ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kn36 ojú ìwé 1-4
  • Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?
  • Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Ṣé Ìbẹ̀rẹ̀ Sànmánì Tuntun Ni?
  • Ìbàyíkájẹ́
  • Àìsàn
  • Àìríná-Àìrílò
  • Ogun
  • Mìlẹ́níọ̀mù Tí Yóò Ṣaráyé Lóore
  • Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè!
  • Ó Yá Jù Ni, Àbí Ó Pẹ́ Jù?
    Jí!—1999
  • Ìgbà Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Kẹta Bẹ̀rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Mímú Ìfẹ́ Tí Ìròyìn Ìjọba No. 36 Ru Sókè Dàgbà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Kí Ni Ká Máa Retí Lọ́jọ́ Ọ̀la?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?
kn36 ojú ìwé 1-4

Ìròyìn Ìjọba No. 36

Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Kí Ni Ká Máa Retí?

Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun Ṣé Ìbẹ̀rẹ̀ Sànmánì Tuntun Ni?

LÁAGO méjìlá òru December 31, ọdún 1999 ni ọ̀rúndún ogún parí.a Ọ̀rúndún tó kún fún làásìgbò ni. Síbẹ̀, ó tún jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ oríṣiríṣi ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìtẹ̀síwájú tó bùáyà nínú ìmọ̀ ìṣègùn, ìsọfúnni yaágbó-yaájù, àti ètò ọrọ̀ ajé kárí ayé tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ láìdáwọ́dúró. Ọ̀pọ̀ ló ti wá tipa báyìí ka mìlẹ́níọ̀mù tuntun náà sí àmì tó ń fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, pé àyípadà dé tán. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ òpin ogun, àìríná-àìrílò, ìbàyíkájẹ́, àti àrùn bí?

Ọ̀pọ̀ ló rò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó dájú pé mìlẹ́níọ̀mù tuntun náà yóò mú ìyípadà tí yóò ṣe ọ́ láǹfààní wá—ìyípadà tí yóò máyé dẹrùn fún ìwọ àti ìdílé rẹ, tí yóò sì fi yín lọ́kàn balẹ̀? Ìwọ tiẹ̀ wo bí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táà ń dojú kọ ṣe kàmàmà tó.

Ìbàyíkájẹ́

Àwọn ilẹ̀ tí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá pọ̀ sí “ń fa ìbàyíkájẹ́ kárí ayé, wọ́n ń fa òórùn àti ìdọ̀tí, wọ́n sì ń fa àìṣedéédéé nínú ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ní ibi púpọ̀.” Bọ́ràn bá ń lọ bó ṣe ń lọ yìí, “ipò àyíká tí Ọlọ́run dá ni a óò wu léwu lọ́nà tí ó ga.”— “Global Environment Outlook—2000,” United Nations Environment Programme.

Àìsàn

“Nígbà tó bá fi máa di ọdún 2020, àwọn àrùn tí kì í ranni la retí pé yóò jẹ́ okùnfà ikú àwọn ẹni méje nínú mẹ́wàá ní àwọn àgbègbè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ní ìyàtọ̀ sí iye tí kò tó ìdajì lónìí.”— “The Global Burden of Disease,” Harvard University Press, 1996.

Àwọn ògbógi kan tiẹ̀ ń sọ pé, “nígbà tó bá fi máa di ọdún 2010, mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́rin yóò ti dín lára iye àwọn ènìyàn [tó máa wà láàyè] ní àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún tó ní àjàkálẹ̀ àrùn tó burú jù lọ [éèdì].”—“Confronting AIDS: Evidence From the Developing World,” a report of the European Commission and the World Bank.

Àìríná-Àìrílò

“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn tí owó tí wọ́n ń rí láti fi gbọ́ bùkátà lójúmọ́ kò tó dọ́là kan, iye tí ó sì sún mọ́ bílíọ̀nù kan ènìyàn ni wọn kì í rí oúnjẹ tó tó jẹ lójúmọ́.”—“Human Development Report 1999,” United Nations Development Programme.

Ogun

“Rìgbòrìyẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín [onírúurú ilẹ̀] lè di èyí tápá ò ká. Bó ti jẹ́ pé [ìpínyà] láàárín ẹ̀yà, ìran, àti ẹ̀sìn ló ń fà á, . . . irú ìwà jàgídíjàgan bẹ́ẹ̀ yóò di . . . irú ìforígbárí kan tó máa wọ́pọ̀ jù lọ ní ọdún márùndínlọ́gbọ̀n àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún yìí . . . , tí yóò máa ṣekú pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn lọ́dọọdún.”—“New World Coming: American Security in the 21st Century,” U.S. Commission on National Security/21st Century.

Nítorí náà, afẹfẹyẹ̀yẹ̀ àti pọ̀pọ̀ṣìnṣìn mìlẹ́níọ̀mù tuntun ló ṣíji bo òtítọ́ náà pé ńṣe ni ewu ìbàyíkájẹ́, àìsàn, àìríná-àìrílò, àti ogun túbọ̀ ń ga sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun tó sì wà nídìí ìṣòro yìí ni ìwọra, àìgbẹ́kẹ̀léni, àti ìmọtara-ẹni-nìkan, èyí tó jẹ́ àwọn ìwà tí ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ti ìmọ̀ ẹ̀rọ, tàbí ti ìṣèlú kò lè mú kúrò.

