ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/01 ojú ìwé 3-6
  • Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti ‘Ṣiṣẹ́ Kára Ká sì Là Kàkà’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti ‘Ṣiṣẹ́ Kára Ká sì Là Kàkà’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí April 2000 Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà” ní April!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 3/01 ojú ìwé 3-6

Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti ‘Ṣiṣẹ́ Kára Ká sì Là Kàkà’

1 Àwọn ọ̀sẹ̀ tó sún mọ́ Ìṣe Ìrántí jẹ́ àkókò kan tí àwọn èèyàn Jèhófà fi máa ń ṣe àṣàrò. Èyí jẹ́ àkókò kan láti ronú nípa ohun tí ikú Kristi ṣe láṣeparí, ká sì ronú nípa ìrètí tí Ọlọ́run fún wa, tó jẹ́ pé ẹ̀jẹ̀ Jésù tí wọ́n ta sílẹ̀ ló mú kó ṣeé ṣe. Bí o ti ń ronú padà sí ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹrin ọdún tó kọjá, kí ló wá sí ẹ lọ́kàn? Ǹjẹ́ o lè rántí àwọn tóo rí nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn? ojúlówó àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ṣẹlẹ̀ níbi Ìṣe Ìrántí náà? tó fi kan ìjíròrò tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ látinú Bíbélì àti àdúrà àtọkànwá tó wáyé níbẹ̀? Bóyá o ti pinnu láti túbọ̀ fi hàn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ bí ìmọrírì tóo ní fún ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní sí ọ ṣe jinlẹ̀ tó. Ipa wo ni irú àṣàrò yẹn ní lórí rẹ nísinsìnyí?

2 Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn Jèhófà máa ń fi ọpẹ́ wọn hàn ní àwọn ọ̀nà mìíràn yàtọ̀ sí fífi ẹnu sọ ọ́. (Kól. 3:15, 17) Lọ́dún tó kọjá, pàápàá lóṣù April, a ṣakitiyan láti fi ìmọrírì wa hàn fún ìpèsè tí Jèhófà ṣe fún ìgbàlà nípa lílà kàkà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Iye àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ wọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí wọ́n sì fi ìpín méjìlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ju iye tí wọ́n jẹ́ ní Nàìjíríà ní oṣù yẹn ní ọdún tó ṣáájú. Ìsapá wọn àti ti gbogbo àwọn olùpòkìkí Ìjọba yòókù mú kí iye wákàtí tí a ní, iye ìwé ìròyìn tí a fi sóde, àti iye ìpadàbẹ̀wò tí a ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Inú wa túbọ̀ dùn láti rí i pé a bẹ̀rẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun tí àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí sì pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ!

3 Ní tòdodo, mímọ̀ tí a mọ̀ pé ohun táa ń retí dá wa lójú ni ó mú kí á kún fún iṣẹ́ pẹrẹu. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kọ̀wé gan-an ló rí pé: “Nítorí fún ète yìí ni àwa ń ṣiṣẹ́ kára, tí a sì ń tiraka, nítorí tí a ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn, ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.”—1 Tím. 4:10.

4 Ní sáà Ìṣe Ìrántí yìí, báwo lo ṣe máa fi ìgbàgbọ́ tóo ní nínú àwọn ìpèsè tí Jèhófà ṣe fún ìyè hàn? Lóṣù April ọdún tó kọjá, ló di ẹ̀ẹ̀kejì tí a tíì ròyìn iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà tó pọ̀ jù lọ ní Nàìjíríà. Ǹjẹ́ a lè kọjá iye yẹn ní April yìí? A lágbára láti kọjá rẹ̀ o. Ṣùgbọ́n, gbogbo akéde ló ní láti kópa níbẹ̀, àtàwọn tó ti ṣèrìbọmi àtàwọn tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun pẹ̀lú lè tóótun láti kópa níbẹ̀. Nípa báyìí, bí o ṣe ń wéwèé láti ṣiṣẹ́ kára kí o sì là kàkà lóṣù April, ronú nípa àwọn ọ̀nà tóo fi lè fún àwọn ẹlòmíràn títí kan àwọn ẹni tuntun àtàwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí níṣìírí, láti bá ọ lọ.

