ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g93 10/8 ojú ìwé 10-13
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
  • Jí!—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Òfin Ìwà Híhù
  • Olórí Ìdílé Tó Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
  • Jẹ́ Kí Ọkàn Àwọn Ọmọ Ẹ Balẹ̀ Nínú Ilé
  • Dá Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe Dúró
  • Òpin Bíbá Àwọn Ọmọdé Ṣèṣekúṣe
  • Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo (Apá Kẹta Nínú Mẹ́rin)
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ọgbẹ́ Ọkàn Àwọn Tí Wọ́n Ti Bá Ṣèṣekúṣe Lọ́mọdé
    Jí!—1991
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
    Jí!—2007
  • Ìṣòro náà Kárí Ayé
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1993
g93 10/8 ojú ìwé 10-13

Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé

Ọmọ ọdún mẹ́sàn-an ni Monique nígbà tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣèṣekúṣe. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé ó máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ wo bí ọmọbìnrin náà ṣe ń bọ́ra sílẹ̀, lẹ́yìn náà ó bẹ̀rẹ̀ sí i lọ sí iyàrá ẹ̀ lóru, á sì máa fọwọ́ kan àwọn ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Nígbà tí ọmọbìnrin yìí yarí, inú bí ọkùnrin náà gan-an. Kódà, ìgbà kan wà tó fi hámà lù ú, ó sì tì í sílẹ̀ látorí àtẹ̀gùn. Monique sọ pé “Kò sí ẹnì kankan tó máa gbà mí gbọ́,” ìyá ẹ̀ gan-an ò ní gbà á gbọ́. Ọkọ ìyá Monique ni èèyànkéèyàn tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣiṣẹ́ ibi yìí.

LỌ́PỌ̀ ìgbà, kì í ṣe àjèjì tàbí ẹnì kan tó ń rìn kiri tó ń fara pa mọ́ sínú igbó ló máa ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. Àwọn tó wà nínú ìdílé ló máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù. Inú ilé ló ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ nínú ilé?

Nínú ìwé tí òpìtàn Dókítà Sander J. Breiner kọ, tó pe orúkọ rẹ̀ ní Slaughter of the Innocents, òpìtàn yìí ṣàyẹ̀wò ohun tó fa bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe lórílẹ̀-èdè márùn-ún kan, ìyẹn orílẹ̀-èdè Íjíbítì, China, Gíríìsì, Róòmù àti Ísírẹ́lì. Ó wá kíyè sí i pé ìwà bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, àmọ́ ìwà burúkú yìí pọ̀ gan-an láwọn ìlú mẹ́rin yòókù tí ọ̀làjú ti bá. Kí ló fà á? Ìdí ni pé a ti kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, èyí sì mú kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Ní gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run, wọ́n máa ń yẹra fún bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. Lóde òní àwọn ìdílé nílò àwọn ìlànà pàtàkì yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.

Àwọn Òfin Ìwà Híhù

Ǹjẹ́ àwọn òfin tó wà nínú Bibeli ń nípa lórí ìdílé rẹ bí? Bí àpẹẹrẹ, Léfítíkù 18:6 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ẹnì kan tí í ṣe ìbátan rẹ̀ láti tú ìhòhò rẹ̀: Èmi ni OLÚWA.” Lọ́nà kan náà ìjọ Kristẹni lónìí ń tẹ̀ lé àwọn òfin lílágbára tó lòdì sí gbogbo onírúurú ìfipábánilòpọ̀. Tí Kristẹni kan bá bá ọmọdé kan ṣèṣekúṣe, ńṣe ni wọ́n á yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́, tó túmọ̀ sí pé wọ́n á lé e kúrò nínú ìjọ.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

Bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ni tí ẹni tó dàgbà bá ń bá ọmọdé lò láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Lára irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni pé kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọdé ní tààràtà tàbí láti ihò ìdí. Ohun kan náà ni tó bá ki ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ sẹ́nu ọmọ náà, tó bá ní kó máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ òun tàbí tí òun náà ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀, ọmú rẹ̀, ìdí rẹ̀ tàbí tó ń hùwà èyíkéyìí tá a lè pè ní ìṣekúṣe. Ó sábà máa ń jẹ́ ohun tí Bibeli pè ní àgbèrè tàbí por·neiʹa. Ó sì tún wà lára àwọn ìwà tí Bíbélì pè ní “ìwà-èérí.”—Gálátíà 5:19-21; wo Ilé-Ìṣọ́nà ti September 15, 1983, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ní ojú ìwé 30.

Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ṣàyẹ̀wò irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ pa pọ̀. Diutarónómì 6:6, 7 rọ̀ wá pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ. Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, ati nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, ati nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ati nígbà tí ìwọ bá dìde.” Tó o bá fẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ yìí wọ àwọn ọmọ ẹ lọ́kàn, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wàá máa sọ ọ́ fún wọn. Ó máa gba pé kó o máa bá wọn jíròrò nígbà gbogbo, kó o sì máa gbọ́ tẹnu wọn. Àtìgbàdégbà ló yẹ kí bàbá àti ìyá máa tẹ òfin Ọlọ́run nípa ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn àti ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi ṣe àwọn òfin náà.

O lè lo àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì, irú bíi ti Támárì àti Ámínónì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Dáfídì láti jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé kò yẹ kí ẹnikẹ́ni bá wọn lò pọ̀ títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wọn.— Jẹ́nẹ́sísì 9:20-29; 2 Sámúẹ́lì 13:10-16.

Ó yẹ káwọn tó wà nínú ìdílé máa bọ̀wọ̀ fáwọn ìlànà yìí. Níbì kan ní Ìlà Oòrùn Ayé, ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń bá ìbátan wọn ṣèṣekúṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ilé tó ti mọ́ wọn lára pé kí àwọn òbí àtàwọn ọmọ jọ máa sùn pa pọ̀ kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ lówó láti gba iyàrá míì. Lọ́nà kan náà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kò yẹ kí tẹ̀gbọ́n tàbúrò tó jẹ́ ọkùnrin àtobìnrin máa sun orí ibùsùn kan náà, kódà kò yẹ kí wọ́n máa sun iyàrá kan náà tí wọ́n bá ti ń dàgbà. Tí ilé wọn ò bá tiẹ̀ tóbi tí wọn ò sì ní iyàrá tó pọ̀, àwọn òbí ṣì gbọ́dọ̀ fọgbọ́n pinnu ibi tí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin á máa sùn sí.

Bíbélì ka mímu ọtí para léèwọ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ó lè jẹ́ kéèyàn hùwà pálapàla. (Òwe 23:29-33) Ìwádìí kan fi hàn pé, nǹkan bí ìpín ọgọ́ta sí àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n bá lò pọ̀ ló sọ pé òbí àwọn ti mutí yó nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ṣèṣekúṣe.

Olórí Ìdílé Tó Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́

Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe pọ̀ gan-an nínú àwọn ìdílé tó jẹ́ pé apàṣẹwàá ni ọkọ. Èrò náà pé àwọn obìnrin wulẹ̀ wà fún ìgbádùn àwọn ọkùnrin lásán ta ko ìlànà Ìwé Mímọ́. Àwọn ọkùnrin kan máa n lo èrò burúkú yìí láti bá ọmọ wọn obìnrin lò pọ̀ tí wọn ò bá rí gbogbo ohun tí wọ́n ń fẹ́ látọ̀dọ̀ ìyàwó wọn. Irú àwọn ìwà burúkú yìí lè mú káwọn obìnrin kan pàdánù èrò ìmọ̀lára wọn. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ ni kò tiẹ̀ ń lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn mọ́. (Fi wé Oníwàásù 7:7.) Ìwádìí kan tún fi hàn pé nígbà tí àwọn bàbá kan kò bá sí nílé torí pé wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣiṣẹ́ nítorí àtigbọ́ bùkátà ìdílé, nígbà míì èyí máa ń mú kí ìbálòpọ̀ wáyé láàárín ìyá àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ? Ṣé ìwọ ọkọ máa ń fi ọwọ́ gidi mú ipò orí àbí ṣe lo máa ń di ojúṣe yẹn lé ìyàwó rẹ lórí? (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ṣé o máa ń fi ìfẹ́, ọlá àti ọ̀wọ̀ bá ìyàwó rẹ lò? (Éfésù 5:25; 1 Pétérù 3:7) Ṣé o máa ń gba ojú ìwòye rẹ̀ rò?

(Jẹ́nẹ́sísì 21:12; Òwe 31:26, 28) Àwọn ọmọ rẹ ńkọ́? Ṣé ohun iyebíye ni wọ́n jẹ́ lójú ẹ? (Orin Dáfídì 127:3) Àbí ṣe lo máa ń wò wọ́n bí ẹrù ìnira débi pé á rọrùn fáwọn míì láti kó wọn nífà? (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 12:14.) Mú àwọn èrò burúkú èyíkéyìí ti kò bá Ìwé Mímọ́ mu kúrò lọ́kàn ẹ, kó o lè dáàbò bo ìdílé ẹ lọ́wọ́ àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe.

Jẹ́ Kí Ọkàn Àwọn Ọmọ Ẹ Balẹ̀ Nínú Ilé

Ọ̀dọ́bìnrin kan tá a máa pè ní Sandi sọ pé: “Nínú ìdílé wa, ṣe la yapa síra wa, a sì máa ń dá wà. Gbogbo èyí sì lè mú kó rọrùn láti ṣèṣekúṣe.” Dídá nìkan wà, fífọwọ́ líle koko mú nǹkan àti pípa gbogbo nǹkan mọ́ láṣìírí lè fa àkóbá, kò bá Bíbélì mu, ó sì máa ń sábà ṣẹlẹ̀ láwọn ilé tí wọ́n ti ń bára wọn ṣèṣekúṣe. (Fi wé 2  Sámúẹ́lì 12:12; Òwe 18:1; Fílípì 4:5.) Jẹ́ kí ara tu àwọn ọmọ ẹ nínú ilé. Ilé yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ibi tí àwọn ọmọ á ti ní òmìnira láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, tí wọ́n á rí ìṣírí gbà, tí wọ́n á sì ti lè sọ̀rọ̀ fàlàlà.

Bákan náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọdé. A lè gbá wọn mọ́ra, a lè fọwọ́ kàn wọ́n lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, a lè di ọwọ́ wọn mú tàbí ká sáré kiri inú ọgbà pẹ̀lú wọn. Má ṣe fawọ́ àwọn nǹkan yìí sẹ́yìn nítorí àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Kọ́ awọn ọmọ rẹ nípa gbígbóríyìn fún wọn, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ọ́ lógún, kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. Sandi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Màmá mi gbà pé téèyàn bá ń gbóríyìn fún ọmọ, ó máa di agbéraga.” Odindi ọdún mẹ́wàá ni wọ́n fi bá Sandi lò pọ̀, kò sì sọ fún ẹnikẹ́ni. Tọ́mọ kan bá lọ ń wo ara rẹ̀ bíi pé òun ò wúlò, òun ò gbọ́n tàbí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ òun, ó máa ń rọrùn fún irú ọmọ bẹ́ẹ̀ láti kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe pàápàá tẹ́ni náà bá ń yìn ín tó sì ń fìfẹ́ hàn sí i.

Ẹnì kan tó bá ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọmọdékùnrin lò pọ̀ fún odindi ogójì (40) ọdún sọ pé àwọn ọmọ tó nílò ọ̀rẹ́ tí wọ́n lè finú hàn lòun máa rí mú jù. Torí náà, má jẹ́ kọ́mọ ẹ kó sínú pańpẹ́ yìí.

Dá Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe Dúró

Nígbà tí Jóòbù kojú àdánwò tó le gan-an, ó sọ pé: “Agara ìwà ayé mi dá mi tán, èmi ó tú àròyé mi sóde lọ́dọ̀ mi, èmi ó máa sọ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.” (Jóòbù 10:1) Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn òbí tí rí i pé àwọn á ṣe ara wọn láǹfààní táwọn bá ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. Ìwé The Harvard Mental Health Letter sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ohun tó ń jẹ́ kí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe gbilẹ̀ sí i ni pé àwọn èèyàn sábà máa ń fojú burúkú wo ọkùnrin tó bá sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe fipá bá òun lò pọ̀ lọ́mọdé.” Ó jọ pé àwọn ọkùnrin tí kò wá ìrànlọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn lò pọ̀ lọ́mọdé máa ń di abọ́mọdé ṣèṣekúṣe táwọn fúnra wọn bá dàgbà. Ìwé The Safe Child Book ròyìn pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọkùnrin tó ń bọ́mọdé lò pọ̀ ló jẹ́ pé wọ́n ti bá àwọn náà lò pọ̀ lọ́mọdé tí wọn ò sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Torí náà, wọ́n máa ń bá àwọn ọmọ míì lò pọ̀ kí wọ́n lè fi ìbínú àti ìrora wọn hàn.—Tún wo Jóòbù 7:11; 32:20.

*Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ni wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé, àmọ́ ìyẹn ò fi dandan sọ pé kí ẹni tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé náà di abọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Ìdí sì ni pé èyí tó dín sí ìdá mẹ́ta nínú àwọn tí wọ́n bá lò pọ̀ ní kékeré ló di abọ́mọdé ṣèṣekúṣe.

Ó máa ń túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti bá ọmọ ṣèṣekúṣe tí ìyá wọn ò bá borí ẹ̀dùn ọkàn tó ní nígbà tí wọ́n bá òun náà lò pọ̀ ní kékeré. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé àwọn obìnrin tí wọ́n bá lò pọ̀ lọ́mọdé sábà máa ń fẹ́ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ abọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Síwájú sí i, tí ìyá kan ò bá tíì borí ẹ̀dùn ọkàn tó ní nígbà tí wọ́n bá òun náà lò pọ̀ ní kékeré, ó lè ṣòro fún un láti jíròrò ọ̀rọ̀ àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Tí wọ́n bá sì bá ọmọ rẹ̀ lò pọ̀, ó lè má mọ̀, tó bá sì wá mọ̀, ó lè má ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Ìyẹn á wá mú káwọn ọmọ náà túbọ̀ jìyà ìwà àìbìkítà ìyá wọn.

Torí náà, irú àwọn nǹkan yìí lè jẹ́ kí ìbọ́mọdé lò pọ̀ máa gbilẹ̀ sí i láti ìran kan dé òmíì. Lóòótọ́, àwọn kan tí wọ́n bá lò pọ̀ ní kékeré máa ń pinnu pé àwọn ò ní sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ní kékeré fún ẹnikẹ́ni, wọ́n sì máa ń borí ẹ̀dùn ọkàn wọn, ìyẹn dáa. Àmọ́ fún ọ̀pọ̀, ìrora yẹn ti máa ń pọ̀ jù fún wọn, ó sì máa ń di dandan pé kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ bóyá kí wọ́n lọ rí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n lè borí ẹ̀dùn ọkàn wọn. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ rí ìrànlọ́wọ́ gbà kí wọ́n sì fòpin sí àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe tó ti nípa lórí ìdílé wọn. Wọn ò kàn fẹ́ jókòó gẹlẹtẹ kí wọ́n sì máa káàánú ara wọn.—Wo Jí! ti March 8, 1992, ojú ìwé 3 sí 11.

Òpin Bíbá Àwọn Ọmọdé Ṣèṣekúṣe

Tó o bá lo àwọn ìsọfúnni tá a ti jíròrò yìí dáadáa, ó máa ṣòro fáwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe láti rí ọmọ ẹ mú. Bó ti wù kó rí, rántí pé àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ ni, ó sì lè jẹ́ ẹnì kan tó o fọkàn tán. Wọ́n máa ń lo ọgbọ́n àgbàlagbà láti fi mú àwọn ọmọdé. Ó ṣeni láàánú pé nígbà míì, ó máa ń jọ pé àwọn kan mú ìwà abèṣe tí kò ṣeé fẹnu sọ yìí jẹ.

Àmọ́, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. (Jóòbù 34:22) Tí wọn ò bá ronú pìwà dà, Ọlọ́run ò ní dárí jì wọ́n, ó sì máa tú àṣírí wọn tó bá yá. (Fi wé Mátíù 10:26.) Ó tún máa fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. Jèhófà ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ tí gbogbo irú àwọn ẹni burúkú bẹ́ẹ̀ ò ní sí mọ́, ó máa ‘fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ ayé,’ kìkì àwọn ọlọ́kàn tútù àti ẹni pẹ̀lẹ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn míì ló máa ṣẹ́ kù. (Òwe 2:22; Orin Dáfídì 37:10, 11, 29; 2 Pétérù 2:9-12) Ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló jẹ́ ká ní ìrètí àgbàyanu yìí. (1 Tímótì 2:6) Ìgbà yẹn nìkan ni bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe máa dópin.

Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wa. Wọ́n ṣeyebíye gan-an! Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ló máa ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. (Fi wé Jòhánù 15:13.) Tí a kò bá dáàbò bo àwọn ọmọ wa, àbájáde rẹ̀ ò ní dáa. Àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, nǹkan ńlá la ṣe fún wọn yẹn. Torí pé wọn ò ní kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, ọkàn wọn á sì balẹ̀. Àwọn náà á lè sọ bíi ti onísáàmù kan pé: “Emi ó wí fún Ọlọ́run pé, Ìwọ ni ààbò àti odi mi; Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀ lé.”—Orin Dáfídì 91:2.

Ẹnì kan tí ìbátan rẹ̀ bá lò pọ̀ ní kékeré fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Ìṣekúṣe máa ń ba ayé àwọn ọmọdé jẹ́, kì í jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹnikẹ́ni, ọkàn wọn kì í sì í balẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká dáàbò bo àwọn ọmọ wa. Kódà, ìsinsìnyí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tún ayé mi tò. Kí wá nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ míì?”

Ṣó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀?

Ẹ Máa Tẹ́tí Sáwọn Ọmọ!

NÍ BRITISH COLUMBIA, lórílẹ̀-èdè Kánádà, wọ́n ṣèwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti mọ irú iṣẹ́ táwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe kan ń ṣe. Àwọn ọgbọ̀n (30) ni wọ́n ṣèwádìí nípa wọn, ohun tí wọ́n sì rí bani lẹ́rù gan-an. Àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (2,099) ni wọ́n ti bá lò pọ̀. Ìdajì wọn ló jẹ́ àwọn ẹni táwọn èèyàn fọkàn tán bí olùkọ́, pásítọ̀, àwọn olùdarí àtàwọn tó ń tọ́jú àwọn ọmọdé. Dókítà kan tó ń tọ́jú eyín tó sì jẹ́ ẹni àádọ́ta (50) ọdún ti bá àwọn ọmọ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ṣèṣekúṣe láàárín ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26).

Síbẹ̀, The Globe and Mail of Toronto sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn mọ̀lẹ́bí ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe, àtàwọn míì kì í fẹ́ kí ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe náà sọ̀rọ̀ síta. Bákan náà, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ ẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe náà kì í fẹ́ kí wọ́n jẹ́wọ́. Irú àwọn nǹkan yìí ti jẹ́ kí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe gbilẹ̀ sí i.”

Àwọn ọmọ kan ti fẹjọ́ àwọn tó bá wọn ṣèṣekúṣe sùn. Àmọ́ The Globe and Mail sọ pé “àwọn òbí ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe kì í gba àwọn ọmọ wọn gbọ́ tí wọ́n bá fẹjọ́ sùn wọ́n.” Yàtọ̀ síyẹn, òṣìṣẹ́ ìjọba kan ní Jámánì sọ pé ìwádìí kan fi hàn pé ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe sábà máa ń fẹjọ́ sun àwọn àgbàlagbà tó ìgbà méje kí wọ́n tó gbà wọ́n gbọ́.

“Wá Ìrànlọ́wọ́ Báyìí”

“TÓ BÁ jẹ́ pé ọkùnrin ni ẹ́, tó o sì ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, o lè máa rò pé, ‘Ọmọ náà ń gbádùn ẹ̀,’ tàbí ‘Ohun tó fẹ́ nìyẹn,’ àbí ‘Mò ń kọ́ ọ nípa ìbálòpọ̀ ni.’ Tó o bá nírú èrò yìí, ṣe lo kàn ń parọ́ tan ara ẹ. Ẹni tá à ń pè lọ́kùnrin kì í bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Tó bá sì jẹ́ lóòótọ́ lo fẹ́ràn ọmọ náà, yé bá a ṣèṣekúṣe! Wá ìrànlọ́wọ́ báyìí.”​—Ìkéde kan tí wọ́n ṣe fún gbogbo èèyàn tó wà nínú ìwé By Silence Betrayed.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́