Ẹ Wá Gbọ́ Àwíyé Fún Gbogbo Ènìyàn Lọ́fẹ̀ẹ́ “Ọ̀nà Kan Ṣoṣo sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
Ní nǹkan bí 20 ọdún sẹ́yìn, Ọ̀mọ̀wé Alvin Silverstein kọ nínú ìwé rẹ̀ náà, Conquest of Death, pé: “A óò túdìí ohun tó wà lẹ́yìn ìwàláàyè. A óò lóye . . . bí ènìyàn ṣe ń darúgbó.” Ó tilẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kò ní sí àwọn ‘arúgbó’ mọ́, nítorí pé ìmọ̀ tí yóò jẹ́ kí a ṣẹ́gun ikú yóò mú wíwà léwe títí ayérayé wá pẹ̀lú.”
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times Magazine ti September 28, 1997, ròyìn lórí ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára ti “mímú ìwàláàyè gùn” tí àwọn ènìyàn bí mélòó kan tí ìlera jẹ lọ́kàn, tí wọ́n ní ìtara-ọkàn nípa ohun tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lè ṣe lóde òní, ní. Onítara-ọkàn kan sọ pé: “Mo gbà gbọ́ gidi pé a lè di ìran àkọ́kọ́ tí yóò wà láàyè títí láé.” Wọ́n sọ nípa òmíràn pé ó “ní ìdánilójú ọlọ́yàyà . . . pé àwọn ìlànà ṣíṣẹ̀kún apilẹ̀ àbùdá yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí àkókò ti ń lọ láti gba [ìran yìí] là nípa dídá ìdarúgbó dúró, bóyá kí ó máa sọ arúgbó dèwe.” Ǹjẹ́ irú ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára bẹ́ẹ̀ yà ọ́ lẹ́nu?
Ìwọ ha gbà gbọ́ pé ènìyàn yóò ṣẹ́gun ikú nípasẹ̀ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ rẹ̀ bí? Àbí ọ̀nà mìíràn ha wà tí a lè gbà wà láàyè títí láé? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn jákèjádò ayé ní ìdánilójú pé a lè rí ìyè àìnípẹ̀kun ní tòótọ́. Kọ́ nípa bí ó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀ nípa gbígba ìkésíni láti wá gbọ́ àwíyé tí ń runi sókè náà, “Ọ̀nà Kan Ṣoṣo sí Ìyè Àìnípẹ̀kun,” tí a óò gbé jáde lákànṣe ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. O lè lọ gbọ́ ọ ní ilẹ̀ ìpàdé kan tí ó sún mọ́ ilé rẹ, nítorí pé láti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, wọn óò sọ ọ́ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àpéjọpọ̀ jákèjádò ayé.
Kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ̀ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí wọ́n ṣe ìwé ìròyìn yìí láti mọ ilẹ̀ àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọ jù lọ.