Ọgbẹ́ Ọkàn Àwọn Tí Wọ́n Ti Bá Ṣèṣekúṣe Lọ́mọdé
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ann sọ pé: “Inú ara mi máa ń bí mi. Gbogbo ìgbà ni mo sì máa ń dá ara mi lẹ́bi pé mi ò ṣe nǹkan kan láti dẹ́kun ìwà yìí. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó ṣe mí bíi pé oníṣekúṣe ni mí.”
Obìnrin míì tó ń jẹ́ Jill sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò tẹ́gbẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni inú mi máa ń bà jẹ́, tí mo sì máa ń ronú pé mi ò wúlò, kódà mo máa ń ronú pé ó sàn kí n kú.”
ÌWÉ The Right to Innocence, látọwọ́ Beverly Engel sọ pé: “Bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe jẹ́ ìwà burúkú gbáà, tó ń tẹni lógo, tó sì ń ṣàkóbá fún èrò àti ara ọmọdé. Ìwà burúkú yìí sì lè sọ ayé ọmọ kan dìdàkudà.”
Bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn ọmọ tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe máa ń yàtọ̀ síra.a Ìdí ni pé ìwà ọmọ kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra, bí kálukú wọn sì ṣe máa ń ronú àti bí wọ́n ṣe lè mú nǹkan mọ́ra tún máa ń yàtọ̀ síra. Ohun míì tó tún máa ń pinnu bó ṣe máa rí lára ọmọ náà ni bí ẹni tó bá a ṣèṣekúṣe ṣe jẹ́ sí i, irú ìṣekúṣe tó ṣe gan-an, iye ìgbà tí ìṣekúṣe náà wáyé, ọjọ́ orí ọmọ náà àtàwọn nǹkan míì. Bákan náà, tí ọwọ́ bá tẹ ọ̀daràn náà, tí ọmọ tó bá ṣèṣekúṣe sì tètè rí ìrànlọ́wọ́ tó nílò, ẹ̀dùn ọkàn ọmọ náà lè dín kù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe ló máa ń ní ọgbẹ́ ọkàn tó le gan-an.
Ìdí Tó Fi Máa Ń Fa Ọgbẹ́ Ọkàn Tó Lékenkà
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tírú ìwà bẹ́ẹ̀ fi máa ń fa ọgbẹ́ ọkàn tó lékenkà. Oníwàásù 7:7 sọ pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” Tí àgbàlagbà bá ṣe bíi wèrè lábẹ́ ìnilára, ẹ fojú inú wo bí ìwà ìkà tó burú jáì ṣe máa rí lára ọmọdé, pàápàá tí ẹni tó hùwà burúkú náà bá jẹ́ òbí tó fọkàn tán. Ó ṣe tán, àsìkò tó gbẹgẹ́ gan-an ni ìgbà tọ́mọ kan wà ní kékeré torí pé ìgbà yẹn ló ń dàgbà nípa tara àti nípa èrò inú. (2 Tímótì 3:15) Àsìkò yẹn ni àwọn ọmọdé máa ń kọ́ ìwà tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, á sì mọ̀ pé òun jẹ́ ẹni iyì. Bó ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ àwọn òbí rẹ̀, á tún kẹ́kọ̀ọ́ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àti béèyàn ṣe ń fọkàn tánni.—Sáàmù 22:9.
Dókítà J. Patrick Gannon sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fáwọn ọmọ tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe láti fọkàn tán ẹnikẹ́ni.” Ṣe lẹni tó bá ọmọ náà ṣèṣekúṣe rẹ́ ẹ jẹ, ó sọ ọ́ dìdàkudà, ó sì lò ó láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn.b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ò lóye ipa tí ìṣekúṣe tẹ́ni náà ń bá wọn ṣe máa ní lórí wọn, ẹ̀rù máa ń ba ọ̀pọ̀ nínú wọn tẹ́ni náà bá fẹ́ hùwàkiwà yìí, ojú máa ń tì wọ́n, inú sì máa ń bí wọn.
Àwọn kan sọ pé bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ni “ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó burú jù lọ.” Èyí mú ká rántí ìbéèrè kan tí Jésù béèrè, ó ní: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì—òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí?” (Mátíù 7:9) Àmọ́ ẹni tó bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ò fìfẹ́ hàn sọ́mọ náà rárá àti rárá, dípò bẹ́ẹ̀ “òkúta” burúkú, ìyẹn ìṣekúṣe lẹ̀bùn tó fún ọmọ yẹn.
Ìdí Tó Fi Máa Ń Pẹ́ Kí Ọgbẹ́ Ọkàn Náà Tó Jinná
Òwe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Ó dájú pé ẹ̀kọ́ táwọn òbí bá fi kọ́ ọmọ láti kékeré máa ń wà lọ́kàn rẹ̀ títí ayé. Báwo ló ṣe máa rí tó bá jẹ́ pé ohun tí òbí kan gbìn sí ọmọ rẹ̀ lọ́kàn ni pé kó má ṣe kọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe? Báwo ló ṣe máa rí tí wọ́n bá kọ́ ọ pé ìṣekúṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí i? Báwo ló ṣe máa rí tí wọ́n bá jẹ́ kó rí ara ẹ̀ bí ẹni tí kò wúlò, tó sì jẹ́ oníṣekúṣe? Kò sí àní-àní pé irú èrò bẹ́ẹ̀ lè wà lọ́kàn ọmọ náà títí ayé. Bó ti wù kó rí, ti pé wọ́n bá ẹnì kan ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé kò túmọ̀ sí pé ó máa hùwàkiwà tó bá dàgbà. Síbẹ̀, ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ ká lóye ìdí táwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé fi máa ń ronú tàbí hùwà lọ́nà kan.
