Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní April àti May: Gbogbo èdè—àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà. Ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan, ₦400. Ọdún kan fún olóṣooṣù tàbí oṣù mẹ́fà ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù, ₦200. Fún ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́, a tún lè lo ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí (yàtọ̀ sí ìwé pẹlẹbẹ Education àti School). June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí ìyẹn kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, lo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, Mankind’s Search for God, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lè é yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bi?, Ki Ni Ete Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun,” Níbi tí ó bá ti yẹ, a lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ bíi, Ẹmi Àwọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?, àti Will There Ever Be a World Without War? lọni. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, àwọn alàgbà ní láti ṣètò fún ìjọ láti lo àkókò púpọ̀ sí i nínú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́.
◼ A ti ṣe àtúnṣe nínú ọ̀nà tí a ń gbà ṣàfidípò káàdì Pioneer Service Identification. Láti ìsinsìnyí lọ, Society ni yóò máa pèse káàdì àfidípò fún àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ó bá ṣí lọ, yí orúkọ wọn padà, sọ káàdì wọn nù, tàbí béèrè fún àyípadà iṣẹ́ àyànfúnni. Kí akọ̀wé kó gbogbo káàdì aṣáájú ọ̀nà tí a kò tí ì kọ ọ̀rọ̀ kún, tí ó lè wà nínú fáìlì danù. A óò máa bójú tó ìyípadà orúkọ àti títún iṣẹ́ yàn fúnni gẹ́gẹ́ bí a ti ń ṣeé látẹ̀yìnwá, tí akọ̀wé ń kọ ìsọfúnni yíyẹ sẹ́yìn káàdì Congregation Report (S-1) fún oṣù náà. Lẹ́yìn náà, Society yóò fi káàdì tuntun fún aṣáájú ọ̀nà náà ráńṣẹ́ sí ìjọ. Ní gbogbogbòò, ìwọ̀nyí yóò máa bá ìwé ìṣírò owó oṣooṣù dé. Ẹ ní láti fi ìyípadà èyíkéyìí ráńṣẹ́ sí Society ní kánmọ́, kí a baà lè mú fáìlì wa pé pérépéré, kí ó sì bá ìsọfúnni lọ́ọ́lọ́ọ́ mu. Síwájú sí i, nígbà tí aṣáájú ọ̀nà kan bá dá ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà dúró, tàbí tí a dá a dúró, ẹ ní láti kọ ọ̀rọ̀ kún ẹ̀da fọ́ọ̀mu S-206, kí ẹ sì fi ránṣẹ́ sí Society láìsí ìdádúró.
◼ Ní àwọn ọjọ́ Saturday April 27 àti May 25, a óò ti ilé Beteli pa. Nítorí náà, ẹ jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tàbí láti wá ra ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí.