ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dín Bí Mo Ṣe Sanra Kù?
Ṣé dandan ni kí n dín bí mo ṣe sanra kù?
Àwọn ọ̀dọ́ kan sọ pé wọ́n fẹ́ dín bí wọ́n ṣe sanra kù. Àmọ́ . . .
Ọ̀pọ̀ ni ìrísí wọn ká lára ju ìlera wọn lọ. Torí kí wọ́n lè dín bí wọ́n ṣe sanra kù, ọ̀pọ̀ ti ṣe oríṣiríṣi àwọn nǹkan bí kí wọ́n febi para wọn tàbí kí wọ́n lo oògùn tó ń dín sísanra kù ní kíákíá. Pàbó làwọn ọ̀nà yìí sábà máa ń já sí, ó sì tún léwu nígbà míì.
“Àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan máa ń febi para wọn kí wọ́n lè tètè rí àyípadà. Àkóbá lèyí sábà máa ń fà, ó sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò kí ìlera wọn tó pa dà bọ̀ sípò.”—Hailey.
Kò yẹ kí ìrònú bá ẹ torí pé o sanra. Bó o ṣe sanra ò burú, àmọ́ èèyàn lè gbà pé òun ti sanra jù tó bá fara ẹ̀ wé àwọn ẹlòmíì àbí tó bá jẹ́ kí èrò pé “lẹ̀pa ló layé” táwọn ilé iṣẹ́ ìpolówó ọjà ń gbé lárugẹ kó sóun lórí.
“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, mo máa ń fara mi wé àwọn ọ̀rẹ́ mi. Mo gbà pé wọ́n á túbọ̀ fẹ́ràn mi tí mo bá rí bí tiwọn, ìyẹn témi náà bá rí tẹ́ẹ́rẹ́ bí tiwọn.”—Paola.
Àmọ́, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ kan dín bí wọ́n ṣe sanra kù. Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé . . .
Kárí ayé, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́tà àti ogójì mílíọ̀nù (340,000,000) àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùn-ún sí mọ́kàndínlógún (19) ló sanra jù.
Lọ́dún 1975, nǹkan bí ìdá kan nínú ogún lára àwọn ọ̀dọ́ ọlọ́dún márùn-ún sí mọ́kàndínlógún (19) ló sanra jù. Àmọ́ ní ọdún 2016, iye wọn ti pọ̀ sí i, ó ti di nǹkan bí ìdá kan nínú márùn-ún.
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kárí ayé, iye àwọn tó sanra jù máa ń pọ̀ ju iye àwọn tó gbẹ lọ.
A tiẹ̀ tún máa ń rí àwọn tó sanra jù ní orílẹ̀-èdè tọ́rọ̀ ajé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ dáa àti láwọn ilé tí wọn ò ti rí oúnjẹ gidi jẹ.
Ọ̀nà wo ló dára jù láti dín sísanra kù?
Èwo lo máa yàn?
Máa sá fún oúnjẹ.
Ṣe eré ìmárale kó o sì jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore.
Lo oògùn tó ń dín sísanra kù.
Ìdáhùn: Ọ̀nà kejì: Ṣe eré ìmárale kó o sì jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore.
Kéèyàn má jẹun déédéé tàbí kó pa oríṣi oúnjẹ kan tì lè mú àyípadà ojú ẹsẹ̀ wá. Àmọ́, ọ̀nà yìí léwu fún ìlera rẹ, kò sì ní pẹ́ tí wàá fi pa dà sanra tó o bá ti pa dà sí bó o ṣe ń jẹun tẹ́lẹ̀.
