Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà” ní April!
1 Ní ọdún tí ó kọjá, ìjẹ́rìí tí a kò ṣe irú rẹ̀ rí ni a fúnni nígbà tí a pín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìwé àṣàrò kúkúrú Ìròyìn Ìjọba, No. 34 kárí ayé. Àwọn akéde ìjọ àti àwọn aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú fi tìtaratìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ tí ń runi sókè yìí. Ìwọ́ ha wà lára wọn bí? Bí o bá wà lára wọn, kò sí iyè méjì pé o gbádùn kíkópa nínú ìgbétásì gígadabú yẹn dáradára. Nísinsìnyí, o lè máa ṣe kàyéfì pé, “Iṣẹ́ àtàtà” wo ni ó wà ní ìpamọ́ fún wa lọ́dún yìí?—Titu 2:14.
2 Ní April àti ní ìbẹ̀rẹ̀ May, a óò ní ayọ̀ ṣíṣe ìpínkiri àkànṣe ìtẹ̀jáde ìwé ìròyin Jí!, April 22, 1996, tí ń gbé kókó ẹ̀kọ́ náà, “Nígbà Tí Ogun Kì Yóò Sí Mọ́,” jáde lákànṣe. Níwọ̀n bí kókó ẹ̀kọ́ yìí yóò ti fa ọ̀pọ̀ onílé mọ́ra, a óò sapá láti pín ìwé ìròyìn náà kiri lọ́nà gbígbòòrò jù lọ tí ó ṣeé ṣe. Lójú ìwòye ìjẹ́pàtàkì ìsọfúnni tí ó wà nínú rẹ̀, a óò gbé ìtẹ̀jáde Jí! yìí jáde lákànṣe ní April àti wọnú May, títí tí àwọn tí a ní lọ́wọ́ yóò fi tán.
3 Góńgó Wa—Ìkópa Gbogbo Akéde: Yóò fúnni níṣìírí ní tòótọ́ bí gbogbo akéde ní orílẹ̀-èdè yìí bá lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù ní April. Pẹ̀lú Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, dájúdájú a óò fẹ́ láti fi ìmọrírì wa fún ìwà rere Ọlọrun hàn nípa rírú “ẹbọ ìyìn” ní tààràtà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.—Heb. 13:15.
4 A ní láti ṣe ìsapá aláápọn láti fòye mọ àìní mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ kí gbogbo ìjọ baà lè nípìn-ín onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní April. (Romu 15:1) Àwọn olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ gbọ́dọ̀ mọ àyíká ipò àwọn tí ń bẹ nínú àwùjọ wọn dunjú, kí wọ́n sì pèsè ìrànwọ́ gbígbéṣẹ́ nígbà tí ó bá pọn dandan. Ẹnìkẹ́ni ha nílò pé kí á fi ohun ìrìnnà gbé òun bí? Ta ní lè pèsè rẹ̀? Àwọn kan ha ń ṣojo tàbí ń ṣàníyàn nípa ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń rò nípa wọn bí? Àwọn akéde tí ó túbọ̀ nírìírí ha lè bá wọn ṣiṣẹ́ bí? Àwọn tí kò lera tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn ńkọ́? Wọ́n ha lè lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí nípa kíkọ lẹ́tà tàbí lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò míràn tí ń méso jáde bí?
5 Àwọn kan tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́ mọ́ ti ń rí ìṣírí tẹ̀mí gbà déédéé, a sì lè sún wọn láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìgbétásì náà pẹ̀lú àkànṣe Jí! yóò pèsè àǹfààní títayọ lọ́lá fún wọn láti di ẹni tí a mú sọjí.
6 Kọ́ Àwọn Èwe Láti Kópa Nínú Rẹ̀: Ọ̀pọ̀ ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti bá àwọn òbí wọn lọ láti ilé dé ilé fún ọ̀pọ̀ ọdún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tí ì máa sìn gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi síbẹ̀. Ìsinsìnyí ha ni àkókò fún wọn láti bẹ̀rẹ̀ bí? Ǹjẹ́ a sún wọn láti inú ọkàn-àyà, tí wọ́n sì ṣe tán láti nípìn-ín jíjọjú nínú iṣẹ́ ilé dé ilé bí? Àwọn olórí ìdílé ní láti lo àkókò nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé láti ran àwọn ọmọ wọn títóótun lọ́wọ́ láti múra ìgbékalẹ̀ kan, tí a mú bá ọjọ́ orí àti agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn mu sílẹ̀. Àwọn tí ó dàgbà lè yan ìbéèrè kan tí ń wádìí ọkàn tí wọn yóò fi ru ọkàn-ìfẹ́ onílé sókè, lẹ́yìn náà kí wọ́n sì tọ́ka sí ìdáhùn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn náà. Àwọn ọmọdé lè jẹ́rìí fúnni ní lílo ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lè fún onílé níṣìírí láti “ka àkànṣe ìwé ìròyìn tí a fi ń lọni kárí ayé lóṣù yìí.” Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìmúrasílẹ̀ ìdílé rẹ, rí i dájú pé o fi àwọn àbá fún bíborí àwọn àtakò wíwọ́pọ̀ kún un. Ìwọ́ yóò rí àwọn àbá díẹ̀ tí ń méso jáde nínú ìwé Reasoning. Nígbà tí ẹ bá ń jẹun àti ní àwọn ìgbà yíyẹ mìíràn, fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé níṣìírí láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.
