Wá Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Ìrètí Àtàtà
ÌWỌ yóò gbọ́ irú ọ̀rọ̀ yẹn níbi àwíyé fún gbogbo ènìyàn tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Bí A Ti Sọ Tẹ́lẹ̀,” tí a ó sọ níbi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tí a ó ṣe lọ́dún yìí wọ January ọdún tí ń bọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí pé ọdún 2000 yóò jẹ́ ọdún ìbùkún fọ́mọ aráyé.
Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní yunifásítì kan sọ pé: “Sáà ẹgbẹ̀rúndún tí ń bọ̀ yìí yóò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wa láti sọ pé ó dìgbà fún ọ̀rúndún burúkú yìí.” Ìwé ìròyìn Maclean’s sì sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọdún 2000 kò yàtọ̀ sọ́dún mìíràn lórí kàlẹ́ńdà, ó kúkú lè lọ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ tuntun pèré.” Ṣùgbọ́n o, lójú gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láyé, bóyá ni àlá yìí lè ṣẹ.
Òtúbáńtẹ́ ni gbogbo kìràkìtà téèyàn ń ṣe láti mú “ìbẹ̀rẹ̀ tuntun” wá. Èé ti rí, nígbà náà, táa fi lè nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe lóhun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún sẹ́yìn pé, “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun”? (Ìṣípayá 21:5) Àsọyé amọ́kànyọ̀ yìí yóò là á yéni yékéyéké. O lè lọ gbọ́ ọ níbi tó sún mọ́ ẹ, nítorí pé bẹ̀rẹ̀ láti October yìí, a ó sọ àsọyé yìí ní àwọn àpéjọpọ̀ tó ju ọgọ́rùn-ún lọ kárí orílẹ̀-èdè yìí.
Béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ, tàbí kí o kọ̀wé béèrè lọ́wọ́ àwa táa ń ṣe ìwé ìròyìn yìí nípa àpéjọpọ̀ tó sún mọ́ ẹ jù lọ. Ìwé ìròyìn wa kejì, ìyẹn Ilé Ìṣọ́, ẹ̀dà ti May 1, 1999, ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbogbo ibi tí a ó ti ṣe àpéjọpọ̀ yìí ní Nàìjíríà.