ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Obìnrin “Tí Ń Pò Ó Rá”
  • Ohun Ìjà Tàbí Ìdàgbàsókè?
  • Ìjàm̀bá Tí Ẹranko Moose Tí Ń Ré Títì Kọjá Ń Fà
  • Ìṣòro Nauru
  • Àrun Sòbìyà Ń Jawà Sílẹ̀
  • Agogo Ọjọ́ Ìparún Sún Síwájú
  • Àwọn Àṣẹ̀dáyé Aròbó Tí A Pa Tì
  • Ìfomipòùngbẹ Lásán Kò Tó
  • Ibojì Lílókìkí ní Ilẹ̀ Íjíbítì Ṣí Sílẹ̀
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbára Dì fún Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé?
    Jí!—2004
  • Ṣópin Ti Dé Bá Ìbẹ̀rù Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ni?
    Jí!—1999
  • Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe Àbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́?
    Jí!—2017
  • Ó Dájú Pé Ewu Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Kò Tíì Kásẹ̀ Nílẹ̀
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àwọn Obìnrin “Tí Ń Pò Ó Rá”

Ìwé ìròyin The Courier, tí Ìparapọ̀ Ilẹ̀ Europe ń tẹ̀ jáde, sọ pé: “Nínú àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ tí a ti ń bá àwọn obìnrin lò ní pẹ̀lẹ́tù bí ó bá kan ọ̀ràn ìlera, ìpíndọ́gba obìnrin 106 sí 100 ọkùnrin ló wà. Òkodoro òtítọ́ kan nìyí nínú ìgbésí ayé.” Ṣùgbọ́n àwọn ìwádìí tí àjọ UN ṣe tún tọ́ka sí òkodoro òtítọ́ mìíràn pé: Ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà bíi China, India, Ilẹ̀ Olómìnira Korea, àti Pakistan, ní ìpíndọ́gba, obìnrin 94 ló wà fún 100 ọkùnrin. Kí ló fà á? Ìwé ìròyin The Courier ṣàlàyé pé: “Ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ sáyẹ́ǹsì ti mú kí ó ṣeé ṣe láti pinnu ẹ̀yà tí ọmọ náà yóò jẹ́ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìlóyún,” ó sì ti mú kí “àìṣedéédéé nínú ìpíndọ́gba iye akọ sí abo tí a ń bí” túbọ̀ pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, ní Ilẹ̀ Olómìnira Korea, ní 1982, nígbà tí a bá fi bí ọmọbìnrin 94, a óò bí 100 ọmọkùnrin, ṣùgbọ́n ní 1989, ìpíndọ́gba yẹ́n ti lọ sílẹ̀ sórí ọmọbìnrin 88 sí 100 ọmọkùnrin. Ìtẹ̀jáde àjọ UN náà, ìwé ìròyin Our Planet, fi kún un pé: “Àkọsílẹ̀ oníṣirò náà ń múni gbọ̀n rìrì: 100 mílíọ̀nù àwọn obìnrin ilẹ̀ Éṣíà ‘ń pò ó rá’ nítorí pípa àwọn ọmọbìnrin ní kékeré àti ṣíṣẹ́yún àwọn ọmọbìnrin.”

Ohun Ìjà Tàbí Ìdàgbàsókè?

