ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Tó Kún Rẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • A Ò Ní Máa Jíròrò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Ní Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Kí ló yẹ ká mẹ́nu kàn nígbà tí a bá ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?

Ìdí táa fi ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ni láti ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ìgbòkègbodò tí yóò tẹ̀ lé e, ìyẹn ni, iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Nítorí náà, ó yẹ kí olùdarí rẹ̀ múra sílẹ̀ dáadáa kí ó sì múra tán láti sọ ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí, tó ṣe tààràtà, tó sì wúlò. Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ nà bá ní í ṣe ní tààràtà pẹ̀lú iṣẹ́ ìwàásù, a lè kà á kí á sì ṣàlàyé rẹ̀ ní ṣókí. Ṣùgbọ́n, kí ìpàdé náà dá lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní pàtàkì, kí ó ran gbogbo àwọn tó fẹ́ lọ sí òde ẹ̀rí lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ dáadáa láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọjọ́ náà ní àṣeyanjú.—2 Tím. 4:5.

A lè ṣàlàyé àwọn kókó tó bá a mu látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa kí gbogbo àwọn tó fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí lè mọ ìwé tí a fi ń lọni ní lọ́ọ́lọ́ọ́ àti bí a ṣe lè fi í lọni. Ní Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn, a lè ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan látinú, “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn.” Bó bá jẹ́ irú iṣẹ́ ìwàásù mìíràn, a lè ṣàlàyé ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì tó bá ìpínlẹ̀ ìjọ mu látinú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. A lè ṣàlàyé ẹ̀ka kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí kí a ṣàṣefihàn rẹ̀, irú bí ọ̀nà tí a lè gbà lo Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà, bí a ṣe lè fèsì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, bí a ṣe lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni, tàbí bí a ṣe lè padà lọ sọ́dọ̀ ẹni tó bá fìfẹ́ hàn.

Kí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn má ṣe kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, pa pọ̀ pẹ̀lú ṣíṣètò àwùjọ, yíyan ìpínlẹ̀ fúnni, àti gbígba àdúrà. Nígbà tí a bá fi máa parí ìpàdé náà, kí gbogbo àwọn tó wá ti mọ ẹni tí wọ́n á bá ṣiṣẹ́ àti ibi tí wọ́n á ti ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpínlẹ̀ ọ̀hún lọ́gán. Nítorí bí ìpàdé ọ̀hún ti máa ń ṣe ṣókí, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tó fẹ́ jáde dé lákòókò. Bí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bá tẹ̀ lé ìpàdé ìjọ, irú bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, kí ó túbọ̀ ṣe ṣókí. Kò pọndandan láti jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ náà, níwọ̀n bí a ti gbádùn àlàyé tó lárinrin látinú Ìwé Mímọ́ lọ́jọ́ náà tẹ́lẹ̀.

Ṣáájú àkókò, kí á yan arákùnrin tí ó tóótun tó ti ṣèrìbọmi, láti darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí kò bá sí arákùnrin kankan láti darí ìpàdé ọ̀hún lọ́jọ́ kan, kí àwọn alàgbà yan arábìnrin tó ti ṣèrìbọmi tí ó lè darí rẹ̀ nígbà tí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kí arábìnrin náà wà lórí ìjókòó, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ náà tàbí lórí àwọn kókó mìíràn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn pápá, kí ó jẹ́ kí àlàyé rẹ̀ ṣe ṣókí. Kí ó fi nǹkan borí.

Àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ́ àǹfààní títayọ fún wa láti gba ìṣírí kí á sì gbára dì láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí olùdarí bá ṣe múra sílẹ̀ dáadáa tó, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò ṣe jàǹfààní tó.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́