ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/95 ojú ìwé 3-4
  • ‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àkànṣe Ìgbòkègbodò Tá A Ó Ṣe Láàárín February 19 sí March 18!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà” ní April!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 9/95 ojú ìwé 3-4

‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’

1 Dájúdájú, a ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun tí ó kún fọ́fọ́ láti fojú sọ́nà fún ní October! Kókó pàtàkì ìpàdé náà ní October 1, lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, yóò jẹ́ ìmújáde Ìròyìn Ìjọba Nọmba 34, olójú-ìwé mẹ́rin, tí ó bá àkókò mu, tí a óò fún ní ìpínkiri gbígbòòrò láti October 1 sí 22, láti ọwọ́ alága. Ìwọ kò ha gbà pé “púpọ̀ rẹpẹtẹ” yóò wà ‘lati ṣe ninu iṣẹ́ Oluwa’ ní oṣù yìí bí?—1 Kor. 15:58, NW.

2 Ìròyìn Ìjọba Àkànṣe Tí A Óò Mú Jáde: Ìpèsè Ìròyìn Ìjọba ni a óò fi ṣọwọ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. A ní láti tọ́jú àwọn páálí tí a kó Ìròyìn Ìjọba náà sínú rẹ̀ sí àwọn ibi tí ó dára, a kò sì gbọdọ̀ já wọn títí òpin ìtòlẹ́sẹẹsẹ ní October 1. Nígbà yẹn ni a óò tó mú Ìròyìn Ìjọba wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìpínkiri fún àwọn ará àti àwùjọ. Ní òpin àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, tàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àpéjọ àkànṣe ní October 1, gbogbo àwọn tí ó bá wà ní ìjókòó yóò gba ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n baà lè mọ àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ dunjú, kí wọ́n sì gbara dì fún ìpínkiri rẹ̀.

3 Àwọn Alàgbà Yóò Ní Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Láti Ṣe: Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní láti pàdé pọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí láti jíròrò ní kíkún nípa ìgbétáásì àkànṣe náà. Ó yẹ kí àwọn ìjọ sapá láti kárí àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wọn. Kí ìgbétáásì náà tó parí, ẹ sapá gidigidi láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ẹ kò tí ì kárí ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn. Nítorí ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ náà, a óò fẹ́ láti ya àkókò tí ó pọ̀ tó sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Kò sí iyèméjì pé, àwọn akéde tí ó pọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ yóò fi orúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tún dara pọ̀ mọ́ wa gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ́wọ́ gbà. Ẹ wo irú àkókò tí ń gbádùn mọ́ni tí a óò ní, bí a ti ń ṣòpò papọ̀ nínú iṣẹ́ Oluwa!

4 Àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ní láti ṣètò tí ó ṣe gúnmọ́ fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ ní Saturday àti Sunday. Ó yẹ kí a fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìṣírí láti ṣàjọpín aláápọn. Ní àfikún sí ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀, ó yẹ kí ẹ ṣètò fún ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́, ó kéré tán ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀, lákòókò ìgbétáásì náà. Àwọn kan lè fẹ́ láti pàdé fún iṣẹ́ ìsìn lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ láti yọ̀ǹda fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí yóò fẹ́ láti túbọ̀ ṣàjọpín láti ṣe bẹ́ẹ̀.

5 Ó yẹ kí ẹ ṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà baà lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní kùtùkùtù. Àwọn ìpàdé wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní láti gbé ìgbékalẹ̀ rírọrùn kan jáde lórí Ìròyìn Ìjọba. Àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn ní ọ̀sán lè ní ìdámọ̀ràn kan tàbí méjì fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti gba Ìròyìn Ìjọba nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn akéde kan lè fẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ìpínkiri náà ní àárọ̀ àti ní ọ̀sán. Fún ìdí èyí, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò fẹ́ láti rí i dájú pé ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ tó wà láti ṣiṣẹ́. A ní láti kọ orúkọ àti àdírẹ́sì gbogbo àwọn tí ó bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sórí àkọsílẹ̀ ilé dé ilé. A lè kọ àwọn ohun tí ó jẹ́ kókó pàtàkì nínú àwọn ohun tí a jíròrò síbi àlàfo àlàyé, ní ṣókí. Èyí yóò mú kí ó rọrùn láti ṣe ìpadàbẹ̀wò ní àárín ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù náà.

6 Bí ìjọ kan bá ran òmíràn lọ́wọ́ láti kárí ìpínlẹ̀ rẹ̀, wọ́n ní láti fún ìjọ tí ń bójú tó ìpínlẹ̀ náà ní orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn olùfìfẹ́hàn.