Ayé lè fi 100 dọ́là United States ra ìbọn AK-47 kan tàbí ìwọn ìdìpọ̀ egbòogi vitamin-A tí ó pọ̀ tó láti dènà ìfọ́jú láàárín 3,000 ọmọ ọlọ́dún kan. Wọ́n lè fi 100 mílíọ̀nù dọ́là ra mílíọ̀nù 10 ohun abúgbàù inú ilẹ̀ tàbí abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó pọ̀ tó láti dáàbò bo 7.7 mílíọ̀nù ọmọdé lọ́wọ́ àwọn àrùn mẹ́fà tí ń pa ọmọdé. Wọ́n lè fi 800 mílíọ̀nù dọ́là ra yálà ọkọ̀ ogun òfuurufu F-16 tí ó jẹ́ 23, tàbí kí wọ́n fi sọ iyọ̀ di eléròja iodine fún ọdún mẹ́wàá, tí yóò dáàbò bo 1.6 bílíọ̀nù ènìyàn lọ́wọ́ àwọn àrùn tí àìtó èròja iodine lára ń fà, irú bí àìgbékánkán iṣẹ́ ọpọlọ. Nǹkan bí 2.4 bílíọ̀nù dọ́là yóò ra yálà ohun ìja átọ́míìkì abẹ́ omi kan tàbí kí wọ́n fi pèsè omi àti ohun èèlò ìmọ́tótó fún mílíọ̀nù 48 ènìyàn. Níbo ni ayé gbé ohun àkọ́múṣe rẹ̀ lé? Gẹ́gẹ́ bí The State of the World’s Children 1996, ṣe sọ, àwọn ohun ìjà ogun tí a tà fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ní 1994 nìkan jẹ́ àròpọ 25.4 bílíọ̀nu dọ́là, owó tí a ti lè lò sórí ìsapá ìdàgbàsókè.

Ìjàm̀bá Tí Ẹranko Moose Tí Ń Ré Títì Kọjá Ń Fà

Èé ṣe tí ẹranko moose fi ń ré títì kọjá? Ọ̀ràn pàtàkì ni ìbéèrè yìí jẹ́ fún àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè inú igbó tàbí àwọn awakọ̀ àdúgbò àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún arìnrìn àjò afẹ́ ní Newfoundland tí ń lo títì ẹkùn ìpínlẹ̀ náà. Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail sọ pé: “Lọ́dọọdún, nǹkan bí 300 ìjàm̀bá láàárín ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ẹranko moose ló ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn títì Newfoundland, tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ lára wọ́n sì ń yọrí sí ikú àwọn awakọ̀. Ẹranko moose kan tí ó wọ̀n tó 450 kìlógíráàmù lè ṣubú tẹ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan bí àpáta tó yẹ̀ lulẹ̀, kí ó sí ṣekúpani tàbí sọni di aláàbọ̀ ara.” Shane Mahoney ti Ẹ̀ka Ọrọ̀ Àlùmọ́nì Àdánidá sọ pé, wíwulẹ̀ dín iye ẹranko moose tí ó tó 150,000 ní erékùṣù náà nísinsìnyí kù lè ṣàìgbéṣẹ́, nítorí pé, ní àwọn àdúgbò kan, tí iye ẹranko moose kéré, iye ìjàm̀bá pọ̀ gan-an. Àwọn onímọ sáyẹ́ǹsí retí láti mọ ìdí tí ẹranko moose, tí ohun ìrìnnà máà ń dẹ́rù bà lọ́nà àdánidá, fi ń ré títì kọjá, nípa ṣíṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìṣíkiri agbo ẹran.

