Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún àwọn ọ̀sẹ̀ January 1 sí April 22, 1996. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bibeli nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ḿbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé-Ìṣọ́nà.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
1. Níwọ̀n ìgbà tí Kristian kan bá ti ronú pé òún ń ṣe ohun tí ó tọ́, ìpinnu rẹ̀ yóò dára. (Owe 14:12) [2, uw-YR ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 8(2)]
2. Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù. [7, uw-YR ojú ìwé 15, ìpínrọ̀ 8]
3. Níwọ̀n bí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìsìn jákèjádò ayé ní ń kọ́ni pé ọkàn ènìyàn jẹ́ àìleèkú, tí ó sì ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú, a gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba èyí gẹ́gẹ́ bí òtítọ́. [1, td-YR 40A]
4. Nípa fífi Romu 8:16 àti Romu 1:7 wéra, a lè rí i pé Paulu ń tọ́ka sí gbogbo aráyé gẹ́gẹ́ bí “ọmọ Ọlọrun.” [17, uw-YR ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 12(3)]
5. Májẹ̀mú tí a mẹ́nu kàn nínú Jeremiah 31:31, 33 tọ́ka sí májẹ̀mú fún Ìjọba tí Jesu bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí a fòróró yàn dá. [6, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 2/1/89 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 12 àti 13.]
6. Jeremiah kọ Ìwé Ẹkún Jeremiah lẹ́yìn ìparun Jerusalemu. [14, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
7. Nígbà Ìkún Omi ọjọ́ Noa, kì í ṣe gbogbo ilẹ̀ ayé ni omi bò, ṣùgbọ́n kìkì ibi tí ènìyàn ń gbé. [10, my-YR Ìtàn 10]
8. Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹni mẹ́ta tí ó bára dọ́gba, tí wọ́n sì para pọ̀ jẹ́ Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà. [6, td-YR 36A]
9. Ènìyàn kò ní àtúnṣe kankan sí wàhálà ayé. [13, td-YR 31E]
10. Ní ọjọ́ Noa, àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n gbé ẹran ara wọ̀ fi ìwà ipá kún orí ilẹ̀ ayé. [8, my-YR Ìtàn 8]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:
11. Níwọ̀n bí ìfẹ́ gíga lọ́lá Jehofa ti sún un láti rán Ọmọkunrin rẹ̀ láti fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, kí ni ó yẹ kí ìfẹ́ wa fún Ọlọrun sún wa láti ṣe? (2 Kor. 5:14, 15) [6, uw-YR ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 6]
12. Kí ni rírìn ní orúkọ Jehofa túmọ̀ sí? [9, uw-YR ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 14]
13. Kí ni a kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jehofa nínú kíka ìwé Ẹkún Jeremiah? (Ẹkún Jer. 3:22, 23, 32) [15, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 9/1/88 ojú ìwé 27.]
14. Ní ọ̀nà wo ní ìwà Jakọbu àti Esau fi yàtọ̀ síra pátápátá? [17, my-YR Ìtàn 17]
15. Fúnni ní àwọn ìdí tí Kristian kan fi gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí. [14, td-YR 19A]
16. Àwọn kókó pàtàkì mẹ́rin wo ni ó ń fi kún ìṣọ̀kan tí àwọn ènìyàn Jehofa ń gbádùn lónìí? [2, 3, uw-YR ojú ìwé 8 sí 9 ìpínrọ̀ 8 àti 9]
17. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti ṣe àdéhùn alákọsílẹ̀ nígbà tí a bá ń kó wọnú òwò pẹ̀lú ẹlẹ́gbẹ́ ẹni tí a jùmọ̀ ń jọ́sìn Jehofa? [7, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 5/1/95 ojú ìwé 30.]