5 Ríran Àwọn Kan Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Tún Bẹ̀rẹ̀ Ìgbòkègbodò Wọn: Bóo bá mọ àwọn kan tí wọn ò jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún oṣù kan tàbí méjì, bóyá o lè fún wọn níṣìírí kí o sì ké sí wọn pé kí wọ́n bá ọ jáde nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí àwọn kan nínú ìjọ bá ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, àwọn alàgbà yóò sapá lákànṣe láti bẹ̀ wọ́n wò, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí láti tún bẹ̀rẹ̀ ní oṣù April.

6 Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti béèrè fún ẹ̀mí Jèhófà láti fún wa lókun nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ẹ̀mí yẹn gbà? Máa ka Ọ̀rọ̀ onímìísí ti Ọlọ́run. (2 Tím. 3:16, 17) A tún gbọ́dọ̀ máa “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ” nípa lílọ sí gbogbo ìpàdé márààrún ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ déédéé. (Ìṣí. 3:6) Àǹfààní nìyí láti ran àwọn tí kò ṣe déédéé àtàwọn tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe nínú bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa wá sí ìpàdé déédéé. (Sm. 50:23) A ń ṣe èyí bí a ti ń kíyè sára gidigidi nípa ire wa nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, ó ṣì ku ohun mìíràn táa ń béèrè.

7 Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé Ọlọ́run máa ń fún “àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso” ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ìṣe 5:32) Irú ìgbọràn yẹn kan kíkọbi ara sí àṣẹ náà láti “wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 1:8; 10:42) Nípa báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a nílò ẹ̀mí Ọlọ́run láti fún wa lókun láti wàásù, ó tún jóòótọ́ pé bí a bá ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fi hàn pé a fẹ́ láti mú inú Jèhófà dùn, òun yóò túbọ̀ máa ràn wá lọ́wọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré ìjẹ́pàtàkì fífi ìmúratán ṣègbọràn, èyí tí í ṣe ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́!

8 Ríran Àwọn Èwe Lọ́wọ́: Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ ti rí ẹ̀rí pé àwọn ọmọ yín ń fẹ́ láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́? Ṣé wọ́n ti ń bá a yín lọ sóde ẹ̀rí? Ṣé ìwà wọn ṣeé wò fi ṣàpẹẹrẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tẹ́ẹ fi ń lọ́tìkọ̀? Lọ bá ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kí o sì wádìí bóyá ọmọ rẹ tóótun láti di akéde lóṣù April ọdún yìí. (Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 99 àti 100.) Mọ̀ pé àwọn ọmọ rẹ lè fi kún ìhó ìyìn sí Jèhófà lọ́nà to pẹtẹrí ní sáà Ìṣe Ìrántí yìí.—Mát. 21:15, 16.

9 Ìyá kan tó jẹ́ Kristẹni ní Georgia, ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń fún ọmọ rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ èwe níṣìírí nígbà gbogbo láti máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Lọ́dún tó kọjá, bí ọmọdébìnrin náà ti ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú ìyá rẹ̀, ó fún ọkùnrin kan ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ó sì ṣàlàyé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé pẹlẹbẹ náà fún ọkùnrin ọ̀hún ní ṣókí. Ọkùnrin náà wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?” Ọmọdébìnrin náà fèsì pé: “Ọdún méje.” Ó ya ọkùnrin náà lẹ́nu bí ọmọdébìnrin yìí ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà dídánmọ́rán bẹ́ẹ̀. Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin yẹn ti sún mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa rí nígbà tó ṣì kéré ṣùgbọ́n kò fìgbà kan rí ronú jinlẹ̀ pé ó yẹ kí òun sọ òtítọ́ di ọ̀nà ìgbésí ayé òun. Láìpẹ́, a bẹ̀rẹ̀ sí bá ọkùnrin ọ̀hún, ìyàwó rẹ̀, àti ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

