ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kr orí 9 ojú ìwé 87-97
  • Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”
  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ní Kí Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́, Ó sì Ṣèlérí Pé Wọ́n Máa Láyọ̀
  • Ọba Wa Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Iṣẹ́ Ìkórè Ńlá Tó Ju Ti Ìgbàkígbà Rí Lọ
  • Ó Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Àbájáde Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ́nà Tó Yéni Yékéyéké
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Inú Gbogbo Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Dùn
  • “Láti Yíyọ Oòrùn Àní Dé Wíwọ̀ Rẹ̀”
  • Ẹ Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ Ní Rabidun!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àwọn Pápá Ti Funfun fún Kíkórè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ẹ Jẹ́ Òṣìṣẹ́ Tí Ń fi Tayọ̀tayọ̀ Kórè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Máa Kó Ipa Tó Jọjú Nínú Ìkórè Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
kr orí 9 ojú ìwé 87-97

ORÍ 9

Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Jèhófà mú kí irúgbìn òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run dàgbà

1, 2. (a) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi rú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú? (b) Irú ìkórè wo ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

JÉSÙ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” Ọ̀rọ̀ náà rú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú. Torí pé, nígbà tí wọ́n wo pápá tí Jésù tọ́ka sí, wọ́n rí i pé kò funfun rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni gbogbo ewé rẹ̀ tutù yọ̀yọ̀ àti pé ọkà báálì yẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń hù ni. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú pé: ‘Ìkórè wo ni Jésù ń sọ? Ọ̀pọ̀ oṣù ló ṣì máa kọjá kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀.’—Jòh. 4:35.

2 Àmọ́, kì í ṣe ìkórè àwọn ohun ọ̀gbìn ni Jésù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì nípa ìkórè tẹ̀mí, ìyẹn kíkórè àwọn èèyàn. Kí làwọn ẹ̀kọ́ náà? Ká lè mọ̀ wọ́n, ẹ jẹ́ ká gbé àkọsílẹ̀ náà yẹ̀ wò ní kíkún.

Ó Ní Kí Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́, Ó sì Ṣèlérí Pé Wọ́n Máa Láyọ̀

3. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Jésù sọ pé: “Àwọn pápá . . . ti funfun fún kíkórè”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ?

3 Ọwọ́ ìparí ọdún 30 Sànmánì Kristẹni ni Jésù sọ ọ̀rọ̀ yẹn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nítòsí ìlú Síkárì tó wà lágbègbè Samáríà. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ìlú náà, Jésù ò bá wọn lọ, ó dúró sídìí kànga kan, ibẹ̀ ló sì ti kọ́ obìnrin kan ní ẹ̀kọ́ òtítọ́. Kò ṣòro rárá fún obìnrin náà láti mọ̀ pé ẹ̀kọ́ pàtàkì ni Jésù kọ́ òun. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pa dà dé, obìnrin náà sáré lọ sí ìlú Síkárì láti sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó ti kọ́ fún àwọn aládùúgbò rẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí obìnrin náà sọ, wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i, wọ́n sì sáré wá bá Jésù nídìí kànga yẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yẹn ni Jésù wò ré kọjá pápá náà, tó rí i pé àwọn ará Samáríà tó pọ̀ ń bọ̀ lọ́dọ̀ òun, tó wá sọ pé: “Ẹ . . . wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.”a Lẹ́yìn náà, kí wọ́n lè mọ̀ pé ìkórè tẹ̀mí lòun ń sọ, pé kì í ṣe ìkórè àwọn ohun ọ̀gbìn, Jésù sọ síwájú sí i pé: “Akárúgbìn ń . . . kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 4:5-30, 36.

4. (a) Ẹ̀kọ́ méjì wo ni Jésù kọ́ni nípa iṣẹ́ ìkórè? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

4 Ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì wo ni Jésù kọ́ni nípa ìkórè tẹ̀mí? Àkọ́kọ́ ni pé, iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú. Nígbà tí Jésù sọ pé “àwọn pápá . . . ti funfun fún kíkórè” ńṣe ló ń sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lè mọ bí iṣẹ́ náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, Jésù sọ síwájú sí i pé: “Nísinsìnyí, akárúgbìn ń gba owó ọ̀yà.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, ìkórè ti bẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ náà ò sì ṣeé fi falẹ̀ rárá! Èkejì, inú àwọn òṣìṣẹ́ ń dùn. Jésù sọ pé àwọn afúnrúgbìn àtàwọn akárúgbìn máa “yọ̀ pa pọ̀.” (Jòh. 4:35b, 36) Bí inú Jésù ṣe dùn nígbà tó rí i pé “ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Samáríà . . . ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa láyọ̀ gan-an bí wọ́n ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìkórè náà. (Jòh. 4:39-42) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní yẹn ṣe pàtàkì fún wa lónìí. Ìdí sì ni pé ó ṣàpẹẹrẹ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, tó jẹ́ àkókò ìkórè ńlá tẹ̀mí tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ìgbà wo ni iṣẹ́ ìkórè tòde òní yìí bẹ̀rẹ̀? Àwọn wo ló ń kópa níbẹ̀? Kí ló sì ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?

