Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀?
“Àjàkálẹ̀ àrùn tó ń gbèèràn báyìí ti rìn jìnnà débi pé ó lè ṣe ìpalára tó pọ̀ fún àwọn ọmọ wa. Báwọn èèyàn nílé lóko ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i, ìṣòro ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ ò ní yé pọ̀ sí i.”—William J. Klish, ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé ló sọ̀rọ̀ yìí.
Ó MÁA ń yá àwọn tí ò sanra lára láti fojú wo àwọn tó ki pọ́pọ́ jù àtàwọn tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀ bí ẹni tó kàn tóbi fọ̀ngbàdì lásán, wọ́n tún lè rò pé aláìfẹ́kan ṣe àti ọ̀lẹ afàjò ni wọ́n. Àmọ́, ṣé bí ìṣòro náà ṣe mọ nìyẹn? Ṣé òótọ́ ni pé ọ̀lẹdàrùn làwọn tó bá sanra jọ̀kọ̀tọ̀ tí wọ́n kì í sì í fẹ́ ṣe eré ìmárale èyíkéyìí? Àbí àwọn nǹkan míì tí ò rọrùn láti ṣe nǹkan sí ló ń fà á fún ọ̀pọ̀ lára wọn?
Ṣé Àbímọ́ Ni? Àbí Ipò Tó Yí Èèyàn Ká? Àbí Méjèèjì?
Ìwé Food Fight sọ pé: “Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń sọ́ èrò tó yàtọ̀ síra lórí bóyá apilẹ̀ àbùdá ló ń fa kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ni àbí ipò tó yí èèyàn ká.” Nínú ohun tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí yìí, kí ló ń jẹ́ apilẹ̀ àbùdá? Èrò táwọn kan ń gùn lé ni pé ara èèyàn máa ń kó àpọ̀jù kálórì tó ń fún ara lókun jọ fún ìlò ọjọ́ iwájú. Ìwé náà tún sọ síwájú sí i pé: “Láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún wá ni wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa apilẹ̀ àbùdá tó ń múni sanra jọ̀kọ̀tọ̀. . . . Ìwádìí sì ti lọ jìnnà báyìí lórí apilẹ̀ àbùdá èèyàn àti béèyàn ṣe ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Wọ́n ti lo ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ tó ga láti fi mọ àwọn apilẹ̀ àbùdá tó máa ń jẹ́ kéèyàn ki pọ́pọ́ àtèyí tó máa ń fa àrùn bí àtọ̀gbẹ. Bá a bá ní ká fi èdè àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé ohun tó fà á táwọn èèyàn fi ń tóbi jura lọ, a lè sọ pé nǹkan bí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún kò ṣẹ̀yìn àwọn apilẹ̀ àbùdá.” Ìwé náà ń bá àlàyé ẹ̀ lọ pé: “Bí a bá wo ti pé àwọn èèyàn máa ń ka ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ sí ẹ̀bi ẹni tó sanra náà, àlàyé yìí jẹ́ ká rí ipa pàtàkì tí àwọn ìyípadà inú ara ń kó, síbẹ̀ ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára ohun tó ń fà á ló ní í ṣe pẹ̀lú béèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ̀.” Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń fà á téèyàn fi ń sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ni ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbésí ayé ẹ̀. Ṣé èròjà kálórì tó wà nínú oúnjẹ tí onítọ̀hún ń jẹ lójúmọ́ ti pọ̀ ju èyí tí ara rẹ̀ ń lò lọ ni? Ṣé oúnjẹ tí ò dàa ló ń jẹ nígbà gbogbo ṣáá? Ṣé ó ń wáyè lójoojúmọ́ láti fi ṣe ìwọ̀nba eré ìdárayá?
