ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/00 ojú ìwé 8
  • Mímú Ìfẹ́ Tí Ìròyìn Ìjọba No. 36 Ru Sókè Dàgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Ìfẹ́ Tí Ìròyìn Ìjọba No. 36 Ru Sókè Dàgbà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìròyìn Ìjọba
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • ‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 11/00 ojú ìwé 8

Mímú Ìfẹ́ Tí Ìròyìn Ìjọba No. 36 Ru Sókè Dàgbà

1 Ṣé o ti pín gbogbo Ìròyìn Ìjọba No. 36 táa kó fún ọ tán? Ó béèrè ìbéèrè kan tó bágbà mu, tó sì yẹ kí gbogbo wa ronú lé lórí: “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?” Gbàrà tọ́dún 2000 ti bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́lé, làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní oríṣiríṣi ìfojúsọ́nà nípa ohun tí mìlẹ́níọ̀mù tuntun náà yóò mú wá fún wọn. Ìròyìn Ìjọba No. 36 gbé díẹ̀ lára àwọn ìfojúsọ́nà wọ̀nyẹn yẹ̀ wò, ó sì tún jẹ́ kó yé wa pé ipò àwọn nǹkan nínú ayé kò mú kí àwọn èèyàn ní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára. Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ti Kristi Jésù ni mìlẹ́níọ̀mù kan ṣoṣo tí yóò mú àlàáfíà àti ààbò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń yán hànhàn fún wá. Ìdánilójú tí a ní pé Ìjọba náà jóòótọ́ ló mú wa pín Ìròyìn Ìjọba No. 36 náà fún olúkúlùkù ẹni tí a lè fún.

2 Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Máa Ń Gba Ìròyìn Ìjọba: Ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba tí a ti ṣe ṣáájú ti túbọ̀ mú orí wa yá sí iṣẹ́ wa. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa ní Kánádà kọ̀wé nípa Ìròyìn Ìjọba No. 35 pé: “Àwọn akéde àti àwọn aṣáájú ọ̀nà fi ìtara ṣètìlẹ́yìn fún ìpínkiri àkànṣe yìí nínú pápá, a sì gbádùn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìrírí afúnniníṣìírí.” Ó dájú pé ìwọ náà ti fi irú ìtara kan náà ṣe ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36.

3 Ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba tí a ń ṣe lọ́wọ́ yìí ni a ti ṣètò pé kí á parí rẹ̀ ní November 17, 2000. Ṣé ẹ ti pín in kárí gbogbo ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ yín? Bí ẹ kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà lè sọ pé kí ẹ máa bá ìpínkiri náà nìṣó títí di ìparí oṣù November.

4 Láti ìgbà tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36 náà, kí ni ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn ní àgbègbè yín? Àwọn díẹ̀ yóò kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ ìwé náà láti fi béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Àmọ́ o, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó f ìfẹ́ hàn sí ọ̀ràn nípa mìlẹ́níọ̀mù lákọ̀ọ́kọ́ má tiẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ kankan títí dìgbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tó padà lọ bẹ̀ wọ́n wò. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ rí i pé a padà bẹ gbogbo àwọn tó f ìfẹ́ hàn wò. Ìgbà wo ló máa dára jù láti ṣe èyí? Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ní kíákíá bí ó bá ṣe lè yá tó.

5 Ṣàkíyèsí àwọn ìrírí wọ̀nyí táwọn ará ní nígbà tí wọ́n padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fún ní Ìròyìn Ìjọba No. 35. Ní Ireland, aṣáájú ọ̀nà kan fún onílé àrójẹ kan ní Ìròyìn Ìjọba. Ìsọfúnni náà wọ obìnrin táà ń wí yìí lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ pé kí arábìnrin yìí padà wá. Arábìnrin náà padà lọ lẹ́yìn ọjọ́ méjì, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀. Ní Denmark, ẹnì kan fi ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba kan há ẹnu ọ̀nà ilé kan níbi tí kò ti sí èèyàn kankan nílé. Lọ́jọ́ kan náà ni obìnrin tó ń gbé ilé náà kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ ìwé náà tó sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́, tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ sì wá fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí ìjọ tó wà ládùúgbò náà. Kí ọ̀sẹ̀ náà tó parí, àwọn arábìnrin méjì wá bẹ obìnrin yìí wò, wọ́n sì ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin yìí mà wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbà àkọ́kọ́!

