Máa Wàásù Nìṣó!
1 Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Fún ìdí yìí, ó ti yan iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà fún wa. (Mát. 24:14) Bí a bá mọrírì ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ máa wàásù nìṣó, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìpínyà ọkàn èyíkéyìí tó bá dojú kọ wá kò ní mú ká dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró.
2 Kí Ló Dé Tá Ò Gbọdọ̀ Fi Jáwọ́? Àwọn nǹkan tó ń fa ìpínyà ọkàn nínú ayé kò lóǹkà, ó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ má ka ohun tí a ń bá wọn sọ sí tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gbàgbé pàápàá. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa rán wọn létí ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run lóòrèkóòrè. (Mát. 24:38, 39) Ní àfikún sí i, nǹkan máa ń yí padà nínú ayé àwọn ènìyàn. Kódà, ipò ayé pàápàá lè yí bírí kójú tóó mọ́. (1 Kọ́r. 7:31) Bó bá tó ọjọ́ bíi mélòó kan, tí àwọn tí a ti wàásù fún bá wá níṣòro tàbí tí ipò nǹkan bá dojú rú, èyí lè mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ìhìn rere tí a ń mú tọ̀ wọ́n wá. Ṣé inú tìrẹ kò dùn pé Ẹlẹ́rìí tó wàásù òtítọ́ náà fún ọ kò jáwọ́ ni?
3 Láti Fara Wé Àánú Ọlọ́run: Jèhófà ti mú sùúrù, ó ti fi àkókò tó pọ̀ sílẹ̀ kí ó tó wá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ lórí àwọn ènìyàn búburú. Ó ń tipa wa rọ àwọn tó ní ọkàn rere láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì ní ìgbàlà. (2 Pét. 3:9) A ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bí a kò bá sọ ìhìn iṣẹ́ àánú Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn náà kí a sì kìlọ̀ fún wọn nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bọ̀ wá sórí gbogbo àwọn tí kò bá yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú. (Ìsík. 33:1-11) Bí àwọn ènìyàn kì í tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìwàásù wa, síbẹ̀ ẹ má ṣe jẹ́ ká dẹwọ́ láé nínú sísapá láti mú kí àwọn olóòótọ́ ọkàn mọrírì àánú ńláǹlà tí Ọlọ́run ní.—Ìṣe 20:26, 27; Róòmù 12:11.
4 Láti Fi Ìfẹ́ Wa Hàn: Jèhófà Ọlọ́run ló tipasẹ̀ Jésù Kristi pàṣẹ pé kí a wàásù ìhìn rere ìjọba náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé. (Mát. 28:19, 20) Kódà nígbà tí àwọn èèyàn kò bá fetí sílẹ̀, a ní àǹfààní láti fi ìfẹ́ àti ìfọkànsìn tí a ní fún Ọlọ́run hàn nípa títẹra mọ́ ṣíṣe ohun tí ó tọ́.—1 Jòh. 5:3.
5 Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa bá a lọ ní wíwàásù! Ká sì máa fi ìtara ṣe é níwọ̀n bí “ọjọ́ ìgbàlà” Jèhófà ti ń bọ̀ lọ́nà.—2 Kọ́r. 6:2.