Wíwo Ayé
Àwọn Aṣíwọ̀lú Ń Fẹ̀mí Wewu
Ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aṣíwọ̀lú láìbófinmu ń fẹ̀mí wewu láti wá iṣẹ́ àti àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé tó sàn jù lọ sí Gúúsù Áfíríkà. A gbọ́ pé àwọn ọ̀nì ti jẹ ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára wọn nígbà tí wọ́n ń wẹ Odò Limpopo kọjá. Àwọn erin ti tẹ àwọn kan pa nígbà tí wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn kọjá Ọgbà Ẹ̀dá ti Orílẹ̀-Èdè ti Kruger tàbí kí àwọn kìnnìún ti pa wọ́n. Láìpẹ́ yìí ni àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà yìnbọn pa kìnnìún márùn-ún tó ti di ajẹ̀nìyàn. Ìwé agbéròyìnjáde The Star, ti Johannesburg, ròyìn pé: “Àyẹ̀wò òkú tí wọ́n ṣe fún àwọn kìnnìún márùn-ún náà fi òkú ènìyàn hàn nínú agbẹ̀du àwọn ẹran náà.” A kò mọ iye àwọn aṣíwọ̀lú láìbófinmu tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti pa gan-an. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Rírìnkiri déédéé ti fi ipasẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń wulẹ̀ pòórá pátápátá hàn. Akọ [kìnnìún] kan tó ti dàgbà dáadáa lè jẹ ẹran tó tó 70 kìlógíráàmù [150 pounds] lẹ́ẹ̀kan. Ó túbọ̀ ṣòro láti rí ara ènìyàn tí wọ́n jẹ kù, pàápàá bí àwọn pẹnlẹpẹ̀ àti akátá bá dé ibi tí kìnnìún náà bá pa ẹran ọdẹ rẹ̀ sí.”
Ìṣòro Tí Àwọn Ọmọdé Ń Ní Nígbà Ogun
Àwọn àjọ Terre des Hommes ń bójú tó àìní àwọn ọmọdé. Gẹ́gẹ́ bí Petra Boxler, alága àjọ náà ní Germany, ṣe sọ, “nǹkan bí mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé ti kú nínú ogun, ìjà ráńpẹ́, àti ìjà ìgboro láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá.” Síwájú sí i, ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ròyìn pé, mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn ọmọdé mìíràn ti fara pa yánnayànna, tí mílíọ̀nù mẹ́wàá sì ti ní ọgbẹ́ ńlá ní ti ìmọ̀lára. Boxler dárò pé ogun ti túbọ̀ ní àbùdá ibi lójú àwọn ọmọdé ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Ní àwọn ilẹ̀ kan, tipátipá ni wọ́n ń dá àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ láti máa pànìyàn, tí wọ́n sì “ń lò” wọ́n “láti máa wá àwọn ohun abúgbàù tí kò tíì bàjẹ́ kiri.”
A Rí Àwọn Ẹranko “Tuntun”
Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, ìmọ̀ tó wọ́pọ̀ gbà pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹranko afọ́mọlọ́mú—àwọn ẹ̀dá abirunlára, ẹlẹ́jẹ̀ gbígbóná, afọ́mọlọ́mú—ni a ti mọ̀ tán. Èyí kì í ṣe òtítọ́ mọ́. Àwọn ìtẹ̀jáde ìwé Mammal Species of the World láàárín 1983 sí 1993 tún ṣàfikún orúkọ 459. Láàárín ọdún mẹ́rin tó kọjá, àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè tún ti ṣàwárí ọ̀pọ̀ sí i—àwọn eku, àdán, ìgalà, ẹtu, akọmàlúù ìgbẹ́, àti àwọn ọ̀bọ pàápàá.” A ti sọ tẹ́lẹ̀ pé 4,600 ẹranko afọ́mọlọ́mú tí a mọ̀ nísinsìnyí yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ tó 8,000. “A ń ṣe ‘àwárí’ àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú” kan “nínú àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, nígbà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ń wo àwọn àkójọ tí a ti ṣe lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn láwòfín.” Láfikún sí i, àpilẹ̀kọ náà wí pé, “ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ tuntun ní ń ní àgbájọ àwọn kòkòrò àfòmọ́ àti àwọn ẹ̀dá kéékèèké mìíràn tí sáyẹ́ǹsì kò tíì mọ̀ lára,” àti pé, “ìpín 1 nínú 3 àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú jẹ́ ẹranko tí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kankan kò rí rí.” Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àwárí tuntun náà la ń ṣe nínú àwọn igbó ilẹ̀ olóoru àti àwọn ẹkùn ilẹ̀ àdádó mìíràn lágbàáyé. Onímọ̀ nípa ẹranko afọ́mọlọ́mú náà, George Schaller, sọ pé: “Ó máa ń yà mí lẹ́nu láti rí àwọn ènìyàn tí ìgbónára wọn ń ru sókè jù nítorí bakitéríà kan tó ṣeé ṣe kó wà nínú Máàsì, nígbà tí pílánẹ́ẹ̀tì tiwa gan-an ní àìlóǹkà irú ọ̀wọ́ tí a kò tíì wá rí nínú.”
