Kí Lẹni Tó Bá Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Lè Rí Ṣe Sí I?
AṢOJÚ ìwé ìròyìn Jí! fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Diane, tó jẹ́ ògbóǹkangí onímọ̀ nípa oúnjẹ, àti Ellen, tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó níwèé ẹ̀rí ìjọba, táwọn méjèèjì jẹ́ ògbóǹkangí nídìí títọ́jú àwọn tó ki pọ́pọ́ jù àti àwọn tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Wọ́n gbà pé jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ń mú kí tááṣì tàbí carbohydrate inú ara dín kù àti jíjẹ oúnjẹ tó máa ń mú kí èròjà protein (bí ẹran) pọ̀ sí i lè mú kéèyàn fọn. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ní tó bá pẹ́ téèyàn ti ń jẹ wọ́n, àwọn nǹkan tí ò dáa lè tìdí ẹ̀ yọ.a Àtẹ ìsọfúnni kan tó dá lórí ìṣègùn tí wọ́n pè ní Maintaining a Healthy Weight jẹ́rìí sí èyí. Ó sọ pé: “Àwọn oúnjẹ tí tááṣì ò pọ̀ nínú wọn lè pani lára o, pàápàá béèyàn bá ń jẹ wọ́n láìjẹ́ pé dókítà mọ̀ sí i.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí àwọn tó bá sanra tètè jò ni. Wọ́n máa ń jẹ́ kí omi ketone (tó máa ń wá látinú ọ̀rá ti ara ti lò darí) pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.” Bó o bá fẹ́ máa jẹ oúnjẹ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní tááṣì nínú, rí i dájú pé o kọ́kọ́ lọ rí dókítà rẹ.
Bó o bá fẹ́ dín bó o ṣe sanra kù, má ṣe mikàn. Dókítà Walter C. Willett sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kéèyàn dín bó ṣe sanra kù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò túmọ̀ sí fífi ebi panú tàbí jíjẹ oúnjẹ tó tètè máa ń súni, ní àjẹtúnjẹ. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló lè dín bí wọ́n ṣe sanra kù, kí wọ́n sì wà bẹ́ẹ̀ fún àkókò gígùn bí wọ́n bá ń jẹun níwọ̀n ṣùgbọ́n lọ́nà tó gbádùn mọ́ wọn tí wọ́n sì ń ṣeré ìdárayá lójoojúmọ́, bí wọ́n bá ń sapá gidigidi tí wọ́n sì mọwọ́ yí padà. Ó gba kéèyàn sapá débi tí agbára ẹ̀ bá gbé e dé tó bá jẹ́ torí ẹ̀mí gígùn àti ara líle ni.”b—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Báwo Ni Eré Ìmárale Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
Dókítà Willett sọ pé: “Yàtọ̀ sí kéèyàn má mu sìgá, eré ìmárale lohun kan ṣoṣo tó dára jù lọ tó o lè ṣe kí ara rẹ lè dá ṣáṣá kó o sì rìn jìnnà pátápátá sí àwọn àìsàn líle koko.” Báwo ló ṣe yẹ kéèyàn máa ṣeré ìmárale tó? Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn má máa jókòó gẹlẹtẹ sójú kan?
Ìmọ̀ràn àwọn ògbógi kan ni pé ṣíṣe eré ìmárale lójoojúmọ́, ì báà jẹ́ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, máa ń ṣe ara lóore gan-an ni. Ṣùgbọ́n, àwọn kan tún ti dámọ̀ràn pé ṣíṣe eré ìmárale nígbà mẹ́ta lọ́sẹ̀ lè ranni lọ́wọ́ láti kòòré àwọn ìṣòro líle koko lọ́jọ́ iwájú. Eré ìmárale máa ń jó kálórì tàbí ooru inú ara dà nù ni, ìbéèrè pàtàkì tó sì yẹ kí ẹnì kan tó bá ń gbìyànjú láti dín bó ṣe sanra kù bi ara rẹ̀ ni pé, Ǹjẹ́ kálórì tí mò ń jó dà nù lójoojúmọ́ pọ̀ ju èyí tí mò ń rí gbà sára látinú oúnjẹ? Bó bá wá jẹ́ pé èyí tó ò ń gbà sára ló pọ̀ ju èyí tí ara ẹ ń jó dà nù, a jẹ́ pé kò sí bó ò ṣe ní máa sanra. Nítorí náà, máa rìn tàbí kó o máa gun kẹ̀kẹ́ dípò kí mọ́tò máa gbé ẹ kiri. Máa gun àtẹ̀gùn dípò kó o máa lo ẹ̀rọ tó ń gbéni ròkè. Máa ṣeré ìmárale! Máa jó kálórì inú ara dà nù!
