ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 11/1 ojú ìwé 4-6
  • Ìgbà Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Kẹta Bẹ̀rẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Kẹta Bẹ̀rẹ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbà Wo La Bí Jésù?
  • Ṣé Ìrètí Wọn Nípa Ẹgbẹ̀rúndún Yóò Já Sásán Ni?
  • Ó Yá Jù Ni, Àbí Ó Pẹ́ Jù?
    Jí!—1999
  • Ọdún 2000—Ṣọ́dún Abàmì Ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Báwo Ni Ọdún 2000 Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
    Jí!—1998
  • Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?
    Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 11/1 ojú ìwé 4-6

Ìgbà Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Kẹta Bẹ̀rẹ̀?

ǸJẸ́ o ti gbọ́ táwọn kan ń sọ pé kì í ṣe ọdún 2000 ni ẹgbẹ̀rúndún kẹta yóò bẹ̀rẹ̀, pé ó di ọdún 2001? Dé àyè kan, wọn ò purọ́. Báa bá gbà pè ọdún 1 ṣááju Sànmánì Tiwa la bí Jésù, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti gbà, nígbà náà, December 31, 2000 ni ẹgbẹ̀rúndún kejì yóò parí, (kò ní jẹ́ 1999), ẹgbẹ̀rúndún kẹta yóò sì wá bẹ̀rẹ̀ ní January 1, 2001.a Ṣùgbọ́n, lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló gbà pé kì í ṣe ọdún 1 ṣááju Sànmánì Tiwa la bí Jésù. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ìgbà wo la bí i?

Ìgbà Wo La Bí Jésù?

Bíbélì kò sọ ọjọ́ gan-an pàtó táa bí Jésù. Àmọ́, ohun tó kàn ṣáà sọ ni pé, a bí i “ní àwọn ọjọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba.” (Mátíù 2:1) Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ló gbà pé ọdún 4 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Hẹ́rọ́dù kú, àti pé a ti bí Jésù ṣáájú ìgbà yẹn—àfàìmọ̀ ni ò fi ní jẹ́ láti nǹkan bí ọdún 5 tàbí 6 ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọ́n gbé èrò wọn ka ohun tí òpìtàn Júù ọ̀rúndún kìíní nì, Flavius Josephus, sọ.b

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Josephus sọ, nígbà tó kù díẹ̀ kí Hẹ́rọ́dù Ọba kú, òṣùpá ṣíji bo oòrùn. Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ tọ́ka sí àkókò kan tí apá kan òṣùpá ṣíji bo apá kan oòrùn, ìyẹn ni March 11, ọdún 4 ṣááju Sànmánì Tiwa, ẹ̀rí kan nìyí pé Hẹ́rọ́dù ti kú ṣáájú ọdún yẹn. Àmọ́ ṣá o, lọ́dún 1 ṣááju Sànmánì Tiwa, ní January 8 òṣùpá ṣíji bo oòrùn pátápátá tí ọ̀sán fi dòru, apá kan òṣùpá sì tún ṣíji bo oòrùn ní December 27. Kò sẹ́ni tó lè wá sọ bóyá ìgbà tí òṣùpá ṣíji bo oòrùn ní ọdún 1 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Josephus ń tọ́ka sí tàbí èyí tó wáyé ní ọdún 4 ṣááju Sànmání Tiwa. Nítorí náà, a kò lè lo ọ̀rọ̀ Josephus láti tọ́ka sí ọdún náà gan-an tí Hẹ́rọ́dù kú. Ká tiẹ̀ gbà pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá, tí kò bá sì ìsọfúnni mìíràn, a kò tíì lè sọ ọjọ́ táa bí Jésù.

Ẹ̀rí tó lágbára jù lọ táa ní nípa ọjọ́ táa bí Jésù wá láti inú Bíbélì. Àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé Jòhánù Oníbatisí, ìbátan Jésù, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tíbéríù Késárì tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù. (Lúùkù 3:1, 2) Ìwè ìtàn jẹ́rìí sí i pé September 15, ọdún 14 Sànmánì Tiwa, ni Tìbéríù joyè Olú Ọba, nítorí náà ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún rẹ̀ yóò jẹ́ apá ìparí ọdún 28 Sànmánì Tiwa sí apá ìparí ọdún 29 Sànmání Tiwa. Ìgbà yẹn ni Jòhánù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì hàn gbangba pé oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tirẹ̀. (Lúùkù 1:24-31) Èyí, àti àwọn ẹ̀rí mìíràn, fi ìgbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí ìgbà ìkórè ọdún 29 Sànmánì Tiwa.c Bíbélì sọ pé Jésù jẹ́ “ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún” nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Lúùkù 3:23) Bó bá jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà ìkórè ọdún 29 Sànmánì Tiwa, a ti gbọ́dọ̀ bí i ní ìgbà ìkórè ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa. Wàyí o, táa bá wa ka ẹgbàá ọdún láti ìgbà ìkórè ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa (táa sì rántí pé kó sí ọdún òfo; nítorí náà, ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa sí ọdún 1 Sànmánì Tiwa jẹ́ ọdún méjì), a ó rí i pé ẹgbẹ̀rúndún kejì parí ní ìgbà ìkórè ọdún 1999, ìgbà yẹn náà sì ni ẹgbẹ̀rúndún kẹta bẹ̀rẹ̀!

