Èé Ṣe Tí A Fi Ń Pa Dà Lọ Ṣáá?
1 O ha ti bi ara rẹ ní ìbéèrè yẹn rí, bóyá bí o ti ń múra fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ kan bí? Ní àwọn àgbègbè kan tí a ti máa ń ṣe ìpínlẹ̀ wa ní àṣetúnṣe, àwọn onílé lè mọ ẹni tí a jẹ́, kí wọ́n sì tètè lé wa. Àwọn díẹ̀ ni ó ń dáhùn pa dà lọ́nà rere. Síbẹ̀, a ní ọ̀pọ̀ ìdí lílágbára tí a ṣe ń pa dà lọ ṣáá.
2 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a pàṣẹ fún wa láti máa bá a nìṣó láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà títí tí òpin yóò fi dé. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Wòlíì Aísáyà béèrè nípa bí yóò ti pẹ́ tó tí òun yóò fi máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìwàásù tí òun ń ṣe. Ìdáhùn tí ó rí gbà ni a kọ sílẹ̀ nínú Aísáyà 6:11. Láìsí tàbí-tàbí—a sọ fún un pé kí ó máa mú ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run pa dà tọ àwọn ènìyàn lọ ṣáá. Bákan náà lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè lé wa, Jèhófà fojú sọ́nà pé kí a máa bá a nìṣó ní kíkésí àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ wa. (Ìsík. 3:10, 11) Ẹrù iṣẹ́ ọlọ́wọ̀ tí a ti fi síkàáwọ́ wa ni èyí jẹ́.—1 Kọ́r. 9:17.
3 Ìdí mìíràn tí a fi ní láti máa pa dà lọ ṣáá ni pé, èyí ń fún wa ní àǹfààní láti fi bí ìfọkànsìn wa sí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó hàn. (1 Jòh. 5:3) Yàtọ̀ sí ìyẹn, nígbà tí a bá ronú nípa ohun tí ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́ ní ní ìpamọ́ fún aráyé, báwo ni a ṣe lè fà sẹ́yìn nínú fífi ìfẹ́ gbìyànjú láti kìlọ̀ fún àwọn aládùúgbò wa? (2 Tím. 4:2; Ják. 2:8) Jíjẹ́ tí a jẹ́ olùṣòtítọ́ ní ṣíṣe iṣẹ́ àyànfúnni wa ń pèsè àǹfààní léraléra fún wọn láti dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà ti Ọlọ́run, kí wọ́n má baà lè sọ pé a kò kìlọ̀ fún àwọn.—Ìsík. 5:13.
4 Ní àfikún sí i, a kò mọ ìgbà tí àwọn ènìyàn kan yóò ní ìyípadà ọkàn. Èyí lè wáyé nítorí àyíká ipò ara ẹni wọn tí ó yí pa dà, ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan nínú ìdílé wọn, tàbí àwọn ipò ayé tí ó mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wọn. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ohun kan tí a sọ lẹ́nu ọ̀nà wọn lè mú kí wọ́n dáhùn pa dà lọ́nà rere. (Oníw. 9:11; 1 Kọ́r. 7:31) Bákan náà, àwọn ènìyàn máa ń pa ibùgbé dà. A lè rí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sí ìpínlẹ̀ wa, tí wọn yóò dáhùn pa dà sí ìhìn rere—bóyá àwọn àgbà ọ̀dọ́, tí wọ́n ti ń dá gbé nísinsìnyí, tí wọ́n sì ń ronú jinlẹ̀ nípa ète ìgbésí ayé wọn.
5 Àwa yóò ha máa pa dà lọ ṣáá bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìwé Mímọ́ fún wa ní ọ̀pọ̀ yanturu ìsúnniṣe láti pa dà tọ àwọn ènìyàn lọ léraléra. Ní òpin rẹ̀, nígbà tí a bá parí iṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà yóò bù kún wa fún ìsapá wa tí ń bá a nìṣó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, yóò sì bù kún àwọn tí wọ́n ti fi ìmoore dáhùn pa dà sí ìhìn rere Ìjọba náà.—1 Tím. 4:16.