7 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Títóótun Tẹ́wọ́ Gba Iṣẹ́ Tí Jesu Ṣe: Jesu kò fi ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mọ sórí fífúnni ní ìtọ́ni lórí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. Ó bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ sínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe máa wàásù. (Luku 8:1; 10:1-11) Báwo ni nǹkan ti rí lónìí? Èyí tí ó ju ìdámẹ́rin mílíọ̀nù ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní a ń ṣe ní Nàìjíríà. Kò sí iyè méjì pé, pẹ̀lú ìṣírí bíbá a mu wẹ́kú, ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí lè gbé ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn, kí wọ́n sì tóótun láti sìn gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi ní April.
8 Bí o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan, gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wó: Akẹ́kọ̀ọ́ náà ha ń ní ìtẹ̀síwájú bí, ní ìbáradọ́gba pẹ̀lú ọjọ́ orí àti agbára rẹ̀ bí? Ó ha ti ń ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn láìjẹ́-bí-àṣà bí? Ó ha ń gbé “àkópọ̀-ìwà titun” wọ̀ bí? (Kol. 3:10) Ó ha kúnjú àwọn ẹ̀rí ìtóótun fún akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 97 títí dé 99 nínú ìwé Iṣetojọ bí? Bí o bá gbà gbọ́ pé ó tóótun, èé ṣe tí o kò fí jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú rẹ̀? Ohun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan nílò kò ju ìkésíni tààràtà láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ náà. Àmọ́ ṣáá o, bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá múra tán, yóò pọn dandan pé kí alábòójútó olùṣalága kọ́kọ́ ṣètò gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí, fún ìjíròrò pẹ̀lú méjì nínú àwọn alàgbà. Ní ọwọ́ kéjì ẹ̀wẹ̀, ohun kan lè máa fa akẹ́kọ̀ọ́ náà sẹ́yìn. Bóyá ọ̀kan nínú àwọn alàgbà lè wà pẹ̀lú rẹ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí ó sì mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ tẹnu rẹ̀ lórí ìmọ̀lára rẹ̀ sí òtítọ́. Lẹ́yìn fífetí sílẹ̀ sí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní láti sọ, ó lè ṣeé ṣe fún alàgbà náà láti pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́, àti ìrànwọ́ Ìwé Mímọ́.
9 ‘Ra Àkókò Padà’ Láti Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Lọ́dọọdún lákòókò Ìṣe Ìrántí, ìmoore fún ìràpadà ń sún ẹgbẹẹgbẹ̀rún láti ‘ra àkókò padà’ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. (Efe. 5:15-17) Bí a tilẹ̀ ní láti ṣe àwọn ìrúbọ díẹ̀, èrè rẹ̀ pọ̀ jọjọ. Iye jíjọjú nínú àwọn èwe ń lo àǹfààní àkókò ìsinmi ní ilé ẹ̀kọ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àwọn àgbà tí ń ṣiṣẹ́ fún àkókò kíkún ń lo àǹfààní ìrọ̀lẹ́ àti ìparí ọ̀sẹ̀ ní kíkún nínú ìgbòkègbodò yìí kan náà. Nípa báyìí, gbogbo ìdílé ti lo àǹfààní náà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pa pọ̀! Ní àwọn ìjọ kan, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti àwọn ìyàwó wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bí a ti gún wọn ní kẹ́ṣẹ́ nípa àpẹẹrẹ onítara wọn, àwọn mìíràn ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, tí ó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú ìjọ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní April.
10 Yálà o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí o kò lè ṣe é, wá ọ̀nà láti mú iṣẹ́ ìsìn rẹ nínú pápá pọ̀ sí i ní April. Gbé góńgó ara ẹni kalẹ̀ fún ara rẹ, ọ̀kan tí yóò gba ìsapá láti lé bá, ṣùgbọ́n tí ọwọ́ lè tẹ̀. Ìfẹ́ ọkàn rẹ láti ‘náwó, kí a sì ná ọ tán pátápátá’ nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa, ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ipò rẹ, yóò jèrè ìbùkún rẹ̀.—2 Kor. 12:15.
11 Àwọn Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: A gbọ́dọ̀ ṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní gbogbo ọjọ́ ìgbétásì Jí!, sí àkókò tí yóò fàyè gba títètè bẹ̀rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. A tún ní láti ṣètò fún ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ akéde yóò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀, nítorí náà, kí àwọn ìjọ ṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní Saturday, láàárọ̀ àti lọ́sàn-án, fún gbogbo àkókò ìpínkiri àkànṣe Jí!