Onírúurú nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì tó lékenkà. Àwọn míì máa ń dá ara wọn lẹ́bi nígbà gbogbo, ojú máa ń tì wọ́n, wọ́n sì máa ń bínú lódìlódì. Ní ti àwọn kan, ó lè ṣòro fún wọn láti fi ìmọ̀lára hàn. Àwọn míì máa ń rí ara wọn bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan, tí ò sì lè dáàbò bo ara rẹ̀. Sally tí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan bá ṣèṣekúṣe sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá bá mi ṣèṣekúṣe, mi ò kì í lè ṣe nǹkan kan, màá kàn máa wò sùù bí ẹni tí ò lè sọ̀rọ̀. Màá máa ronú pé kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi?” Dókítà kan tó ń jẹ́ Cynthia Tower sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé máa ń wo ara wọn bí ẹni ẹ̀tẹ́.” Wọ́n lè fẹ́ ọkùnrin táá máa lù wọ́n, kí wọ́n máa ṣe bí ẹni tí ò lè gbèjà ara ẹ̀, kí wọ́n má sì dáàbò bo ara wọn tẹ́nì kan bá halẹ̀ mọ́ wọn.
Bó ṣe sábà máa ń rí, nǹkan bí ọdún méjìlá (12) ni ara àwọn ọmọdé fi máa ń múra sílẹ̀ fún àwọn ìmọ̀lára tí wọ́n máa ń ní tí wọ́n bá bàlágà. Àmọ́, tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ọmọ kan ṣèṣekúṣe láti kékeré, àwọn ìmọ̀lára yìí lè pàpọ̀jù fún un bó ṣe ń dàgbà. Ìwádìí kan fi hàn pé, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kẹ́ni náà gbádùn ìbálòpọ̀ lẹ́yìn tó bá ṣègbéyàwó. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Linda sọ pé: “Ìbálòpọ̀ wà lára ohun tó ṣòro jù fún mi nígbà tí mo ṣègbéyàwó. Ó máa ń ṣe mí bíi pé bàbá mi ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ẹ̀rù á sì máa bà mí.” Ṣùgbọ́n bó ṣe máa ń rí lára àwọn míì yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Jill sọ pé: “Ìṣekúṣe wọ̀ mí lẹ́wù débi pé mo di ajá ìgboro, kódà ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí mi ò mọ̀ rí.”
Ó lè ṣòro fáwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe láti ní àjọṣe tó ṣe gúnmọ́ pẹ̀lú àwọn míì. Àwọn kan kì í fẹ́ bá ọkùnrin sọ̀rọ̀, ó sì máa ń ṣòro fún wọn láti fi ara wọn sábẹ́ ẹni tó wà nípò àṣẹ. Àwọn míì kì í lọ́rẹ̀ẹ́ tàbí kí ayọ̀ má wà nínú ìgbéyàwó wọn torí pé àwọn náà lè fẹ́ jẹ gàba lórí àwọn míì. Àwọn míì sì rèé, wọ́n lè má fẹ́ sún mọ́ ẹnikẹ́ni rárá àti rárá.
Àwọn kan tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe máa ń kórìíra ara wọn, wọ́n sì lè fẹ́ ṣe ara wọn léṣe. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Reba sọ pé: “Ti pé ara mi máa ń dìde tẹ́ni náà bá fẹ́ bá mi ṣèṣekúṣe máa ń jẹ́ kí inú ara mi bí mi.” Kò yani lẹ́nu pé oríṣiríṣi nǹkan nirú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe láti gbé èrò ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kúrò lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan kì í jẹun dáadáa,c àwọn kan sì máa ń ṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́. Àwọn míì máa ń mutí lámujù tàbí kí wọ́n máa lo oògùn olóró. Àwọn míì tiẹ̀ máa ń ṣe ara wọn léṣe. Reba sọ pé: “Mo máa ń fi nǹkan ya ara mi, mo sì máa ń fi èékánná ya ọwọ́ mi tàbí kí n máa fi iná jó ara mi. Ó máa ń ṣe mí bíi pé ohun tó tọ́ sí mi nìyẹn.”
Àmọ́ ṣá o, má ṣe ronú pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe. Àwọn nǹkan míì wà tó lè mú kéèyàn máa ṣe ara ẹ̀ léṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé àwọn míì tó máa ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ara wọn ni àwọn tó dàgbà nínú ilé tí ò tòrò rárá. Àwọn òbí wọn lè máa lù wọ́n nílùkulù, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, kí wọ́n pa wọ́n tì tàbí kó jẹ́ pé ọ̀mùtí làwọn òbí yẹn tàbí kí wọ́n máa lo oògùn olóró.
