ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 11/1 ojú ìwé 3-4
  • Ọdún 2000—Ṣọ́dún Abàmì Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọdún 2000—Ṣọ́dún Abàmì Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbà Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Kẹta Bẹ̀rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Báwo Ni Ọdún 2000 Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
    Jí!—1998
  • Ó Yá Jù Ni, Àbí Ó Pẹ́ Jù?
    Jí!—1999
  • Wá Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Ìrètí Àtàtà
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 11/1 ojú ìwé 3-4

Ọdún 2000—Ṣọ́dún Abàmì Ni?

ǸJẸ́ ohun kan wà tó jẹ́ bàbàrà nípa ọdún 2000? Ní gbogbo gbòò, àwọn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Ayé kà á sí ọdún àkọ́kọ́ nínú Ẹgbẹ̀rúndún Kẹta. Ìmurasílẹ̀ rẹpẹtẹ ti ń lọ lọ́wọ́ báyìí láti ṣayẹyẹ rẹ̀. Wọ́n ti gbé aago gbàǹgbà kan tó ń lo bátìrì kọ́ báyìí, èyí ni yóò máa ka ìṣẹ́jú àáyá títí ilẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún náà yóò fi mọ́. Ètò ti ń lọ lọ́wọ́ lórí jíjó ijó Àìsùn Ọdún Tuntun náà. Àwọn ilé ìtajà tó wà ní àwọn ìgbèríko, àtèyí tó wà ni ìlú ńláńlá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ta àwọn ṣẹ́ẹ̀tì alápá péńpé táa kọ àkọlé amóríwú nípa ìparí ẹgbẹ̀rúndún sí.

Gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì, ńláńlá àti kéékèèké, ni yóò kópa nínú ayẹyẹ tí yóò gba odindi ọdún kan yìí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tó ń bọ̀, Póòpù John Paul Kejì la retí pé yóò lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti ṣáájú àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì nínú ohun tí wọ́n pè ní “àjọ̀dún júbílì ẹgbẹ̀rúndún ti Ìjọ Roman Kátólíìkì.” A fojú bù ú pé, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ sí mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn aṣèbẹ̀wò, látorí àwọn tó gba ẹ̀sìn lójú méjèèjì títí dórí àwọn tó wá ṣe ojúùmító, ló ń wéwèé láti bẹ Ísírẹ́lì wò lọ́dún tí ń bọ̀.

Kí ló dé tí èrò tó pọ̀ tó báyìí fi ń múra àtiṣèbẹ̀wò sí Ísírẹ́lì? Nígbà tí Roger Kádínà Etchegaray, ọ̀gá kan lábẹ́ Ìjọba Póòpù, ń gbẹnu sọ fún Póòpù, ó wí pé: “Ọdún 2000 jẹ́ ọdún tí a ó fi ṣàjọ̀dún Kristi àti ìgbésí ayé rẹ̀ nílẹ̀ yìí. Nítorí náà, bó ti yẹ kó rí náà nìyẹn pé, Póòpù yóò wá síbí.” Kí wá ni ọdún 2000 ní í ṣe pẹ̀lú Kristi? Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ọdún 2000 ni yóò jẹ́ ẹgbàá ọdún gééré táa bí Kristi. Ṣùgbọ́n, ṣóòótọ́ ni? Tóò, ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

Àwọn ẹlẹ́sìn kan tiẹ̀ wà tọ́dún 2000 jọ lójú bí nǹkan míì. Wọ́n gbà pé láàárín ọdún tí ń bọ̀ yìí sẹ́, Jésù yóò padà sí Òkè Ólífì, ogun Amágẹ́dọ́nì, táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá, yóò sì jà ní àfonífojì Mẹ́gídò. (Ìṣípayá 16:14-16) Látàrí ohun tí wọ́n ń retí yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùgbé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ti gbé ilé wọn tà, ọ̀pọ̀ ti ta dúkìá wọn, wọ́n sì ti ń ṣí lọ sí Ísírẹ́lì. Fún àǹfààní àwọn tí ò lè fi ilé wọn sílẹ̀, ajíhìnrere kan tó gbajúgbajà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà la gbọ́ pé ó ti ṣèlérí láti kéde ìpadàbọ̀ Jésù lórí tẹlifísọ̀n—lọ́nà tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀!

Ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Ayé, ọ̀pọ̀ ètò láti ṣayẹyẹ ẹgbẹ̀rúndún kẹta túbọ̀ ń rinlẹ̀ sí i. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ èèyàn láwọn ilẹ̀ míì ló jẹ́ pé ìgbésí ayé tiwọn ni wọ́n kọjú mọ́. Àwọn wọ̀nyí—ìyẹn àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú olùgbé ayé—kò gbà pé Jésù ti Násárétì ni Mèsáyà náà. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ fífi orúkọ rẹ̀ ka ọjọ́ ṣááju Sànmánì Tiwa àti ní Sànmánì Tiwa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ló ní kálẹ́ńdà tiwọn, nínú èyí tó jẹ́ pé ọdún tó ń bọ̀ yóò jẹ́ ọdún 1420—kì í ṣe ọdún 2000. Àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí máa ń ka ọdún tiwọn láti ìgbà tí wòlíì Mọ̀ọ́mọ́dù sá láti Mẹ́kà lọ sí Mẹ̀dínà. Gbogbo ẹ̀, gbògbò ẹ̀, nǹkan bí ogójì kàlẹ́ńdà tó yàtọ̀ síra làwọn èèyàn ń lò kárí ayé.

Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọdún 2000 jẹ́ ọdún bàbàrà lójú àwọn Kristẹni? Ṣé lóòótọ́ ni January 1, 2000, yóò jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé? A ó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́