12 Àwọn tí ń darí àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Kí a kọ́kọ́ kárí àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti ṣe tipẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò gbọdọ̀ ṣe àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni tí Society ń bójú tó láìgba àṣẹ Society. O ha ní ìpínlẹ̀ ara ẹni kan tàbí méjì tí ó ti pẹ́ tí o ti ṣe bí? Bí ìwọ yóò bá nílò ìrànwọ́ láti ṣe wọ́n lákòókò ìgbétásì náà, bá alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí arákùnrin tí ń bójú tó ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀, inú wọn yóò sì dùn láti ṣètò fún ọ láti rí ìrànwọ́ díẹ̀ gbà.
13 Ìwé Ìròyìn Mélòó Ni Ìwọ Yóò Fi Sóde? Ìbéèrè yẹn wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti dáhùn. Láti pinnu iye ìwé ìròyìn tí o lè fi sóde lákòókò ìgbétásì náà, ronú nípa irú ìpínlẹ̀ tí ìwọ yóò ti ṣiṣẹ́, ọjọ́ orí rẹ, ìlera rẹ, iye àkókò tí o lè yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ náà, àti àwọn kókó mìíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, kíyè sí ìránnilétí tí a fi fúnni nínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1994 pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìdábàá kan, àwọn akéde lè ní góńgó kan, ki a sọ pé ìwé-ìròyìn 10 lóṣù, gẹ́gẹ́ bi ipò nǹkan bá ṣe rí fún wọn; àwọn aṣáájú-ọ̀nà lè lépa 90.” Irú góńgó kan náà yóò ha ṣeé ṣe fún ọ bí?
14 Ẹ̀yin Alàgbà—Ẹ Nílò Ìwéwèé Kínní-kínní: Ẹ rí i dájú pé a ṣe gbogbo ìpínlẹ̀ tí ìjọ ní pẹ̀lú àkànṣe ìtẹ̀jáde Jí! náà, bí ó bá ṣeé ṣe. A ní láti fún ṣíṣe àwọn ìpínlẹ̀ ìṣòwò tí a yàn fún ìjọ ní àfiyèsí kínní-kínní. Àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ níbẹ̀ gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ dáradára, kí wọ́n sì múra nigín-nigín. A kò nílò ìgbékalẹ̀ jàn-ànràn jan-anran. Nígbà tí o bá fẹ́ bá ọkùnrin oníṣòwò kan sọ̀rọ̀, o lè sọ pé o kì í sábà bá àwọn oníṣòwò nílé, ìdí nìyẹn tí o fi ń ké sí i nídìí ọjà rẹ̀ láti fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan tí ó dájú pé yóò nífẹ̀ẹ́ sí lọ̀ ọ́. Lẹ́yìn náà, o lè ṣàjọpín kókó pàtó kan nínú ìwé ìròyìn náà pẹ̀lú rẹ̀ ní ṣókí. A gbọ́dọ̀ ṣètò ṣíṣe ìjẹ́rìí òpópónà pẹ̀lú ìwé ìròyìn lọ́nà yíyẹ láàárín ìpínlẹ̀ ìjọ. Ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jù lọ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òpópónà jẹ́ láti lo ìdánúṣe, kí o sì tọ àwọn tí ń ré kọjá lọ, dípo kí o dúró de ìgbà tí wọn yóò tọ̀ ọ́ wá. Níwọ̀n bí ìwọ yóò ti wà lójútáyé, ó yẹ kí o rí sí i pé ìrísí rẹ wuyì. Àwọn ibòmíràn lè wà ní ìpínlẹ̀ yín tí ẹ lè ṣe nígbà ìgbétásì náà, irú bí ibùdókọ̀ òfuurufú, ilé ìwòsàn, ibi ìgbọ́kọ̀sí, àti ọjà. Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ pinnu ìṣètò yíyẹ tí a lè ṣe fún ìjẹ́rìí ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí, ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín.
15 Jehofa jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kì í ṣàárẹ̀. (Joh. 5:17) Ó dá ọ̀run àti ayé àti ewéko àti ẹranko; ṣùgbọ́n ó ń bá iṣẹ́ nìṣó títí tí ó fi dá olórí àṣeyọrí rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé—ènìyàn. Òtítọ́ náà pé a ní ìwàláàyè jẹ́ àbájáde tààràtà ìmúratán Ọlọrun láti ṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí “aláfarawé Ọlọrun,” ìfẹ́ wa fún un gbọ́dọ̀ sún wa láti jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Efe. 5:1; Titu 2:14) Níwọ̀n bí Jehofa ti yẹ fún gbígba ìsapá wa dídára jù lọ, tí ìfẹ́ ọkàn láti rí àbájáde sì ti jẹ́ ànímọ́ ẹnì kan tí ó ní ìtara, ó yẹ kí á ní ìfẹ́ ọkàn nínú ṣíṣe ojúlówó iṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí a ti lè retí, Jehofa mọrírì ìrúbọ èyíkéyìí tí a bá ṣe fún un, iṣẹ́ wa kì í sì í ṣe asán. (1 Kor. 15:58) Nítorí náà, pẹ̀lú ọkàn tí ó kún fún ìmoore, ẹ jẹ́ kí á lo ara wa ní kíkún fún ìgbòkègbodò onítara ní April, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé níní ìtẹ́wọ́gbà òun ìbùkún Jehofa àti àṣeyọrí jìngbìnnì!