ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/01 ojú ìwé 8
  • “A Ti Ṣe Ìpínlẹ̀ Wa Lọ́pọ̀ Ìgbà!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “A Ti Ṣe Ìpínlẹ̀ Wa Lọ́pọ̀ Ìgbà!”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣó O Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tara Ẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tìrẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àwọn Pápá Ti Funfun fún Kíkórè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 5/01 ojú ìwé 8

“A Ti Ṣe Ìpínlẹ̀ Wa Lọ́pọ̀ Ìgbà!”

1 Ǹjẹ́ o ti ronú rí pé ẹ ń ṣe ìpínlẹ̀ yín lemọ́lemọ́ débi pé kò tún sí àwọn ẹni bí àgùntàn níbẹ̀ mọ́? Bóyá o ti ronú pé: ‘Mo mọ báwọn èèyàn yẹn á ṣe hùwà padà. Kí nìdí tí màá fi máa padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò fìfẹ́ hàn?’ Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ la máa ń ṣe lemọ́lemọ́. Ṣùgbọ́n, èrò rere ló yẹ ká ní nípa kókó yìí, kò yẹ ká ní èrò tí kò dára nípa rẹ̀. Nítorí kí ni? Kíyè sí àwọn ìdí mẹ́rin tí a mẹ́nu kàn nísàlẹ̀ yìí.

2 Jèhófà Ti Dáhùn Àwọn Àdúrà Wa: Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:2) Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún la ti fi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kí ó túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ibi, nísinsìnyí, a ti ní àfikún àwọn òṣìṣẹ́ tí a nílò, a sì túbọ̀ ń ṣe àwọn ìpínlẹ̀ wa lóòrèkóòrè. Ǹjẹ́ kò yẹ kí dídáhùn tí Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà wa mú ká láyọ̀?

3 Àìṣíwọ́ Ń Mú Èso Rere Wá: Kódà láwọn ìpínlẹ̀ táa sábà máa ń ṣe, àwọn èèyàn ń dáhùn sí ìhìn Ìjọba náà, wọ́n sì ń ní ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa padà lọ léraléra kí a sì máa nírètí pé a ó túbọ̀ rí àwọn olóòótọ́ ọkàn. (Aísá. 6:8-11) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí ti ṣe, “lọ léraléra” sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ọ, kí o sì sakun láti ru ìfẹ́ wọn sí Ìjọba Ọlọ́run sókè.—Mát. 10:6, 7.

4 Ní ilẹ̀ Potogí, ọ̀pọ̀ ìjọ máa ń ṣe ìpínlẹ̀ wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ń wá àwọn ẹni bí àgùntàn kiri síbẹ̀. Arábìnrin kan ní pàtàkì ní ẹ̀mí tó dára gidigidi. Ó sọ pé: “Kí n tó lọ sóde láràárọ̀, mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè rí ẹni tó máa fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Lọ́jọ́ kan, ó ṣètò láti bá àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ aṣerun-obìnrin-lóge ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ẹnì kan ṣoṣo ló ń wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ẹni yẹn sọ pé: “Àwọn yòókù kò nífẹ̀ẹ́ sí i, ṣùgbọ́n èmi fẹ́.” Láàárín oṣù kan, obìnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì fáwọn ẹlòmíràn. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe ìrìbọmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn náà!

5 Iṣẹ́ Náà Ń Di Ṣíṣe: A ń wàásù ìhìn rere náà gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò rí. (Mát. 24:14) Àní ní àwọn ibi tí àwọn èèyàn ibẹ̀ kì í ti í “fẹ́ láti fetí sí [wa],” iṣẹ́ ìwàásù náà jẹ́ ìkìlọ̀ fún wọn. A retí pé àwọn kan kò ní tẹ́wọ́ gba òtítọ́, àní wọ́n tilẹ̀ lè takò ó pàápàá. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ kìlọ̀ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dáadáa nípa ìdájọ́ Jèhófà tí ń bọ̀.—Ìsík. 2:4, 5; 3:7, 8, 19.

