ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g93 10/8 ojú ìwé 5-8
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa?
  • Jí!—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ!
  • Jẹ́ Kí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Kúnná
  • Gbọ́n Bí Ejò
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
    Jí!—2007
  • Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Nínú Ilé
    Jí!—1993
  • Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Jí!—1993
g93 10/8 ojú ìwé 5-8

Báwo Ni A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa?

“O ò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni. Ọ̀rọ̀ àṣírí ni o.”

“Kò sí ẹnikẹ́ni tó máa gbà ẹ́ gbọ́.”

“Bí o bá sọ, àwọn òbí rẹ máa kórìíra ẹ. Wọ́n á mọ̀ pé ẹ̀bi rẹ ni.”

“Ṣé o ò fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ mi àtàtà mọ́ ni?”

“Mo mọ̀ pé o ò ní fẹ́ kí n lọ sẹ́wọ̀n, àbí o fẹ́ bẹ́ẹ̀?”

“Màá pa àwọn òbí ẹ tí o bá sọ fún ẹnikẹ́ni.”

LẸ́YÌN lílo àwọn ọmọdé láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn, lẹ́yìn tí wọ́n gba ìfọ̀kànbalẹ̀ wọn, tí wọ́n sì sọ àwọn ọmọ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yìí di ìdàkudà, wọ́n tún máa ń wá nǹkan míì. Ìyẹn sì ni pé káwọn ọmọ náà ṣe ọ̀rọ̀ náà LÁṢÌÍRÍ. Káwọn ọmọ náà lè panu mọ́, wọ́n máa ń dójú ti àwọn ọmọ náà, wọ́n máa ń fìyà jẹ wọ́n, wọ́n sì máa ń bo gbogbo ẹ̀ mọ́lẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ọmọ náà lè fi gbèjà ara ẹ̀ ni wọ́n ti gbà lọ́wọ́ ẹ̀ báyìí, ìyẹn sì ni pé kò lè sọ̀rọ̀ síta débi táwọn àgbàlagbà míì á fi dáàbò bò ó.

Ohun tó bani nínú jẹ́ jù ni pé ṣe ló dà bíi pé àwọn àgbàlagbà gan-an ń gbé ìwà burúkú yìí lárugẹ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọn ò sapá láti mọ̀ nípa ewu tó wà nínú ìwà burúkú yìí, wọn kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ìtàn àròsọ ni wọ́n sì máa ń gbà gbọ́. Àìmọ̀kan, ìsọfúnni tí kò jóòótọ́ àti ìpanu mọ́ ń dáàbò bo àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe, kì í ṣe àwọn ọmọ náà ló ń dáàbò bò.

Bí àpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n ṣe Àpérò Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì lórílẹ̀-èdè Canada, wọ́n sọ pé “bí gbogbo èèyàn ṣe panú mọ́” ti mú kí bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe gbilẹ̀ láàárín àwọn àlùfáà Kátólíìkì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìwé ìròyìn Time sọ pé ìpanumọ́ nípa ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan tímọ́tímọ́, ti wulẹ̀ mú “kí ìwà ìkà tó burú gan-an” yìí gbilẹ̀ nínú ìdílé.

Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé ìròyìn Time sọ pe ìpanumọ́ yìí ò lè wà pẹ́ títí. Kí nìdí? Ní ṣókí, ìdálẹ́kọ̀ọ́ lá mú ká borí ẹ̀. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Gbogbo àwọn ọ̀mọ̀wé ló fohùn ṣọ̀kan pé ohun ìjà tó gbéṣẹ́ jù lọ lòdì sí bíbá ọmọdé lò pọ̀ ni pé káwọn ọmọdé mọ bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ara wọn.” Káwọn òbí lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ ewu tó wà níbẹ̀. Ẹ má ṣe fàyè gba àwọn èrò tó ń dàábò bo àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe dípò àwọn ọmọdé.—Wo àpótí tí ó wà nísàlẹ̀.

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ!

Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ fún ọmọkùnrin rẹ̀ pé ìmọ̀, ọgbọ́n àti agbára ìrònú lè dáàbò bò ó kúrò ní “ọ̀nà búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà.” (Òwe 2:10-12) Ìyẹn kì í ha ṣe ohun tí àwọn ọmọdé nílò gẹ́lẹ́? Ìwé pẹlẹbẹ Child Molesters: A Behavioral Analysis ti FBI sọ èyí lábẹ́ àkòrí náà “Àpẹẹrẹ Òjìyà Pípé”: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ló jẹ́ pé àwọn òbí wọn kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.” Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ jẹ́ “àpẹẹrẹ òjìyà pípé.” Kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ káwọn ọmọ ti mọ àwọn ìyípadà tó máa bá ara wọn kí wọ́n tó bàlágà. Àìmọ̀kan máa ń kó ìdààmú àti ìtìjú bá wọn, ó sì máa ń mú kí wọ́n kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe.