7 Ẹ̀yin òbí, àwọn ọmọ yín ha ń sapá gidigidi láti di akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi bí? A ti kíyè sí i pé, ní àwọn ìjọ kan, àwọn ọmọ tí ara wọ́n balẹ̀ ti tẹ̀ lé àwọn òbí wọn lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ọmọ náà sì ń ṣe dáradára, bí wọn kò tilẹ̀ tí ì di akéde ìhìn rere. Ó yẹ kí àwọn òbí ṣàyẹ̀wò bóyá àwọn ọmọ wọn tóótun ní tòótọ́ fún àǹfààní yìí. Méjì lára àwọn alàgbà lè jíròrò gbogbo ohun tí ó ní nínú pẹ̀lú olórí ìdílé, kí wọ́n sì pinnu bóyá a lè ka ọmọ náà sí akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi.—om-YR ojú ìwé 99 sí 100.

8 Akéde kankan ha wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín tí kò jẹ́ aláápọn mọ́ nínú rírúbọ ìyìn sí Jehofa? (Heb. 13:15) Ó lè jẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àwọn àníyàn ìgbésí ayé ni ó ṣẹ́pá àwọn kan tí wọn kò ṣiṣẹ́ mọ́, bí wọ́n tilẹ̀ ń bá a lọ láti di àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere ti Bibeli mú. Ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀kan lára àwọn alàgbà lè sún wọn láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ déédéé, àti láti tún bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ní àkókò tí ó yẹ.

9 Gbogbo Àwọn Tí Ó Bá Tóótun Lè Ṣàjọpín Nínú Iṣẹ́ Tí Ń Gbádùn Mọ́ni Yìí: Ó ha ń nira fún díẹ̀ lára ẹ̀yin ọmọdé tàbí ẹ̀yin ọ̀dọ́langba láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé? Ẹ̀yin ẹni titun tí ìrírí yín nínú iṣẹ́ ìwàásù kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan ńkọ́? Ẹ̀yin yóò rí i pé, ẹ óò gbádùn ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba àkànṣe yìí gidigidi gan-an! Gbogbo ohun tí a nílò kò ju ìgbékalẹ̀ rírọrùn kan.

O lè sọ ohun kan bí èyí:

◼ “Ní oṣù yìí, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ó tó 190,000 ń pín ìhìn iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì kiri ní ọ̀pọ̀ èdè níhìn-ín ní Nigeria. Ìpínkiri ìhìn iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì yìí ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé. A ṣe é fún àwọn ènìyàn tí yóò fẹ́ láti rí i kí àwọn ìṣòro tí gbogbo wa ń dojú kọ lónìí dópin. Ẹ̀dà tìrẹ nìyí.”

Tàbí o lè gbìyànjú èyí:

◼ “A ń rọ gbogbo ènìyàn láti ka ìhìn iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì yìí, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní [ka àkọlé Ìròyìn Ìjọba náà]. Ṣàkíyèsí ohun tí ó sọ níhìn-ín ní ojú ìwé 2 nípa ìbísí nínú àwọn ìṣòro . . . [ka gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a ṣàyàn láti inú Ìròyìn Ìjọba]. Ó dá wa lójú pé ìwọ yóò gbádùn kíka èyí tí ó kù nínú ìhìn iṣẹ́ tí ó bá àkókò mu yìí. Ẹ̀dà tìrẹ nìyí.”

10 Fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó bá gba Ìròyìn Ìjọba náà. Fi ara balẹ̀, kí o sì sọ̀rọ̀ ketekete; kò sí ìdí láti sáré sọ̀rọ̀. A fẹ́ láti kárí ìpínlẹ̀ wa kúnnákúnná, kí a sì rí i pé a fún gbogbo àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn nínú kíka Ìròyìn Ìjọba náà ní ẹ̀dà kan. Níbi tí kò ti sí ẹnikẹ́ni nílé, rọra kọ ọ́ sínú àkọsílẹ̀ ilé dé ilé rẹ, kí ó baà lè ṣeé ṣe fún ọ láti padà lọ, ní àkókò tí ó bá yẹ, láti fi Ìròyìn Ìjọba náà lọ onílé. A lè lo Ìròyìn Ìjọba yìí nínú ìjẹ́rìí òpópónà, nígbà tí ẹnì kan bá fi ìfẹ́ hàn nínú kíka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà. A kò ní láti fi wọ́n lé tajá tẹran lọ́wọ́ bíi pé wọ́n jẹ́ ìwé ìléwọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, tọ àwọn tí ń rìn lọ, kí o sì ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ìhìn iṣẹ́ tí a ń gbé jáde lákànṣe náà. Lo Ìròyìn Ìjọba nínú ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, bíi nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò tàbí nígbà tí o bá ń jẹ́rìí fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, ní àkókò oúnjẹ. Àwọn tí a sé mọ́lé tàbí tí wọ́n ṣàìlera lè fi wọ́n lọ àwọn tí ń ṣèbẹ̀wò, àwọn dókítà àti àwọn nọ́ọ̀sì, àwọn tí ń tajà, àti àwọn mìíràn tí ń wá sí ilé wọn.

