ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Tí Èèyàn Ẹ Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Ṣàkóso Ìbínú? Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí O Ṣàkóso Ìbínú Rẹ?” (June 8, 1997) Inú ìdílé ńlá kan la ti tọ́ mi, mo sì fojú rí ọ̀pọ̀ ìjàkadì nínú ilé mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀, mo sì máa ń bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti ìgbà náà wá. Mo ti gbàdúrà sí Jèhófà léraléra pé kí ó ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro yìí. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìyàlẹ́nu tó láti ka àpilẹ̀kọ tí o jọ pé èmi ni a darí rẹ̀ sí yìí! Mo ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí—bí àpẹẹrẹ, Éfésù 4:26, tó wí pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” Èmi àti ọkọ mi ti mú èyí lò. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà àti àpilẹ̀kọ yìí, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti borí ìṣòro mi.

A. R. S., United States

Kíkojú Ìkọlù Ìpayà Mo gbọ́dọ̀ dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ Jèhófà fún àpilẹ̀kọ náà, “Kíkojú Ìkọlù Ìpayà.” (June 8, 1996) Láìpẹ́ yìí ni arábìnrin mi ní àrùn ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ àti ìmọ̀lára. A kò mọ ohun tí ń ṣe é, nítorí pé kò sí dókítà tí ó lè mọ àrùn náà. Níkẹyìn, wọ́n gbà á sílé ìwòsàn, wọ́n sì sọ pé ó ní ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ àti ìmọ̀lára àti ìkọlù ìpayà. Àpilẹ̀kọ náà dé lásìkò yíyẹ gan-an, tó mú kí a nímọ̀lára pé Jèhófà ń bìkítà nípa wa. Ńṣe ni arábìnrin mi jókòó, tí ó ń sunkún bí ó ṣe ń kà á, nítorí ó wá mọ̀ nígbà náà pé Jèhófà lóye ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí òun gẹ́lẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ arábìnrin tí a fà yọ nínú àpilẹ̀kọ náà, tó sọ pé léraléra ni òun rí i pé Jèhófà jẹ́ ojúlówó orísun okun àti ìtùnú, fi bí Ọlọ́run wa, Jèhófà, ti jẹ́ àgbàyanu tó hàn.

A. E. W., Gúúsù Áfíríkà

“Sínú Etí Ọmọdé Kan” Àpilẹ̀kọ yìí (June 8, 1997), wọ̀ mí lọ́kàn gidigidi. Nínú ìṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, mo sábà ń bá àwọn ọmọdé pàdé. Láìpa-wọ́n-tì àti láìfojú-kéré-wọn, mo sábà máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Párádísè. Mo dúpẹ́ gan-an pé ẹ tẹ ìrírí yìí jáde, nítorí pé ó fún mi ní ìṣírí láti máa ṣe báyìí nìṣó. Ta ló mọ etí tó kàn tí yóò jẹ́ “etí ọmọdé kan”?

M. O. U., Nàìjíríà

Àpilẹ̀kọ yìí nípa lórí mi gan-an! Nígbà tí mo dé apá tó sọ pé “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì,” tí mo sì ka bí ó ṣe ya Louise lẹ́nu tó nígbà tí ó ka Sáàmù 37:9 nípa níni ilẹ̀ ayé—tí ó tún jẹ́ láti inú ìtumọ̀ ti King James! tirẹ̀—omi bọ́ lójú mi gan-an. Ẹ ṣeun fún àwọn ìtàn ìgbésí ayé wọ̀nyí, ẹ sì jọ̀wọ́, ẹ máa tẹ̀ wọ́n jáde déédéé nínú Jí!

P. C., England

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa Mo mọrírì gbogbo ìwé ìròyìn tí a ń gbà. Ní pàtàkì, mo gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn òǹkàwé sọ nínú Jí! June 8, 1997, nípa ìyọlẹ́gbẹ́. A ti yọ mí lẹ́gbẹ́ rí, a sì gbà mí padà lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló rò pé ìgbésẹ̀ yìí ti le jù. Àmọ́ ní tòótọ́, kò rí bẹ́ẹ̀. Kò rọrùn láti gba ìbáwí tí a fún mi, ṣùgbọ́n ní kedere, kò le jù. Mo mọ̀ pé àwọn alàgbà wulẹ̀ ń gbìyànjú láti ràn mí lọ́wọ́ ni. Kíkọ̀ tí mo kọ ìrànlọ́wọ́ wọn ló yọrí sí yíyọ tí a yọ mí lẹ́gbẹ́. Ní gbàrà tí a yọ mí lẹ́gbẹ́, mo wá mọ bí ìgbésí ayé tí kò ní Jèhófà nínú ti jẹ́ ìnìkanwà tó. Àlàfo ńlá kan wá wà nínú ìgbésí ayé mi tí kò ṣeé dí títí mo fi yí ọ̀nà ìgbésí ayé mi padà, tí mo sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Dídi ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ mú kí n rẹ ara mi sílẹ̀, ó sì fi hàn mí pé mo nílò Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀.

A. C., Kánádà

Jí! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ forí jì mí fún gbígbàgbé tí mo gbàgbé láti sọ àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn títayọ náà, Jí!, dọ̀tun. Ó jẹ́ ìwé ìròyìn tí ń fúnni ní ìsọfúnni, tí ń kọ́ni, tó sì ń gbé òtítọ́ jáde nínú àwọn kókó ọ̀rọ̀ asúnniṣiṣẹ́, tó sì ń tani jí. Mo fẹ́ láti gba àwọn ẹ̀dà tó ti kọjá tí n kò gbà tẹ́lẹ̀. N kò fẹ́ láti pàdánù èyíkéyìí nínú wọn. Ẹ ṣeun fún ìsapá tí ẹ ń ṣe nìṣó láti gbógun ti àìmọ̀kan.

N. S., Sri Lanka

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́