Ìṣòro Nauru

Nígbà kan rí, a mọ Nauru, orílẹ̀-èdè olómìnira tí ó kéré jù lọ, tí ó sì dá wà jù lọ lágbàáyé, mọ́ ẹwà ilẹ̀ olóoru rẹ̀. Àwọn atukọ̀ ojú omi, ará Europe, tí wọ́n kọ́kọ́ rí erékùṣù oní kìlómítà 20 lóròó níbùú náà ní ọ̀rúndún kejìdínlógún pè é ní Erékùṣù Alárinrin. Bí ó ti wù kí ó rí, kìkì ilẹ̀ etíkun tọ́rọ́rọ́ kan ni ó ṣeé gbé nísinsìnyí, ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sì sọ pé, Nauru ti di “orílẹ̀-èdè tí a ba àyíká rẹ̀ jẹ́ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.” Kí ló fà á? Ìwakùsà láti ojú ilẹ̀. Fún 90 ọdún, a ti ń wa kùsa phosphates, tí ó jẹ́ ìyọrísí ìyàgbẹ́ ẹyẹ láàárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún àti àwọn ohun alààyè tíntìntín inú omi, “ti a wá fi kìkì ìtòjọ gogoro òkúta yọyọ aláwọ̀ eérú, tí ó ní ihò, tí ó sì bani lẹ́rù, tí àwọn kan lára wọ́n ga tó ẹsẹ bàtà 75 [mítà 22], sílẹ̀.” Ooru tí ń jáde láti inú ìdá mẹ́rin nínú márùn-ún tí a ti wa kùsà ní erékùṣù náà tún ti nípa lórí ojú ọjọ́, tí kò fàyè gba ìkùukùu òjò, tí ó sì ń fi ọ̀dá dá ilẹ̀ náà. A retí pé a óò wa apá tí ó kẹ́yìn lára àkójọ kùsa phosphate náà láàárín ọdún márùn-ún. Ọ̀pọ̀ ará Nauru rò pé ọ̀nà àbájáde kan ṣoṣo náà ni láti fi Nauru sílẹ̀, kí wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn ra erékùṣù tuntun kan tí wọ́n lè kó lọ máa gbé.

Àrun Sòbìyà Ń Jawà Sílẹ̀

Ìwé ìròyin The Economist sọ pé: “Lẹ́yìn àrùn ìgbóná, sòbìyà ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àrùn kejì tí ń bá ènìyàn jà, tí a óò pa run. Iye ìṣẹ̀lẹ rẹ̀ tí a ń ròyìn, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 900,000 kárí ayé lẹnu àìpẹ́ yìí, ní 1989, ti lọ sílẹ̀ sí 163,000 ní èṣín, tí ó sì ń lọ sílẹ̀ sí bi ìdajì lọ́dọọdún ní àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ jù lọ.” Ilẹ̀ Sudan ni ọ̀rọ̀ náà ti yàtọ̀, “tí ń fi hàn pé ogun àti àrún jùmọ̀ máa ń rìn pọ̀ ni.” A ti pa sòbìyà, kòkòrò àfòmọ́ kan tí a ń kó láti inú omi, tí ó máa ń bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ekùkù tí kò ṣeé fojú rí, run ní Àárín Gbùngbun Éṣíà, Pakistan, àti àwọn orílẹ̀-ède Áfíríkà mélòó kan. Àwọn àjọ ìlerá ti káwọ́ rẹ̀ nípa lílo àwọn kẹ́míkà tí ń sọ omi di mímọ́, kíkọ́ àwọn ènìyàn láti fi aṣọ sẹ́ omi tí wọ́n ń mu, àti dídí àwọn tí ó ti ní in lọ́wọ́ láti má ṣe wẹ̀ sínú àwọn orísun omi mímu tàbí fẹsẹ̀ wọ́ wọn. Nígbà tí a bá ti gbé e mì, àwọn akọ ń kú lẹ́yìn ìbálòpọ̀, àwọn abó sì lè gùn tó mítà kan ṣáájú kí wọ́n tóó yọ jáde díẹ̀díẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ láti ojú ìléròrò onírora ní ẹsẹ̀ ẹni tí ó bá ní in, tí wọ́n sì máa ń sọ iṣan ara dí aláìlágbára, tí wọ́n sì ń bà á jẹ́.