Wo Jí! ti February 22, 1992 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 3-11, àti July 8, 1992, ojú ìwé 30.

Wọ́n fipá bá obìnrin kan tá a máa pè ní Janet lò nígbà tó wà lọ́mọdé, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n tún fipá bá àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì lò pò. Ó sọ pé: “Nígbà tá à ń dàgbà, wọn kì í bá wa sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ rárá, torí náà, ojú máa ń ti èmi náà láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bó sì ṣe rí nígbà tí mo bímọ tèmi náà nìyẹn. Kì í ṣòro fún mi láti bá àwọn ọmọ míì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, àmọ́ ojú máa ń tì mí láti bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Mo mọ̀ pé kò dáa, torí ó máa ń rọrùn fáwọn ọmọ láti kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe tí wọn ò bá mọ nǹkan kan nípa ìbálòpọ̀.”

Àtikékeré ló ti yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ wa nípa bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ara wọn. Tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ lórúkọ àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bíi òbò, ọmú, ihò ìdí, okó, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ẹ̀yà ara yìí dáa, àmọ́ ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án. “Ẹlòmíì ò lè fọwọ́ kàn án, Mọ́mì àti Dádì náà ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kódà dókítà ò lè fọwọ́ kàn án àfi tí Mọ́mì àbí Dádì bá sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.” Ohun tó dáa jù ni pé àwọn òbí méjèèjì gbọ́dọ̀ wà níjòókòó táwọn òbí bá máa sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fáwọn ọmọ wọn, tó bá sì jẹ́ pé ọ̀dọ̀ alágbàtọ́ ni wọ́n ń gbé, wọ́n gbọ́dọ̀ sọ ọ́ fún wọn níṣojú àwọn míì tó ṣeé ṣe kí wọ́n jọ wà nínú ilé.

*Ó dájú pé àwọn òbí ló máa wẹ àwọn ọmọ wọn jòjòló, wọ́n sì máa ń pààrọ̀ aṣọ wọn. Láwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fọ ẹ̀yà ìbímọ wọn. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé kó o kọ́ àwọn ọmọ ẹ bí wọ́n á ṣe máa dá wẹ̀ láti kékeré. Kódà, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ọmọdé sọ pé ó dáa káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè dá wẹ̀ tí wọ́n bá ti pé ọmọ ọdún mẹ́ta.

Nínú ìwé The Safe Child Book, Sherryll Kraizer sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé lè sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ bá wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n lè kígbe, wọ́n tiẹ̀ lè pariwo mọ́ onítọ̀hún, àmọ́ wọn kì í fẹ́ yájú sí wọn. Nípa báyìí ó yẹ kí àwọn ọmọdé mọ̀ pé àwọn àgbàlagbà kan máa ń ṣe nǹkan tí kò dáa àti pé kò yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí ẹnikẹ́ni tó ní kí wọ́n ṣe ohun tí kò dáa. Ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ ọmọ kan ní gbogbo ẹ̀tọ́ láti sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣe kọ̀ láti jẹ oúnjẹ aláìmọ́ èyí táwọn àgbààgbà nílẹ̀ Bábílónì fẹ́ kí wọn jẹ.—Dáníẹ́lì 1:4, 8; 3:16-18.

Ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n bi wọ́n pé “Kí ni wọ́n máa ṣe tí tibí tàbí tọ̀hún bá ṣẹlẹ̀?” Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè béèrè pé: “Kí lo máa ṣe tí olùkọ́ rẹ bá sọ fún ọ pé kí o lu ọmọ míì?” Tàbí: “Tí màmá ẹ, bàbá ẹ, òjíṣẹ́ tàbí ọlọ́pàá kan ba sọ fún ẹ pe kí o bẹ́ sílẹ̀ láti orí ilé gíga kan, kí lo máa ṣe?” Ìdáhùn ọmọ náà lè má kún rẹ́rẹ́ tó tàbí kí ó tiẹ̀ má tọ̀nà, má jágbe mọ́ ọ. Àwọn ìbéèrè náà kò gbọdọ̀ mú kí ọmọ rẹ jáyà tàbí kó bẹ̀rù. Kódà àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pe ó ṣe pàtàkì kọ́kàn àwọn ọmọ balẹ̀ táwọn òbí bá fẹ́ kọ́ wọn nírú ẹ̀kọ́ yìí.