Àmọ́ tó o bá ní in lọ́kàn pé o fẹ́ ní ìlera tó dáa, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì gbádùn ara ẹ bó o ṣe fẹ́. Dókítà kan tó ń jẹ́ Michael Brandy asọ pé “Ọ̀nà tó dáa jù lọ, tó fini lọ́kan balẹ̀, tó sì máa mú àyípadà tó máa wà pẹ́ títí wá ni kéèyàn . . . ṣàtúnṣe sí bó ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó máa ṣe é láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tó o bá fẹ́ dín bó o ṣe sanra kù, kọ́ bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó yàtọ̀ kì í ṣe kó o ṣètò oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ kan.
Ohun tí wàá ṣe
Bíbélì sọ pé ká “má ṣe jẹ́ aláṣejù,” èyí sì kan bá a ṣe ń jẹun. (1 Tímótì 3:11) Ó tiẹ̀ dìídì sọ pé a ò gbọdọ̀ jẹ́ alájẹkì. (Òwe 23:20; Lúùkù 21:34) Torí náà, bó o ṣe ń fi àwọn ìlànà yẹn sọ́kàn, gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí kó o lè kọ́ bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó túbọ̀ dáa sí i:
Mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ oúnjẹ tó ń ṣe ara lóore.
Kò pọn dandan kó o máa fìyà jẹ ara rẹ̀ nípa oúnjẹ tó o máa jẹ, àmọ́ tó o bá mọ díẹ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore, ó máa jẹ́ kó o lè máa jẹun tó dáa. Jíjẹ oúnjẹ tó ń ṣe ara lóore jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tó o lè ṣe tó ò bá fẹ́ sanra jù.
Máa ṣe eré ìdárayá déédéé.
Ronú lórí àwọn ohun tó o lè máa ṣe lójoojúmọ́ tá a mú kára ẹ jí pépé. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa lo ẹ̀rọ tó ń gbé èèyàn sókè, máa lo àtẹ̀gùn. Dípò kó o máa lo àkókò tó pọ̀ nídìí géèmù, ṣe ni kó o rìn jáde.
Fi oúnjẹ aṣaralóore dípò àwọn oúnjẹ midinmíìdìn.
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sophia sọ pé: “Mi ò kì í jẹ́ káwọn nǹkan ìpápánu tó ń ṣara lóore bí èso àti ewébẹ̀ wọ́n mi. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí àwọn oúnjẹ tí kì í ṣara lóore wọ̀ mí lójú.”
Má kánjú jẹun.
Àwọn kan máa ń kánjú tí wọ́n bá ń jẹun débi pé wọn ò ní mọ̀gbà tí wọ́n yó! Torí náà, rọra máa jẹun. Ó yẹ kó o sinmi díẹ̀ kó o tó gba oúnjẹ sí i. O tiẹ̀ lè wá rí i pé ebi ò pa ẹ́ tó bó o ṣe rò.
Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ tó ní èròjà afáralókun pọ̀ jù nínú oúnjẹ rẹ.
Ka ìsọfúnni nípa bí èròjà afáralókun tó wà nínú oúnjẹ ẹ ṣe pọ̀ tó. Àbá: Ọtí ẹlẹ́rìndòdò àtàwọn ìpápánu máa ń ní èròjà afáralókun tó pọ̀, ó sì lè mú kéèyàn sanra.
Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì.
Sara tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) sọ pe: “Nígbà tó yá, ó wọ̀ mí lára débi pé kí n tó jẹ oúnjẹ kankan, màá kọ́kọ́ wo bí èròjà afáralókun tó wà nínú ẹ̀ ṣe pọ̀ tó!” Má ti àṣejù bọ̀ ọ́, kò sóhun tó burú nínú kéèyàn jẹ oúnjẹ afáralókun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó sì tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn.
Àbá: Jẹ́ kí dókítà rẹ mọ̀ pé bó o ṣe sanra kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Tó bá ti mọ bí ara ẹ ṣe rí, ó máa kọ́ ẹ ní ohun tí wàá máa ṣe tó máa jẹ́ kí ìlera rẹ dára sí i.
a Látinú ìwé When Things Get Crazy With Your Teen.