Ilé Ìtọ́jú Mayo ṣàlàyé ṣókí nípa ohun tó ń fa kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀, ó sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé apilẹ̀ àbùdá ló ń fa kíki pọ́pọ́ jù tàbí sísànra jọ̀kọ̀tọ̀ o, àmọ́, ohun tó ò ń jẹ àti ohun tó o bá ń fara ṣe lá á pàpà pinnu bó o ṣe máa ki tó tàbí bó o ṣe máa sanra tó. Lẹ́yìn àkókò gígùn téèyàn bá ti ń jẹ oúnjẹ tó ní èròjà kálórì lájẹjù, tó ń jókòó sójú kan, tàbí kó máa ṣe méjèèjì pọ̀, ó lè dẹni tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ìwé náà tún ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ohun tí wọ́n bí mọ́ ọ ò ní kó o dẹni tó sanra. . . . Ohun yòówù tí ì báà wà nínú apilẹ̀ àbùdá rẹ, àwọn nǹkan tó o bá yàn láti máa jẹ àtàwọn ìgbòkègbodò tó o bá ń kópa nínú ẹ̀ ló máa pinnu bó o ṣe máa ki tó tàbí bó o ṣe máa sanra tó.”
Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń báwọn èèyàn ṣe é kí wọ́n lè jò ń pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là wọlé báwọn èèyàn ti ń wá bára wọn á ṣe padà sípò ní gbogbo ọ̀nà. Síbẹ̀, kí làwọn ògbógi ń sọ nípa àwọn ètò yìí? Ìwé Food Fight sọ pé: “Ìṣòro kéèyàn sanra jọ̀kọ̀tọ̀ kì í lọ bọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń dín bí wọ́n ṣe sanra kù ò sì tíì róògùn ẹ̀ ṣe. Ohun tó jẹ́ ìròyìn rere jù lọ nínú ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni àfojúbù náà pé ìdámẹ́rin àwọn tó ń dín bí wọ́n ṣe sanra kù ni wọn kì í padà sanra jọ̀kọ̀tọ̀, ìyẹn sì sábà máa ń jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbìyànjú ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”
Ewu Tó Ń Bẹ Nínú Kéèyàn Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀
Béèyàn bá sanra jọ̀kọ̀tọ̀, ó lè láwọn ìṣòro ìlera tó le koko. Dókítà Scott Loren-Selco, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ètò iṣan ara ní ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn University of Southern California Medical Center, ṣèkìlọ̀ pé àwọn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀, pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ lè ní àrùn àtọ̀gbẹ oríṣi kejì. (Wo Jí! May 8, 2003.) Ó sọ pé: “Ní báyìí o, gbogbo ìgbà là ń rí wọn, àní sẹ́, ó ń bani lẹ́rù. Mo máa ń sọ fún [àwọn tó wá gbàtọ́jú nítorí pé wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀] pé mo lè mú wọn lọ sí wọ́ọ̀dù àwọn alárùn àtọ̀gbẹ, kí n sì fi ohun tó ṣeé ṣe kó gbẹ̀yìn ayé wọn hàn wọ́n, àwọn tó kún ibẹ̀ ni àwọn afọ́jú, àwọn agépá àti agésẹ̀, àti àìníye àwọn èèyàn tí wọ́n ti di abirùn pátápátá nítorí àrùn [àtọ̀gbẹ] oríṣi kejì, tí gbogbo wọn sì sanra jọ̀kọ̀tọ̀.” Kí ni ọ̀kan lára ohun tó máa ń fà á? Loren-Selco sọ pé: “Wọ́n ń rówó ra búrẹ́dì tí wọ́n fi ẹ̀ran há láàárín àti ànàmọ́ díndín, wọn ò sì yé jẹ wọ́n. Kò sẹ́ni tó ń sọ fún wọn pé kò dáa kí wọ́n máa jẹ irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé àwọn iléeṣẹ́ tó ń ta oúnjẹ àyáragbọ́ ò jẹ́ sọ fún wọn, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tàwọn dókítà tí wọn ò kọ́ nípa tìfuntẹ̀dọ̀ oúnjẹ.”