Dókítà Willett ṣàlàyé pé: “Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn lè fi rọ́pò ìgbòkègbodò mìíràn tí kì í jẹ kéèyàn jókòó sójú kan ni ìrìn nítorí pé kò gba kéèyàn lo irinṣẹ́ pàtàkì kankan, kò sì léwu nínú.” Àmọ́, ìrìn kánmọ́kánmọ́ ni ìmọ̀ràn rẹ̀ dá lé lórí o, kì í ṣe ìrìn gbẹ̀fẹ́. Ó dábàá pé, bó bá ṣeé ṣe, kéèyàn máa ṣe é fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lójoojúmọ́.
Ṣé Iṣẹ́ Abẹ Ló Dáa Jù Láti Fi Yanjú Ìṣòro Náà?
Àwọn kan tí wọ́n sanra kọjá sísọ máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn onímọ̀ nípa ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ tí wọ́n máa ń dábàá oríṣiríṣi iṣẹ́ abẹ nítorí kí wọ́n bàa lè dín bí wọ́n ṣe sanra kù kí wọ́n má sì tún tóbi sí i lọ́jọ́ iwájú. Ta ló yẹ kó ṣe irú iṣẹ́ abẹ́ bí èyí? Àmọ̀ràn tí àwọn tó kọ ìwé Mayo Clinic on Healthy Weight mú wá ni pé: “Dókítà rẹ lè dábàá iṣẹ́ abẹ bí o bá ti wọ̀n ju ogójì BMI lọ, èyí tó fi hàn pé o ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀ jù.” (Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 5.) Àkọsílẹ̀ kan tí wọ́n pè ní Mayo Clinic Health Letter sọ pé: “Àwọn tí wọ́n sábà máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ fún nítorí pé wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀ làwọn èèyàn tí wọ́n wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí márùndínláàádọ́rin tí wọ́n sì wọ̀n ju ogójì BMI lọ, tí ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ wọn sì ń wu ìlera wọn léwu.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe iṣẹ́ abẹ náà? Lára wọn ni fífi iṣẹ́ abẹ dín oúnjẹ tó ń kọjá sínú ìfun kù, dídí àwọn apá ibì kan nínú agbẹ̀du, mímú kí ihò tí oúnjẹ ń gbà kọjá nínú agbẹ̀du tín-ínrín sí i àti dídí agbẹ̀du títí tá a fi ku ihò tóńtó kan tí oúnjẹ á máa gbà bọ́ sínú ìfun kékeré. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é tó fi ń ku ihò tóńtó ni pé wọ́n á fi nǹkan mú apá òkè agbẹ̀du, èyí tá á sún ibi tí oúnjẹ ń gbà kọjá nínú ẹ̀ kì títí tá á fi ku ojú ihò tóńtó tó lè gba ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá gé ìfun kékeré, wọ́n á sì rán an mọ́ ojú ihò tóńtó náà. Nípa bẹ́ẹ̀, oúnjẹ á máa pẹ́ ìwọ́rọ́kù ńlá sílẹ̀ á sì kọjá lọ tààràtà sínú ìfun kékeré.
Wàyí o, àwọn èèyàn tí wọ́n ti wá dín bí wọ́n ṣe tóbi tó kù ń kọ́? Ṣé gbogbo wàhálà tí wọ́n ṣe tiẹ̀ ti já síbì kankan?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lára àwọn nǹkan náà ni kí èròjà iron pọ̀ jù nínú ẹ̀jẹ̀, kí kíndìnrín má ṣiṣẹ́ dáadáa àti kí inú kún.
b Àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì fẹ́ lo ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní ìdí púpọ̀ láti dín bí wọ́n ṣe sanra kù kí ara wọn sì jí pépé. Dípò kí wọ́n kú láìtọ́jọ́, wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ lo ọ̀pọ̀ ọdún tó níláárí sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Róòmù 12:1.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àbá Nípa Bó Ṣe Yẹ Kéèyàn Máa Jẹun Sí
Míndin-mín-ìndìn Ìmọ́mọ́rán, súìtì
(má máa sábà jẹ ẹ́; kó má ju kálórì
márùndínlọ́gọ́rin lọ lóòjọ́)
Oúnjẹ Ọlọ́ràá Òróró ólífì, oríṣiríṣi ẹ̀pà,
òróró “canola,” píà (ìwọ̀n mẹ́ta sí márùn-ún
lóòjọ́; ìwọ̀n kan ni síbí òróró kan tàbí ṣíbí
ẹ̀pà méjì)
Èròjà “Protein” àti Ohun Tá À Ń Rí Lára Ohun
Ọ̀sìn Ẹ̀wà, ẹja, ẹran níwọ̀nba, ẹyin, mílíìkì,
yúgọ́ọ̀tì, wàràkàṣì (ìwọ̀n mẹ́ta sí méje lóòjọ́; ìwọ̀n
kan jẹ́ gíráàmù márùndínláàádọ́rùn-ún ẹran tàbí ẹja
bíbọ̀)
Oúnjẹ Onítááṣì Pàápàá àwọn oúnjẹ oníkóró, oúnjẹ
alápòpọ̀, búrẹ́dì, ìrẹsì, àtàwọn oúnjẹ míì tó ṣeé pò bí
ògì (ìwọ̀n mẹ́rin sí mẹ́jọ lóòjọ́; ìwọ̀n kan jẹ́ ègé búrẹ́dì
kan)
Èso àti Ewébẹ̀ Ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan (ìwọ̀n tó o bá lè jẹ ni; bó ò bá jẹ ẹ́ rárá ni kó o jẹ ìwọ̀n mẹ́ta)
Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ irú oúnjẹ jíjẹ tàbí ọ̀nà èyíkéyìí téèyàn lè fi dín bó ṣe sanra kù o. Ṣùgbọ́n, ńṣe ló wulẹ̀ ń sọ fún àwọn tó ń kà á nípa oríṣiríṣi ìtọ́jú téèyàn lè rí gbà. Á dáa kí olúkúlùkù tọ dókítà rẹ̀ lọ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe eré ìmárale èyíkéyìí tàbí kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ oúnjẹ jẹ.