10 Ọ̀pọ̀ èwe ló ti di akéde, a sì máa ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ wọn nígbà tí a bá jọ lọ sóde ẹ̀rí. Àwọn èwe wọ̀nyí lè fún àwọn èwe bíi tiwọn níṣìírí, wọ́n sì lè mú kí wọ́n ṣe ohun tó yẹ. Ṣùgbọ́n oṣù April tún jẹ́ àkókò tó yẹ kí olúkúlùkù ìdílé mú kí ìdílé wọn túbọ̀ wà nírẹ̀ẹ́pọ̀, kí wọ́n sì mú kí ipò tẹ̀mí wọn túbọ̀ lágbára sí i nípa jíjùmọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Àwọn olórí ìdílé ló yẹ kó mú ipò iwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Òwe 24:27.

11 Ríran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́: Àwọn ẹni tuntun tóo ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńkọ́? Ṣé wọ́n lè ṣe àfikún ìsapá àkànṣe lóṣù April yìí? Bóyá wọ́n ti sọ pé àwọn fẹ́ láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tí àwọn ń kọ́ bí ẹ ṣe ń jíròrò orí 2, ìpínrọ̀ 22, tàbí orí 11, ìpínrọ̀ 14, nínú ìwé Ìmọ̀. Bí ẹ bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí ìwé náà, múra láti jíròrò ọ̀rọ̀ yìí dáadáa bí ẹ ti ń jíròrò orí 18, ìpínrọ̀ 8, tó sọ pé: “Bóyá o ń háragàgà láti sọ fún àwọn ìbátan rẹ, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn mìíràn nípa ohun tí o ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Níti tòótọ́, o ti lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí, àní bí Jesu ti ṣàjọpín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn mìíràn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. (Luku 10:38, 39; Johannu 4:6-15) Nísinsìnyí o lè fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i.” Ṣé bọ́ràn àwọn tóo ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ṣe rí nìyí?

12 Ǹjẹ́ ẹni tóo ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́? Ṣé ó máa ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò? Ṣé ó ti mú kí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run? Ṣé ó ti ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ? Ṣé ó fẹ́ láti sin Jèhófà Ọlọ́run? Nígbà náà, kí ló dé tí o kò fún un níṣìírí pé kó bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè pinnu bóyá ó tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, kí ó sì bá ọ jáde lóṣù April? (Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 97 sí 99.) Lọ́nà yìí, òun fúnra rẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí rí i bí ètò àjọ Jèhófà yóò ṣe ran òun lọ́wọ́ nínú ìsapá òun láti sin Jèhófà.

13 Lóòótọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan máa ń yára tẹ̀ síwájú ju àwọn mìíràn. Nítorí èyí, ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2000, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 5 àti 6, ọ̀pọ̀ ló ti ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ìwé kejì pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n kọ́kọ́ fìfẹ́ hàn ṣùgbọ́n tí wọ́n nílò ìrànwọ́ sí i láti bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ dáadáa. A kò jẹ́ ṣíwọ́ nínírètí pé àwọn aláìlábòsí-ọkàn wọ̀nyí yóò di ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi, “yálà ní àkókò kúkúrú tàbí ní àkókò gígùn.” (Ìṣe 26:29) Síbẹ̀, bí iye oṣù tí o ti fi ń bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ bá jẹ́ èyí tí a lè pè ní “àkókò gígùn,” ǹjẹ́ sáà Ìṣe Ìrántí yìí lè jẹ́ àǹfààní rere kan fún ẹni tí o ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí fi hàn bí ìmọrírì rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ fún ìràpadà Kristi tó?