Dókítà Edward Taub, gbajúgbajà òǹkọ̀wé nípa oúnjẹ tó ń ṣara lóore, sọ pé: “Gbígbàgbọ́ pé kò sóhun tó burú nínú kíki pọ́pọ́ jù àti pé ó wulẹ̀ jẹ́ ohun tó bá ayé òde òní mu ti wá di ohun táwọn èèyàn gba tiẹ̀ báyìí, wọ́n tiẹ̀ máa ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ pé kò burú. Dájúdájú, itú ńlá táwọn tó ń bá àwọn ilé iṣẹ́ oúnjẹ tajà ti pa láti máa jèrè nìṣó látara oúnjẹ tó ń mú ká sanra bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ nìyẹn jẹ́.”
Àwọn ògbógi sọ pé ó ṣeé ṣe kí ìlera àwọn tí wọ́n sanra sídìí, tí wọ́n ní àpọ̀jù ọ̀rá lápá ìbàdí sàn ju tàwọn tí wọ́n sanra sí ikùn, nítorí ọ̀rá tó ká wé wọn ní abonú (pàápàá jù lọ bí ìbàdí wọn bá ti fẹ̀ jù). Kí ló dé tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìwé Mayo Clinic on Healthy Weight sọ pé: “Ìdí ni pé ọ̀rá inú ikùn máa fi kún ohun tó lè fa kí ìfúnpá ga, àrùn inú òpójẹ̀, àtọ̀gbẹ, rọpárọsẹ̀ àti irú àrùn jẹjẹrẹ kan báyìí. Bó o bá ní ìbàdí ńlá, tí àwọn itan rẹ rí pòrìkìpòrìkì tí ìdí ẹ sì ṣe bẹ̀bẹ̀rẹ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ dájú pé ìyẹn á pa ẹ́ lára ju bó ṣe yẹ lọ.”
Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, ojútùú wo ló wà fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgbà àtọmọdé kárí ayé tí wọ́n ki pọ́pọ́ jù tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ní àìlera líle koko àtèyí tó díjú? Ṣé oògùn ajẹ́bíidán èyíkéyìí wà?
[Àpótí/Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 5]
Kí ni ìdíwọ̀n “BMI”? Kí ló sì ń sọ nípa ara rẹ?
Ìdíwọ̀n BMI (tó ń jẹ́ ká mọ bí ara ṣe tẹ̀wọ̀n tó) ni fifi bí ẹnì kan ṣe ga tó wéra pẹ̀lú bó ṣe tẹ̀wọ̀n tó, èyí tá á jẹ́ kéèyàn mọ̀ bóyá òun ki pọ́pọ́ jù tàbí òun ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ ilé ìtọ́jú Mayo Clinic ṣe sọ, ẹni tó bá wọn bíi BMI méjìdínlógún àtààbọ̀ sí nǹkan bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ìlera ẹ̀ dáa jù lọ. Bó o bá wọn BMI mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí nǹkan bí ọgbọ̀n, a jẹ́ pé o ti ki pọ́pọ́ jù nìyẹn. Béèyàn bá ti wọ̀n kọjá ọgbọ́n BMI báyìí, onítọ̀hún ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Kí lo wọ̀n nígbà tó o wo àtẹ ìsọfúnni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí? Àbí wàá lọ rí dókítà rẹ fún àwọn ìdámọ̀ràn rẹ̀ tàbí kó o lè rí àrídájú nípa ipò tí ara ẹ wà?
Bó o bá fẹ́ mọ iye “BMI” tó o wọ̀n, kọ́kọ́ mọ bó o ṣe lọ́rìn tó. Ìwọ̀n kìlógíráàmù ni kó o lò o. Wá fi iye mítà tó fi ga pín in lẹ́ẹ̀mejì. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá wọn àádọ́rùn ún [90] kìlógíráàmù, tó o sì ga tó mítà kan àti ẹ̀sún mẹ́jọ [1.8], BMI tó o wọ̀n á jẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n [28] (90 ÷ 1.8 ÷ 1.8 = 28).
