Àwọn Pápá Ti Funfun fún Kíkórè
1. Iṣẹ́ pàtàkì wo ló ń lọ lọ́wọ́?
1 Lẹ́yìn tí Jésù jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà kan, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35, 36) Ìkórè tẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ nígbà ayé Jésù, ó sì mọ bí iṣẹ́ yìí ṣe máa gbòòrò tó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni Jésù wà, ó ṣì ń kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìkórè náà. (Mát. 28:19, 20) Àwọn ẹ̀rí wo ló wà pé iṣẹ́ náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tó sì ń bá a nìṣó ní pẹrẹu bó ṣe ń lọ sí òpin?
2. Àwọn ẹ̀rí wo ló fi hàn pé iṣẹ́ ìkórè tá à ń ṣe kárí ayé túbọ̀ ń pọ̀ sí i?
2 Ìkórè Kárí Ayé: Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2009, ó lé ní ìdá mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún tí iye àwọn akéde fi pọ̀ sí i kárí ayé. Ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù pàápàá, ìdá mẹ́rìnlá nínú ọgọ́rùn-ún ni iye àwọn akéde fi pọ̀ sí i. Àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń darí lóṣooṣù ju mílíọ̀nù méje àti ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàwá [7,619,000] lọ, èyí sì ju àròpọ̀ gbogbo àwọn akéde lọ. Iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ròyìn yìí fi nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ju iye tá a ròyìn lọ́dún 2008 lọ. Bí iṣẹ́ náà ṣe túbọ̀ ń gbòòrò ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a túbọ̀ ń fẹ́ àwọn míṣọ́nnárì tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì àtàwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ láti lọ ṣèrànwọ́. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìbísí túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Ó hàn gbangba pé Jèhófà ń mú kí iṣẹ́ náà yára kánkán bí ìkórè náà ṣe ń lọ sí òpin. (Aísá. 60:22) Ṣé o ní èrò tó dára nípa “pápá” tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ rẹ?
3. Kí làwọn kan lè máa rò nípa iṣẹ́ ìkórè tí wọ́n ń ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn?
3 Iṣẹ́ Ìkórè Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ: Àwọn kan lè sọ pé: “Àwọn èèyàn kì í sábà tẹ́tí sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.” Òótọ́ ni pé láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ìwàásù, nígbà tó jẹ́ pé láwọn ibòmíì wọ́n máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n máa ń fetí sílẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí wọn ò fetí sílẹ̀ mọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan lè wá parí èrò sí pé àwọn tó fẹ́ gbọ́ ìwàásù ti gbọ́, ìwọ̀nba èèyàn náà ló kù kí wọ́n gbọ́. Ṣé òótọ́ ni èrò yìí ṣá?
4. Èrò tó tọ́ wo ló yẹ ká ní nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí sì nìdí?
4 Iṣẹ́ àṣekára ni iṣẹ́ ìkórè náà láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dópin. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé ìkórè náà jẹ́ iṣẹ́ kánjúkánjú, ó ní: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:37, 38) Jèhófà ni Ọ̀gá ìkórè, òun ló mọ ìgbà tá a máa kórè àti ibi tá a ti máa kórè. (Jòh. 6:44; 1 Kọ́r. 3:6-8) Kí wá ni ojúṣe tiwa? Bíbélì dáhùn pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi.” (Oníw. 11:4-6) Bó ṣe rí nìyẹn o, kì í ṣe ìgbà tí ìkórè ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin ló yẹ ká jẹ́ kí ọwọ́ wa sinmi!
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó láti fi ìtara wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó dà bíi pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù?
5 Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Nìṣó: Bó bá tiẹ̀ dà bíi pé ẹ ti wàásù ní gbogbo ìpínlẹ̀ ìwàásù yín léraléra, tó sì dà bíi pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù, ìdí pàtàkì ṣì wà tó fi yẹ ká máa fi ìtara àti ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ ìkórè yìí. (2 Tím. 4:2) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé máa ń mú káwọn èèyàn yí ìwà wọn pa dà kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe túbọ̀ ń dàgbà, wọ́n lè wá rí i pé àwọn nílò ààbò àti ìbalẹ̀ ọkàn. Ó sì lè jẹ́ pé bá a ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn míì léraléra ló máa mú kí wọ́n fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Àwọn tí kò fetí sílẹ̀ lónìí lè fetí silẹ̀ lọ́la. Kódà, a gbọ́dọ̀ kìlọ̀ fún àwọn tó dìídì kọ̀ láti fetí sí ìwàásù.—Ìsík. 2:4, 5; 3:19.
6. Bí iṣẹ́ ìwàásù kò bá rọrùn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi ìtara wàásù?
6 Bí iṣẹ́ ìwàásù kò bá rọrùn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi ìtara wàásù? A lè máa wàásù láwọn ọ̀nà míì tó yàtọ̀ sí ìwàásù ilé-dé-ilé, irú bíi wíwàásù láwọn ibi ìṣòwò tàbí fífi tẹlifóònù jẹ́rìí. A lè máa yí àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wa pa dà, ká bàa lè lo ọ̀nà tuntun láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. A lè ṣètò àkókò wa ká bàa lè máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ tàbí láwọn ìgbà míì táwọn èèyàn sábà máa ń wà nílé. A lè sapá láti kọ́ èdè tuntun ká bàa lè wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i. A lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i nípa ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí ká lọ sí ibi tí kò ti sí àwọn olùkórè púpọ̀. Bá a bá ní èrò tó tọ́ nípa ìṣẹ́ ìkórè náà, a ó máa fi taratara kópa nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì yìí.
7. Títí dìgbà wo la gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ ìkórè náà?
7 Àkókò tí àwọn àgbẹ̀ máa ń ní láti fi kórè kì í sábà tó nǹkan, torí náà wọn kì í sinmi tàbí kí wọ́n dẹwọ́ títí tí iṣẹ́ náà fi máa parí. Ìkórè tẹ̀mí yìí náà jẹ́ iṣẹ́ kánjúkánjú. Ìgbà wo la máa ṣe iṣẹ́ ìkórè náà dà? Yóò máa báa lọ ní gbogbo àkókò “ìparí ètò àwọn nǹkan” àti títí dé “òpin.” (Mát. 24:14; 28:20) Bíi ti ẹni tó jẹ́ òléwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́ Jèhófà, a fẹ́ parí iṣẹ́ tí Jèhófà fi sí ìkáwọ́ wa. (Jòh. 4:34; 17:4 ) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìṣó pẹ̀lú ìtara àti ìdùnnú, ká sì máa ní èrò tó dára nípa iṣẹ́ náà títí òpin yóò fi dé. (Mát. 24:13) Ìkórè náà kò tíì dópin o!
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 2]
Iṣẹ́ àṣekára ni iṣẹ́ ìkórè náà láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dópin