14 Bí A Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Kópa Níbẹ̀: A lè kọ́ ohun púpọ̀ nípa bí a ṣe lè ran àwọn tó tóótun lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa ṣíṣàyẹ̀wò bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Kì í ṣe pé ó kàn kó àwọn èèyàn jọ tó sì wá sọ pé kí àwọn àpọ́sítélì òun bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ó kọ́kọ́ tẹnu mọ́ ọn pé iṣẹ́ ìwàásù yẹ ní ṣíṣe, ó fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa gbàdúrà, ó sì wá fún wọn ní nǹkan mẹ́ta pàtàkì tí wọ́n nílò, ìyẹn ni: ẹni tí wọ́n máa jọ ṣiṣẹ́, ibi tí wọn yóò ti ṣiṣẹ́, àti ohun tí wọn yóò sọ. (Mát. 9:35-38; 10:5-7; Máàkù 6:7; Lúùkù 9:2, 6) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bóyá ọmọ rẹ lẹni tóo fẹ́ ràn lọ́wọ́ ni o, tàbí akẹ́kọ̀ọ́ tuntun kan, tàbí ẹlòmíràn kan tí kò tíì ròyìn fún ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn, á dára pé kí o sapá lákànṣe láti ṣe àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí.

15 Tẹnu Mọ́ Ọn Pé Ó Yẹ Bẹ́ẹ̀: Tẹ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù mọ́ ẹni náà lọ́kàn. Sọ nǹkan tó dáa nípa rẹ̀. Sọ àwọn ìrírí tó ń fi ohun tí ìjọ ń ṣe láṣeparí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ hàn. Fi irú ẹ̀mí tí Jésù fi hàn nínú Mátíù 9:36-38 hàn. Fún ẹni tó ṣeé ṣe kó di akéde yìí tàbí ẹni tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ náà níṣìírí pé kí ó gbàdúrà nípa bí òun yóò ṣe kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti fún àṣeyọrí iṣẹ́ náà jákèjádò ayé.

16 Fún Ẹni Náà Níṣìírí Pé Kó Ronú Nípa Ọ̀pọ̀ Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí: Mẹ́nu kàn án pé ó ṣeé ṣe láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti jẹ́rìí láti ilé dé ilé. Sọ pé ó lè bá àwọn ìbátan àti ojúlùmọ̀ sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì lè bá àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń lọ ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lákòókò oúnjẹ ọ̀sán. Nígbà téèyàn bá wọ ọkọ̀ èrò, ọ̀pọ̀ ìgbà lèèyàn lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa wíwulẹ̀ fìfẹ́ hàn sí àwọn tí wọ́n jọ wọkọ̀. Nígbà táa bá lo ìdánúṣe, èyí sábà máa ń mú kí àǹfààní ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí dáadáa. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà táa lè lò láti fi sọ nípa ìrètí wa fún àwọn ẹlòmíràn “láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Sm. 96:2, 3.

17 Ṣùgbọ́n o, ó ṣeé ṣe, ó sì dára pé kí ìwọ àti akéde tuntun náà jọ ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé bó bá ti ṣeé ṣe kó yá tó. Bí o bá ti pinnu láti mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ pọ̀ sí i lóṣù April, béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ bóyá ìpínlẹ̀ tó rọrùn fún ọ wà. Bó bá wà, èyí á jẹ́ kí o láǹfààní láti ṣe é dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, bí o bá parí iṣẹ́ ìsìn tàbí bí o bá ń lọ sí ìpàdé tàbí sáwọn ibòmíràn, o lè ṣàkíyèsí pé èèyàn wà ní ilé kan tó jẹ́ pé nígbà tóo débẹ̀ tẹ́lẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀ tàbí tó jẹ́ pé wọ́n fìfẹ́ hàn níbẹ̀. Bó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ nígbà tí ìyẹn yóò bá gbéṣẹ́ gidigidi. Èyí á wá mú kí ayọ̀ rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa pọ̀ sí i, tí wàá sì máa rí i pé o ń ṣàṣeyọrí.

