ lọ ra nǹkan lọ́jà, tó ò sì ṣàdédé rí mi mọ́ ńkọ́? Báwo lo ṣe máa wá mi kàn?” Ìdáhùn ọmọ náà lè máà rí gẹ́lẹ́ bó o ṣe rò, àmọ́ o lè fàwọn ìbéèrè míì tọ́ ọ sọ́nà, bíi, “Ṣó o rò pé nǹkan míì wà tí ì bá dára jù pé kó o ṣe?”

O lè lo àwọn ìbéèrè míì bẹ́ẹ̀ yẹn láti fi wádìí ohun tọ́mọ kan máa rò pé ó sàn jù kóun ṣe bí ẹnì kan bá gbìyànjú láti fọwọ́ kàn án níbi tí kò yẹ. Bírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ bá tètè máa ń já ọmọ ẹ láyà, o lè gbìyànjú láti sọ ìtàn kan fún un nípa ọmọ mìíràn. Bí àpẹẹrẹ: “Ọmọbìnrin kékeré kan wà pẹ̀lú ìbátan rẹ̀ kan tó fẹ́ràn, àmọ́ ẹni yẹn wá ń gbìyànjú láti fọwọ́ kàn án níbi ti kò yẹ. Kí lo rò pó dáa jù tí ì bá ṣe?”

Kí ló yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ ẹ pé kí wọ́n ṣe bọ́ràn bá rí bíi ti ọmọbìnrin kékeré tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí? Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Bí wọ́n bá lọgun pé ‘Mi ò fẹ́ kéèyàn fọwọ́ kàn mí níbẹ̀ yẹn!’ tàbí ‘Ẹ má dán an wò!’ tàbí ‘Ẹ fi mi sílẹ̀!’ ẹ̀rù á tètè ba ẹni tó fẹ́ fọwọ́ síbi tí kò yẹ náà, á gbọ́wọ́ ẹ̀ padà, á sì wá ibòmíì gbà lọ.” Máa wá àyè díẹ̀díẹ̀ láti jẹ́ kọ́mọ ẹ fi bó ṣe máa ṣe hàn ẹ́. Èyí á jẹ́ kó lè nígboyà láti lọgun pé òun ò fẹ́rú ẹ̀, á lè tètè sá kúrò níbẹ̀, á sì lè tètè fẹjọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sùn ẹ́. Bó bá tiẹ̀ dá bíi pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ye ọmọ kan dáadáa, ó lè tètè gbàgbé ẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù díẹ̀. Nítorí náà, máa tún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe déédéé.

Gbogbo àwọn tó bá wà nípò láti máa tọ́jú ọmọ náà, tó fi mọ́ àwọn tó jẹ́ ọkùnrin lára wọn, ì báà jẹ́ bàbá ẹ̀, ọkọ ìyá ẹ̀, tàbí ìbátan míì tó jẹ́ ọkùnrin, ló yẹ kí ìjíròrò náà ṣojú wọn tàbí kí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí gbogbo àwọn tó bá wà níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ń dọ́gbọ́n sọ ni pé àwọn ò ní jẹ́ bá irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ṣèṣekúṣe. Ó bani nínú jẹ́ pé lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ gan-an ni ọ̀pọ̀ ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ti máa ń wáyé. Àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí á sọ bó o ṣe lè mú kínú ilé jẹ́ ibi ààbò nínú ayé tí wọ́n ti ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe yìí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ògbógi kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe lè má sọ nǹkan kan, wọ́n ṣì máa ń fi hàn lọ́nà míì pé ẹnì kan ti báwọn ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ kan bá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó ti fi sílẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé, bíi kó máa tọ̀ sílé, kó máa lọ́ máwọn òbí ẹ̀ káàkiri, tàbí kí ẹ̀rù máa bà á láti dá wà, ìyẹn lè jẹ́ àpẹẹrẹ pé láburú kan tó ń bà á nínú jẹ́ ti ṣẹlẹ̀ sí i. Kò wá pọn dandan pé kéèyàn máa wo irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé wọ́n ti bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe. Fara balẹ̀ wádìí lọ́dọ̀ ọmọ rẹ kó o bàa lè mọ ohun tó ń dà á lọ́kàn rú, kó o bàa lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un, kó o mú un lọ́kàn lé, kó o sì dáàbò bò ó.

b Kí àlàyé tá à ń ṣe lè rọrùn, a ó máa sọ̀rọ̀ ẹni tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe àti ẹni tí wọ́n ń bá ṣèṣekúṣe bí ẹni pé ọkùnrin ni wọ́n. Àmọ́, tọkùnrin tobìnrin làwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí wúlò fún.

c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tọ́mọ ẹ á lè rí sá tọ̀

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Kọ́ ọmọ ẹ lóhun tó yẹ kó mọ̀ nípa ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ bó ṣe lè gbara ẹ̀ sílẹ̀