[Àtẹ Ìsọfúnnni]
Ará Ẹ Le O Ki Pọ́pọ́ Jù O Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀
BMI 18.5 sí 24.9 25 sí 29.9 30 tàbí kó lé
Gíga Ìwọ̀n kìlógíráàmù
1.47 mítà 53 tàbí kó dín 54 sí 64 65 tàbí kó lé
1.50 mítà 56 tàbí kó dín 57 sí 67 68 tàbí kó lé
1.52 mítà 57 tàbí kó dín 58 sí 69 70 tàbí kó lé
1.55 mítà 59 tàbí kó dín 60 sí 71 72 tàbí kó lé
1.57 mítà 61 tàbí kó dín 62 sí 73 74 tàbí kó lé
1.60 mítà 63 tàbí kó dín 64 sí 76 77 tàbí kó lé
1.63 mítà 66 tàbí kó dín 67 sí 79 80 tàbí kó lé
1.65 mítà 67 tàbí kó dín 68 sí 81 82 tàbí kó lé
1.68 mítà 70 tàbí kó dín 71 sí 84 85 tàbí kó lé
1.70 mítà 72 tàbí kó dín 73 sí 86 87 tàbí kó lé
1.73 mítà 74 tàbí kó dín 75 sí 89 90 tàbí kó lé
1.75 mítà 76 tàbí kó dín 77 sí 91 92 tàbí kó lé
1.78 mítà 79 tàbí kó dín 80 sí 94 95 tàbí kó lé
1.80 mítà 80 tàbí kó dín 81 sí 97 98 tàbí kó lé
1.83 mítà 83 tàbí kó dín 84 sí 100 101 tàbí kó lé
1.85 mítà 85 tàbí kó dín 86 sí 102 103 tàbí kó lé
1.88 mítà 89 tàbí kó dín 90 sí 106 107 tàbí kó lé
1.90 mítà 90 tàbí kó dín 91 sí 108 109 tàbí kó lé
[Credit Line]
A mú ìsọfúnni yìí látinú ìwé Mayo Clinic on Healthy Weight
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Kí ni kálórì?
Kí la lè sọ nípa kálórì tó wà nínú oúnjẹ téèyàn ń jẹ? Kálórì ni ìwọ̀n agbára ooru tí oúnjẹ ń pèsè sínú ara. Nítorí náà, bó o bá ń làágùn, kálórì tàbí ooru inu ara rẹ ń dín kù nìyẹn. Ìwé Balance Your Body, Balance Your Life sọ pé: “Ooru inú ara tó bá pọ̀ tó kálórì kan á mú kí omi tó gba inú agolo mílíìkì mẹ́ta àtààbọ̀ lọ́ wọ́ọ́rọ́ díẹ̀.” Ìwọ̀n tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò lára ooru tàbí okun tí oúnjẹ ń fún ara yìí yàtọ̀ síra, ó sì sinmi lórí bí onítọ̀hún ṣe ga sí, bó ṣe tẹ̀wọ̀n tó, ọjọ́ orí ẹ̀ àti irú iṣẹ́ tó ń ṣe.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ẹni tó ń jókòó sójú kan ni ọ́ bó bá jẹ́ pé
◼ Àkókò tó pọ̀ jù lọ lójúmọ́ lo fi ń jókòó láti wo tẹlifíṣọ̀n tàbí sídìí tábìlì tàbí láti wakọ̀, ká ṣáà sọ pé o kì í kúrò lójú kan
◼ O kì í sábàá rìn ju ọgọ́rùn-ún mítà lọ
◼ O kì í ṣiṣẹ́ tá á mú kó o máa rìn lọ rìn bọ̀
◼ O kì í lo bí ogún sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú láti ṣeré ìdárayá, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀
[Credit Line]
A gbé ìsọfúnni yìí karí ìwé Mayo Clinic on Healthy Weight