ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/8 ojú ìwé 32
  • “Mo Nílò Ìṣírí àti Ìrètí”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mo Nílò Ìṣírí àti Ìrètí”
  • Jí!—1996
Jí!—1996
g96 12/8 ojú ìwé 32

“Mo Nílò Ìṣírí àti Ìrètí”

O ha ní ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ ní ìgbà kankan rí bí? Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní òde òní ń ṣe bẹ́ẹ̀. Obìnrin kan láti Fort Smith, Arkansas, kọ ìwé sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, ó sì ṣe àlàyé pé:

“Ìwé yín, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, kún fún ìsọfúnni àti agbára ìsúnniṣe. Mo kà á láti páálí dé páálí ní àárín ìwọ̀nba ọjọ́ mélòó kan. Ó fún mi ní ìrètí pé ní àìpẹ́, ayé tuntun tí a ṣèlérí lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi yóò dé. Mo ń yán hànhàn fún ọjọ́ yẹn.

“Títí di ìgbà náà, mo ń bá wíwà nìṣó nínú ayé yìí yí, ní dídúró de kí ìyẹ́n ṣẹlẹ̀. Ìgbésí ayé asán, tí ń súni, tí kò fara rọ yìí ń mú mi rẹ̀wẹ̀sì gan-an. Mo nílò ìṣírí àti ìrètí. Ẹ sọ pé bí a bá fẹ́, a lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ ètò àjọ yín. Ẹ jọ̀wọ́, ǹjẹ́ ẹ lè jẹ́ kí n mọ ohun tí mo ní láti ṣe kí èyí lè tẹ̀ mí lọ́wọ́? Mo rò pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé yìí yóò fún mi ní ìṣírí.”

Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tàbí bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnì kan wáá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé kan pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́