Ìṣòro náà Kárí Ayé
Ọ̀NÀ bíburú jáì tí wọ́n gbà pa àwọn ọmọ tí kò nílé nípakúpa ní Brazil tún jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn tí ń fi hàn pé ó rọrùn láti ṣèpalára fún àwọn ọmọ tí a kọ̀ sílẹ̀. Ìròyìn láti orílẹ̀-èdè yẹn sọ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé ni wọ́n ń pa lọ́dọọdún.
A ń ṣèpalára yánnayànna fún àwọn ọmọdé tí a ń kọ lù ní Dunblane, Scotland, àti Wolverhampton, ilẹ̀ England, àti ní ọ̀pọ̀ àgbègbè mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, fojú inú wo ìyà tí ó jẹ Maria, ọmọ ọdún méjìlá, tí ó jẹ́ ọmọ òrukàn láti Àǹgólà tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ tí ó sì lóyún. Lẹ́yìn náà, wọ́n fipá mú un láti fẹsẹ̀ rin nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún lé ogún [320] kìlómítà, ẹ̀yìn ìyẹn ni ó bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé tí ó lo ọ̀sẹ̀ méjì péré láyé. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni àìsàn àti àìjẹun kánú pa Maria.
Ìròyìn Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) sọ ní ọdún 1992 pé, “‘gbígbé ogun dìde sí àwọn ọmọdé’ jẹ́ ìhùmọ̀ ọ̀rúndún ogún.” Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí Àjọ UNICEF gbé jáde ní ọdún 1996, ojú ìwòye àwọn kan ni pé ‘ìran àwọn ọ̀tá ọjọ́ iwájú, tí í ṣe àwọn ọmọ tí àwọn ọ̀tá bí pàápàá ni a gbọ́dọ̀ mú kúrò.’ Alálàyé kan nípa òṣèlú sọ nípa rẹ̀ pé: “Láti lè pa àwọn eku ńláńlá, o gbọ́dọ̀ pa àwọn eku kéékèèké.”
Mílíọ̀nù méjì ọmọdé ni wọ́n ti ṣìkà pa láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá. Àwọn mílíọ̀nù mẹ́rin mìíràn ti di abirùn, afọ́jú, tàbí kí ọpọlọ wọn ti bàjẹ́ nítorí ọṣẹ́ tí ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ ṣe, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti máa bá ìgbésí ayé nìṣó pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ogun ti sọ di aláìnílé. Abájọ tí a fi pe àkọlé ìròyìn kan ní: “Àwòrán Ìwà Ìkà Ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ Tí Ogun Ń Fojú Àwọn Ọmọdé Rí.”
Àwọn ìwà ìkà bíburú jáì tí a ń hù sí àwọn ọmọdé wọ̀nyí fi hàn pé kò sí ìgbatẹnirò mọ́, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ọmọdé wà nínú ewu, kì í ṣe ni àwọn orílẹ̀-èdè kan bí kò ṣe kárí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ níyà ni wọ́n tún hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí.
Àwọn Tí Wọ́n Fọkàn Tán Ló Dà Wọ́n
Híhùwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọmọ kan lè dá ọgbẹ́ ayérayé sí i lọ́kàn. Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì tó bá jẹ́ pé òbí kan, tàbí ọ̀rẹ́, tàbí atọ́nisọ́nà kan ló hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọmọ náà. Bí ọ̀ràn nípa àwọn òbí tó ń hùwà àìdáa sí ọmọ wọn ṣe burú tó ni a lè rí dájú nígbà tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ń tẹ gbajúmọ̀ abánikẹ́dùn kan láago lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí a pè ní “Ìbẹ̀rù Láìfọhùn: Títú Ìhùwà Àìdáa sí Àwọn Ọmọdé Fó àti Fífi Òpin Sí I,” tí olókìkí Oprah Winfrey ṣe olóòtú rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Olùgbé-sinimá-jáde, Arnold Shapiro, sọ ohun tí a ṣàyọlò rẹ̀ nínú ìwé àtìgbàdégbà Children Today pé: “Èyí tí ó bani lẹ́rù jù nínú àwọn ìtẹniláago nípa ìṣòro náà ni èyí tó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọdé tí ń fi ìbẹ̀rù sọ̀rọ̀, tí wọ́n fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìrora ìwà àìdáa tí a ń hù sí wọn, yálà nípa líluni tàbí bíbáni-ṣèṣekúṣe.”
