ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/13 ojú ìwé 2
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tìrẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Wàá Fẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tìrẹ?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣó O Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tara Ẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Bí A Ṣe Lè Wàásù Ní Ìpínlẹ̀ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 1/13 ojú ìwé 2

Ṣé Wàá Fẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tìrẹ?

1. Kí ni ìpínlẹ̀ ìwàásù ara ẹni?

1 Kí ni ìpínlẹ̀ ìwàásù ara ẹni? Láwọn ìjọ tó ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀, ìpínlẹ̀ ìwàásù ara ẹni ni ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n yàn fún akéde kan pé kó ti máa wàásù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibi tó sún mọ́ ilé akéde náà. Ìwé A Ṣètò Wa, lójú ìwé 103 sọ pé: “Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n fún ọ bá sún mọ́ ibi tó ò ń gbé, ìyẹn á jẹ́ kó o lè lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára jù lọ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. O sì tún lè ké sí akéde míì kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ.”

2. Báwo lo ṣe lè fi ìpínlẹ̀ ìwàásù tìrẹ ti ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ lẹ́yìn?

2 Àfikún Ló Jẹ́ sí Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀: Tó o bá gba ìpínlẹ̀ ìwàásù tìrẹ sí tòsí ibi tó o ti ń ṣiṣẹ́, o lè máa wàásù níbẹ̀ lákòókò ìsinmi ọ̀sán pẹ̀lú akéde míì tó ṣeé ṣe kóun náà máa ṣiṣẹ́ nítòsí ibi iṣẹ́ rẹ. O sì lè wàásù níbẹ̀ kó o tó pa dà sílé lẹ́yìn iṣẹ́. Tí ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ bá wà nítòsí ilé rẹ, ìwọ àti ìdílé rẹ lè máa ṣe ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ níbẹ̀. Bí o kò bá lọ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, á dáa kó o gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. (Fílí. 4:6) Láfikún sí i, má ṣe jẹ́ kí àkókò tí ò ń lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ ṣàkóbá fún àkókò tó yẹ kó o fi ti ètò tí ìjọ ṣe fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ lẹ́yìn. Ó yẹ kó o kọ́wọ́ ti àwùjọ rẹ lẹ́yìn, pàápàá láwọn òpin ọ̀sẹ̀ tí ọ̀pọ̀ akéde máa ń wá sí òde ẹ̀rí.

3. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tirẹ̀?

3 Àwọn Àǹfààní Tó Wà Níbẹ̀: Tó o bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tìrẹ, a jẹ́ pé o ti ní ibi tó o ti lè máa wàásù nígbàkigbà tó o bá ṣètò fúnra rẹ nìyẹn. Wàá túbọ̀ ní àkókò tó pọ̀ láti wàásù torí pé ìrìn á dín kù. Èyí à jẹ́ káwọn akéde kan lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ó máa rọrùn fún ẹ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé àwọn tó o fẹ́ bẹ̀ wò máa wà ní àdúgbò kan náà. Àwọn akéde kan ti rí i pé báwọn ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tiwọn ti jẹ́ káwọn mọ àwọn onílé dáadáa. Àwọn onílé pàápàá sì ti fọkàn tán wọn. Èyí máa ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ yẹn bí ẹ̀ẹ̀melòó kan kí wọ́n tó dá a pa dà, káwọn akéde míì lè béèrè fún un. Ǹjẹ́ kò ní dáa tó bá lè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tìrẹ, kí ìwọ àti ìdílé rẹ lè túbọ̀ máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín ní kíkún?—2 Tím. 4:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́