Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
1. Kí nìdí tá a fi ń fẹ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó wà létòlétò?
1 Jésù fàpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó wà létòlétò àti lọ́nà tó gbéṣẹ́. Bó sì ṣe wu àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé lónìí láti máa ṣe iṣẹ́ náà nìyẹn. Kí èyí bàa lè ṣeé ṣe, àwọn ìjọ kárí ayé máa ń lo ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti gbà ṣètò àwùjọ àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run fún iṣẹ́ ìsìn pápá.—Mát. 24:45-47; 25:21; Lúùkù 10:1-7.
2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
2 Ètò Tó Dára: A ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá káwọn tó ti múra tán láti lọ sóde lè gba ìṣírí, ìtọ́ni tó gbéṣẹ́ àti ìtọ́sọ́nà. A lè jíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ ní ṣókí, tó bá ṣe kedere pé ó tan mọ́ ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù. Láwọn ìgbà míì, a lè rán ara wa létí àwọn kókó kan látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bíbélì Kí A Sì Máa Báa Nìṣó tàbí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ká bàa lè múra ọkàn àwọn tó fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn sílẹ̀. A lè ṣàṣefihàn ṣókí tó dá lórí ìtẹ̀jáde tá a fẹ́ lò. Gbogbo àwọn tó fẹ́ jáde ti gbọ́dọ̀ mọ ẹni tí wọ́n á jọ ṣiṣẹ́ àti ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n ń lọ, ká tó gbàdúrà ìparí tàbí lẹ́yìn àdúrà ìparí. Lẹ́yìn ìpàdé tí kò ní ju ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ yìí, kó má ṣe pẹ́ táwọn ará á fi forí lé ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a yàn fún wọn.
3. Ojúṣe àwọn wo ni láti ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
3 Bá A Ṣe Ṣètò Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Ojúṣe alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, tó ń múpò iwájú, ló jẹ́ láti ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Ojúṣe àwọn alábòójútó àwùjọ tàbí àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn ni láti bá àwọn àwùjọ wọn ṣiṣẹ́ láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Ó lè ṣeé ṣe fáwọn alábòójútó àwùjọ tàbí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti bá àwùjọ wọn ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀. Àwọn alábòójútó àwùjọ á máa ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, kí wọ́n lè ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀ táwọn àwùjọ wọn á ti máa ṣe ìwàásù ilé-dé-ilé láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Láàárín ọ̀sẹ̀, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn á ṣètò bá a ṣe máa kó àwọn àwùjọ lọ sóde ẹ̀rí.
4-6. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ nígbà tá a bá ń ṣètò ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá? (b) Kí ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò tá a bá fẹ́ mọ ibi tó dáa jù àti ìgbà tó dáa jù láti ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
4 Ibo La Ti Lè Máa Ṣàwọn Ìpàdé Yìí, Ìgbà Wo sì Ni? Dípò kí gbogbo ìjọ máa pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá níbì kan ṣoṣo, ohun tó sábà máa ń dáa ni pé ká máa ṣe é láwọn ibi tí kò jìnnà jù fáwọn ará láti dé. A lè lo àwọn ilé àdáni tó wà láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ká bàa lè jẹ́rìí kúnnákúnná láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. A tún lè lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún Ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá. Ọ̀pọ̀ ìjọ máa ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá kété lẹ́yìn àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́jọ́ Sunday. Ká sapá láti rí i pé ìrìn-àjò wa sí ìpínlẹ̀ ìwàásù ò pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Torí náà, a lè máa ṣàyẹ̀wò àwọn ètò tá a ṣe látìgbàdégbà, ká lè rí i dájú pé àwọn ibi tá a ti ń ṣàwọn ìpàdé náà ṣì ń mú kó rọrùn láti jẹ́rìí kúnnákúnná, ká sì tún kárí àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù.
5 Bí ìpínlẹ̀ ìwàásù bá ṣe rí ló máa pinnu ìgbà tó dáa jù lọ láti máa ṣe ìpàdé yìí àti iye ìgbà tó yẹ kó máa wáyé lọ́sẹ̀. Àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí lè ṣèrànwọ́ láti mọ ibi tó dáa jù lọ láti máa ṣe àwọn ìpàdé náà àti ìgbà tó dáa jù láti ṣe é.
6 Ìpínlẹ̀ ìwàásù wo ló nílò àfiyèsí púpọ̀ sí i? Ìgbà wo ló dáa jù láti ṣe ìwàásù ilé-dé-ilé? Ṣó máa dáa láti yan ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan fún ìwàásù ilé-dé-ilé tàbí ìpadàbẹ̀wò? Kí gbogbo ètò fún iṣẹ́ ìsìn pápá wà lára pátákó ìsọfúnni. Gbogbo akéde Ìjọba Ọlọ́run ló ń fẹ́ láti máa kárí àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn dáadáa, débi tí wọ́n á fi lè sọ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Èmi kò ní ìpínlẹ̀ tí a kò tíì fọwọ́ kàn mọ́.”—Róòmù 15:23.