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

ÌBỌ́MỌDÉ-ṢÈṢEKÚṢE TI DI ÌṢÒRO TÓ KÁRÍ AYÉ

Lọ́dún 2006, akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè jábọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé fún Àjọ Gbogbo Gbòò ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè. Ìròyìn tó jábọ̀ náà dá lórí àwọn ọmọdé táwọn èèyàn ń fipá mú ṣe ohun tí kò ti ọkàn wọn wá. Ògbógi kan tó ń dáṣẹ́ ṣe ló kó ìròyìn náà jọ fún Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọmọbìnrin tó tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́jọ [150,000,000] àtàwọn ọmọbìnrin tó tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́tàléláàádọ́rin [73,000,000] tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún ni wọ́n “fipá bá lò pọ̀ tàbí ni wọ́n fi agídí bá ní irú ìbálòpọ̀ èyíkéyìí mìíràn.” Iye yẹn mà ti pọ̀ jù o! Àmọ́, ìròyìn náà sọ síwájú sí i pé: “Ó ju iye yìí lọ dáadáa.” Àgbéyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lórí ìwádìí kan tó ti orílẹ̀-èdè méjìlélógún wá fi hàn pé láwọn ibì kan, bá a bá kó ọgọ́rùn-ún obìnrin àti ọgọ́rùn-ún ọkùnrin jọ, mẹ́rìndínlógójì lára àwọn obìnrin náà àti mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lára àwọn ọkùnrin náà ni wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe rí, lọ́nà kan tàbí òmíràn, nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìbátan irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ló pọ̀ jù lára àwọn tó bá wọn ṣèṣekúṣe!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ọ̀NÀ TÍ WỌ́N Ń GBÀ TAN ỌMỌDÉ JẸ

Abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ò ní ṣàìmọ̀ pé bóun bá fagbára ṣe é, ọwọ́ òun ò ní tẹ nǹkan tóun ń wá. Nítorí náà, á kúkú yàn láti máa tan ọmọ náà jẹ díẹ̀díẹ̀. Á kọ́kọ́ wá ọmọ tó máa dójú sọ, èyí tó sábà máa ń jẹ́ ọmọ tó dùn ún tàn jẹ, tó jẹ́ ẹni-o-rí-o-bá-lọ, táá sì ṣeé tì síbí tì sọ́hùn-ún. Lẹ́yìn náà, á wá bó ṣe máa dá wà lóhun nìkan pẹ̀lú ọmọ náà. Ó tún lè gbìyànjú láti fa ojú àwọn òbí ọmọ náà mọ́ra. Àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe mọ béèyàn ṣe ń díbọ́n gan-an ni. Wọ́n á máa ṣe bíi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà àtàwọn tó wà nínú ìdílé tọ́mọ náà ti wá.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe náà á bẹ̀rẹ̀ sí í gbára dì láti bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, á bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe àwọn ohun tó lè mú kóun àtọmọ náà máa fara kanra, bíi kó jẹ́ kójú òun àti tọmọ náà máa ṣe mẹ́rin, kó máa fìfẹ́ hàn sí i, kó máa bá a ṣerépá, tàbí kó máa fọwọ́ kàn án lára. Ó lè máa ra ẹ̀bùn fún un kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú ọmọ náà mọ́ra débi pé á mú un kúrò láàárín àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò rẹ̀, àtàwọn òbí rẹ̀, kó bàa lè dá wà pẹ̀lú rẹ̀ lóun nìkan. Ó tiẹ̀ lè bá a débi tó fi máa sọ fún ọmọ náà pé kó máa pa àwọn àṣírí pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan mọ́ fáwọn òbí ẹ̀. Á ní kò gbọ́dọ̀ sọ fún wọn pé òun ra nǹkan fún un, kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun fẹ́ mú un jáde lọ síbì kan. Kò sí méjì lẹ́yìn irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀ ju pé kó lè bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe lọ. Lẹ́yìn tí ọmọ náà àtàwọn òbí ẹ̀ bá ti wá gbára lé abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe náà tán pátápátá, kí àáyá rẹ̀ bẹ́ sílẹ̀, kó bẹ́ sáré ló kù.

Síbẹ̀ náà, ó ṣeé ṣe kó ṣì máa fọgbọ́n ṣe é dípò tí ì bá fi máa fi agbára tàbí agídí ṣe é. Ó lè lo àǹfààní ti pé ọmọ náà ò mọ púpọ̀ nípa ìbálòpọ̀ láti fi tàn án jẹ, kó wá máa ṣe bíi pé ṣe lòun ń kọ́ ọ, tàbí kó máa sọ fún un pé kó jẹ́ káwọn jọ ṣe eré àrà ọ̀tọ̀ kan tó jẹ́ pé àwọn méjèèjì nìkan làwọn máa mọ̀ nípa ẹ̀. Ó lè gbìyànjú láti fi àwòrán oníhòòhò han ọmọ náà kó bàa lè rò pé kò sóun tó burú nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Bó bá fi lè bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe pẹ́nrẹ́n, ó di pé kó máa wá ọ̀nà tí ọmọ náà ò fi ní sọ fún ẹnikẹ́ni. Ó lè dá onírúurú ọgbọ́n, kó máa dẹ́rù ba ọmọ náà, kó máa sọ pé ohun á fẹjọ́ ẹ̀ sun àwọn òbí ẹ̀, kó máa dá a lẹ́bi, kódà gbogbo ohun tá a sọ yìí ló lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó lè sọ pé: “Ìwọ lo fà á. O ò sọ pé o ò fẹ́.” Ó tún lè sọ pé: “Bó o bá sọ fáwọn òbí ẹ, wọ́n á pe ọlọ́pàá, wọ́n á sì jù mí sẹ́wọ̀n títí láé.” Ó sì lè sọ pé: “Àárín èmi àti ẹ ni kó mọ o. Bó o bá sọ, kò sẹ́ni tó máa gbà ẹ́ gbọ́. Báwọn òbí ẹ bá fi lọ mọ̀ pẹ́nrẹ́n, màá ṣe wọ́n ní jàǹbá.” Kò sírú ọgbọ́nkọ́gbọ́n tàbí ọgbọ́n jàǹbá tírú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè dá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Má máa dá ọmọ ẹ dá ohun tó bá ń ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Rí i pé o kọ́ ọmọ ẹ lóhun tó yẹ kó mọ̀ nípa ìbálòpọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Kọ́ ọmọ ẹ pé kó má ṣe gba gbẹ̀rẹ́, kó sì kọ̀ jálẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́