Àwọn Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
1 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, August 1995 ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìlànà fún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Nísinsìnyí, a ń ṣe àwọn ìyípadà díẹ̀ sí àwọn ohun tí a sọ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yẹn. Ó sọ pé nígbàkígbà tí a bá ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn ìpàdé ní òwúrọ̀ Sunday, ẹnì kan ṣoṣo ni ó gbọ́dọ̀ máa darí wọn, nígbà tí àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò pé jọ sí àwọn àgbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà; àwọn olùdarí gbọ́dọ̀ ṣe yíyan ìpínlẹ̀ àti alábàáṣiṣẹ́ fún àwùjọ wọn, lẹ́yìn náà a óò gbàdúrà kan ṣoṣo pa pọ̀.
2 A ń ṣe àwọn àtúnṣe nísinsìnyí láti fún àwọn ìjọ láyè láti ṣètò ohun tí ó dára jù lọ fún àyíká ipò àdúgbò wọn. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè jẹ́ pé ìpàdé kan fún iṣẹ́ ìsìn pápá ti tó. Nínú àwọn ọ̀ràn míràn, ó lè dára jù lọ fún àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan láti ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tiwọn ní apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ìyẹn jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì níbi tí a bá ti ní oríṣiríṣi yàrá, irú bí ilé ẹ̀kọ́ kejì, ibi àkójọ ìwé kíkà, tàbí àwọn ibi àyè míràn nínú ọgbà yín tí yóò fàyè gba àwọn àwùjọ láti pé jọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ láìdí ara wọn lọ́wọ́. A fi sílẹ̀ fún àwọn alàgbà láti lo ọgbọ́n inú láti pinnu ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ipò wọn.
3 Ohun kan náà ni ó ṣẹlẹ̀ sí àdúrà. A lè gbàdúrà ṣáájú tàbí lẹ́yìn tí a bá ti yan ìpínlẹ̀ àti alábàáṣiṣẹ́ fúnni. Àyíká ipò àdúgbò ni yóò pinnu ohun tí yóò ṣàǹfààní jù lọ. Kókó pàtàkì tí ó wà níbẹ̀ ni pé, kí á kọ́kọ́ ṣètò gbogbo nǹkan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ná, kí àwùjọ tó lọ sí ìpínlẹ̀ wọn, kí ó má baà sí àwùjọ àwọn ará tí wọ́n ń dúró kiri ìpínlẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, bí ẹnì kan bá dara pọ̀ mọ́ àwùjọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a lè yan ìpínlẹ̀ àti alábàáṣiṣẹ́ fún wọn.
4 Nítorí náà, kò sí òfin kànńpá lórí bí a ṣe ní láti darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwùjọ gbọ́dọ̀ sakun láti ṣiṣẹ́ fún ìṣọ̀kan àti àlàáfíà àwọn ará, kí wọ́n baà lè ní ìpín kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ipò àyíká àdúgbò ni ó ní láti pinnu ohun tí ó dára jù lọ fún ìjọ, ní fífi àṣẹ Ìwé Mímọ́ nínú 1 Korinti 14:40 sọ́kàn pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà bíbójúmu ati nipa ìṣètò.”