Lẹ́yìn ìyẹn, kọ́ àwọn ọmọ ẹ pé kí wọ́n kọ̀ jálẹ̀ tẹ́nì kan bá ń bá wọn ṣeré akọ, tó sì ń mú kí wọ́n ní èrò tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, béèrè pé, “Tí ọ̀rẹ́ Mọ́mì tàbí ọ̀rẹ́ Dádì kan bá fẹ́ fẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà tí kò tọ́, kí lo máa ṣe?” Ó sábà máa ń dáa káwọn ọmọ naa ṣàṣefihàn ohun tí wọ́n máa ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó ṣe tán, àwọn kan sọ pé ibi eré la ti ń mọ òótọ́ ọ̀rọ̀.

*Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé tó o bá fi dandan lé e pé ọmọ ẹ gbọ́dọ̀ fẹnu ko gbogbo ẹni tó bá sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́nu tàbí kí wọ́n gbá wọn mọ́ra, ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ wọn ò ní wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Torí náà, àwọn òbí kan ti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ohun tí wọ́n lè sọ tẹ́nì kan bá ní kí wọ́n ṣe ohun tí kò bá wọn lára mu.

Ní ọ̀nà kan náà, àwọn ọmọdé lè dènà àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè béèrè pé: “Tẹ́nì kan bá sọ fún ẹ pé, ‘Ṣé o mọ̀ pé ìwọ ni mo fẹ́ràn jù, ṣé o ò fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ mi mọ́ ni?’” Kó o wá gbọ́ ohun tọ́mọ náà máa sọ. Tọ́mọ náà bá ti rí i pé ìtànjẹ lásán nìyẹn, jẹ́ kó mọ ohun tó yẹ kó ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, tún sọ àwọn nǹkan míì fún un. O lè bí i pé: “Tí ẹnì kan bá sọ fún ẹ pé, ‘Ṣé o fẹ́ bà mí nínú jẹ́ ni?’ Kí ni wàá sọ?” Jẹ́ kí ọmọ náà mọ ohun tó yẹ kó sọ lójú ẹsẹ̀, títí kan ohun tó yẹ kó ṣe láì fàkókò ṣòfò. Ẹ rántí pé àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe máa ń fẹ́ dán àwọn ọmọdé náà wò kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Torí naa, ẹ gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ yín láti kọ̀ jálẹ̀ kí wọ́n sì sọ pé, “Màá fẹjọ́ rẹ sùn.”

Jẹ́ Kí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Kúnná

Má ṣe fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ sí ìjíròrò ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Àwọn ọmọdé nílò ọ̀pọ̀ àsọtúnsọ. Ìwọ lo máa pinnu bó ṣe yẹ kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà gbòòrò tó. Àmọ́, rí i dájú pé ó kúnná, ó sì ṣe kedere láì fi ohunkóhun bò.

Bí àpẹẹrẹ, rí i dájú pé o jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ̀ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ sọ fún un pé kó fi ọ̀rọ̀ kan bò. Sọ fún un pé àgbàlagbà kankan ò gbọ́dọ̀ sọ fún un pé kó fi ọ̀rọ̀ kankan bò fáwọn òbí ẹ̀, tó bá ṣẹlẹ̀, ó gbọ́dọ̀ sọ. Jẹ́ kí ọmọ náà mọ̀ pé gbogbo ìgbà ló gbọ́dọ̀ máa sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹ̀yin òbí ẹ̀, bó bá tiẹ̀ ti sọ fún onítọ̀hún pé òun ò ní sọ. Jẹ́ kí ọkàn ọmọ náà balẹ̀ pé kò sóhun táá ṣẹlẹ̀. (Fi wé Númérì 30:12, 16.) Táwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe bá mọ̀ pé ọmọ kan ti ṣàìgbọràn sáwọn òbí ẹ̀, wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ ọn pé “Mi ò ní fẹjọ́ ẹ̀ sùn tíwọ náà ò bá ti ní fẹjọ́ mi sùn.” Torí náà, fi àwọn ọmọ náà lọ́kàn balẹ̀ pé tírú ẹ̀ bá ṣẹ̀lẹ̀ kò sóhun tó máa ṣe wọ́n tí wọ́n bá fẹjọ́ ẹni náà sùn. Ohun tó yẹ kí wọn ṣe gan-an nìyẹn, ṣe ni kí wọ́n fẹjọ́ ẹ̀ sùn kíákíá.

Rí i dájú pé o ki ọmọ ẹ láyà débi pé ohunkóhun tíì bá jẹ́ táwọn èèyàn kéèyàn yẹn bá sọ ò ní dẹ́rù bà á. Àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe kan tiẹ̀ máa ń pa àwọn ẹranko kéékèèké níṣojú àwọn ọmọ tí wọ́n bá lò pọ̀, wọ́n á wá halẹ̀ mọ́ wọn pé bí wọ́n ṣe máa pa àwọn òbí wọn nìyẹn tí wọ́n bá sọ. Àwọn míì sì máa ń sọ fáwọn ọmọ náà pé tí wọ́n bá sọ àwọn máa bá ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn lò pọ̀. Torí náà, kọ́ àwọn ọmọ ẹ pe wọ́n gbọ́dọ̀ fẹjọ́ sùn tí ẹnikẹ́ni bá ṣerú ẹ̀ fún wọn, láìka ohunkóhun tó lè sọ, wọ́n gbọ́dọ̀ sọ.