Ọba Wa Ń Mú Ipò Iwájú Nínú Iṣẹ́ Ìkórè Ńlá Tó Ju Ti Ìgbàkígbà Rí Lọ

5. Ta ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìkórè tó kárí ayé yìí, báwo sì ni ìran tí Jòhánù rí ṣe fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú?

5 Nínú ìran kan tí Ọlọ́run fi han àpọ́sítélì Jòhánù, Jèhófà mú kó ṣe kedere pé òun ti yan Jésù láti mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ kíkórè àwọn èèyàn kárí ayé. (Ka Ìṣípayá 14:14-16.) Nínú ìran yìí, Jésù dé adé, ó sì mú dòjé lọ́wọ́. “Adé wúrà” tó wà “ní orí [Jésù]” fi hàn pé ó ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba. “Dòjé mímú [tó wà] ní ọwọ́ rẹ̀” jẹ́ ká mọ̀ pé ó jẹ́ Olùkórè. Bí Jèhófà ṣe tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan sọ pé “ìkórè ilẹ̀ ayé tí gbó kárakára,” fi hàn kedere pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú. Kò sí àní-àní pé, “wákàtí láti kárúgbìn ti tó,” iṣẹ́ náà ò gbọ́dọ̀ falẹ̀ rárá! Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ pé “ti dòjé rẹ bọ̀ ọ́,” Jésù ti dòjé rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì kórè ilẹ̀ ayé, ìyẹn ni pé ó kórè àwọn èèyàn tó wà láyé. Ìran tó dùn mọ́ni yìí tún rán wa létí pé “àwọn pápá . . . ti funfun fún kíkórè.” Ǹjẹ́ ìran yìí jẹ́ ká mọ ìgbà tí iṣẹ́ ìkórè tó kárí ayé yìí bẹ̀rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni!

6. (a) Ìgbà wo ni “àsìkò ìkórè,” bẹ̀rẹ̀? (b) Ìgbà wo gan-an ni “ìkórè ilẹ̀ ayé” bẹ̀rẹ̀? Ṣàlàyé.

6 Nínú ìran tí Jòhánù rí, tó wà nínú ìwé Ìṣípayá orí 14, Jésù tó jẹ́ Olùkórè dé adé (ẹsẹ 14), èyí fi hàn pé Jésù ti di Ọba ní ọdún 1914. (Dán. 7:13, 14) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Ọlọ́run pàṣẹ pé kí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkórè (ẹsẹ 15). Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe tẹ̀ léra kò yàtọ̀ sí ti àkàwé tí Jésù sọ nípa ìkórè àlìkámà, níbi tó ti sọ pé: “Ìkórè ni ìparí ètò àwọn nǹkan.” Torí náà, àkókò kan náà ni àsìkò ìkórè àti ìparí ètò àwọn nǹkan yìí bẹ̀rẹ̀, ìyẹn lọ́dún 1914. Nígbà tó yá, ní àárín kan “ní àsìkò ìkórè,” ni ìkórè gangan wá bẹ̀rẹ̀. (Mát. 13:30, 39) Tá a bá wo àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, a lè rí i kedere pé ìkórè náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba. Lákọ̀ọ́kọ́, láti ọdún 1914 títí di apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, Jésù ṣe iṣẹ́ ìfọ̀mọ́ láàárín àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mál. 3:1-3; 1 Pét. 4:17) Lẹ́yìn náà, lọ́dún 1919, “ìkórè ilẹ̀ ayé” bẹ̀rẹ̀. Jésù kò fi nǹkan falẹ̀ rárá, ó lo ẹrú olóòótọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀.

7. (a) Kí làwọn ará wa gbé yẹ̀ wò tó jẹ́ kí wọ́n mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ti jẹ́ kánjúkánjú tó? (b) Kí la fún àwọn ará wa níṣìírí láti ṣe?

7 Ní oṣù July ọdún 1920, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé: “Lẹ́yìn tá a yẹ Ìwé Mímọ́ wò dáadáa, ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fún ṣọ́ọ̀ṣì ní àǹfààní ńlá láti máa kéde ìhìn ìjọba rẹ̀.” Bí àpẹẹrẹ, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jẹ́ kí àwọn ará rí i pé wọ́n gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba náà kárí ayé. (Aísá. 49:6; 52:7; 61:1-3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ bí iṣẹ́ náà ṣe máa dèyí tó kárí ayé, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí. (Ka Aísáyà 59:1.) Bó ṣe wá ṣe kedere pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú, a fún àwọn ará wa níṣìírí láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ náà. Kí làwọn ará wá ṣe?

8. Lọ́dún 1921, ohun pàtàkì méjì wo ló yé àwọn ará wa nípa iṣẹ́ ìwàásù?

8 Ní oṣù December ọdún 1921, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kéde pé: “A ṣe dáadáa lọ́dún yìí ju ti ọdún èyíkéyìí mìíràn lọ; láti àwọn ọdún yìí wá, ọdún 1921 ni àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ gbọ́ ìwàásù òtítọ́ nípa Ọlọ́run.” Ìwé ìròyìn náà wá sọ pé: “Iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe o. . . . Ẹ jẹ́ ká fayọ̀ ṣe é.” Kíyè sí bí àwọn ará wa ṣe fi hàn pé àwọn lóye ohun pàtàkì méjì tí Jésù tẹ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́kàn nípa iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn ni pé: Iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú àti pé inú àwọn òṣìṣẹ́ ń dùn.