Ṣé ìyẹn já mọ́ nǹkankan ni? Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún kẹta yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù Kristi, táa tọ́ka sí nínú ìwé Ìṣípayá? Rárá o. Kò sí ibì kan tí Bíbélì ti sọ pé ẹgbẹ̀rúndún kẹta ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ẹgbẹ́rùn Ọdún Ìjọba Kristi.

Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa míméfò nípa ọjọ́. Ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 1:7) Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti sọ fún wọn pé òun kò tiẹ̀ mọ ìgbà tí Ọlọ́run yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ètò burúkú yìí, tí ìyẹn yóò sì jẹ́ kí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi bẹ̀rẹ̀. Ó wí pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.”—Mátíù 24:36.

Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé Kristi yóò padà wá nígbà tó bá pé ẹgbàá ọdún gééré táa ti bí i gẹ́gẹ́ bí èèyàn? Rárá o, kò bọ́gbọ́n mu. Jésù fúnra rẹ̀ mọ ọjọ́ táa bí i. Ó sì mọ bó ṣe lè ka ẹgbàá ọdún sí ìgbà náà. Síbẹ̀, kò mọ ọjọ́ àti wàkátí tí òun yóò wá. Ó ṣe kedere pé, mímọ́ ọjọ́ tí yóò padà wá kò kàn lè rọrùn bẹ́ẹ̀! “Ìgbà àti àsìkò” wà ní ọwọ́ Baba, ìyẹn ni pé, òun nìkan ló mọ ìgbà tí àkókò náà yóò jẹ́.

Síwájú sí i, Jésù kò pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti dúró de òun ní ibì kan pàtó. Ó wí fún wọn pé, kí wọn má ṣe kóra jọ sójú kan, kí wọ́n láwọn ń dúró de òun, ṣùgbọ́n kí wọ́n fọ́n káàkiri lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” kí wọ́n sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Kò tíì yí àṣẹ yẹn padà.—Ìṣe 1:8; Mátíù 28:19, 20.

Ṣé Ìrètí Wọn Nípa Ẹgbẹ̀rúndún Yóò Já Sásán Ni?

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹlẹ́sìn kan tó jẹ́ pé ìtumọ̀ ṣáńgílítí ni wọ́n ń fún ẹ̀kọ́ Bíbélì gbà pé kutupu ó hu lọ́dún 2000. Wọ́n gbà pé láàárín oṣù díẹ̀ sí i, àwọn apá kan nínú ìwé Ìṣípayá yóò nímùúṣẹ ní ṣáńgílítí. Kódà, wọ́n tilẹ̀ gbà pé àwọn gan-an ni ọ̀rọ̀ náà yóò ṣẹ sí lára. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ táa kọ sílẹ̀ nínú Ìṣípayá 11:3, 7, 8, èyí tó sọ nípa àwọn ẹlẹ́rìí méjì tó sọ tẹ́lẹ̀ nínú “ìlú ńlá títóbi náà, èyí tí a ń pè lọ́nà ìtumọ̀ ti ẹ̀mí ní Sódómù àti Íjíbítì, níbi tí a ti kan Olúwa wọn mọ́gi.” Nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́ ìjẹ́rìí wọn, ẹranko ẹhànnà burúkú kan tó jáde wá láti inú ọ̀gbun pa wọ́n jẹ.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn The New York Times Magazine ti December 27, 1998, ti sọ, aṣáájú ẹ̀sìn kan “ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́rìí méjì táa ti kádàrá wọn pé àwọn ni yóò kéde ìparun ayé àti bíbọ̀ Olúwa—tí Sátánì yóò sì wá pa wọ́n sí ìgboro Jerúsálẹ́mù.” Abájọ tọ́kàn àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Ísírẹ́lì ò fi balẹ̀ mọ́. Wọ́n ń fòyà pé àwọn agbawèrèmẹ́sìn kan lè gbìyànjú láti “mú” àsọtẹ́lẹ̀ náà “ṣẹ” lọ́wọ́ ara wọn—kódà bí ìyẹn bá tiẹ̀ máa dá ogun sílẹ̀! Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ò nílò “ìrànlọ́wọ́” ènìyàn láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ni yóò nímùúṣẹ nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ni yóò sì gbà ṣẹ.