18 Múra Ọ̀rọ̀ Tó Lárinrin: Ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn fẹ́ láti máa sọ ìhìn Ìjọba náà, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ tún ni pé kéèyàn láyà nípa bí òun ṣe máa sọ ọ́, pàápàá bó bá jẹ́ pé ńṣe lẹni náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ tàbí tó pẹ́ tó ti lọ sóde ẹ̀rí kẹ́yìn. Àkókò táa bá lò láti ran àwọn ẹni tuntun àtàwọn tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ jẹ́ àkókò táa lò dáadáa. Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lè jẹ́ ká mọ ohun táa lè sọ, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè rọ́pò pé kéèyàn fúnra rẹ̀ múra sílẹ̀.

19 Báwo lo ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá? Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni, máà jẹ́ kó le, sì jẹ́ kó ṣe ṣókí! Sọ pé kí wọ́n ronú nípa àwọn ohun tí ìròyìn sọ pé ó ṣẹlẹ̀ tí àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ yín yóò fẹ́ sọ nípa rẹ̀, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá kókó kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tó jẹ mọ́ ọn. Ẹ jọ fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà dánra wò, kí ẹ sì lò ó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó.

20 Mú Kí Àǹfààní Tí A Ní Láti Pọ̀ Sí I Lọ́jọ́ Iwájú Túbọ̀ Gbòòrò Sí I: Lọ́dún tó kọjá, iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí jákèjádò ayé fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Iye àwọn tó ròyìn gẹ́gẹ́ bí akéde kàn fi díẹ̀ ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ ni. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ló fìfẹ́ hàn débi tí wọ́n fi lè wá síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkànṣe yìí níbi tí wọ́n ti gbọ́ àlàyé nípa ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Wọ́n láǹfààní láti mọ díẹ̀ lára wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn wú wọn lórí. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló gbóríyìn fún wa, tí wọ́n ṣe ìtọrẹ fún ìtìlẹ́yìn iṣẹ́ wa kárí ayé, tí wọ́n sì gbèjà wa níwájú àwọn ẹlòmíràn. Àwùjọ ńlá yìí jẹ́ ẹ̀rí pé a lè pọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Kí la lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú sí i?

21 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ń wá sí Ìṣe Ìrántí ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ọ̀kan lára wa pe olúkúlùkù wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí túmọ̀ sí pé ó kéré tán, ẹnì kan wà tí wọ́n mọ̀ nínú ìjọ. Bí a bá ké sí ẹnì kan, tó sì wá, ojúṣe wa ni láti mú kí ara tù ú ká sì ràn án lọ́wọ́ láti jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Níwọ̀n bí inú gbọ̀ngàn yóò ti kún fún èrò, bá a wá ìjókòó. Yá a ní Bíbélì, sì sọ pé kí ẹ́ jọ lo ìwé orin tìrẹ. Dáhùn ìbéèrè tó bá ní. Àfiyèsí ọlọ́yàyà tí ìwọ fúnra rẹ bá fún un lè ṣe bẹbẹ láti mú kí ìfẹ́ tó ní pọ̀ sí i. Àmọ́ ṣá o, ojúṣe gbogbo wa ni, bí a bá rí ẹni tí a ò mọ̀ rí, kí a kí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí a sì bá a jíròrò ní ṣókí láti dojúlùmọ̀ rẹ̀.