9. (a) Lọ́dún 1954, kí ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ nípa iṣẹ́ ìkórè náà, kí sì nìdí? (b) Ìbísí wo ló ti wáyé kárí ayé nínú iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run láti àádọ́ta [50] ọdún sẹ́yìn? (Wo àtẹ ìsọfúnni náà, “Ìbísí Kárí Ayé.”)

9 Lọ́dún 1930 sí ọdún 1939, lẹ́yìn tó yé àwọn ará wa pé ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àgùntàn mìíràn ló máa tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba náà, wọ́n túbọ̀ fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Aísá. 55:5; Jòh. 10:16; Ìṣí. 7:9) Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Iye àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ sókè látorí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì [41,000] lọ́dún 1934 sí ìdajì mílíọ̀nù [500,000] lọ́dún 1953! Ilé Ìṣọ́ December 1, ọdún 1954 lédè Gẹ̀ẹ́sì, wá sọ lọ́nà tó bá a mu pé: “Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà àti agbára Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló mú ká lè ṣe iṣẹ́ ìkórè ńlá tó kárí ayé yìí láṣeyọrí.”b—Sek. 4:6.

ÌBÍSÍ KÁRÍ AYÉ

Orílẹ̀-èdè

1962

1987

2013

Ọsirélíà

15,927

46,170

66,023

Brazil

26,390

216,216

756,455

Faransé

18,452

96,954

124,029

Ítálì

6,929

149,870

247,251

Japan

2,491

120,722

217,154

Mẹ́síkò

27,054

222,168

772,628

Nàìjíríà

33,956

133,899

344,342

Philippines

36,829

101,735

181,236

Amẹ́ríkà

289,135

780,676

1,203,642

Sáńbíà

30,129

67,144

162,370

ÀWỌN TÁ À Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ Ń PỌ̀ SÍ I

1950

234,952

1960

646,108

1970

1,146,378

1980

1,371,584

1990

3,624,091

2000

4,766,631

2010

8,058,359

Ó Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Àbájáde Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ́nà Tó Yéni Yékéyéké

10, 11. Àwọn apá wo nípa bí irúgbìn náà ṣe dàgbà ni àkàwé nípa hóró músítádì sọ̀rọ̀ rẹ̀?

10 Nínú àkàwé tí Jésù sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ìkórè náà lọ́nà tó yéni yékéyéké. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àkàwé nípa hóró músítádì àti àkàwé ìwúkàrà. Ohun tá a máa fún láfiyèsí jù ni bí wọ́n ṣe nímùúṣẹ ní àkókò òpin yìí.

11 Àkàwé nípa hóró músítádì. Ọkùnrin kan gbin hóró músítádì. Nígbà tó hù, ó di igi tí àwọn ẹyẹ ń gbé lórí rẹ̀. (Ka Mátíù 13:31, 32.) Àwọn apá wo nípa bí irúgbìn náà ṣe dàgbà ni àkàwé yìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (1) Irúgbìn náà gbèrú lọ́nà tó kàmàmà. Irúgbìn tó jẹ́ “tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn” wá di igi tó ní “àwọn ẹ̀ka ńlá.” (Máàkù 4:31, 32) (2) Ó dájú pé irúgbìn náà máa dàgbà. ‘Nígbà tí a gbin irúgbìn náà, ó yọ.’ Jésù kò sọ pé, “Ó ṣeé ṣe kó yọ.” Rárá o, ohun tó sọ ni pé: “Ó yọ.” Kò sẹ́ni tó lè dá a dúró pé kó má dàgbà. (3) Igi náà fani mọ́ra, ó sì di ibùwọ̀. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: “Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run . . . wá” wọ́n sì “rí ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji rẹ̀.” Báwo làwọn apá mẹ́ta yìí ṣe ní ìmúṣẹ nínú iṣẹ́ ìkórè ti òde òní?

12. Báwo ni àkàwé nípa hóró músítádì ṣe ń ní ìmúṣẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè ti òde òní? (Tún wo àtẹ ìsọfúnni náà, “Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ń Pọ̀ Sí I.”)