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ṣèrànwọ́ gan-an láti mú èrò pé àwọn tí ń hùwà àìdáa sí ọmọdé jẹ́ àwọn àjèjì tí wọ́n síngbọnlẹ̀ tí ìrísí wọn sì ń dẹ́rù bani kúrò. Shapiro parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ pé, òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé “ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìwà àìdáa náà ló jẹ́ àwọn òbí àti àwọn ìbátan tí ó súnmọ́ wọn jù ló ń hù ú sí wọn.” Ìwádìí mìíràn fẹsẹ̀ àwárí yìí múlẹ̀, ó sì tún fi hàn pé nígbà mìíràn, àwọn ọ̀rẹ́ tí ìdílé gbẹ́kẹ̀ lé máa ń fa ojú ọmọ náà àti ìdílé mọ́ra ṣáájú kí wọ́n tó hùwà àìdáa tí wọ́n ti múra sílẹ̀ dáadáa láti hù sí ọmọ náà. Ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan ni ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí ó burú jù.
Ọ̀ràn nípa àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ni ewu mìíràn tí àwọn ọmọdé ń dojú kọ jákèjádò ayé. Lẹ́tà ìròyìn Trends & Issues in Crime and Criminal Justice túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí: “Ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe túmọ̀ sí níní òòfà ìbálòpọ̀ sí àwọn ọmọdé. . . . Ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe tún ní híhu àwọn ìwà ọ̀daràn bíi fífipá-báni-lòpọ̀, ìwà àìtọ́ àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ríru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè lára àwọn ọmọdé nínú.”
Ìròyìn tí ń kóni nírìíra nípa àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn tí ń bọ́mọdé-ṣèṣekúṣe, tó sì ń fi ọ̀kánjúwà kó àwọn ọmọdé nífà ìbálòpọ̀, ti ń pọ̀ jù káàkiri àgbáyé. (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 7.) Àwọn èwe lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń dojú kọ ìṣòro náà. Nígbà tí àwọn ọkùnrin oníwàkiwà bá tàn wọ́n jẹ tán, tí wọ́n sì bá wọn ṣe ìṣekúṣe wọn óò wá halẹ̀ mọ́ wọn tàbí kí wọ́n kẹ́ wọn lákẹ̀ẹ́bàjẹ́ láti tù wọ́n lójú kí wọ́n lè máa rí wọn lò nínú “ẹgbẹ́” náà. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń wéwèé tí wọ́n sì ń hu ìwà búburú yìí sábà máa ń jẹ́ àwọn aṣáájú tó lókìkí láwùjọ tí wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan àti ààbò àwọn ọlọ́pàá àti àwọn aṣòfin.
Ìṣekúṣe tí àwọn àlùfáà ń bá àwọn ọmọdé ṣe tún burú rékọjá ààlà. Àwọn ìròyìn káàkiri àgbáyé fi hàn bí ìwà àìdáa tí àwọn àlùfáà ń hù sí àwọn ọmọdé ti pọ̀ tó, wọ́n máa ń ṣe é ní orúkọ Ọlọ́run pàápàá nígbà mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, àlùfáà Áńgílíkà kan tí a ti dá lẹ́bi sọ fún ọmọ ọdún mẹ́wàá tó bá ṣèṣekúṣe pé “Ọlọ́run ń gba ẹnu òun [àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì náà] sọ̀rọ̀, ohunkóhun tí òun bá ṣe tàbí ohunkóhun tí [ọmọdékùnrin náà] bá ṣe ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí tí ó sì tọ̀nà.”
Ní Ọsirélíà, àtúnyẹ̀wò ìwé náà, The Battle and the Backlash: The Child Sexual Abuse War, sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn àlùfáà àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà ní ipò tí ó ṣeé fọkàn tán ṣe ń hùwà àìdáa sí àwọn ọmọdé. Ó ni ó dà bí pé àníyàn àwọn àjọ tí ọ̀rán kàn ni láti má ṣe jẹ́ kí orúkọ tiwọn fúnra wọn bàjẹ́ àti láti dáàbò bo ara wọn dípò kí wọ́n dáàbò bo àwọn ọmọ tí kò ní olùrànlọ́wọ́ náà.
