ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/8 ojú ìwé 22-25
  • Ǹjẹ́ O mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O mọ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
Jí!—1997
g97 2/8 ojú ìwé 22-25

Ǹjẹ́ O mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 25. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Kí ni kò jẹ́ kí Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ agbára láàárín àwọn ènìyàn tí ó wà ní àgbègbè ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀? (Máàkù 6:5, 6)

2. Àwọn irúgbìn méjì wo ni Jésù mẹ́nu bà ní títọ́ka sí ìpamọ́ fínnífínní dórí bínńtín ọ̀ràn ìdámẹ́wàá tí àwọn Farisí ń ṣe? (Lúùkù 11:42)

3. Ẹranko wo ni a lò lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ láti fi bí Jésù yóò ṣe dúró ‘láìyanu’ nígbà tí a bá ń pọ́n ọn lójú hàn? (Aísáyà 53:7)

4. Ta ni àlùfáà àgbà tí a dá lẹ́bi nítorí tí ó bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ju Jèhófà lọ? (Sámúẹ́lì Kíní 2:27-29)

5. Kí ni Jésù “bá wí lọ́nà mímúná,” tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fi ìyá ìyàwó Símónì sílẹ̀, tí ara obìnrin náà sì dá? (Lúùkù 4:38, 39)

6. Kí ni a ti ń pe apá kìíní ìtọ́wọ̀ọ́rìn kan? (Ẹ́kísódù 14:19)

7. Kí ni a fi àìwàpẹ́ ìgbésí ayé ènìyàn wé, ní ìyàtọ̀ sí ìwàtítí “àsọjáde Jèhófà”? (Pétérù Kíní 1:24, 25)

8. Àgbègbè ijù wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ́kọ́ jẹ mánà, tí a sì gbé òfin Sábáàtì kalẹ̀? (Ẹ́kísódù 16:1, 13-31)

9. Àwọn ohun díẹ̀ wo ni àwọn òrìṣà kò lè ṣe? (Orin Dáfídì 115:5-7)

10. Àwọn ènìyàn wo ni a dù láǹfààní wíwọ Ilẹ̀ Ìlérí nítorí pé wọn kò ya Ọlọ́run sí mímọ́, tí wọn kò sì bọlá fún un níbi omi Mẹ́ríbà? (Númérì 20:12)

11. Ẹ̀yà ara wo ni a máa ń lò láti fi ṣàpẹẹrẹ ìtóótun-pegedé láti lo okun tàbí agbára? (Aísáyà 51:9)

12. Nígbà tí ó ń fi ìlọ́lájù ipò àlùfáà Kristi hàn, kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé Léfì san nígbà tí ó ṣì wà ní abẹ́nú Ábúráhámù? (Hébérù 7:9, 10)

13. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì lò láti tọ́ka sí i pé ọba kan ní Ísírẹ́lì ń ṣojú fún ìṣàkóso àtọ̀runwá ti Jèhófà? (Kíróníkà Kíní 29:23)

14. Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin inú ìran Jòhánù fara jọ? (Ìṣípayá 4:7)

15. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn tí a bá ti lé Èṣù kúrò ní ọ̀run? (Ìṣípayá 12:12)

16. Ọ̀nà wo ni a gbà pín Ilẹ̀ Ìlérí náà láàárín àwọn ẹ̀yà 12 náà? (Númérì 26:55, 56)

17. Ẹyẹ wo ni ojú rẹ̀ méjèèjì ń wo iwájú, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lè fi ojú méjèèjì rí nǹkan kan lẹ́ẹ̀kan náà? (Orin Dáfídì 102:6)

18. Kí ni Tímótì yóò mú kí ó fara hàn kedere fún àwọn ẹlòmíràn nípa fífi ara rẹ̀ fún àwọn ohun tẹ̀mí léraléra? (Tímótì Kíní 4:15)