12 (1) Bó ṣe gbèrú tó: Àkàwé náà jẹ́ ká mọ bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti ìjọ Kristẹni ṣe máa gbèrú tó. Láti ọdún 1919, a ti kó àwọn tó ń fìtara ṣiṣẹ́ ìkórè jọ sínú ìjọ Kristẹni tá a mú bọ̀ sípò. Nígbà yẹn, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìwàásù ò tó nǹkan, àmọ́ wọ́n yára pọ̀ sí i. Kódà, bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900 títí dòní yani lẹ́nu gan-an. (Aísá. 60:22) (2) Ìdánilójú: Kò sẹ́ni tó lè dí ìjọ Kristẹni lọ́wọ́ pé kó má gbèrú. Kò sí bí àtakò táwọn ọ̀tá Ọlọ́run ń ṣe ṣe lè le tó, wọn kò lè dí irúgbìn náà lọ́wọ́ kó má dàgbà. (Aísá. 54:17) (3) Ibùwọ̀: “Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run” tí wọ́n rí ibùwọ̀ lábẹ́ igi náà dúró fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ọlọ́kàn títọ́, tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí ó tó igba ó lé ogójì [240], tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà, tí wọ́n sì di ara ìjọ Kristẹni. (Ìsík. 17:23) Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ tẹ̀mí, wọ́n sì ń rí ìtura àti ààbò.—Aísá. 32:1, 2; 54:13.

Onírúurú ẹyẹ lórí igi músítádì

Àkàwé nípa hóró músítádì fi hàn pé ìjọ Kristẹni máa jẹ́ ibùwọ̀ àti ibi ààbò fún àwọn tó wà níbẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11, 12)

13. Àwọn apá wo nípa bí ìhìn rere náà ṣe máa gbèrú ni àkàwé nípa ìwúkàrà sọ̀rọ̀ rẹ̀?

13 Àpèjúwe nípa ìwúkàrà. Lẹ́yìn tí obìnrin kan fi ìwúkàrà díẹ̀ sínú ìṣùpọ̀ ìyẹ̀fun, ìwúkàrà náà mú kí gbogbo ìṣùpọ̀ náà wú. (Ka Mátíù 13:33.) Àwọn apá wo nípa bí ìhìn rere náà ṣe máa gbèrú ni àkàwé yìí ń tọ́ka sí? Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀ wò. (1) Ìhìn rere ń mú ìyípadà wá. Ìwúkàrà náà tàn yíká “títí gbogbo ìṣùpọ̀ náà fi di wíwú.” (2) Ìhìn rere máa dé ibi gbogbo. Ìwúkàrà náà sọ gbogbo “òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́ta” di wíwú, ìyẹn gbogbo ìṣùpọ̀ náà. Báwo làwọn nǹkan méjì yìí ṣe bá iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí tá à ń ṣe lónìí mu?

14. Báwo ni àkàwé nípa ìwúkàrà ṣe kan iṣẹ́ ìkórè tá à ń ṣe lónìí?

14 (1) Ìyípadà: Ìwúkàrà náà dúró fún ìhìn Ìjọba Ọlọ́run, nígbà tí ìṣùpọ̀ ìyẹ̀fun náà dúró fún aráyé. Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá po ìwúkàrà mọ́ ìyẹ̀fun, ó máa ń mú kí ìyẹ̀fun náà yí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìhìn Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń yí ọkàn àwọn èèyàn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n bá gba òtítọ́. (Róòmù 12:2) (2) Ó dé ibi gbogbo: Bí ìwúkàrà náà ṣe tàn ká dúró fún bí ìhìn Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tàn káàkiri. Ìwúkàrà máa ń wọ ara ìyẹ̀fun títí tó fi máa tàn yíká gbogbo ìṣùpọ̀ náà. Lọ́nà kan náà, ìhìn Ìjọba Ọlọ́run ti tàn “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Apá yìí nínú àkàwé náà fi hàn pé kódà, láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, ìhìn rere Ìjọba náà á ṣì máa tàn yíká, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lè má kíyè sí iṣẹ́ ìwàásù wa níbẹ̀.

15. Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 60:5, 22 gbà ní ìmúṣẹ? (Tún wo àwọn àpótí náà “Jèhófà Ló Mú Kó Ṣeé Ṣe,” ojú ìwé 93, àti “Bí ‘Ẹni Tí Ó Kéré’ Ṣe Di ‘Alágbára Ńlá Orílẹ̀-Èdè,’” ojú ìwé 96 àti 97.)

15 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] ọdún ṣáájú kí Jésù tó sọ àwọn àkàwé yẹn, Jèhófà ti tipasẹ̀ Aísáyà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wọni lọ́kàn nípa bí iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí tá à ń ṣe lónìí ṣe máa gbòòrò tó àti ayọ̀ tí iṣẹ́ ìkórè náà máa mú wá.c Jèhófà ṣàpèjúwe pé àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an “láti ibi jíjìnnàréré” yóò máa wá sínú ètò rẹ̀. Ó darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí “obìnrin” kan tó dúró fún àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé lónìí, ó sọ pé: “Ìwọ yóò wò, ìwọ yóò sì wá tàn yinrin dájúdájú, ọkàn-àyà rẹ yóò sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní tòótọ́, yóò sì gbòòrò, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni ọlà òkun yóò darí sí; àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.” (Aísá. 60:1, 4, 5, 9) Òtítọ́ mà ni ọ̀rọ̀ yẹn o! Lónìí, inú àwọn tó ti ń sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń rí i tí iye àwọn akéde Ìjọba tó wà ní ilẹ̀ wọn ń pọ̀ sí i látorí ìwọ̀nba èèyàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún.

Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Inú Gbogbo Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Dùn

16, 17. Kí lohun tó ń mú kí ‘afúnrúgbìn àti akárúgbìn yọ̀ pa pọ̀’? (Tún wo àpótí náà “Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Méjì Yí Ẹni Méjì Lọ́kàn Pa Dà ní Àgbègbè Amazon.”)

16 Rántí pé Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Akárúgbìn ń . . . kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí afúnrúgbìn àti akárúgbìn bàa lè yọ̀ pa pọ̀.” (Jòh. 4:36) Báwo la ṣe ń “yọ̀ pa pọ̀” lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè tó kárí ayé yìí? Oríṣiríṣi ọ̀nà la gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta lára wọn yẹ̀ wò.

17 Lákọ̀ọ́kọ́, à ń yọ̀ bí a ṣe ń rí ipa tí Jèhófà ń kó nínú iṣẹ́ náà. Tá a bá ń wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run, ńṣe là ń fúnrúgbìn. (Mát. 13:18, 19) Tá a bá wá ran ẹnì kan lọ́wọ́ débi tó fi di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ìgbà yẹn là ń kórè ohun tá a gbìn. Inú gbogbo wa sì ń dùn gan-an bá a ṣe ń rí i pé Jèhófà ń mú kí irúgbìn Ìjọba náà “rú jáde, ó sì dàgbà sókè,” lọ́nà tó yani lẹ́nu. (Máàkù 4:27, 28) Àwọn irúgbìn míì tí a fọ́n ká, máa hù tó bá yá, àwọn ẹlòmíì ló sì máa kórè rẹ̀. Ìwọ náà lè ti ní irú ìrírí tí Arábìnrin Joan ní. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ń gbé, ó sì ṣèrìbọmi ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mo ti bá àwọn èèyàn kan pàdé tí wọ́n sọ fún mi pé nígbà tí mo wàásù fún àwọn lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni mo ti gbin òtítọ́ sínú ọkàn àwọn. Mi ò mọ̀ pé nígbà tó yá àwọn Ẹlẹ́rìí míì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà. Inú mi dùn pé irúgbìn tí mo gbìn dàgbà, wọ́n sì kórè rẹ̀.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.

JÈHÓFÀ LÓ MÚ KÓ ṢEÉ ṢE

JÉSÙ sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 18:27) Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè dá iṣẹ́ ìwàásù dúró, Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó.

Zacharie

Zacharie Elegbe (ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin [66], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1963) Arákùnrin yìí sọ pé bí ìjọba ṣe fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Benin ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Lọ́dún 1976, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [2,300]. Ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa, wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n kéde ìfòfindè náà lórí rédíò ní gbogbo èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè wa. Irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Benin lé ní ọgọ́ta [60], èdè márùn-ún péré ni wọ́n sábà máa ń lò lórí rédíò. Torí náà nígbà tí wọ́n kéde ìfòfindè náà ní gbogbo èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ níbí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ń gbé láwọn abúlé tó jìnnà réré ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí sì nìdí tí ìjọba fi fòfin de iṣẹ́ wọn?’ Nígbà tá a wàásù dé àwọn abúlé yẹn nígbà tó yá, kò pẹ́ rárá tí ọ̀pọ̀ nínú wọn fi tẹ́wọ́ gba òtítọ́.” Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Benin lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ààbọ̀ [11,500].

Mariya

Mariya Zinich (ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin [74], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1957) sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá 12, wọ́n kó gbogbo ìdílé wa kúrò ní orílẹ̀-èdè Ukraine lọ sí àgbègbè Siberia, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Bí ìjọba ṣe sapá tó láti rí i pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ní gbogbo orílẹ̀-èdè Soviet Union àtijọ́, ńṣe là ń pọ̀ sí i. Mo rí i pé ńṣe ni iye wá pọ̀ sí i lọ́nà tó yani lẹ́nu láìka inúnibíni rírorò sí, èyí mú kó dá mi lójú pé iṣẹ́ Jèhófà là ń ṣe. Kò sẹ́ni tó lè dá a dúró!” Arábìnrin míì tí orúkọ rẹ̀ náà ń jẹ́ Mariya (ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73], tó ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1960) kíyè sí i pé: “Bí ìjọba ṣe kó àwọn ará wa lọ sí àgbègbè Siberia, mú kí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ibi àdádó níbẹ̀ gbọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́.”

Jesús

Jesús Martín (ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [77], tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1955) rántí pé: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì kò ju ọ̀ọ́dúrún [300] lọ. Lọ́dún 1960, wọ́n túbọ̀ ń ṣe àtakò sí wa lọ́nà tó rorò. Ìjọba pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá pa gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà yẹn, ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé a máa wàásù ìhìn rere dé ibi gbogbo lórílẹ̀-èdè wa. Ó dà bí i pé kò sọ́nà tá a lè gbé e gbà. Àmọ́ lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́fà [111,000]. Bí a ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i láìka àtakò sí mú kó túbọ̀ dá mi lójú pé bí Jèhófà bá ṣáà ti wà lẹ́yìn wa, kò sóhun tá ò lè ṣe!”

