A Mọyì Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Hungary
Olùkọ́ kan ní Balmazújváros kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsi Watch Tower ní Hungary pé: “Mo ti rí ìwé kan tí ó gba àfiyèsí mi. Bí ó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fí ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí mi. Orúkọ rẹ̀ ni Iwe Itan Bibeli Mi.” Lẹ́yìn tí ó ti di ojúlùmọ̀ ìwé yìí, ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ kan ní Budapest kọ̀wé béèrè pé: “A óò fẹ́ láti béèrè fún 20 ẹ̀dà Iwe Itan Bibeli Mi fún Ilé Ẹ̀kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ No. 6.”
Ẹnì kan láti Balatonboglár tí ó ti ka ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ kọ̀wé pé: “Ìwé náà ń múni ronú, àwọn ìdáhùn tí a gbé karí Bíbélì tí a pèsè nínu rẹ̀ sì péye. Ìwé náà ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni, mo sì rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí mo ní. N óò fẹ́ láti túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ mi lókun sí i. Nítorí náà, bí ó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì ránṣẹ́ sí mi.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyọ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí wọ́n bá ní ìfẹ́ ọkàn láti ní ìmọ Bíbélì púpọ̀ sí i. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan lára àwọn ìwé tí a dárúkọ lókè tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kán kàn sí ọ láti bá ọ jíròrò lóri Bíbélì, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, fún ìsọfúnni síwájú sí i, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5.