6 Ohun Tí Wàá Sọ Nígbà Tóo Bá Padà Lọ: Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí a fún ní Ìròyìn Ìjọba rọrùn, ó sì jẹ́ apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tí ń gbádùn mọ́ni. Yóò bọ́gbọ́n mu láti mu ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba No. 36 dání bí o bá ń padà lọ bẹ ẹnì kan wò, nítorí onílé náà lè máà ní ẹ̀dà tirẹ̀ lọ́wọ́. O lè lo àwọn àbá wọ̀nyí.

7 Lẹ́yìn tí o bá ti rán onílé náà létí ẹni tí o jẹ́, o lè sọ pé:

◼ “Mo fi ìwé alábala méjì kan tó ní àkọlé náà ‘Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?’ sílẹ̀ fún ọ nígbà tí mo wá síbí. Kò ha fúnni níṣìírí bí láti kà pé láìpẹ́ Ìjọba Ẹgbẹ̀rúndún Kristi Jésù yóò bẹ̀rẹ̀, tí yóò sì wá mú kí ilẹ̀ ayé di Párádísè? [Fi àpèjúwe Párádísè tó wà nínú Ìròyìn Ìjọba No. 36 hàn án.] Ní ẹ̀yìn ìwé náà, a rọ̀ ọ́ láti béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?” Fi ìwé pẹlẹbẹ náà hàn án, ṣí i sí ẹ̀kọ́ 5, ka ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ìpínrọ̀ 1 àti 2, kí o sì jẹ́ kí onílé náà dáhùn. Ka ẹsẹ ìwé mímọ́ kan tàbí méjì kí ẹ sì jíròrò rẹ̀. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ ka ìbéèrè àti ìpínrọ̀ mìíràn, lẹ́yìn náà, ṣètò ìgbà tí wàá padà wá láti máa bá ìjíròrò náà lọ.

8 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwé pẹlẹbẹ “Béèrè” tàbí ìwé “Ìmọ̀” la máa fi lọ àwọn èèyàn nígbà ìpadàbẹ̀wò nínú oṣù November, o lè sọ pé:

◼ “Nígbà tí mo bẹ̀ ọ́ wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo fi ẹ̀dà kan ‘Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?’ sílẹ̀ fún ọ. Ìwé yìí ṣàlàyé pé a lè wá bá ọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́. Ìdí tí mo sì fi padà wá jẹ́ láti fi ìwé tí a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà hàn ọ́. [Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè hàn án, kí o ṣí ìwé náà sí ẹ̀yìn pátápátá; tàbí kí o fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì ṣí i sí ojú ìwé 188 àti 189.] Ẹgbẹ̀rúndún tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì yóò mú irú àwọn ipò tí o rí nínú àwòrán yìí wá. Kí á lè tóótun fún ìyè nínú Párádísè, a gbọ́dọ̀ gba ìmọ̀ pípéye ti Ọlọ́run sínú. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ń fi hàn ọ́ ní ṣókí bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

9 Ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36 ti mú ká káràmáásìkí ìpín tí a ń ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì ti mú ká jẹ́rìí lọ́nà tó túbọ̀ múná dóko. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí èyí ti ru ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìpínlẹ̀ wa sókè. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìsapá àjùmọ̀ṣe wa láti mú kí àwọn èèyàn ní irú ìfẹ́ tí wọ́n ní yìí yóò mú ká máa fi tayọ̀tayọ̀ wá ọ̀pọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn láwàárí.—Mát. 10:11; Ìṣe 13:48, 49, 52.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́