“Ó Kọ Ọ́ Sínú Ìwé Agbéròyìnjáde”
Ohun tí ọmọdébìnrin olùmoore kan ní Kánádà sọ nínú lẹ́tà ìdúpẹ́ kan tí ó kọ sí Watch Tower Society nìyẹn. Ó kópa nínú ìdíje ọ̀rọ̀ ìta gbangba kan ní ilé ẹ̀kọ́, ohun tí ó sọ sì dùn mọ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ onídàájọ́ nínú gan-an tí ó fi béèrè pé kí wọ́n gba òun láyè láti tẹ̀ ẹ́ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò.
Báwo ni ọmọdébìnrin náà ṣe yan kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì mi, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdébìnrin, ní ìṣòro òfófó ṣíṣe.” Nítorí náà, ó gbé ìjíròrò rẹ̀ karí ìsọfúnni tí ó kà nínú Jí! Wọ́n tẹ apá kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde nínú The Review, ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò kan ní Ibi Ìtàkìtì Omi Niagara, Ontario, lábẹ́ àkọlé “Òfófó Lè Pani Lára; Báwo Ni Yóò Ṣe Rí Lára Rẹ?”
Kí ni ohun tí ó wú ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ onídàájọ́ náà lórí tó bẹ́ẹ̀? Ṣàkíyèsí àwọn ohun díẹ̀ tí a fà yọ nínú ọ̀rọ̀ ọmọdébìnrin náà: “Òfófó wọ́pọ̀ gan-an láwùjọ òde òní. Ó lè fa ìṣòro púpọ̀, àìróorunsùn àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ń ṣe ìpalára fún ìmọ̀lára. . . .
“Jíjáwọ́ nínú òfófó kò ṣeé ṣe nítorí pé ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti máa sọ̀rọ̀. Ohun kan tí a lè ṣe ni láti ṣàkóso rẹ̀. Àwọn àmọ̀ràn díẹ̀ lórí bí a ṣe lè ṣe èyí ni: 1. Má ṣe lọ́wọ́ nínú òfófó ṣíṣe nípa dídá sí i. 2. Má ṣe tẹ́tí sí òfófó náà. . . . Nípa títẹ́tí sí òfófó, ó lè jọ pé o fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí ó ń sọ. 3. Òfófó tí ń ṣèpalára lè sọ ọ́ di òpùrọ́ pẹ̀lú. 4. Ìmọ̀ràn tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo rẹ̀ ni pé kí o máa ronú kí o tó máa sọ̀rọ̀! Bi ara rẹ léèrè pé ‘Báwo ni yóò ṣe rí lára mi bí wọ́n bá sọ èyí nípa mi?’”
Ọmọdébìnrin náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ṣàmúlò àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́rin yìí, ó sì lè ṣeé ṣe gan-an pé kí o di ẹni tí ó sàn jù.”
Ẹ wo irú ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí èyí jẹ́ fún gbogbo ènìyàn, láìṣe fún àwọn èwe tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nìkan! Jí! ń gbìyànjú láti gbé àwọn ìsọfúnni tí ó bágbà mu, tí ó sì wà lójú ọpọ́n, jáde lórí oríṣiríṣi kókó ọ̀rọ̀. Bí o bá fẹ́ láti máa gba ìwé ìròyìn yìí déédéé, béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà míràn tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.