Àkóbá Tẹ̀mí
Àkóbá tó burú jù tí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe máa ń ṣe ni pé ó máa ń ba àjọṣe tẹ́nì kan ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ìdí ni pé bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe jẹ́ “ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Tẹ́nì kan bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, tó sì rẹ́ ẹ jẹ, kò ní jẹ́ kọ́mọ náà lóye ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ọmọ náà ò sì ní máa ronú lọ́nà tó tọ́. Èyí lè mú kí ọmọ náà máa jó rẹ̀yìn nípa tẹ̀mí, kó sì máa hùwàkiwà.
Ìwé Facing Codependence látọwọ́ Pia Mellody sọ pé: “Ìwà ìkà èyíkéyìí tí wọ́n bá hù sọ́mọdé máa ń ṣàkóbá fún un nípa tẹ̀mí torí pé kò ní jẹ́ kọ́mọ náà fọkàn tán ẹnikẹ́ni tó wà nípò àṣẹ.” Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ellen sọ pé: “Mi ò kì í rí Jèhófà bíi bàbá torí pé ẹni tó rorò tó sì ń dẹ́rù bani ni mo ka ẹnikẹ́ni tó jẹ́ bàbá sí.” Arábìnrin míì tó ń jẹ́ Terry sọ pé: “Mi ò kì í ka Jèhófà sí Bàbá. Lóòótọ́ mo gbà pé òun ni Ọlọ́run, Olúwa, Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ, àmọ́ mi ò rí i bíi bàbá rárá àti rárá!”
Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn tó ní irú èrò yìí jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí tàbí pé wọn ò nígbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe ń sapá láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì fi hàn pé wọ́n lókun nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, ẹ wo bó ṣe máa rí lára wọn tí wọ́n bá ka ẹsẹ Bíbélì bíi Sáàmù 103:13, tó sọ pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” Wọ́n lè gbà pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ yẹn sọ. Àmọ́ torí pé bàbá wọn ò fìfẹ́ hàn sí wọn, ó lè ṣòro fún wọn láti lóye ẹsẹ Bíbélì yẹn débi táá fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn!
Bíbélì rọ̀ wá pé ká dà “bí ọmọdé” níwájú Ọlọ́run torí pé àwọn ọmọdé lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n máa ń fọkàn tánni, wọn ò sì dákan mọ̀. Àmọ́ ó máa ń ṣòro fáwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè má fẹ́ sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wọn tí wọ́n bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. (Máàkù 10:15) Ó sì lè ṣòro fún wọn láti fi ọ̀rọ̀ Dáfídì tó wà nínú Sáàmù 62:7, 8 sílò tó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi àti ògo mi wà. Àpáta lílágbára mi, ibi ìsádi mi wà nínú Ọlọ́run. Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà. Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.” Àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lè má fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ yẹn torí pé wọ́n máa ń dá ara wọn lẹ́bi, ó sì máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò wúlò. Ẹnì kan tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí sọ pé: “Mo gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀ lóòótọ́. Àmọ́, mo máa ń ronú pé irú mi kọ́ ló yẹ kó wà níbẹ̀.”
Òótọ́ ni pé bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe máa ń yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, kò ṣòro fáwọn kan láti rí Jèhófà bíi bàbá onífẹ̀ẹ́, ó sì rọrùn fún wọn láti gbàdúrà sí i látọkànwá. Èyí ó wù kó jẹ́, tó bá jẹ́ pé wọ́n ti bá ẹ ṣèṣekúṣe rí nígbà tó o wà lọ́mọdé, á dáa kó o ronú lórí ipa tí ìwà burúkú yìí ti ní lórí ìgbésí ayé rẹ. Àwọn kan lè ti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣì ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún ẹ, fọkàn balẹ̀. Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, ọgbẹ́ ọkàn rẹ á jinná.
a Ìjíròrò wa dá lórí ohun tí Bíbélì pè ní por·neiʹa, ìyẹn àgbèrè. (1 Kọ́ríńtì 6:9; fi wé Léfítíkù 18:6-22.) Èyí sì ní nínú, gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe. Lára àwọn ìwà burúkú míì ni, kẹ́nì kan máa fi ìhòòhò rẹ̀ han ọmọdé, kó máa wo ìhòòhò ọmọdé tàbí kó máa fi àwòrán oníhòòhò han ọmọdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwà yìí kì í ṣe por·neiʹa ní tààràtà, síbẹ̀ wọ́n máa ń ṣàkóbá fún ọmọ tí wọ́n bá ṣe irú ẹ̀ sí.
b Àwọn ọmọdé máa ń fọkàn tán àwọn àgbàlagbà. Torí náà tí mọ̀lẹ́bí, ẹ̀gbọ́n tàbí ẹlòmíì tí wọn ò mọ̀ rí bá bá wọn ṣèṣekúṣe, ìwà ọ̀dàlẹ̀ gbáà lẹni yẹn hù sí wọn.
c Wo Jí! December 22, 1990 lédè Gẹ̀ẹ́sì.