Mìlẹ́níọ̀mù Tí Yóò Ṣaráyé Lóore

Òǹkọ̀wé ìgbà láéláé kan sọ nígbà kan rí pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Kì í ṣe agbára láti ṣàkóso ayé nìkan lènìyàn ò ní, ènìyàn ò tún ní ẹ̀tọ́ láti ṣe é. Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run nìkan, ló ní ẹ̀tọ́ tí ó sì tún mọ ọ̀nà àtiyanjú àwọn ìṣòro aráyé.​—⁠Róòmù 11:​33-36; Ìṣípayá 4:⁠11.

Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni yóò ṣe é? Báwo sì ni yóò ṣe ṣé e? Ẹ̀rí pé a ti sún mọ́ òpin “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” pọ̀ lọ jàra. Jọ̀wọ́, ṣí Bíbélì rẹ, kí o sì ka 2 Tímótì 3:​1-5. Kedere ló ṣàpèjúwe ìwà tí àwọn ènìyàn yóò máa hù ní “àwọn àkókò lílekoko” wọ̀nyí. Mátíù 24:​3-14 àti Lúùkù 21:​10, 11 tún ṣàpèjúwe “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ọ̀rọ̀ ibẹ̀ dá lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táa lè fojú rí, tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti ọdún 1914 wá, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí ogun, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ tí ń tàn kálẹ̀.

Láìpẹ́ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yóò dópin. Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba [ti ayé] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Nípa báyìí, wọ́n ti sọ ọ́ ṣaájú pé Ọlọ́run yóò fìdí Ìjọba, tàbí àkóso kan múlẹ̀, tí yóò ṣàkóso lórí ayé. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 20:4 ṣe sọ, ìjọba yìí yóò ṣàkóso fún ẹgbẹ̀rún ọdún, tí í ṣe mìlẹ́níọ̀mù kan! Ìwọ wo àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí ipò ìgbé ayé yóò gbà sunwọ̀n sí i fún gbogbo aráyé nígbà Mìlẹ́níọ̀mù ológo yìí:

Ọ̀ràn Ìgbọ́bùkátà. “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”​​—⁠Aísáyà 65:​21, 22.

Ọ̀ràn Ìlera. “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”​—⁠Aísáyà 33:24; 35:​5, 6.

Ipò Àyíká. Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”​—⁠Ìṣípayá 11:⁠18.

Àjọṣepọ̀ Láàárín Ẹ̀dá Ènìyàn. “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”​—⁠Aísáyà 11:⁠9.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló gba àwọn ìlérí Bíbélì wọ̀nyí gbọ́, wọ́n sì ti tipa báyìí ní èrò pé, dájúdájú, nǹkan ń bọ̀ wá dáa lẹ́yìnwá ọ̀la. Ìyẹn ló fi ṣeé ṣe fún wọn láti kojú gbogbo kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé. Báwo ni Bíbélì yóò ṣe di ohun tó ń ṣamọ̀nà rẹ láti máa gbé ìgbésí ayé?

Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè!

Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ máa ń ṣeni lójú yòyò nígbà míì! Síbẹ̀, ìmọ̀ ènìyàn kò mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ayọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. Ìmọ̀ kan ṣoṣo tó lè mú èyí wá ni a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì ní Jòhánù 17:​3, èyí tó wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”

Inú Bíbélì nìkan la ti lè rí irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ti fi gbogbo ara sọ̀rọ̀ nípa ìwé mímọ́ yìí, àwọn tó ti gbìyànjú láti yẹ̀ ẹ́ wò fúnra wọn kò tó nǹkan. Ìwọ ńkọ́? Òótọ́ ni pé ó ń gba ìsapá gidi láti ka Bíbélì. Ṣùgbọ́n ó tó bẹ́ẹ̀, ó sì jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bíbélì nìkan ni ìwé tí “Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.”​—⁠2 Tímótì 3:⁠16.

Nígbà náà, báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í mọ Bíbélì dáadáa? O ò ṣe gba ìrànlọ́wọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pèsè? Lọ́fẹ̀ẹ́ ni wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn nínú ilé wọn. Láti lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọ̀nà yìí, onírúurú ìtẹ̀jáde táa gbé karí Bíbélì ni wọ́n máa ń lò, irú bí ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ó ń pèsè ìdáhùn tó ṣe ṣàkó sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè tí o lè ní nípa Bíbélì. Àwọn ìbéèrè bíi: Ta ni Ọlọ́run? Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo ni Bíbélì ṣe lè mú kí ìgbésí ayé ìdílé rẹ sunwọ̀n sí i?

Bí o bá fẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bẹ̀ ọ́ wò ní ilé rẹ, jọ̀wọ́ kọ ọ̀rọ̀ sínú àlàfo ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí. Inú wọn yóò dùn láti fún ọ ní ìsọfúnni kíkún sí i nípa Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rúndún Ìjọba ológo ti Ọlọ́run!

□ Màá fẹ́ láti gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Kọ irú èdè tóo fẹ́

□ Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èrò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé nípa mìlẹ́níọ̀mù tuntun la ń tọ́ka sí níbí o. Táa bá ní ká sọ bó ṣe jẹ́ gan-an, January 1, 2001 ni mìlẹ́níọ̀mù tuntun máa tó bẹ̀rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́