“Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?”
1 Ìbéèrè yẹn wà lọ́kàn àwọn èèyàn káàkiri ayé. Nígbà tó jẹ́ pé ìran èèyàn ti ṣàṣeyọrí àwọn ohun tí kò lóǹkà ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, àwọn èèyàn ni a ti já kulẹ̀ nítorí pé àwọn ìṣòro tó ti ń bá ẹ̀dá èèyàn jà látọdún gbọ́nhan ṣì wà síbẹ̀. (Jóòbù 14:1; Sm. 90:10) Ibo wá ni aráyé yóò ti rí ìrànlọ́wọ́ báyìí o?
2 Ní oṣù October àti November, a óò ní àǹfààní àkànṣe láti dáhùn ìbéèrè yìí fún àwọn aládùúgbò wa. Lọ́nà wo? Nípa ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36 ni. A pe àkọlé rẹ̀ ní “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?” Ní ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àkọ́kọ́ nínú oṣù October, a óò fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Lẹ́yìn náà, láti ọjọ́ Monday, October 16, títí di Friday, November 17, a óò ṣe ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36 lọ́nà àkànṣe. Nígbà ìpínkiri yìí, a óò gbájú mọ́ pípín Ìròyìn Ìjọba No. 36 láàárín ọ̀sẹ̀. Tó bá wá di òpin ọ̀sẹ̀, a óò máa fi lọni pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́.
3 Ṣé Wàá Kópa Nínú Rẹ̀ Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? Àwọn alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà yóò mú ipò iwájú nínú ìpínkiri yìí, bó ti jẹ́ pé àwọn náà ni òléwájú nínú iṣẹ́ náà. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ akéde láti tún àwọn ètò wọn ṣe kí wọ́n lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí oṣù méjèèjì tí a fi máa ṣe ìpínkiri náà. Tiẹ̀ gbọ́ ná, kí ló dé tóò kúkú fi í ṣe góńgó rẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Tóo bá sì rí i pé kò ní rọrùn fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, kúkú ṣètò láti lo àkókò tó pọ̀ ju èyí tóo máa ń lò tẹ́lẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
4 Àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè kó ipa ribiribi láti fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àwùjọ wọn níṣìírí láti kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36 yìí. Àwọn akéde kan lè wà tí wọ́n ti dáwọ́ ìwàásù dúró. Kí àwọn alàgbà bẹ̀ wọ́n wò kí wọ́n sì ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n ṣètò pé kí akéde kan tó nírìírí bá ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láàárín àwọn oṣù tí a fi máa ṣe ìpínkiri náà. Ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun tí akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ náà nílò láti padà bọ̀ sípò kò ju ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rírọrùn tí a fi pín Ìròyìn Ìjọba No. 36 fúnni.
5 Èyí yóò tún jẹ́ àǹfààní tó dára fún àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ tán tí wọ́n sì ti tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi láti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Kódà, àwọn ògo wẹẹrẹ wa lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ amọ́kànyọ̀ yìí.
6 Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rírọrùn kan ni gbogbo ohun tí o nílò. O lè sọ pé:
◼ “Mo ti yọ̀ǹda àkókò mi fún ṣíṣèrànwọ́ láti pín ìsọfúnni pàtàkì yìí fún gbogbo ìdílé ní [orúkọ ìlú tàbí ìpínlẹ̀]. Ẹ̀dà tìrẹ rèé. Jọ̀wọ́ kà á.” A lè ṣàìfẹ́ láti gbé àpò òde ẹ̀rí lọ́wọ́ nígbà tí a bá ń pín Ìròyìn Ìjọba No. 36 kiri.
7 Àwọn Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tí A Ṣètò Dáadáa: Kí àwọn alàgbà rí i dájú pé àwọn ètò tí wọ́n ṣe fún iṣẹ́ ìwàásù rọrùn, ó sì gbéṣẹ́. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ní pàtàkì rí i dájú pé ìpínlẹ̀ tó pọ̀ tó wà fún ìjẹ́rìí ilé dé ilé àti àwọn àgbègbè okòwò kí gbogbo àwọn ará lè kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ náà. Níbikíbi tó bá ti ṣeé ṣe, kí á ṣètò fún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láàárín ọ̀sẹ̀, ní òpin ọ̀sẹ̀, àti ní ìrọ̀lẹ́. A tún lè ṣètò pé kí á pàdé ní ọjọ́rọ̀ fún àǹfààní àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ àṣegbà, àti àwọn mìíràn.
8 Ohun Tí A Lè Ṣe Nípa Àwọn Tí Kò Bá Sí Nílé: Góńgó wa ni láti bá àwọn onílé púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó sọ̀rọ̀. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni kò bá sí nílé nígbà tí o ṣe ìkésíni, kọ àdírẹ́sì ibẹ̀ sílẹ̀ kí o sì padà ṣe ìkésíni ní àkókò mìíràn. Bí gbogbo ìsapá rẹ láti kàn sí àwọn onílé wọ̀nyí bá já sí pàbó títí di ọ̀sẹ̀ tó kẹ́yìn ìpínkiri náà, o lè fi ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba No. 36 há sí ẹnu ọ̀nà níbi tí àwọn èèyàn tó ń kọjá kò ti lè rí i. Àwọn alàgbà ìjọ lè fún àwọn ará nítọ̀ọ́ni láti fi ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba No. 36 sílẹ̀ fún àwọn tí kò sí nílé nígbà ìkésíni àkọ́kọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè ìgbèríko àti níbi tí ìpínlẹ̀ ti pọ̀ ju ohun tí ẹ lè kárí nígbà ìpínkiri náà.
9 Ẹ Jẹ́ Kí Ọwọ́ Wa Dí Jọjọ! Kí àwọn ìjọ sakun láti kárí ìpínlẹ̀ wọn kí ìpínkiri náà tó parí ní November 17. Bí ìpínlẹ̀ ìjọ yín bá tóbi gan-an, àwọn akéde kan lè dá ṣiṣẹ́ bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá gbéṣẹ́ tí kò sì léwu. Èyí yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni yíyẹ tó pọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Rí i dájú pé o pa àkọsílẹ̀ tó péye mọ́ nípa gbogbo ibi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn.
10 Kí àwọn alàgbà ronú ṣáájú nípa iye àfikún ìwé ìròyìn tí ìjọ yóò nílò, kí wọ́n sì kọ̀wé béèrè fún iye náà. Ẹ kò ní láti kọ̀wé béèrè fún Ìròyìn Ìjọba No. 36, níwọ̀n bí a ti ń kó wọn ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, aṣáájú ọ̀nà déédéé, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn yóò gba igba [200] ẹ̀dà láti pín kiri, nígbà tí a óò fún akéde ìjọ kọ̀ọ̀kan ní àádọ́ta [50] ẹ̀dà. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé o ti múra tán tí o sì ń hára gàgà láti mú kí ọwọ́ rẹ dí nínú ìgbòkègbodò àkànṣe yìí? Ẹ wo àǹfààní ńláǹlà tí a ní pé a lè jẹ́ kí àwọn aládùúgbò wa mọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún ọjọ́ ọ̀la kan tí kò jìnnà mọ́!