A Ò Ní Máa Jíròrò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Ní Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Mọ́
Látẹ̀yìnwá, a máa ń jíròrò ẹsẹ ojoojúmọ́ ní ṣókí nígbà tá a bá ń ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, tó bá jẹ mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ní báyìí, a fẹ́ ṣe àyípadà lórí èyí. A ò ní máa lo ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ fún ìjíròrò nígbà ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá mọ́. Bá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, ẹni tó ń darí ìpàdé náà lè lo Bíbélì, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tó dá lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kí àwọn tí wọ́n yàn láti darí ìpàdé náà múra sílẹ̀ láti jíròrò àwọn ohun tó máa ṣé àwọn tó fẹ́ jáde òde ẹ̀rí làǹfààní. Bíi ti tẹ́lẹ̀, kí ìpàdé náà má ṣe kọjá ìṣẹ́jú 10 sí 15, ó sì lè má tó bẹ́ẹ̀ tá a bá fẹ́ ṣé e lẹ́yìn tá a parí ìpàdé ìjọ.