Iná Ìsìn Jó Dé Orí Kókó
Konrad Raiser, akọ̀wé gbogbogbòò fún Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé sọ pé: “Bí a ti ń lọ sí òpin ọ̀rúndún àti ẹgbẹ̀rúndún yìí, èrò kan wà pé kì í ṣe ààlà ìbẹ̀rẹ̀ àfiṣàpẹẹrẹ kan lásán, pé ohun kan tó jẹ́ ìyípadà aláìláfiwé ń ṣẹlẹ̀. Ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé a kò lóye ìhà ibi tí ìyípadà náà ń darí wa lọ dáradára. Nítorí náà, a ń ní ìdíwọ́ lọ́nà kan nínú ìkópa wa láti darí ìgbésẹ̀ ìyípadà náà, kàkà kí ó jẹ́ wíwulẹ̀ máa dáhùn padà tàbí kí a máa hùwà padà sí [i].” Ọ̀mọ̀wé Raiser dárúkọ “ìsọdipúpọ̀ ìsìn” gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn kan tí ó yẹ láti kò lójú. Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin fa ọ̀rọ̀ tó sọ yọ pé Kirisẹ́ńdọ̀mù “ṣì jẹ́ apá kan ìṣòro náà ju bí ó ti jẹ́ apá kan ojútùú rẹ̀ lọ.” Ó fi kún un pé: “A ko tíì ṣàgbékalẹ̀ àwọn ọ̀nà tí a lè gbà bá ara wa gbé bí aládùúgbò láìsí pé a ń bá a lọ láti máa wo ẹnì kejì, tí ìdánilójú ìsìn àti ọ̀nà ìjọsìn rẹ̀ yàtọ̀ sí tẹni, bí ewu, dípò kí a wò ó bí . . . ẹni tó ṣeé ṣe kó jẹ́ orísun ìmúsunwọ̀n.”
Ẹgbẹ̀rúndún Náà Ti Parí Kẹ̀?
Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé ti sọ, “ẹgbẹ̀rúndún náà ti wáyé ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Ó mà ṣe o, gbogbo wa la ò mọ̀.” Èrèdí rẹ̀? Àwọn kàlẹ́ńdà wa “la gbé karí ìpín àkókò àdábọwọ́,” tí a rò pé a gbé karí ìgbà tí wọ́n bí Kristi. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ náà sọ pé, àwọn ọ̀mọ̀wé òde òní gbà gbọ́ pé, ní gidi, wọ́n ti bí Jésù ní ọdún mélòó kan “ṣáájú Kristi.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe wí, ìyẹn “túmọ̀ sí pé a ti wọnú ẹgbẹ̀rúndún kẹta dáadáa.” Dionysius Kúkúrú, tí Póòpù John Kìíní gbé iṣẹ́ fún láti ṣàgbekalẹ̀ kàlẹ́ńdà ètò ìsìn ní 525 C.E. ló ṣe àṣìṣe náà. Dionysius pinnu láti lo ìbí Jésù gẹ́gẹ́ bí déètì tí a gbé kàlẹ́ńdà náà kà, ṣùgbọ́n ó ṣe àṣìṣe ní ṣíṣírò rẹ̀. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Àwọn òpìtàn kì yóò mọ ìgbà tí a bí Jésù gan-an lọ́nà tó dájú láé. Kódà, yíyan ọjọ́ Kérésìmesì, tí ó jẹ́ ayẹyẹ ìbí rẹ̀, jẹ́ àdábọwọ́. Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé, ṣọ́ọ̀ṣì yan Dec. 25, láti bá àwọn ayẹyẹ ọjọ́ tí ó gùn jù lọ láàárín ọdún nígbà òtútù tí àwọn kèfèrí máa ń ṣe dọ́gba—kí ó sì ta kò wọ́n lọ́nà ti ìsìn.” Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ nínú Bíbélì tọ́ka sí i pé, wọ́n bí Jésù ní ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa.
A Ti Fi Àwọn Ológbò Kún un Nísinsìnyí
Láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún wá ni ó ti jẹ́ ìwà ọ̀daràn ní Ìpínlẹ̀ New York láti kúrò níbi tí ìjàǹbá kan bá ti ṣẹlẹ̀, tí ó kan màlúù, ẹṣin, tàbí ajá kan, láìwá ẹni tó ni ẹranko náà rí tàbí ó kéré tán, láìfi tó àwọn ọlọ́pàá àdúgbò létí. A kò fi ológbò kún un. Bí o ti wù kí ó rí, àbá tuntun kan tí ọ̀pọ̀ èrò gbà wọlé tí a sì fọwọ́ sí, tó di òfin, ti bójú tó ọ̀ràn yẹn nísinsìnyí. Òfin yìí, tí a mọ̀ sí àbádòfin “Ìnàgbalaja Ológbò,” sọ ọ́ di ìwà ọ̀daràn fún ẹnì kan láti kúrò níbi tí ìjàǹbá kan bá ti ṣẹlẹ̀, tí ó pa ológbò kan lára, ó kéré tán, láìfi tó àwọn ọlọ́pàá létí. Ìkùnà láti fi tó wọn létí lè yọrí sí pé kí “àwọn tí ń fi ìkọlunisálọ ṣèpalára” fún ológbò san owó ìtanràn 100 dọ́là. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, “Fún àwọn olólùfẹ́ ológbò, ó dúró fún ṣíṣeéṣe kedere pé a lè fòpin sí ìyàsọ́tọ̀ irú ọ̀wọ́ kan.”