19. Ipò wo ni Dáníẹ́lì dì mú nínú àkóso ilẹ̀ Bábílónì? (Dáníẹ́lì 2:48)

20. Kí ni Ádámù àti Éfà gán pọ̀ fi ṣe aṣọ? (Jẹ́nẹ́sísì 3:7)

21. Kí ni Jákọ́bù sọ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ kò lè mú jáde nígbà tí ó ń tẹnu mọ́ kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí a má ṣi ahọ́n lò? (Jákọ́bù 3:12)

22. Àwọn aláìsàn wulẹ̀ ní láti fọwọ́ kan apá wo lára ẹ̀wù Jésù kí ara wọn lè dá ṣákáṣáká? (Mátíù 14:36)

23. Kí ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run ní láti máa jẹ́ àmì fún? (Jẹ́nẹ́sísì 1:14)

24. Àwọn wo ní pàtàkì ni ó yẹ kí a mọ̀ mọ ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ó ní ọ̀wọ̀ onífọkànsìn àti àwọn iṣẹ́ rere? (Títù 2:2, 3)

25. Kí ni Aísáyà sọ pé a óò dárí rẹ̀ ji àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí”? (Aísáyà 33:24)

26. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ tí ó yọ lò, Orin Dáfídì 140:3, pè é ní “paramọ́lẹ̀ abìwo” (NW), orúkọ àmọ̀dunjú wo ni Pọ́ọ̀lù fi pe ejò olóró yìí? (Róòmù 3:13)

27. Èwo ni lẹ́tà kẹfà nínú àwọn wóróhùn èdè Hébérù?

28. Ọ̀rọ̀ wo ni a ń lò láti fi ẹnì kan tí kì í ṣe Júù hàn yàtọ̀? (Róòmù 2:9, 10; wo ìtúmọ̀ King James Version.)

29. Kí ni orúkọ èbúté ilẹ̀ Ítálì tí Pọ́ọ̀lù ti lo ọ̀sẹ̀ kan lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń lọ dúró níwájú Késárì? (Ìṣe 28:13, 14)

30. Àwọn ohun wo tí a kò rí, tí ó wà títí àìnípẹ̀kun, ni Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá láti tẹ ojú wa mọ́? (Kọ́ríńtì Kejì 4:18)

31. Kí ni kò yẹ kí àwọn Kristẹni ṣe fún ara wọn, níwọ̀n bí Jèhófà yóò ti bójú tó o? (Róòmù 12:19)

32. Nígbà tí Jésù ń tẹnu mọ́ bí Gẹ̀hẹ́nà ṣe ń pa nǹkan run tó, kí ni ó sọ pé kì í kú níbẹ̀? (Máàkù 9:48)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Àìnígbàgbọ́ wọn

2. Efinrin, ewéko rue

3. Àgùntàn

4. Élì

5. Ibà obìnrin náà

6. Iwájú

7. Koríko tí ń rọ

8. Ijù Sínì

9. Sọ̀rọ̀, ríran, gbọ́ràn, gbóòórùn, fọwọ́ bà, rìn

10. Mósè àti Áárónì

11. Apá

12. Ìdámẹ́wàá

13. “Jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa”

14. Kìnnìún, ẹgbọrọ akọ màlúù, ènìyàn, idì

15. Ègbé

16. Nípa ìṣẹ́kèké

17. Òwìwí

18. Ìlọsíwájú rẹ̀

19. Olórí onítọ̀ọ́jú

20. Ewé ọ̀pọ̀tọ́

21. Ólífì

22. Ìṣẹ́tí

23. Àkókò, ọjọ́, ọdún

24. Àwọn ọkùnrin àti awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí

25. Àìṣedéédéé wọn

26. Ejò gùǹte

27. Waw

28. Kèfèrí

29. Pútéólì

30. “Àwọn ohun tí a kò rí”

31. Gbẹ̀san

32. “Ìdin wọn”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́