18. Kí ló wà nínú 1 Kọ́ríńtì 3:8 tó fi hàn pé ó yẹ ká máa láyọ̀?

18 Ohun kejì tó máa jẹ́ ká máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni pé ká fi ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ sọ́kàn, ó sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò gba èrè tirẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òpò tirẹ̀.” (1 Kọ́r. 3:8) Òpò tí kálukú ṣe ló máa jẹ́ kó rí èrè gbà, kì í ṣe àbájáde iṣẹ́ náà. Ó dájú pé èyí á mú kí àwọn tó ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti fi bẹ́ẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ máa láyọ̀! Lójú Ọlọ́run, gbogbo Ẹlẹ́rìí tó bá ń fi tọkàntọkàn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ fífúnrúgbìn ń ‘so èso púpọ̀,’ torí náà ó yẹ kí wọ́n máa láyọ̀.—Jòh. 15:8; Mát. 13:23.

19. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 24:14 ṣe ń mú ká láyọ̀? (b) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé kò sẹ́ni tó di ọmọ ẹ̀yìn nínú àwọn tí à ń wàásù fún?

19 Ohun kẹta ni pé, inú wa ń dùn pé iṣẹ́ wa ń mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Ronú nípa bí Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè tí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bi í pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Ó sọ fún wọn pé apá kan lára àmì yẹn ni pé, iṣẹ́ ìwàásù máa kárí ayé. Ṣé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù ń sọ? Rárá o. Ó sọ pé: “A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí.” (Mát. 24:3, 14) Torí náà, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn fífúnrúgbìn, jẹ́ apá kan àmì náà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, bí a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, à ń fi sọ́kàn pé bí kò bá tiẹ̀ sẹ́ni tó di ọmọ ẹ̀yìn nínú àwọn tí à ń wàásù fún, à ń ṣe àṣeyọrí torí pé iṣẹ́ wa jẹ́ “ẹ̀rí” fún àwọn èèyàn.d Yálà àwọn èèyàn gbọ́ ìwàásù wa tàbí wọn ò gbọ́, à ń kópa nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ, a sì láǹfààní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9) Ìdí pàtàkì mà nìyẹn jẹ́ fún wa láti máa láyọ̀ o!

“Láti Yíyọ Oòrùn Àní Dé Wíwọ̀ Rẹ̀”

20, 21. (a) Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Málákì 1:11 gbà ń ní ìmúṣẹ? (b) Kí ni wàá máa ṣe báyìí nípa iṣẹ́ ìkórè náà, kí sì nìdí?

20 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Jésù ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí i pé iṣẹ́ ìkórè náà jẹ́ kánjúkánjú. Láti ọdún 1919, Jésù ti ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ òde òní lọ́wọ́ kí àwọn náà lè mọ̀ pé iṣẹ́ ìkórè náà jẹ́ kánjúkánjú. Èyí sì ti mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ fi kún ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ náà. Kódà, ó ti ṣe kedere pé kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ ìkórè náà dúró. Bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Málákì, à ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù lónìí “láti yíyọ oòrùn àní dé wíwọ̀ rẹ̀.” (Mál. 1:11) Bẹ́ẹ̀ ni, láti yíyọ oòrùn dé wíwọ̀ oòrùn, láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn, ìyẹn ni pé kárí ayé, àwọn afúnrúgbìn àtàwọn akárúgbìn ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n sì ń yọ̀ pa pọ̀. Bákan náà, láti yíyọ oòrùn dé wíwọ̀ oòrùn, ìyẹn láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, à ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́nà tó fi hàn pé iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú.

21 Tá a bá ronú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, tá a sì rí bí àwùjọ àwọn èèyàn kéréje tó ń sin Ọlọ́run ṣe tí wá di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè,” ńṣe ni ọkàn wa “gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní tòótọ́, [ó] sì gbòòrò” nítorí ayọ̀. (Aísá. 60:5, 22) Ǹjẹ́ kí ayọ̀ yẹn àti ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, “Ọ̀gá ìkórè” náà, mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe ipa tirẹ̀ ká lè parí iṣẹ́ ìkórè tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ yìí!—Lúùkù 10:2.

a Nígbà tí Jésù sọ pé ‘àwọn pápá funfun,’ ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí aṣọ funfun tí àwọn ará Samáríà tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ wọ̀.

b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún yẹn àti ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ka ìwé náà Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom ojú ìwé 425 sí 520 (lédè Gẹ̀ẹ́sì), tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí iṣẹ́ ìkórè ṣàṣeparí rẹ̀ láti ọdún 1919 sí 1992.

c Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo ìwé Asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, ojú ìwé 303 sí 320.

d Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn ti lóye òtítọ́ pàtàkì yìí. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì ti November 15, ọdún 1895, sọ pé: “Bó bá tiẹ̀ jẹ́ àlìkámà díẹ̀ lá rí kó jọ, ó kéré tán à ń jẹ́rìí ní kíkún sí òtítọ́. . . . Gbogbo èèyàn ló lè wàásù ìhìn rere.”

Ṣé O Gbà Lóòótọ́ Pé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso?