6 A Kò Tíì Parí Iṣẹ́ Náà: Kì í ṣe tiwa láti pinnu ìgbà tí a máa dá iṣẹ́ ìwàásù dúró. Jèhófà ló mọ ìgbà tó yẹ kó parí gan-an. Ó mọ̀ bóyá àwọn èèyàn wà ní ìpínlẹ̀ wa tí wọ́n ṣì lè dáhùn sí ìhìn rere náà. Lónìí, àwọn èèyàn kan ń sọ pé àwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé wọn, bí ìpàdánù iṣẹ́, àìsàn lílekoko, àti ikú ẹni tí wọ́n fẹ́ràn, lè mú kí wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà míì. Nítorí ẹ̀tanú tàbí nítorí pé ọwọ́ wọn wulẹ̀ dí jù láti fetí sílẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tíì gbọ́ ohun tí a ń wàásù ní ti gidi. Pípadà dé ọ̀dọ̀ wọn léraléra lọ́nà ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ kí wọ́n fiyè sí wa kí wọ́n sì fetí sílẹ̀.

7 Àwọn tó ti dàgbà sí i láwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ tí àwọn fúnra wọn sì ti wá ní ìdílé tiwọn túbọ̀ ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìgbésí ayé, wọ́n sì ń béèrè àwọn ìbéèrè tó jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ló lè dáhùn wọn. Ìyá kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wá sí ilé rẹ̀, ó sì wí pé: “Nígbà tí mo wà ní ọmọdébìnrin, ìdí tí ìyá mi fi máa ń lé àwọn Ẹlẹ́rìí padà tó sì máa ń sọ fún wọn pé òun kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn kò yé mi, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa Bíbélì ni wọ́n fẹ́ sọ. Mo pinnu lọ́kàn ara mi pé nígbà tí mo bá dàgbà, tí mo ṣègbéyàwó, tí mo sì ní ibùgbé tèmi, màá ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá kí wọ́n sì ṣàlàyé fún mi nípa Bíbélì.” Ohun tó ṣe nìyẹn, ìyẹn sì mú kí inú àwọn Ẹlẹ́rìí tó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ dùn.

8 Ǹjẹ́ O Lè Túbọ̀ Gbéṣẹ́ Sí I? Ó lè má fi ìgbà gbogbo jẹ́ pé àwọn èèyàn tí a ń lọ bá ló jẹ́ kí ó dà bíi pé ṣíṣe ìpínlẹ̀ wa lemọ́lemọ́ ṣòro. Nígbà mìíràn, àwa gan-an ló máa ń fà á. Ṣé èrò tí kò dára là ń gbé sọ́kàn tọ̀ wọ́n lọ? Èyí lè ní ipa lórí ìhùwàsí wa, ó sì lè ní ipa lórí ìró ohùn wa àti ìwò ojú wa. Fi ẹ̀mí tó dára hàn kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ fani mọ́ra. Gbìyànjú ọ̀nà ìyọsíni tuntun. Jẹ́ kí ọ̀nà tí o ń gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ jẹ́ onírúurú, kí o sì sakun láti mú kí ó sunwọ̀n sí i. Bóyá o lè yí ìbéèrè tí o fi ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ padà tàbí kí o lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn nínú ìjíròrò rẹ. Béèrè lọ́wọ́ àwọn ará yòókù nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ní àṣeyọrí nínú ṣíṣe ìpínlẹ̀ náà. Bá onírúurú àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, kí o sì kíyè sí ohun tó mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbéṣẹ́.

9 Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní ìtẹ́wọ́gbà àti ìbùkún Jèhófà, kíkópa tí a bá sì ń kópa nínú rẹ̀ ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-39) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ki a máa ṣe iṣẹ́ wa nìṣó títí dé òpin rẹ̀, kí a má ṣe káàárẹ̀ ní ṣíṣe ìpínlẹ̀ wa nígbà gbogbo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́