22 Wíwá sí Ìṣe Ìrántí lè ní ipa pàtàkì lórí ìrònú ẹnì kan. Wíwá tó wá sípàdé lè túmọ̀ sí pé kò tíì rí ohun tó ń wá níbòmíràn àti pé a kọ́ ọ ní ohun kan tó ronú pé ó yẹ kí òun túbọ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Àlàyé tí a ṣe nípa ìpèsè ìràpadà tó jẹ́ àgbàyanu lè jẹ́ ìṣípayá jíjinlẹ̀ fún ẹnì kan tí kò mọ̀ nípa èròǹgbà ìfẹ́ aláìláàlà tí Jèhófà ní. Ó lè rí i dáadáa pé a yàtọ̀, ìyẹn ni pé a jẹ́ olóòótọ́, a ń yára mọ́ni, a nífẹ̀ẹ́, a sì ń bọ̀wọ̀ fúnni. Àwọn ohun tó rí nínú gbọ̀ngàn wa kò jọ èyí tó máa ń rí nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n máa ń ní ère àtàwọn ààtò tí kò nítumọ̀. Ó dájú pé àwọn ẹni tuntun yóò ṣàkíyèsí pé onírúurú àwọn èèyàn ló wà níbẹ̀, kò sì sí pé a ń gbégbá owó. Ohun tí wọ́n bá mọ̀ lọ́nà yìí lè mú kí wọ́n tún padà wá.

23 Lẹ́yìn Ìṣe Ìrántí, ẹnì kan gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn láti padà lọ ṣèrànwọ́ fún olúkúlùkù ẹni tó wá. Bí o bá ké sí àwọn ẹni tuntun wá, o níṣẹ́ gidi láti ṣe. Kí wọ́n tó lọ, rí i dájú pé wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìpàdé yòókù tí a máa ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Sọ àkòrí àsọyé fún gbogbo èèyàn tí yóò tẹ̀ lé e. Jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí ẹ ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó sún mọ́ ilé wọn jù lọ àti àkókò tí ẹ máa ń ṣe é.

24 Ṣètò fún ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ sí ilé wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀, tí yóò mú kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì. Bí wọn kò bá tíì máa kẹ́kọ̀ọ́, fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n. Dábàá pé kí wọ́n ka ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ṣàlàyé dáadáa nípa bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ké sí wọ́n láti wá wo àwọn fídíò wa, irú bíi, Our Whole Association of Brothers. Ṣètò fún wọn láti pàdé pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Láwọn oṣù tó ń bọ̀, máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tuntun; ké sí wọn láti wá sí àwọn ìpàdé nígbà tí alábòójútó àyíká bá bẹ̀ wá wò tàbí nígbà tí ẹ bá ní àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àkànṣe. Fún wọn ní gbogbo àǹfààní láti fi ara wọn hàn lẹ́ni tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun”!—Ìṣe 13:48.

25 Nǹkan Táwọn Alàgbà Lè Ṣe: Dé ìwọ̀n kan tó jọjú, àṣeyọrí àfikún ìsapá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣù April yóò sinmi lórí àwọn alàgbà. Bí o bá jẹ́ olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tí o lè ṣe láti ran olúkúlùkù àwọn tó wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ lọ́wọ́ láti kópa nínú ìgbòkègbodò àkànṣe yìí. Ǹjẹ́ àwọn kan wà nínú àwùjọ tìrẹ tí wọ́n jẹ́ èwe tàbí tí wọ́n jẹ́ ẹni tuntun, tàbí tí wọn kì í ṣe déédéé, tàbí tí wọ́n jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́? Wádìí láti mọ̀ bóyá àwọn òbí, àwọn aṣáájú ọ̀nà, tàbí àwọn akéde mìíràn ti lo ìdánúṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣe gbogbo ìrànwọ́ tí ìwọ alára bá lè ṣe fún olúkúlùkù wọn. Arábìnrin kan tí kò ṣe déédéé mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá fún ọdún méjì lò ju àádọ́ta wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣù April ọdún tó kọjá. Kí ló mú un ṣe ìyípadà yìí? Ó sọ pé ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tí ń gbéni ró tí àwọn alàgbà ṣe sọ́dọ̀ òun ló fà á.