  • Àwọn àṣeyọrí wo ni Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí?

  • Ọ̀nà wo ni àkàwé nípa hóró músítádì àti àkàwé nípa ìwúkàrà gbà fún ẹ níṣìírí láti máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?

  • Kí làwọn ìdí tó fi yẹ kó o máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?

ÌWÉ ÀṢÀRÒ KÚKÚRÚ MÉJÌ YÍ ẸNI MÉJÌ LỌ́KÀN PA DÀ NÍ ÀGBÈGBÈ AMAZON

Antônio Simões

Antônio Simões

ALÀGBÀ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] kan tó jẹ́ adúróṣinṣin, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antônio Simões máa ń fi tayọ̀tayọ̀ rántí bí bàbá rẹ̀ àti ọkọ ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ ṣe rí òtítọ́ nípasẹ̀ ìwé àṣàrò kúkúrú méjì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Ó bi àwọn tó wá kí i pé: “Ṣé ẹ fẹ́ mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀?” Wọ́n fèsì pé: “A fẹ́ mọ̀ ọ́n.” Inú Antônio dùn, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì jókòó láti sọ ìtàn ara rẹ̀.

“Orúkọ bàbá mi ni Zeno, pásítọ̀ ni ní ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi. Lọ́dún 1931, ó rin ìrìn àjò lọ síbi tó jìnnà gan-an ní igbó Amazon láti kí ará ṣọ́ọ̀ṣì wọn kan. Bàbá mi rí ìwé àṣàrò kúkúrú méjì tó ṣàlàyé Bíbélì ní ilé obìnrin náà. Inú ṣọ́ọ̀ṣì ni obìnrin náà ti rí i, àmọ́ kò mọ ẹni tó fi síbẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpáàdì, èkejì sì sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde. Nígbà tí bàbá mi ka àwọn ìwé náà, ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an ni. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ronú nípa ọkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Guilherme, torí ó ti máa ń sọ fún bàbá mi pé: ‘Mi ò gbà gbọ́ pé iná ọ̀run àpáàdì wà. Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kò lè dá ibi kan táá ti máa fi iná dá àwọn èèyàn lóró.’ Bàbá mi fẹ́ tètè fi ìwé náà han Guilherme, torí náà wákàtí mẹ́jọ ló fi tukọ̀ rẹ̀ lọ sí Manaquiri, tó wà ní ìlú Manaus, níbi tí Guilherme ń gbé.

Antônio Simões fi fọ́tò ìjọ méjì àkọ́kọ́ ní Manaquiri, ìpínlẹ̀ Amazon lórílẹ̀-èdè Brazil, hàn wá

Ìjọ àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Amazon lórílẹ̀-èdè Brazil

“Lẹ́yìn tí bàbá mi àti ọkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ka àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà, àwọn méjèèjì sọ pé, ‘Òtítọ́ nìyí!’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wa ní Brazil, pé kí wọ́n fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sáwọn. Bàbá mi kọ̀wé fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, òun àti ọkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní àwọn àdádó. Àwọn èèyàn náà tẹ́wọ́ gba ìwàásù dáadáa tó fi jẹ́ pé láàárín ọdún kan wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ ní Manaquiri. Láìpẹ́, àwọn ará abúlé náà tó ń wá sí ìpàdé tó àádọ́rin [70], tó fi jẹ́ pé nígbà yẹn, ìjọ yẹn ló ní akéde tó pọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè Brazil.” Antônio dánu dúró díẹ̀. Ó wá béèrè pé, “Ṣé kò wú yín lórí bẹ́ ẹ ṣe gbọ́ nípa bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe wọ àgbègbè Amazon?” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn o. Irúgbìn kékeré méjì tá a fọ́n ká, ìyẹn àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú méjì tó ṣàlàyé Bíbélì, ló wá gbilẹ̀ nínú igbó ńlá Amazon tó sì di ìjọ tó ń tẹ̀ síwájú. Lónìí, ó ti tó ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] tí Ìjọ Manaquiri ti wà ní àgbègbè Amazon lórílẹ̀-èdè Brazil, àmọ́ ní báyìí ìjọ mẹ́tàlélógóje [143] ló wà níbẹ̀!

BÍ “ẸNI TÍ Ó KÉRÉ” ṢE DI “ALÁGBÁRA ŃLÁ ORÍLẸ̀-ÈDÈ”

“ẸNI tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísá. 60:22) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ní ìmúṣẹ? Ipa wo ni ìmúṣẹ rẹ̀ ní lórí àwọn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé?

Börje Nilsson

Börje Nilsson (ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1943): “Mo rántí arákùnrin ẹni àmì òróró kan tó ń ṣe iṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri láwọn ọdún 1920. Nígbà tí wọ́n pín ibi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì orílẹ̀-èdè Sweden fún un pé ibẹ̀ ni kó ti máa wàásù, ó ṣègbọràn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Jèhófà sì bù kún ìsapá rẹ̀ àti tàwọn olóòótọ́ míì gan-an! Lónìí, àwọn akéde wa lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti dàgbà báyìí, mo fẹ́ máa bá a nìṣó láti jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà kí n sì máa sìn ín. Ta ló mọ àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣì máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú?”

