Ó Yá Jù Ni, Àbí Ó Pẹ́ Jù?
Ọ̀RỌ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún àti ẹgbẹ̀rúndún kẹta lẹ́yìn ìbí Jésù Kristi ló gbòde kan báyìí. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, “ó jọ pé ọ̀rúndún ogún, tó bẹ̀rẹ̀ bí Ọ̀rúndún Ogun Runlérùnnà, tó sì wá di Sànmánì Alágbára Átọ́míìkì, wá ń parí lọ báyìí gẹ́gẹ́ bíi Sànmánì Eré Ìnàjú.” Nínú ẹ̀dà tí ìwé ìròyìn yìí gbé jáde ní January 22, 1997, ó ròyìn pé: “Èèyàn ò lè rí yàrá gbà mọ́ nínú àwọn òtẹ́ẹ̀lì kárí ayé,” nítorí wọ́n ti rà wọ́n pa fún Ọjọ́ Àìsùn Ọdún Tuntun, tí yóò wáyé ní December 31, 1999.
Àmọ́, ṣe làwọn kan tún wá ń sọ pé ọjọ́ ayẹyẹ ọ̀hún ṣì jìnnà. Wọ́n ní ohun táwọn èèyàn ń sọ ò tọ̀nà, wọ́n ní kì í ṣe January 1, 2000, ni ọ̀rúndún kọkànlélógún àti ẹgbẹ̀rúndún tuntun yóò bẹ̀rẹ̀ bí kò ṣe January 1, 2001. Níwọ̀n bí kò ti sí ọdún òdo, wọ́n ní ọ̀rúndún kìíní bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kìíní sí ọdún ọgọ́rùn-ún [1-100], ọ̀rúndún kejì sì bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kọkànlélọ́gọ́rùn-ún sí ọdún igba [101-200], àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Fún ìdí yìí, wọ́n ní ó di December 31, 2000, kí ọ̀rúndún ogún, tó bẹ̀rẹ̀ ní January 1, 1901, àti ẹgbẹ̀rúndún kejì, tó bẹ̀rẹ̀ ní January 1, 1001, tó dópin.
Ó ṣì ku nǹkan kan tó tún yẹ láti ronú lé. Kàlẹ́ńdà táà ń lò lóde òní pín àkókò sí ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìbí Kristi. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wá rí i báyìí pé wọ́n ti bí Jésù ṣáájú ìgbà tí àwọ́n ń rò tẹ́lẹ̀ pé wọ́n bí i, ìyẹn sì wá jẹ́ kí déètì tí wọ́n gbé kàlẹ́ńdà náà kà mẹ́hẹ. Ohùn ò ṣọ̀kan nípa ìgbà ìbí Jésù, ṣùgbọ́n ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tọ́ka sí ọdún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa. Báa bá ṣírò rẹ̀ láti ìgbà yẹn, á jẹ́ pé ìgbà ìwọ́wé ọdún yìí gan-an ni ẹgbẹ̀rúndún kẹta lẹ́yìn ìbí Kristi bẹ̀rẹ̀ ní tòótọ́! Ìsọfúnni púpọ̀ sí i wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti May 22, 1997, ojú ìwé 28, àti ti December 22, 1975, ojú ìwé 27 [Gẹ̀ẹ́sì].a
Àmọ́ ṣá o, á dáa kéèyàn yẹra fún fífi gbogbo ẹnu sọ pé ọ̀rúndún kọkànlélógún àti ẹgbẹ̀rúndún tuntun yóò wọlé dé lẹ́nu ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí i. Ṣùgbọ́n ṣá, nítorí ojú ìwòye tó gbòde kan, Jí! rí i pé ó bójú mu lọ́wọ́ táa wà yìí láti jíròrò kókó náà “Ọ̀rúndún Ogún—Àwọn Ọdún Ìyípadà Pípabanbarì.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tún wo ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti November 1, 1999.