Agogo Ọjọ́ Ìparún Sún Síwájú

Láìpẹ́ yìí, a ti yí ọwọ́ tí ń ka ìṣẹ́jú lára gbajúmọ̀ agogo ọjọ́ ìparun tí ó wà lẹ́yìn ìwé ìròyin The Bulletin of the Atomic Scientists síwájú pẹ̀lú ìṣẹ́jú mẹ́ta, sún mọ́ ọ̀gànjọ́ òru. Agogo náà ń ṣàpẹẹrẹ bí àgbáyé ṣe sún mọ́ ogun alágbára átọ́míìkì tó. Láti ìgbà ìgbékalẹ̀ rẹ̀ ní 1947, a ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà ní ìgbà 16 ní ìdáhùnpadà sí bí àwọn àlámọ̀rí ayé ṣe ń yí padà. Àkókò tí ó sún mọ́ ọ̀gànjọ́ òru alágbára átọ́míìkì jù lọ—ó ku ìṣẹ́jú méjì—jẹ́ ní ọdún 1953, lẹ́yìn ìbúgbàù bọ́m̀bù eléròja hydrogen kìíní ní United States. Ìgbà tí a yí i padà kẹ́yìn jẹ́ ní 1991, nígbà tí a yí i padà sẹ́yìn sí ìṣẹ́jú 17 ṣáájú ọ̀gànjọ́ òru, nítorí ìfojúsọ́nà fún rere tí a ní lẹ́yìn Ogun Tútù. Yíyí ọwọ́ agogo náà padà sí ìṣẹ́jú 14 fi ìdàníyàn tí ń pọ̀ sí i nípa àìfararọ inú ayé, àìláàbò ìtòjọ pelemọ ohun ìja átọ́míìkì, àti ewu ìpániláyà olóhun ìja átọ́míìkì, hàn. Leonard Rieser, alága ìwé ìròyin The Bulletin, sọ pé: “Àgbáyé ṣì jẹ́ ibi eléwu gan-an síbẹ̀.”

Àwọn Àṣẹ̀dáyé Aròbó Tí A Pa Tì

Ní Ítálì, pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn òfin, ìyá kan lè kọ̀ láti gba àṣẹ̀dáyé ọmọ rẹ̀, kí ó sì fi ẹrù iṣẹ́ wíwá tọkọtaya tí ó bá fẹ́ láti gbà á ṣọmọ sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn aláṣẹ tí ń bójú tó àwọn màjèṣí. Síbẹ̀, láàárín ọdún 1995, iye àwọn ọmọdé tí ó pọ̀ tó 600 ni a pa tì ní gbàrà tí a bí wọn tán, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica, ti ilẹ̀ Ítálì ṣe sọ, “púpọ̀ wọ́n wà nínú garawa ìdalẹ̀nù, àwọn mìíràn lẹ́bàá ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ibùdó ìpèsè ìlera.” Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń wáyé ní àwọn àdúgbò tí ó ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, tí ó sì lọ́rọ̀ jú lọ ní orílẹ̀-èdè náà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àdúgbò tí ó tálákà, tí kò sì ní ìdàgbàsókè rárá. Gẹ́gẹ́ bí Vera Slepoj, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ọ̀nà Ìfìṣemọ̀rònú ti Ítálì, ṣe sọ, èyí jẹ́ “àmì ìkìlọ̀ ìmọ̀lára ikú” tí ó gba àwùjọ kan.