Ìwé Ìṣípayá kún fún “àwọn àmì.” Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 1:1 ti sọ, Jésù fẹ́ fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han “àwọn ẹrú rẹ̀” (kì í ṣe gbogbo ayé lápapọ̀). Láti lóye ìwé Ìṣípayá, àwọn ẹrú Kristi, tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, yóò nílò ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, èyí tí Jèhófà ń fún àwọn tó bá wù ú. Bó bá jẹ́ pé a kàn lè lóye ìwé Ìṣípayá ní ṣáńgílítí bẹ́ẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ pàápàá lè kà á, káwọn náà sì lóye rẹ̀. Nígbà náà, kò ní sídìí kankan fáwọn Kristẹni láti máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́, kí wọ́n bàa lè lóye rẹ̀.—Mátíù 13:10-15.

A ti rí i pé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí Bíbélì, táa bá ṣírò rẹ̀ láti ìgbà táa bí Jésù, ìgbà ìkórè ọdún 1999 ni ẹgbẹ̀rúndún kẹta bẹ̀rẹ̀, kókó mìíràn sì ni pé yálà ìgbà ìkórè yẹn ló bẹ̀rẹ̀ o, tàbí January 1, ọdún 2000, tàbí January 1, 2001, ọdún kan kò ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ. Síbẹ̀, ẹgbẹ̀rúndún kan ń bẹ tí àwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ sí gan-an. Tí kì í bá wá ṣe ẹgbẹ̀rúndún kẹta, èwo wá ni? Àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ yìí ni yóò dáhùn rẹ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ṣọ́dún 2000 Ni Àbí Ọdún 2001?” lójú ìwé 5.

b Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò ọjọ́ táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wọ̀nyí gbé kalẹ̀, ó ti yẹ kí ẹgbẹ̀rúndún kẹta bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1995 tàbí 1996.

c Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ wo ìwé Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 1094 sí 1095.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Ṣọ́dún 2000 Ni Àbí Ọdún 2001?

Láti lóye ìdí tí àwọn kan fi sọ pé ṣíṣírò ẹgbẹ̀rúndún kẹta láti ìgbà ìbí Jésù yóò bọ́ sí January 1, 2001, gbé àkàwé yìí yẹ̀ wò. Kà gbà pé ò ń kàwé kan tí ojú ewé tó ní jẹ́ igba. Nígbà tóo dè òke òjú ìwé igba, ó ti ka ojú ìwé mọ́kàndínnígba tán, ó kú ojú ìwé kan ṣoṣo fún ẹ láti kà. Oò lè sọ pé o ti kàwé náà tán láì tí ì kà á dé òpin ojú ìwé igba. Bákan náà, tó bá di December 31, 1999, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti gbà, ọdún kọkàndínlẹ́gbàá nínú ẹgbẹ̀rúndún táà ń lò lọ yìí, yóò ti kọjá, ó ṣì ku ọdún kan ká tó parí ẹgbẹ̀rúndún náà. Táa bá tẹ̀ lé ìṣirò yìí, ẹgbẹ̀rúndún kẹta yóò bẹ̀rẹ̀ ní January 1, ọdún 2001. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ yìí ti fi hàn, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé, ọjọ́ yẹn gan-an ni yóò pé ẹgbàá ọdún táa bí Jésù.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Bí Wọ́n Ṣe Gbé Ìṣirò Ọdún Ṣááju Sànmánì Tiwa àti Ọdún Sànmánì Tiwa Kalẹ̀

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹfà Sànmánì Tiwa, Póòpù John Kìíní fún ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dionysius Exiguus láṣẹ láti gbé ètò kan kalẹ̀ tí ṣọ́ọ̀ṣì yóò lè máa fi ṣírò ọjọ́ ọdún Easter.

Dionysius dáwọ́ lé iṣẹ́ náà. Ó ṣírò ọjọ́ padà sẹ́yìn, ó gbé e kọjá àkókò tí Jésù kú, ó gbé e lọ sí ọdún tó gbà pé a bí Jésù; ó wà bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọdún láti ọdún yẹn síwájú. Dionysius lo “A.D.” (ìyẹn ni Anno Domini—“ní ọdún Olúwa wa”) láti dúró fún àwọn ọdún tó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìbí Jésù. Níbi tí Dionysius ti ń wá bí a ó ṣe máa ṣírò ọjọ́ ọdún Easter, bó ṣe di ẹni tó gbé ọgbọ́n ṣíṣírò ọdún láti ìgbà ìbí Kristi síwájú kalẹ̀ nìyẹn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ni kò gbà pé a bí Jésù ní ọdún tí Dionysius lò fún ìṣirò rẹ̀, ètò ìṣirò ọdún tó lò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí àwọn nǹkan ṣe ń ṣẹlẹ̀ láti ọdún sí ọdún, a sì ń rí i bí wọ́n ṣe so kọ́ra.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́