ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/22 ojú ìwé 32
  • Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu fún Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu fún Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé
  • Jí!—1997
Jí!—1997
g97 5/22 ojú ìwé 32

Ọjọ́ Ọ̀la Àgbàyanu fún Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé

ÌWÉ agbéròyìnjáde Globe and Mail ti Toronto sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé ìsinsìnyí ni Ilẹ̀ Ayé tí ì móoru jù lọ láti 600 ọdún sẹ́yìn.” Ní 1995, ìgbì ooru kan ní àárín gbùngbùn United States gba ẹ̀mí ènìyàn tí ó lé ní 500 ní Chicago. Àwọn ipò lílégbákan bí èyí ṣẹlẹ̀ sí Íńdíà àti Australia, nígbà tí ilẹ̀ England nírìírí “ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn mímúná jù lọ kẹta láàárín 200 ọdún.”

Kí ló fa èyí? Henry Hengeveld, ògbógi nípa ojú ọjọ́ tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀ka Àyíká ti ìjọba àpapọ̀ ní Kánádà, sọ pé: “Ẹ̀rí púpọ̀ jù lọ tọ́ka sí òtítọ́ náà pé, ipa ìbàjẹ́ tí ó ṣeé fojú rí tí ẹ̀dá ènìyàn ń fà ń fara hàn lójú ọjọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn inú ìwé agbéròyìnjáde Globe and Mail ṣe sọ, “ipò ojú ọjọ́ ṣíṣàjèjì náà bára mu délẹ̀ pẹ̀lú àwọn oríṣi kọ̀ǹpútà tí ń ṣe àpẹẹrẹ ipa ìmóoru ilẹ̀ ayé, tí a lérò pé sísun àwọn epo àkẹ̀kù níkan ló ń ṣokùnfà rẹ̀.”

A ṣì ń jiyàn lórí bóyá ilẹ̀ ayé ń móoru láwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ìran aráyé ń yára lo àyíká ojú ọjọ́ nílòkulò ju bí wọ́n ṣe ń lóye rẹ̀ lọ.”

A láyọ̀ pé Bíbélì sọ fún wa pé ayé “dúró títí láé.” (Oníwàásù 1:4) Èyí jẹ́ nítorí pé Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà Ọlọ́run, kò ní gba ènìyàn tàbí ipá àdánidá mìíràn láyè láti pa á run. Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, òun yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.”—Ìṣípayá 11:17, 18.

Láfikún sí i, Bíbélì mú un dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run ní ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu ní ìpamọ́ fún pílánẹ́ẹ̀tì wa, Ilẹ̀ Ayé, àti fún gbogbo aráyé onígbọràn. “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” Ẹ wo bí a ti kún fún ayọ̀ tó pé ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ ayé wa wà lọ́wọ́ Ọlọ́run, láìkì í ṣe lọ́wọ́ ènìyàn!—Orin Dáfídì 37:11; 72:16; Aísáyà 65:17-25; Pétérù Kejì 3:13.

Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè gba àwọn ìtẹ̀jáde Jí! lọ́jọ́ iwájú, jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè rẹ, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Fọ́tò NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́