26 Kí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i dájú pé ìpínlẹ̀, ìwé ìròyìn, àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó wà lọ́wọ́ lóṣù tó ń bọ̀ yìí. Ǹjẹ́ ẹ lè ṣètò fún àfikún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ ṣèfilọ̀ àwọn ètò àkànṣe tí ẹ bá ṣe. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà sí Jèhófà lápapọ̀ tàbí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ẹ béèrè fún ìbùkún Jèhófà lórí oṣù wa yìí tí a óò mú kí ìgbòkègbodò Ìjọba náà pọ̀ sí i.—Róòmù 15:30, 31; 2 Tẹs. 3:1.

27 Ní oṣù kẹrin ọdún tó kọjá, ní ìjọ kan ní Àríwá Carolina, àwọn alàgbà fún ìjọ níṣìírí gidigidi láti mú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i. Ní àwọn ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n rọ àwọn akéde láti fi tàdúràtàdúrà ronú jinlẹ̀ bóyá wọ́n lè forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ ṣí sílẹ̀, gbogbo àwọn tó jẹ́ alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa mímú kí oṣù April jẹ́ ìgbà tí wọn tíì ṣe dáadáa jù lọ. Nítorí èyí, ìpín méjìdínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akéde, títí kan gbogbo alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló ṣe aṣáájú ọ̀nà lóṣù náà!

28 Ayọ̀ Kíkópa Ní Kíkún: Kí làwọn ìbùkún táa máa rí bí a ṣe ‘ń ṣiṣẹ́ kára, tí a sì ń là kàkà’ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? (1 Tím. 4:10) Ní ti ìgbòkègbodò onítara tí ìjọ wọn ṣe lóṣù April ọdún tó kọjá, àwọn alàgbà táa mẹ́nu kan lókè yẹn kọ̀wé pé: “Àwọn ará sábà máa ń sọ nípa bí wọ́n ṣe túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn sí i tí àjọṣe wọn sì túbọ̀ dán mọ́rán látìgbà tí wọ́n ti túbọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.”

29 Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí kò lè sá sókè sódò fẹ́ láti kópa nínú ìgbòkègbodò àkànṣe oṣù April ọdún tó kọjá yẹn. Nípa fífarabalẹ̀ wéwèé àti pẹ̀lú ìrànwọ́ ìyá rẹ̀ àti tàwọn ará, ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn, ó sì ṣàṣeyọrí. Kí lèrò rẹ̀ nípa ohun tó ṣe yìí? Ó sọ pé: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé mi, ó dà bíi pé mo jẹ́ abarapá èèyàn.”

30 Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé lọ́pọ̀ yanturu, Jèhófà ń bù kún àwọn tó bá ń gbé àǹfààní tí wọ́n ní láti sọ nípa ipò ọba rẹ̀ níyì. (Sm. 145:11, 12) Bí a ti ń ṣèrántí ikú Olúwa wa, a mọ̀ pé àwọn ìbùkún tó wà fún ìfọkànsìn Ọlọ́run yóò tiẹ̀ tún pọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yán hànhàn fún èrè ìyè ayérayé. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé èyí kì í ṣe ohun tí òun kàn lè fọwọ́ lẹ́rán kí òun sì máa retí. Ó kọ̀wé pé: “Fún ète yìí ni èmi ń ṣiṣẹ́ kára ní tòótọ́, mo ń tiraka ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ rẹ̀, èyí tí ń fi agbára ṣiṣẹ́ nínú mi.” (Kól. 1:29) Jèhófà tipasẹ̀ Jésù fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń gbẹ̀mí là, Ó sì lè ṣe ohun kan náà fún wa lóde òní. Ṣé bí ọ̀ràn tìrẹ ṣe máa rí lóṣù April ọdún yìí nìyẹn?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Ta Ni O Lè Fún Níṣìírí Láti Kéde Lóṣù April?

Ṣé ọmọ rẹ ni?

Tàbí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Tàbí ẹni kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́