11 Àwọn ìpadàbẹ̀wò mélòó ní ẹ óò ṣe nígbà ìgbétáásì náà? Púpọ̀ rẹpẹtẹ, láìsí àníàní, níwọ̀n bí a óò tí ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n fí ìfẹ́ hàn nínú Ìròyìn Ìjọba. Ó dára jù lọ láti sọ̀rọ̀ lórí kìkì Ìròyìn Ìjọba, nígbà ìkésíni àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá padà lọ, sọ̀rọ̀ ṣókí nípa bí ìhìn iṣẹ́ tí ó wà nínú Ìròyìn Ìjọba náà ṣe bá àkókò mu. Fetí sílẹ̀ dáradára bí onílé náà ti ń sọ ojú ìwòye rẹ̀ lórí ohun tí ó ti kà. Àwọn àlàyé rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí o máa fi lọ̀ ọ́ nínú àwọn ìwé ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn àti bóyá bí o ṣe lè múra àwọn ìjíròrò síwájú sí i sílẹ̀. Bí ìdáhùnpadà nígbà ìpadàbẹ̀wò náà bá dára, gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.—1 Kor. 3:6, 7.

12 “Òpò Yín Kì Í Ṣe Asán”: Gbogbo iṣẹ́ yìí yóò ha yẹ fún ìsapá náà bí? Paulu mú un dá àwọn ará Korinti lójú pé: “Òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹlu Oluwa.” (1 Kor. 15:58, NW) A ti bù kún àwọn ìsapá wa láti ṣe ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá. Tọkọtaya kan tí ń kó lọ sínú ilé tí kò sí ẹnikẹ́ni nínú rẹ̀, rí ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba ògbólógbòó kan nínú àpótí tábìlì kan. Ohun kan ṣoṣo tí a fi sílẹ̀ nínú gbogbo ilé náà nìyẹn. Lẹ́yìn tí wọ́n tí kà á, wọ́n kàn sí ìjọ àdúgbò, wọ́n sì béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí gbogbo ìpàdé, wọ́n sì fi ìfẹ́ wọn láti ṣe ìrìbọmi hàn, nígbà tí ó yá. Bóyá ẹ̀dà kan tí o bá fi sílẹ̀ yóò mú àbájáde kan náà wá!—Wo Jí!, November 8, 1976 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 15.

13 A ní iṣẹ́ ràbàtàrabata kan níwájú wa. Góńgó wa ni, kí ìjọ kọ̀ọ̀kan kárí ìpínlẹ̀ tí a yàn fún un, tí ó bá máa fi di October 22 tàbí òpin oṣù náà, bí ó bá pọndandan láti sún àkókò náà síwájú sí i fún ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba náà. Ẹrù náà pọ̀ débi pé aṣáájú ọ̀nà déédéé àti olùrànlọ́wọ́ kọ̀ọ̀kan yóò gba ẹ̀dà 250 Ìròyìn Ìjọba. Akéde kọ̀ọ̀kan yóò gbà tó ẹ̀dà 50. Kìkì iye ẹ̀dà tí wọ́n bá lè pín kiri ni kí àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà gbà, kí wọ́n sì dá àwọn èyí tí ó bá ṣẹ́ kù padà, fún àwọn ẹlòmíràn láti lò. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó dára nínú ọ̀ràn yìí yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti fún ìhìn iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì yìí ní ìpínkiri tí ó gbòòrò jù lọ tí ó ṣeé ṣe. Bí àwọn ìjọ kan kò bá tí ì kárí àwọn ìpínlẹ̀ wọn títí fi di October 22, nítorí pé ìpínlẹ̀ wọ́n tóbi, tí wọ́n sì ní àwọn ẹ̀dà lọ́wọ́, ó lè jẹ́ ohun tí ó gbéṣẹ́ láti ké sí àwọn ìjọ tí ó wà nítòsí láti ṣèrànwọ́. Ní àwọn ìjọ mìíràn, wọ́n lè fúnra wọn kájú àìní náà bí àwọn akéde bá fi kún ìgbòkègbodò wọn nípa fíforúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí nípa títúbọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ léraléra sí i.

14 A óò nílò ìfọkànsìn tọkàntọkàn sí Jehofa, bí a óò bá ṣàṣeparí iṣẹ́ wa. (Kol. 3:23) Ìwàláàyè wé mọ́ ọn. Àwọn ènìyàn kò lè ṣàìkọbiara sí ìtumọ̀ àwọn ipò nǹkan nínú ayé lónìí. Àkókò ń tán lọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ dojú kọ òtítọ́ náà pé, ènìyàn kò ní ojútùú sí àwọn ìṣòro ayé yìí. Ọlọrun ni ó ní in. Àwọn tí wọ́n fẹ́ láti gba ìbùkún Ọlọrun gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tìpinnutìpinnu, láìjáfara, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí ó béèrè fún.

15 Àwa yóò ha dẹwọ́ sílẹ̀ dẹgbẹrẹ ní òpin ìgbétáásì àkànṣe náà ní October 22 bí? Rárá! Ọwọ́ wa yóò máa bá a lọ láti dí fọ́fọ́, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn onímìísí ti Paulu.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́