Ojú ìwé 2
Báwo Ni O Ṣe Lè Bójú Tó Ọ̀ràn Ìnáwó Rẹ? 3-12
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ẹni 3 lára ẹni 4 tí ó ní káàdì ìrajà àwìn ní United States ní ń jẹ gbèsè tí wọ́n wá ń san díẹ̀díẹ̀ ní ìwọ̀n èlé tí ó ga ré kọjá ààlà. Báwo ni àwọn ìdáwóléni náà ṣe pọ̀ tó? Báwo ni o ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ gbèsè?
Ìpakúpa ní Èbúté Arthur—Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣẹlẹ̀? 16
Oníbọn kan yìnbọn pa ènìyàn púpọ̀ ní ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan ju iye àwọn tí a ti pa láàárín ọdún mẹ́rin ṣáájú àkókò náà ní gbogbo ilẹ̀ Tasmania. Kí ló ń fa irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀?
Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú 19
Ka ìtàn amúniláyọ̀ nípa ìgbésí ayé Edward Michalec, tí ó lo ohun tí ó lé ní 50 ọdún gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní Bolivia