Ìfomipòùngbẹ Lásán Kò Tó

Ọ̀mọ̀wé Mark Davis, ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìṣe àti ìgbòkègbodò eré ìmárale nínú ìgbésí ayé, sọ pé: “Bí ẹnì kán bá ń fomi pòùngbẹ lásán, kì yóò mumi púpọ̀ tó.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò lómi lára tó, nítorí ìmọ̀lára òùngbẹ máa ń wá nígbà tí omi ará bá ti lọ sílẹ̀. Bí ènìyán bá si ṣe ń dàgbà sí i tó, ni agbára ìmọ̀lára òùngbẹ rẹ̀ ń lọ sílẹ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ròyin rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times, a nílò omi lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ojú ọjọ́ bá gbóná tàbí tí ó tutù kọjá ààlà tí ó sì gbẹ, nígbà tí a bá ṣe eré ìmárale tàbí tí a bá febi panú, àti nígbà tí a bá ní oríṣi àrùn èyíkéyìí tí ó ní irú àwọn ipò bí ìgbẹ́ gbuuru, ibà, àti èébì rẹpẹtẹ, èyí tí ń fa ìpàdánù omi ara, nínú. Àwọn tí ń jẹ oúnjẹ oní ṣákítí púpọ̀ nílò omi púpọ̀ sí i láti lè jẹ́ kí ṣákítí náà lè kọjá geere nínú ìfun. Nígbà tí ó ṣeé ṣe kí àwọn èso àti ewébẹ̀ ní ìpín púpọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tí ó jẹ́ omi, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àìní wa ni a ń tẹ́ lọ́rùn nípa mímu omi. Omi ni ó dára jù lọ láti fi pa òùngbẹ, níwọ̀n bí ó ti yára ń dà lára. Bí ohun mímu kán bá ṣe dùn tó ni ó ṣe máa ń pẹ́ tó kí ó tóó dà lára. Àwọn ohun mímu oní sódà lè túbọ̀ pa ọ́ lóùngbẹ gan-an, nítorí o nílò omi láti mú kí ṣúgà náà dà lára. Níwọ̀n bí kaféènì àti ohun mímu ọlọ́tí líle ti máa ń fa àfikún ìtọ̀, gbígbára lé wọ́n lè yọrí sí ìpàdánù omi. Ìwé agbéròyìnjáde Times sọ pé: “Ó kéré pin, àwọn àgbàlagbà gbọ́dọ̀ máa mu ife omi mẹ́jọ, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n jẹ́ ìwọn ounce mẹ́jọ [2.4 dẹ̀sílítà] lóòjọ́.”

Ibojì Lílókìkí ní Ilẹ̀ Íjíbítì Ṣí Sílẹ̀

Ibojì Nefertari ní Àfonífojì Àwọn Ayaba ní Luxor, tí a ti tì pa fún ọ̀pọ̀ ọdún, ni a ti mú padà bọ̀ sípò, tí a sì ti ṣí sílẹ̀ fún àwọn aráàlú. “Mohammed el-Soghayer, olórí ẹ̀ka Ìgbìmọ̀ Àwọn Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé Gíga Jù Lọ ní Luxor sọ pé: ‘Ní ti gidi, ibojì yìí ni ó fani mọ́ra jù lọ ní etídò ìhà ìwọ̀ oòrun Luxor, tàbí ní gbogbo Íjíbítì pàápàá. Ó ṣe kedere pé oníṣẹ́ ọnà tí ó lóye iṣẹ́ jù lọ ní àkókò ìṣàkóso Ramses Kejì ni ó kọ́ ibi ìsìnkú ọlọ́ba yìí nítorí ìfẹ́ ńlá tí ó ní sí Nefertari. Ó fẹ́ kí ó ní ibojì tí ó ṣeé ṣe kí ó dára jù lọ.’” Bí ó ti wù kí ó rí, àkúnya omi, ẹrẹ̀, àti èérún iyanrìn tí ń wọnú rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ba àwọn àwòrán dídán gbinrin, tí ó jojú ní gbèsè, tí ó gba àyè 430 mítà níbùú lóròó náà jẹ́. Lẹ́yìn ìfinúkonú ọlọ́pọ̀ ọdún, agbo àwọn òṣìṣẹ́ kan láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àfìṣọ́raṣe kan ní 1986, láti to àfọ́kù ògiri náà pọ̀, ní lílo àwọn fọ́tò tí Ernesto Schiaparelli, ará Ítálì, ẹlẹ́kọ̀ọ́ nípa ilẹ̀ Íjíbítì, tí ó ṣàwárí ibojì náà, yà. Bí ó ti wù kí ó rí, a ti pààlà sí iye olùṣèbẹ̀wò nítorí ìdàníyàn lórí ọ̀rinrin. Ramses Kejì tún dá Nefertari lọ́lá, nígbà tí ó ya ọ̀kan lára àwọn tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Abu Simbel sí mímọ́ fún un.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́