“Àjàkálẹ̀ Ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀”
Nígbà tí ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ń tọ́ka sí ìkìlọ̀ kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe, ó sọ pé: “Ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ jẹ́ àjàkálẹ̀ tí ń gbilẹ̀ sí i, tí ó sì ń wu ìlera àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn léwu kárí ayé. Àwọn ògbóǹkangí onímọ̀ nípa ìlera láti orílẹ̀-èdè 25 sọ pé bí ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ ṣe ń gbilẹ̀ láàárín àwọn àgbàlagbà ti pọ̀ tó ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù àti àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Iye náà lọ sókè sí ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín àwọn obìnrin ní ìlà oòrùn Yúróòpù àti àwọn orílẹ̀-èdè àgbègbè Mẹditaréníà àti láàárín àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú ní United States. Ilẹ̀ Melanesia, Micronesia, àti Polynesia ni ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ ti gbilẹ̀ jù—ó pọ̀ tó ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ní àwọn àgbègbè kan.” Àwọn ògbóǹkangí náà kìlọ̀ pé, bí kò bá jẹ́ pé àwọn ènìyàn yan àwọn oúnjẹ tí kò lọ́ràá púpọ̀ nínú, kí wọ́n sì máa túbọ̀ gbé ìgbésí ayé àìjókòó-lójúkan, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní yóò ní iye ènìyàn rẹpẹtẹ tó ní àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn-àyà, àwọn àrùn tó kan mímí, àrùn ẹ̀gbà, àrùn inú àpò òróòro, àrùn jẹjẹrẹ, àrùn àtọ̀gbẹ, àti àwọn àrùn iṣan àti egungun ara. “Àwọn ògbóǹkangí náà sọ pé: ‘a gbọ́dọ̀ ka’ ìsanrajọ̀kọ̀tọ̀ ‘sí ọ̀kan nínú àwọn àrùn aráàlú tí a kò já kúnra ní àkókò tiwa, tí ó sì ń nípa búburú [tí] ó lè pọ̀ tó ti sìgá mímu lórí ìlera.’”
Ìfọkànsìn Oníṣìnà Ni Bí?
Ní June 1, 1997, ìrísí àwòrán kan—tí ó ṣe kedere pé ọ̀rinrin ló fà á—fara hàn lára ògiri kan ní ọ̀kan nínú àwọn ibùdó Ọkọ̀ Abẹ́lẹ̀ Ìlú Ńlá Mexico. Lójú ọ̀pọ̀ Kátólíìkì olùfọkànsìn, èyí jẹ́ ìfarahàn lọ́nà ìyanu ti Wúńdíá ti Guadalupe—orúkọ kan tí wọ́n fún Màríà Wúńdíá ní Mexico. Ìwé agbéròyìnjáde El Universal sọ pé: “Ìjọ Kátólíìkì kò ka ìfarahàn Wúńdíá Ibùdókọ̀ Abẹ́lẹ̀ náà sí iṣẹ́ ìyanu to ṣeé gbà gbọ́ bí kò ṣe ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́nà àdánidá nígbà tí omi sẹ̀ sára ògiri ibùdókọ̀ náà.” Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló dúró ṣe ìjọsìn níwájú rẹ̀, “àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ní wákàtí kan sì ti ṣèbẹ̀wò” sídìí ìrísí àwòrán náà. Wọ́n ti kọ́ ilé ère kékeré kan fún ìrísí àwòrán náà, àlùfáà Kátólíìkì kan ló sì ṣèfilọ́lẹ̀ rẹ̀.
Jíjèrè Lára Àwọn Ohun Àsọdibárakú
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé nǹkan bí 340 mílíọ̀nù àwọn ajoògùnyó ló wà kárí ayé. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ròyìn rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde Jornal da Tarde, “lílo egbòogi amárarọni àti oògùn akunnilóorun ló gbapò kìíní, 227.5 mílíọ̀nù, tàbí iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 4 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo olùgbé ayé, ló ń lò ó. Marijuana, tí mílíọ̀nù 141, tàbí ìpín 2.5 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ayé ń lò, ló tẹ̀ lé e.” Wọ́n tún fojú díwọ̀n pé ìpín 5 sí ìpín 10 péré lára gbogbo oògùn tí kò bófin mu ni àwọn ọlọ́pàá ń rí gbẹ́sẹ̀ lé. Òwò títa àwọn oògùn líle ń pa tó 400 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn tí ń tà á ń jèrè tó ìpín 300 nínú ọgọ́rùn-ún—“èrè tí a kò jẹ irú rẹ̀ nínú oríṣi òwò èyíkéyìí mìíràn.”