Etienne Esterhuyse

Etienne Esterhuyse (ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1942): “Lónìí, tí mo bá bojú wẹ̀yìn, ó máa ń yà mí lẹ́nu pé iye àwọn èèyàn Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè South Africa ti pọ̀ gan-an látorí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] lọ́dún 1942 sí ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94,000] báyìí. Bí ètò Ọlọ́run ṣe ti wá gbòòrò sí i yìí ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun gan-an ni!”

Keith Gaydon

Keith Gaydon (ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin [82], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1948): “Bí iye àwọn akéde tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe pọ̀ sí i látorí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá ó lé ọgọ́rùn-ún méje [13,700] lọ́dún 1948 sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógóje [137,000] lónìí mú kó ṣe kedere sí mi pé Jèhófà ló ń ṣe iṣẹ́ náà. Ó kọjá agbára ẹ̀dá èèyàn, torí pé Jèhófà ni ‘Ẹni tí ń ṣe àwọn ohun ìyanu.’”—Ẹ́kís. 15:11.

Ulrike Krolop

Ulrike Krolop (ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1952): “Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìtara tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti fara da inúnibíni ìjọba Násì fi ń sin Jèhófà ta àwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì jí gan-an. Àwọn èèyàn nílò ìtùnú, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ṣe tán láti tù wọ́n nínú torí pé a kò lọ́wọ́ sí ogun tí wọ́n ti pa àwọn èèyàn nípakúpa yẹn. Láti ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn, mo ti ń kíyè sí bí Ọlọ́run ṣe ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn èèyàn rẹ̀. Lónìí, ó wúni lórí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gọ́jọ [164,000]!”

Mariya Brinetskaya

Mariya Brinetskaya (ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1955): “Kí àwọn ọlọ́pàá má bàa mú wa, òru ni mo ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá wọ́n rán ọkọ mi lọ sí àgọ́ tí wọ́n ti ń mú àwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó torí pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ń bá a nìṣó láti máa wàásù ní abúlé wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tìṣọ́ratìṣọ́ra, àwọn aládùúgbò wa mélòó kan sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Nígbà yẹn àwọn ará ò pọ̀ rárá. Inú mi dùn pé lónìí àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́sàn-án [168,000] ló wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà!”

Kimiko Yamano

Kimiko Yamano (ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79], ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1954): “Nígbà tí mo gbọ́ lọ́dún 1970 pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] omijé ayọ̀ bọ́ lójú mi, èyí sì mú kí n ṣèlérí fún Jèhófà lákọ̀tun pé, ‘Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, mo fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí ọ.’ Ẹ wo bí ayọ̀ mi ti pọ̀ tó lónìí, tá a ti wá ní akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́rìndínlógún [216,000]!”

Daniel Odogun

Daniel Odogun (ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83]): “Ọdún 1950 ni mo ṣèrìbọmi, nígbà yẹn ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] ni iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lónìí, a ti tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [351,000]! Tá a bá wà ní àwọn àpéjọ tí mo sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá síbẹ̀, orí mi máa ń wú, ó sì máa ń mú kí n ronú nípa ohun tó wà nínú ìwé Hágáì 2:7. Jèhófà ń mi gbogbo orílẹ̀-èdè lóòótọ́, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra sì ń wọlé wá. Mo ṣì máa ń sapá láti ṣe gbogbo ohun tí agbára mi gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, torí ọ̀nà yìí ni mo gbà ń sọ pé, ‘Jèhófà, o ṣeun!’”

Carlos Silva

Carlos Silva (ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79]): “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Brazil nígbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1952 ò ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] lọ. Lọ́dún yẹn, a ṣe àpéjọ kan ní gbọ̀ngàn eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ São Paulo. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì péré ló wà níbi tá à ń gbé ọkọ̀ sí. Arákùnrin kan tọ́ka sí Pápá Ìṣeré Pacaembu tó wà nítòsí, ó sì bi mí pé ‘Ṣé o rò pé a máa kún ibí yìí lọ́jọ́ kan?’ Ó dà bíi pé kò ní ṣeé ṣe, àmọ́ lọ́dún 1973 pápá ìṣeré náà kún fọ́fọ́, iye àwọn tó wá síbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún lé mẹ́rin àti okòódínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́fà [94,586]! Lónìí àwọn ará wa ọ̀wọ́n tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil lé ní ọ̀kẹ́ méjìdínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin [767,000]. Ohun àgbàyanu ni ìbísí yìí jẹ́!”

Carlos Cázares

Carlos Cázares (ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73]): “Lọ́dún 1954 tí mo ṣèrìbọmi, àwọn akéde ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ààbọ̀ [10,500] ló wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. A nílò àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ gan-an débi pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] péré ni mí nígbà tí wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Ìbùkún ló jẹ́ fún mi láti rí bí Jèhófà ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 60:22 ṣẹ. Iye akéde tá a ní báyìí ju ogójì ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbàáta [806,000], wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Ìbùkún yìí kọjá àfẹnusọ!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́