Àwọn Ìyọrísí Amúnibanújẹ́
Ọmọdé sábà máa ń gbẹ́kẹ̀ léni pátápátá láìkọminú. Nítorí náà, bí a bá dà wọ́n, ó máa ń ní ipa bíburú jáì lórí èrò inú ọmọdé tó bá lójijì náà. Ìtẹ̀jáde náà, Child Abuse & Neglect sọ pé: “Àwọn ènìyàn àti àwọn àgbègbè kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ibi ààbò tàbí ìfẹ̀yìntì ti wá di èyí tí a ń kà kún eléwu àti ohun abanilẹ́rù. Ìgbésí ayé ọmọdé wá di èyí tí a kò lè sọ bó ṣe máa rí tí a kò sì lè ṣàkóso.”
Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí irú ìhùwà àìdáa sí wọn bẹ́ẹ̀, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ti ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ọmọdé kan ti di ẹni tí kò lè bẹ́gbẹ́ ṣe àti ẹni tó ní àrùn ọpọlọ nínú ìgbésí ayé wọn, tí èyí sì bá wọn dàgbà. Ìwà ọ̀dàlẹ̀ yìí máa ń ṣèpalára gan-an níwọ̀n bí a ti yan ọmọ náà jẹ nítorí pé ó jẹ́ ọmọdé. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí a hùwà àìdáa sí ni kì í sọ—kókó yìí sì máa ń fi àwọn tí ń hùwà àìdáa sọ́mọdé lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni.
Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, ẹ̀rí nípa ìhùwà-àìdáa-sọ́mọdé ti ń gbilẹ̀, tó fi jẹ́ pé irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ti pọ̀ gan-an tí a kò fi lè sẹ́ ẹ mọ́ tàbí kí a ṣàìnáání rẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ gbà pé dídá ìhùwà-àìdáa-sọ́mọdé dúró jẹ́ iṣẹ́ kíkọyọyọ tí kò sì rọrùn. Àwọn ìbéèrè tí a wá ń béèrè báyìí ni pé: Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè dáàbò bo àwọn ọmọ wa ní ti gidi? Báwo ni àwa tí a jẹ́ òbí ṣe lè dáàbò bo ogún tí Ọlọ́run fún wa kí a sì máa bójú tó ìgbésí ayé àwọn ọmọ wa tí wọ́n rọrùn láti pa lára? Ta ni àwọn òbí lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀nà Tí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet Ń Gbà Mú Ọ̀daràn
Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá gbé ìgbésẹ̀ tí ó jẹ́ ọ̀kan lára èyí tí ó lágbára jù tí wọ́n tí ì gbé lòdì sí ríru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè lára àwọn ọmọdé lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn ọlọ́pàá ní orílẹ̀-èdè méjìlá gbógun ti ilé àwọn tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún tí a fura sí pé wọ́n jẹ́ abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Ó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] àwòrán tí wọ́n fi ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe àwọn ọmọdé sókè tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọ̀daràn kan ṣoṣo tó fi Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ibùjókòó.
Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ṣe kòkáárí ìwádìí olóṣù márùn-ún náà lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet sọ pé: “Láìsí-tàbítàbí àwọn àwòrán náà yóò run ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn nínú ṣáá ni.” Tọkùnrin tobìnrin ni àwọn ọmọ tí wọ́n lò nínú àwọn àwòrán náà, àwọn kan nínú wọn kò tilẹ̀ ju ọmọ ọdún méjì lọ. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ Belgium sọ pé àwọn àwòrán orí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet náà ni “èyí tí ó tí ì burú jù lọ nínú gbogbo àwòrán tí wọ́n fi ń ru ìfẹ́ ọmọdé sókè sí ìṣekúṣe. . . . Ó burú débi pé àwọn kan bá ọmọ ara wọn ṣèṣekúṣe láti lè gbé àwòrán tó gbàfiyèsí jù jáde.” Ọkùnrin kan kó àwọn fọ́tò ara rẹ̀ níbi tí ó ti ń fipá bá ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dàpọ̀ wọnú ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà rẹ̀.
Àwọn tó wà lára àwọn tí a fura sí ni àwọn olùkọ́, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, akẹ́kọ̀ọ́ òfin, akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn, ọ̀gá síkáòtù, oníṣirò owó, àti ọ̀jọ̀gbọ́n yunifásítì kan.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ohun abúgbàù kan ló rọ ọmọkùnrin yìí lọ́wọ́ ọ̀tún
[Credit Line]
Fọ́tò UN/DPI tí Armineh Johannes yà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]
Fọ́tò ILO/J. Maillard