18. Ní àfikún sí àwọn ànímọ́ títayọ Jehofa tí í ṣe, ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti agbára, kí ni a lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà rẹ̀ fífani mọ́ra láti inú Eksodu 34:6, Orin Dafidi 86:5, àti Ìṣe 10:34, 35? [5, uw-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 3]
19. Lẹ́yìn fífi Johannu 14:9, 10 wéra pẹ̀lú Luku 5:12, 13, èé ṣe tí a fi lè parí èrò sí pé Jehofa jẹ́ oníyọ̀ọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí aráyé tí ń jìyà? [12, uw-YR ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 12(1)]
20. Kí ni ìtumọ̀ òṣùmàrè tí ó kọ́kọ́ fara hàn lẹ́yìn Ìkún Omi? [11, my-YR Ìtàn 11]
21. Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú ẹ̀rí náà pé aya Loti pàdánù ìwàláàyè rẹ̀, tí ó sì di ọwọ̀n iyọ̀ nígbà tí ó ń sá kúrò ní Sodomu? [15, my-YR Ìtàn 15]
22. Ànímọ́ wo ni Abrahamu fi hàn ní pàtàkì tí ó fún un ní orúkọ oyè náà, “Ọ̀rẹ́ Ọlọrun”? [13, my-YR Ìtàn 13]
23. Ta ni ó ń fa wàhálà ayé ní pàtàkì? [10, td-YR 31A]
24. Nígbà tí Jehofa sọ fún Jeremiah pé: “Gba aago ọtí wáìnì ìbínú mi yìí kúrò lọ́wọ́ mi, kí o sì jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí èmi yóò rán ọ sí, mu ún,” (Jer. 25:15) kí ni ó ní lọ́kàn? [4, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 3/15/80 ojú ìwé 23.]
25. Nígbà wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ròyìn nínú Jeremiah 52:5-11 ṣẹlẹ̀? [13, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 4/1/88 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 18.]
Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
26. Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nítorí pé (àwọn olùtumọ̀ pè é bẹ́ẹ̀; àwọn ọkùnrin olùfọkànsìn ni ó kọ ọ́; Ọlọrun darí kíkọ ọ́ ní tààràtà). [10, uw-YR ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 2]
27. Bí o bá ń ka ojú ìwé (kan; méjì; mẹ́rin) péré lójoojúmọ́ nínú Bibeli, ìwọ yóò parí odindi Bibeli ní nǹkan bí (oṣù mẹ́fà; oṣù mẹ́sàn-án; ọdún kan). [11, uw-YR ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 9]
28. Jehofa sọ Jeremiah di “òmùgọ̀” ní ti pé (Ó fi ẹ̀tàn mú un láti wàásù ìhìn iṣẹ́ ìdálẹ́bi; Ó lò ó láti ṣàṣeparí ohun tí kò lè ti dá ṣe nínú okun ti ara rẹ̀; Òun kò mú ìparun tí Jeremiah sọ tẹ́lẹ̀ wá). (Jer. 20:7, NW) [3, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 5/1/89 ojú ìwé 31.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
29. Ebedmeleki jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú fún_________________________ tí a óò pa mọ́ láàyè ní _________________________ nítorí pé wọ́n bá _________________________ àwọn arákùnrin Kristi dọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n sì tì wọ́n lẹ́yìn. [9, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 4/1/83 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 11.]
30. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pe Jesu ní “ọlọrun kan,” ni Johannu 17:3 òún pe Jehofa ní “Ọlọrun tòótọ́ _________________________ naa,” àti nínú Johannu 20:17 ó tọ́ka sí Jehofa gẹ́gẹ́ bí “Ọlọrun _________________________ ati Ọlọrun _________________________ [8, uw-YR ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 12]
So àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
Owe 3:5, 6; Jer. 23:33; 32:9, 10; Ẹkún Jer. 3:44; Ìṣí. 15:3, 4.
31. Ìpìlẹ̀ fún ìṣọ̀kan tòótọ́ nínú ìjọsìn jẹ́ mímọ Jehofa àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀. [1, uw-YR ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1]
32. Gbogbo ipa ọ̀nà ìgbésí ayé wa pátápátá—láìka ibi tí a wà sí, láìka ohun tí a ń ṣe sí—yẹ kí ó fi ẹ̀rí hàn pé ìrònú wa àti ète ìsúnniṣe wá jẹ́ èyí tí Ọlọrun ń darí. [4, uw-YR ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 11]
33. Jehofa kì í fetí sí àdúrà àwọn ẹni ibi. [15, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 7/15/87 ojú ìwé 15.]
34. Ìhìn iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ wíwúwo láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kún fọ́fọ́ fún ègbé, tí ń kéde ìparun Kirisẹ́ńdọ̀mù tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. [4, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 3/1/94 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 18, 20.]
35. Nígbà tí a bá ń kówọ inú òwò pẹ̀lú ẹlẹ́gbẹ́ ẹni tí a jùmọ̀ ń jọ́sìn Jehofa, àdéhùn alákọsílẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti dènà èdè àìyedè tí ó lè dìde lẹ́yìn ọ̀la. [7, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 5/1/95 ojú ìwé 30.]