[Credit Line]
Látinú àwọn àbá ti “Mayo Clinic” dá
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Káwọn kan lè dín bí wọ́n ṣe sanra kù, wọ́n ti fàwọn ìdámọ̀ràn yìí sílò:
1 Rí i pé o mọ bí kálórì tó wà nínú ohun tó ò ń jẹ tàbí ohun tó ò ń mu ṣe pọ̀ tó. Fi sọ́kàn pé: Ó lè jẹ́ látinú
2 ohun tó ò ń mu lo ti ń gba kálórì tó pọ̀ jù lọ sínú ara, pàápàá àwọn omi èso tí wọ́n bá fi ṣúgà sí. Kálórì rẹpẹtẹ tún máa ń wà nínú ọtí líle. Kó o sì tún ṣọ́ra fún àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí wọ́n máa ń polówó yẹyẹ̀ẹ̀yẹ. Wo bí kálórì tó wà nínú ẹ̀ ṣe pọ̀ tó níbi tí wọ́n kọ́ ọ sí lára ẹ̀. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu.
3 Má ṣe jẹ́ kóúnjẹ fẹjú mọ́ ẹ. Bí ìpápánu díndín, ṣokoléètì, tàbí bisikíìtì ò bá wọ́n lọ́wọ́ ẹ, kò sí bó ò ṣe ní jẹ wọ́n o! Dípò ìyẹn, máa jẹ àwọn ìpápánu tí kálórì inú wọn ò pọ̀, bí ápù, kárọ́ọ̀tì, àtàwọn bisikíìtì tí wọ́n fi àsán kóró ọkà ṣe.
4 Kọ́kọ́ máa wá nǹkan panu tàbí kó o kọ́kọ́ máa fi nǹkan tẹ́lẹ̀ ikùn kó o tó jẹun gidi. Ìyẹn á dín ebi tó ń pa ọ́ foo kù, kò sì ní jẹ́ kó o jẹun jù.
5 Má máa jẹ gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ṣáà ti gbé síwájú ẹ. Ṣe ni kó o máa yan èyí tó o bá máa jẹ. Má ṣe jẹ ohun tó o bá mọ̀ pé ó máa fún ọ ní kálórì tó pọ̀ jù.
5 Ṣe pẹ̀lẹ́. Èwo làbùrọ̀ kánjú? Gbádùn oúnjẹ ẹ nípa ṣíṣe àkíyèsí ẹ̀ dáadáa, mọ irú àwọ̀ tó ní, mọ bó ṣe dùn tó, àti bí àpapọ̀ oúnjẹ yẹn ṣe rí lẹ́nu. Mọ ìgbà tí ikùn ẹ bá sọ fún ẹ pé “èyí tó o jẹ́ tó.”
6 Ṣíwọ́ oúnjẹ kó tó di pé ikùn ẹ ràn bọnbọn.
7 Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ilé àrójẹ kan wà tí àṣejù ti wọ bí wọ́n ṣe máa ń fi oúnjẹ tó pọ̀ jù bọ́ àwọn èèyàn. Máa jẹ oúnjẹ tí wọ́n bá gbé síwájú ẹ kù, tàbí kí ìwọ àti ẹlòmíì jọ máa jẹ ẹ́.
8 Kò pọn dandan kó o mu nǹkan míì yàtọ̀ sómi lẹ́yìn oúnjẹ. Ó sàn kó o jẹ èso tàbí ohun mìíràn tí kálórì inú ẹ̀ ò pọ̀ lẹ́yìn oúnjẹ.
9 Àjẹkún oúnjẹ làwọn tó ń ṣe oúnjẹ á fẹ́ kó o máa jẹ. Èrè tí wọ́n máa jẹ ló jẹ wọ́n lógún ní tiwọn. Wọ́n ti rí i pé o lè máà ní àmójúkúrò. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n fi ìpolówó ọjà tí wọ́n fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ṣe àtàwọn àwòrán àrímáleèlọ tàn ọ́ jẹ o. O lè sọ pé o ò fẹ́!
[Credit Line]
A mú àwọn àbá yìí wá látinú ìwé Eat, Drink, and Be Healthy, látọwọ́ Dókítà Walter C. Willett
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Máa ṣeré ìmárale!