7. Kí ni ojúṣe ẹni tá a yàn láti darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
7 Bá A Ó Ṣe Máa Darí Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Ẹni tá a bá yàn láti darí ìpàdé yìí gbọ́dọ̀ fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún ìṣètò Ọlọ́run yìí, nípa mímúra sílẹ̀ dáadáa. Kí ìpàdé náà bẹ̀rẹ̀ lákòókò tó yẹ, kó kún fún ẹ̀kọ́, kó ṣe ṣókí, kó má sì ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ. Ẹni tó máa darí ìpàdé náà ti gbọ́dọ̀ mọ ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a ti máa ṣiṣẹ́ kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀. Tí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn bá ti parí, kò pọn dandan pé ká dúró de àwọn tó bá pẹ́ lẹ́yìn. Àmọ́, ó lè ṣèrànwọ́ tá a bá ránṣẹ́ sílẹ̀ káwọn tó bá pẹ́ lè mọbi táwọn ará á ti ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn ìpàdé náà, kó má ṣe pẹ́ táwọn ará á fi forí lé ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a yàn fún wọn. Bí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bá wà létòlétò tó sì kún fún ẹ̀kọ́, ó dájú pé á pèsè ìtọ́sọ́nà yíyẹ tó máa jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá pésẹ̀ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ́nà tó dára lọ́jọ́ yẹn.—Òwe 11:14.
8. Àwọn ọ̀nà wo làwọn tó pésẹ̀ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lè gbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó bá ń darí ìpàdé náà?
8 Pípésẹ̀ sí Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe pàtàkì. (Héb. 13:17) Tó bá ṣeé ṣe, kí ẹni tó ń kó àwọn ará jáde ṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá nílò ẹni tó máa bá ṣiṣẹ́. Á dáa káwọn akéde tó nírìírí wà níbẹ̀, kí wọ́n lè ran àwọn akéde tuntun àtàwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí lọ́wọ́. Ó máa ń dáa gan-an táwọn akéde kan bá yọ̀ọ̀da láti báwọn míì ṣiṣẹ́ láwọn ìgbà míì. (Òwe 27:17; Róòmù 15:1, 2) Kí olúkúlùkù sapá gidigidi láti máa tètè dé. Tá a bá ní ọ̀wọ̀ fún ètò tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí, tá a sì ń gba tàwọn ará wa rò, èyí á mú ká ṣàwọn àtúnṣe tó bá yẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí.—2 Kọ́r. 6:3, 4; Fílí. 2:4.
9. Àwọn ọ̀nà tó ṣèrànwọ́ wo làwọn aṣáájú-ọ̀nà lè máa gbà kọ́wọ́ ti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
9 Báwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ṣe Ń Kọ́wọ́ Tì Í: A mọrírì báwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe ń kọ́wọ́ ti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ìyẹn sì ń fún gbogbo wa níṣìírí. Gbogbo wa la mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ojúṣe làwọn aṣáájú-ọ̀nà ní. Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń ṣàwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìpadàbẹ̀wò, wọ́n tún lè láwọn ojúṣe tí wọ́n ń bójú tó nínú ìdílé wọn lójoojúmọ́, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn náà ò sì gbẹ́yìn. Torí náà, kò pọn dandan pé káwọn aṣáájú-ọ̀nà máa pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí ìjọ ṣètò, àgàgà tó bá jẹ́ pé ojoojúmọ́ ní ìpàdé náà máa ń wáyé. Àmọ́ ṣá, àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣì lè máa pésẹ̀ sáwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó kéré tán, ní ìgbà mélòó kan lọ́sẹ̀. Dé ìwọ̀n àyè kan, a máa ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Bákan náà, òye kíkún nípa tẹ̀mí àti ìrírí táwọn aṣáájú-ọ̀nà ní lè ṣèrànwọ́ gan-an fáwọn míì. Torí pé wọ́n máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó ti jẹ́ kí wọ́n nírìírí púpọ̀, àwọn míì sì lè jàǹfààní látinú àwọn ìrírí wọn. Bí wọ́n ṣe máa ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ti mú kí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. A sì máa ń mọrírì bí wọ́n ṣe máa ń kópa nínú àwọn ìpàdé yìí gan-an.
10. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo akéde Ìjọba Ọlọ́run máa sapá gidigidi láti kọ́wọ́ ti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
10 Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wà láyé, à ń ṣe èyí tó pọ̀ nínú ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nípa jíjẹ́rìí láti ilé dé ilé. Ìdí tá a fi ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ni láti fún ara wa níṣìírí, ká sì lè ṣiṣẹ́ náà lọ́nà tó múná dóko. Ó yẹ kí gbogbo àwọn akéde ìhìn rere máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti máa kọ́wọ́ ti irú ìṣètò Ọlọ́run bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 5:42; 20:20) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa sapá gidigidi láti máa kọ́wọ́ ti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà á tì wá lẹ́yìn, a ó sì máa múnú Jésù Kristi Aṣáájú wa dùn, bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Mát. 25:34-40; 28:19, 20.