ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 11/8 ojú ìwé 3
  • Ṣé Ìṣòro Ni Pé Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìṣòro Ni Pé Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ìsanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Túmọ̀ Sí?
  • Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
    Jí!—2004
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2004
  • Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Ǹjẹ́ Kò Ti Ń di Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Kárí Ayé Báyìí?
    Jí!—2003
  • Ìgbà Tí Kò Dára Láti Sanra
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 11/8 ojú ìwé 3

Ṣé Ìṣòro Ni Pé Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?

“Àfi bí àjàkálẹ̀ àrùn lọ̀rọ̀ báwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ṣe ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀ rí.” —S. K. Wangnoo, dókítà àgbà tó mọ̀ nípa omi inú ara ní Ọsibítù Indraprastha Apollo, ní ìlú Delhi lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

BÍ Ọ̀RỌ̀ ṣe rí gan-an ni dókítà náà ṣe sọ ọ́ yìí o, ọ̀pọ̀ àwọn ará Íńdíà tí wọ́n jẹ́ mẹ̀kúnnù ti wá ń gbé irú ìgbésí ayé tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ máa sanra jọ̀kọ̀tọ̀ báyìí. Àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti wá ń di àrùn àjàkáyé tó ti ń gbèèràn lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè báwọn èèyàn ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ ṣeré ìdárayá mọ́ tí wọ́n sì wá ń jẹ oúnjẹ pàrùpárù. Dókítà kan tó mọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà sọ pé: “Ìran èèyàn tí wọ́n máa bí [nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì] lọ́jọ́ iwájú, ló máa . . . sanra jù lọ láyé.” Ìwé ìròyìn Guardian Weekly sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ìṣòro àwọn àgbàlagbà nìkan ni ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀. Ní báyìí ṣá, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀wọ́ àwọn èwe kan wà tí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jẹun àti jíjókòó tí wọ́n máa ń jókòó gẹlẹtẹ sójú kan ń kó wọn sínú àwọn ìṣòro tó jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà la ti kọ́kọ́ gbúròó wọn. Sísanra tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀ lè mú kí wọ́n láwọn àrùn bí àtọ̀gbẹ, àìsàn àyà àti àrùn jẹjẹrẹ.”

Àwọn tó kọ̀wé Food Fight sọ pé: “Àjẹranjú ti wá gbapò àìjẹunrekánú báyìí, bá a bá ń sọ̀rọ̀ àwọn ìṣòro oúnjẹ tó le koko jù lágbàáyé.” Nínú ìwé tí Don Peck kọ sínú ìwé ìròyìn The Atlantic Monthly, ó sọ pé: “Ó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́sàn-án àwọn ará Amẹ́ríkà tí ‘ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ ti di àárẹ̀ sí lára,’ èyí tó fi hàn pé nǹkan bíi kìlógíráàmù márùndínláàádọ́ta [tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bí àpò sìmẹ́ǹtì kan] tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi lọ́rìn ju bó ṣe yẹ lọ.” Àwọn àìsàn tó jẹ mọ́ kéèyàn ki ju bó ṣe yẹ lọ ló fa ikú àìtọ́jọ́ fún nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] èèyàn lọ́dún kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, “òun ló tún pààyàn tó pọ̀ jù lẹ́yìn sìgá mímu.” Ibi tí Peck parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ sí ni pé: “Ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ ń bọ̀ wá di ìṣòro tá á wu ìlera àwọn aráàlú lewu jù lọ níbi gbogbo lágbàáyé. Ìyẹn á sì ré kọjá ìṣòro ebi àtàwọn àìsàn tí ń ranni.” Ta ní wá jẹ́ gbójú fo ewu ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ dá? Nínú ìwé Eat, Drink, and Be Healthy, tí Dókítà Walter C. Willett kọ, ó sọ pé, “bá a bá yọwọ́ ti pé bóyá ò ń mu sìgá, ohun tó o bá wọ̀n lórí ìwọ̀n ló tún ṣe pàtàkì jù tó o lè fi mọ bí ìlera rẹ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú.” Kókó pàtàkì tá à ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni ìlera ọjọ́ iwájú.

Kí Ni Ìsanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Túmọ̀ Sí?

Nígbà wo gan-an la lè sọ pé ẹnì kan sanra jọ̀kọ̀tọ̀ tí kì í sì í ṣe pé ó wulẹ̀ ki pọ́pọ́ ju bó ṣe yẹ lọ ni? Ilé Ìtọ́jú Mayo tó wà ní ìlú Rochester, ní ìpínlẹ̀ Minnesota, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ká sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn jù lọ láti yéni, ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ túmọ̀ sí kéèyàn ki pọ́pọ́ ju bó ṣe yẹ lọ nítorí ọ̀rá tó pọ̀ jù nínú ara ẹ̀.” Àmọ́, báwo la ṣe lè mọ̀ bí ẹnì kan bá ki pọ́pọ́ jù tàbí bó bá sanra jọ̀kọ̀tọ̀? Àwọn àtẹ ìsọfúnni tó lo bí ẹnì kan ṣe ga sí àti bó ṣe lọ́rìn tó lè fúnni ní nọ́ńbà téèyàn á fi mọ̀. (Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 5.) Àmọ́ ṣá o, ìyẹn ò ní í ṣe pẹ̀lú bí ara ẹnì kan ṣe rí o. Ilé Ìtọ́jú Mayo sọ pé: “Bí ọ̀rá tó wà lára ṣe pọ̀ tó ló dáa jù láti fi díwọ̀n bára ẹnì kan ṣe dá ṣáṣá sí, kì í ṣe bí onítọ̀hún ṣe lọ́rìn tó.” Bí àpẹẹrẹ, ara ẹni tó jẹ́ eléré ìdárayá lè ki pọ́pọ́ nítorí iṣan ara rẹ̀ tó ṣù jọ tàbí nítorí eegun ara rẹ̀ tó gbó keke. Kí làwọn nǹkan tó ń mú kéèyàn ki pọ́pọ́ jù tàbí kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀? Àpilẹ̀kọ tó kàn á dáhùn ìbéèrè náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́