“Wíwá Oníṣẹ́ Ọnà Títóbi Jù Lọ Kiri”
Àkọlé tí Jí!, November 8, 1995, gbé jáde nìyẹn. Kókó ẹ̀kọ́ náà mú ìhùwàpadà dídùnmọ́ni wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òǹkàwé jákèjádò àgbáyé.
Amang kọ̀wé wá láti Douala, Cameroon, pé: “Àwọn àpilẹ̀kọ náà nípa lórí mi gan-an nítorí mo fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà, ní pàtàkì, yíyàwòrán àwọn ohun mèremère. Nísinsìnyí, mo lóye rẹ̀ pé Oníṣẹ́ Ọnà kan ń bẹ tí ó tóbi ju Van Gogh, Rembrandt, Da Vinci, àti àwọn mìíràn lọ—kì í ṣe ẹlòmíràn, bí kò ṣe Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀.”
Láti St. Barthélemy, ní French West Indies, Frederick sọ pé: “Ìgbà mẹrin ni mo kà á, nígbà kọ̀ọ̀kan ni mo sì ń kún fún ìmoore nítorí àwọn ohun mèremère tí Ẹlẹ́dàá wa fi fún wa.”
Assunta kọ̀wé wá láti Ítálì pé: “Ó ru ìfẹ́ ọkàn láti máa yàwòrán sókè lọ́kàn mi. Ó mú ìtara ọkàn mi fún ayé tuntun Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i.” Irena sì kọ̀wé wá láti Ilẹ̀ Olómìnira Czech pé: “Nígbà tí a bá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé àkójọpọ̀ àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé, a ní láti sanwó láti wo àwọn iṣẹ́ ọnà, nígbà tí ó jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá gbogbo ẹwà àdánidá ń fi wọ́n fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ lójoojúmọ́.” Aline kọ̀wé wá láti Brazil pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni a ń ní àwọn àpilẹ̀kọ tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì àkópọ̀ ìwà Jèhófà, ìwọ̀nyí wọ̀ mí lọ́kàn. Wọ́n fúnni ní kúlẹ̀kúlẹ̀ púpọ̀ nípa ìṣẹ̀dá tí ó túbọ̀ mú kí ìmọrírì wa fún ìfẹ́ Jèhófà pọ̀ sí i.”
Láti ilẹ̀ olótùútù ti Wisconsin, U.S.A., Anne kọ̀wé wá pé: “Ó ràn mí lọ́wọ́ gidi láti mọyì ẹwà ìṣẹ̀dá. Nígbà míràn, ó máa ń ṣòro láti rí i nígbà òtútù. Lọ́jọ́ tí mo ka àpilẹ̀kọ náà gan-an, mo jáde síta, mo sì kíyèsí èérún omi dídì lára ẹ̀ka kan, ewé kan tí òjò dídì bò, ipa ẹsẹ̀ àwọn ẹranko nínú òjò dídì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ ṣeun fún ìránnilétí nípa bí a ṣe lè mọyì ‘Oníṣẹ́ Ọnà Títóbi Jù Lọ.’”
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti máa gba ìwé ìròyìn yìí déédéé, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.