Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Mo fi ìkíni àtọkànwá mi ránṣẹ́ sí yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?” (May 22, 1996) Ẹ kò lè finú wòye bí àpilẹ̀kọ yìí ṣe ràn mí lọ́wọ́ tó. Ó fi hàn mí pé, láìka àwọn ìdènà sí, ó ṣeé ṣe láti ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pípẹ́ títí. Nígbà míràn, a ń pàdánù àwọn ọ̀rẹ́ nítorí pé a ń sún yíyanjú àwọn èdèkòyédè síwájú. Àpilẹ̀kọ yìí ràn mí lọ́wọ́ láti tiraka láti borí àwọn àìlera mi ní apá ibí yìí.
A. M. P., Brazil
Àpilẹ̀kọ náà bọ́ sákòókò gẹ́lẹ́. Ní oṣù mẹ́ta sẹ́yìn, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí mo fọkàn ṣìkẹ́ jù lọ pẹ̀lú ọmọbìnrin mìíràn kan bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn; a bá a dé orí yíyan ara wa lódì. Nígbà tí àpilẹ̀kọ náà dé, èmi àti ọ̀rẹ́ mi kà á, a sì wá mọ̀ pé a ti ń hùwà òmùgọ̀. A jíròrò àwọn ọ̀ràn, a sì yanjú àwọn ọ̀wọ́ èdèkòyédè mélòó kan. Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa ti lókun sí i lákọ̀tun báyìí.
N. T., Ítálì
Ìjábá Òkè Ayọnáyèéfín Mo rántí àwọn ìròyìn nípa bí Òkè Ńlá Pinatubo ṣe fọ́ yángá ní 1991. Ṣùgbọ́n mo ti gbàgbé nípa rẹ̀ títí di ìgbà tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Lahar—Àtubọ̀tán Òkè Ńlá Pinatubo.” (May 22, 1996) N kò gbọ́ nípa lahar rí, àpilẹ̀kọ náà sì wọ̀ mí lọ́kàn. Ìgboyà àti ìrànlọ́wọ́ tí ìdílé Garcia fi hàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà ní ipa ọ̀nà lahar, ta yọ lọ́lá.
S. F., Kánádà
Àpilẹ̀kọ náà mú mi káàánú gan-an. Ó máa ń wọni lọ́kàn láti ka ìrírí àwọn Kristẹni arákùnrin tí wọ́n di ìtara wọn fún àwọn ohun tẹ̀mí mú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bá ara wọn ní àwọn ipò tí kò fara rọ. Èyí ti fún mi níṣìírí láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ìṣòro kéékèèké mú kí n pa àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ, tàbí kí wọ́n dí mi lọ́wọ́ láti má ṣe lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà!
S. D., Ítálì
Èmi àti ọkọ mi kò gbọ́ nípa lahar rí, ṣùgbọ́n ní báyìí, a mọ bí ó ti burú, tí ó sì léwu tó. A óò fẹ́ kí àwọn ará wa ní Philippines mọ̀ pé a ń gbàdúrà fún wọn àti fún àwọn tí ó ṣeé ṣe fún láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
C. A. B., Guatemala
Ìbùyẹ̀rì Aláwọ̀ Ewéko Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka àpilẹ̀kọ náà, “O Ha Rí Ìbùyẹ̀rì Aláwọ̀ Ewéko Rí Bí?” (May 22, 1996), tán ni. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, nígbà tí mo ń fò nínú ọkọ̀ òfuurufú ní ijù ilẹ̀ Alaska, ó yà mí lẹ́nu láti rí ìtànṣán aláwọ̀ ewé òun búlúù kan tí ó wà fún àkókò kúkúrú gan-an kan. Títí di ìsinsìnyí, n kò tí ì rí àpilẹ̀kọ kan tí ń ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ yí fún mi. Nígbà míràn, mo máa ń rò pé, ó ní láti jẹ́ ohun kan tí mo wulẹ̀ finú wòye!
G. C., Alaska
Ìkọlù Ìpayà Mo fẹ́ fi ìmoore mi hàn fún àpilẹ̀kọ náà, “Kíkojú Ìkọlù Ìpayà.” (June 8, 1996) Mo ti jìyà irú ìkọlù bẹ́ẹ̀ fún ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn tí mo ti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà (ajíhìnrere alákòókò kíkún) fún ọdún kan, mo ní láti dúró nítorí pé n kò ní okun láti kojú àwọn ìkọlù náà. Ẹ wo bí ó ti dùn mí tó pé àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kò lóye èyí nítorí pé ìrísí mi kò jọ ti aláìlera. Ó ṣòro láti ṣàpèjúwe bí mo ṣe láyọ̀ tó láti ka àpilẹ̀kọ yìí.
O. S., Ukraine
Mo ti lo ọdún mẹ́jọ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ṣùgbọ́n, fún àwọn ọdún mélòó kan, mo ti ní ìmọ̀lára àìjámọ́ǹkan, mo sì ti dààmú púpọ̀. Nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ tí ń ṣàpèjúwe àwọn àmì àrùn tí ó bára mu pẹ̀lú tèmi yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìmọ̀ràn tí ó fúnni lọ́gán. Àwọn ìmọ̀lára mi ti ń sunwọ̀n sí i, ọkàn àyà mi sì ti balẹ̀ sí i.
K. M., Thailand
Mo ti gbàtọ́jú fún ìkọlù ìpayà, mo sì ti gba ìrànlọ́wọ́. Síbẹ̀, ìbéèrè náà, ‘Mo ha ṣàìlágbára tàbí ya ọ̀lẹ nípa tẹ̀mí ni bí?’ ń yọ mí lẹ́nu lábẹ́lẹ̀. Kíka àpilẹ̀kọ náà gbé ẹrù ìnira bàǹtàbanta kan kúrò léjìká mi.
P. P., Finland