Bíbélì ló dáa jù tẹ́ ẹ lè fi kọ́ àwọn ọmọ yín. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà lágbára gan-an, Jèhófà sì lè tú àṣírí àwọn èèyànkéèyàn náà. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ mọ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bò wọ́n bó ti wù kí ìhàlẹ̀ náà le tó. (Dáníẹ́lì 3:8-30) Kódà, táwọn èèyàn burúkú bá pa àwa èèyàn Jèhófà lára, Jèhófà lè mú ìbànújẹ́ náà kúrò, kó sì mú kí nǹkan pa dà bọ̀ sípò. (Jóòbù, orí 1, 2; 42:10-17; Aísáyà 65:17) Jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà ń rí ohun gbogbo, títí kan àwọn èèyàn burúkú. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń kíyè sí àwọn èèyàn rere tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dènà àwọn ẹni burúkú.—Fi wé Hébérù 4:13.

Gbọ́n Bí Ejò

Àwọn tó ń bọ́mọdé lò pọ̀ kì í sábà fipá mú wọn, ṣe ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ fọgbọ́n dọ̀rẹ́ àwọn ọmọ náà. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fi ìmọ̀ràn Jésù sílò tó sọ pé ká “gbọ́n bí ejò.” (Mátíù 10:16) Ọ̀nà tó dáa jù táwọn òbí lè gbà dáàbò bo àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n máa bójú tó wọn lójú méjèèjì, kó sì jẹ́ lọ́nà onífẹ̀ẹ́. Àwọn kan tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe máa ń wá àwọn ọmọ tó dá wà níta gbangba, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó lè nífẹ̀ẹ́ sí, kọ́mọ náà lè fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹ̀. Wọ́n lè sọ pé. “Ṣé o fẹ́ràn kẹ̀kẹ́?” “Ṣé o fẹ́ kí n ra fóònù fún ẹ?” “Wá wo àwọn ọmọ ajá tó wà nínú mọ́tò mi.” Lóòótọ́, kò ṣeé ṣe pé kó o máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ nígbà gbogbo, kódà àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọmọdé gbà pé ó yẹ káwọn ọmọ lómìnira láti dá rìn nígbà míì. Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń ṣọ́ra láti má ṣe fún àwọn ọmọ wọn lómìnira nígbà tí wọn ò tíì lè dáàbò ara wọn.

Rí i dájú pé o mọ gbogbo àwọn àgbàlagbà tó sún mọ́ àwọn ọmọ ẹ dáadáa, kó o sì fọgbọ́n pinnu ẹni tó máa bójú tó àwọn ọmọ ẹ tó ò bá sí nílé. Ṣọ́ra fún àwọn tó ń báni tọ́jú ọmọ àmọ́ tó máa ń jẹ́ káwọn ọmọ rẹ ní ìmọ̀lára tó yàtọ̀ tàbí tí kì í jẹ́ kára wọn balẹ̀. Bákan naa, ṣọ́ra fún àwọn ọ̀dọ́langba tó dàbí ẹni pé wọ́n sábà máa ń ṣeré àṣerégèé pẹ̀lú àwọn ọmọdé kékeré, tí wọn kò sì ní àwọn ọ̀rẹ́ tí ó jẹ́ ojúgbà wọn. Ṣàyẹ̀wò àwọn ilé jẹ́lé-ó-sinmi àti ilé ẹ̀kọ́ kínníkínní. Rìn yíká gbogbo ilé naa kí o sì fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́nu wò, kí o fi tìṣọ́ratìṣọ́ra kíyè sí bí wọn ṣe ń bá àwọn ọmọdé lò. Béèrè bóyá o lè yà láti wo ọmọ rẹ ní àwọn àkókò tí wọn kò retí; bí wọn kò ba yọ̀ǹda fún èyí, wá ibòmíràn.—Wo Jí! ti December 8, 1987, ojú ìwé 3-11.

Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ kan ni pé àwọn òbí tó dára jù lọ pàápàá ò lè ṣàkóso ohun gbogbo tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.—Oníwàásù 9:11.

Bí àwọn òbí ba ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n máa lè ṣàkóso ilé wọn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ilé ni wọ́n ti sábà máa ń bá àwọn ọmọdé ṣe ìṣekúṣe jù lọ, ohun tá a máa jíròrò nìyẹn nínú kókó tó kàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́